ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/8 ojú ìwé 8-9
  • Rírí Ojútùú Pípéye

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rírí Ojútùú Pípéye
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwàdéédéé Kristian
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Wíwá Ojútùú Ṣíṣètẹ́wọ́gbà
    Jí!—1996
  • Fífa Gbòǹgbò Ìsọdèérí Tu—Kuro Ninu Ọkan-aya ati Ero-inu
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ì Bá Dára Ká Ní Afẹ́fẹ́ Mímọ́ Gaara Díẹ̀!
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/8 ojú ìwé 8-9

Rírí Ojútùú Pípéye

Ọ̀RỌ̀ ỌLỌRUN, Bibeli, sọ nípa àkókò kan nígbà tí ìjọba ọ̀run ti Ọlọrun yóò ti yanjú gbogbo ìṣòro aráyé, títí kan ìṣòro ìbàjẹ́ tí ohun ìrìnnà ń ṣe. Ìjọba Messia yìí, tí a ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn láti máa gbàdúrà fún, yóò ha pèsè ojútùú pípé nípa ṣíṣe ohun ìrìnnà tí kò lè bàyíká jẹ́ jáde bí? Tàbí ọwọ́ yóò tẹ ojútùú pípé náà nípa pípalẹ̀ ohun ìrìnnà mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé? Níwọ̀n bí Bibeli kò ti fúnni ni ìdáhùn pàtó kan, kò sí ohun tí a lè ṣe ju kí a duró máa wòran lọ.—Matteu 6:9, 10.

Ṣùgbọ́n ohun tí ó lè dá wa lójú nìyí: Ìjọba Ọlọrun kì yóò fàyè gba ìbàyíkájẹ́ láti ba ẹwà ìṣẹ̀dá jẹ́ nínú Paradise tí a mú padà bọ̀ sípò, tí Ìjọba náà yóò mú wá.—Isaiah 35:1, 2, 7; 65:17-25.

Níwọ̀n bí a ti ń dá àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lẹ́kọ̀ọ́ fún ìwàláàyè nínú ayé tuntun kan tí ó bọ́ lọ́wọ́ ìbàyíkájẹ́, ìhà wo ni ó yẹ kí wọ́n kọ sí lílo ohun ìrìnnà lónìí? Jí!, December 22, 1987, jíròrò kókó náà, “Kinni Nṣẹlẹ Sí Awọn Igbó Wa?” Ó ròyìn pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kán rò pé ìsopọ̀ kán wà láàárín àwọn ohun aṣèbàjẹ́ tí ń tú jáde nínú ọkọ̀ àti igbó tí ń kú àkúrun. Èyí mú kí òǹkàwé kan tí ọ̀rọ̀ náà mú lọ́kàn kọ̀wé sí Watchtower Society ní bíbéèrè bóyá, pẹ̀lú kókó yìí, ó tọ́ fún àwọn Kristian láti máa wa ọkọ̀. Ó ń ṣe kàyéfì lórí bóyá ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò fi àìlọ́wọ̀ hàn fún ìṣẹ̀dá Jehofa.

Lápá kan, a fèsì lẹ́tà rẹ̀ báyìí: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi tòótọ́tòótọ́ ṣègbọràn sí àwọn òfin tí àwọn ìjọba ń ṣe láti dín ìbàyíkájẹ́ kù. (Romu 13:1, 7; Titu 3:1) Gbígbé ìgbésẹ̀ kọjá ohun tí ìjọba ń bèèrè fún sinmi lórí ọgbọ́n ìwòyemọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan. Bí ẹnì kán bá pinnu láti má wakọ̀ mọ́, ọ̀ràn ara rẹ̀ ni. Síbẹ̀síbẹ̀, àpilẹ̀kọ inú Jí! náà fi bí àwọn ènìyàn kan ṣe nímọ̀lára hàn, nípa sísọ ní ojú ìwé 8 pé: ‘Ọpọ ngbegbeesẹ ti o ṣeemulo lati din awọn ìsọdèérí afẹfẹ ku de iwọn ti o fi ilọgbọninu ṣeeṣe. Wọn ńwakọ̀ jẹ́jẹ́, wọn din irin-ajo wọn ku, wọn nkorajọpọ lati rinrin-ajo papọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ, wọn nlo epo gasoline ti ko ni lead, wọn si nṣegbọran si awọn ilana ti nkoju ìsọdèérí afẹfẹ ti a fi lelẹ lati ọwọ ijọba.’”

Ìwàdéédéé Kristian

Ìdáhùn yìí fi ìwàdéédéé Kristian hàn. A gbọ́dọ̀ rántí pé àwọn ohun ìrìnnà nìkan kọ́ ní ń ṣèbàjẹ́. Àwọn ọkọ̀ òfuurufú àti ọkọ̀ ojúurin—ní gidi, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀nà ìtibìkan-débìkan òde òní—ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò pilẹ̀ ṣe àwọn ọ̀nà ìtibìkan-débìkan wọ̀nyí pẹ̀lú ète ṣíṣèbàjẹ́. Ìṣèbàjẹ́ tí ń jẹ yọ láti ibẹ̀ jẹ́ àbájáde búburú kan, tí ń bani nínú jẹ́, ṣùgbọ́n tí ó wá láti inú ìmọ̀ tí ó mọ níwọ̀n àti ìṣarasíhùwà àìpé.

Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1993, ojú ìwé 31, jíròrò ọ̀ràn yìí, ní wíwí pé: “Gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí Jehofa, awa daniyan jinlẹjinlẹ nipa ọpọlọpọ awọn iṣoro nipa ibugbe awọn alaaye eyi ti o kan ile wa ori ilẹ̀-ayé nisinsinyi. Ju pupọ awọn eniyan lọ, a mọriri pe ilẹ̀-ayé ni a dá lati jẹ́ ile mimọgaara, ti o sì kun [fun] ilera fun idile ẹ̀dá eniyan pipe kan. (Genesisi 1:31; 2:15-17; Isaiah 45:18) . . . Nipa bayii o tọ́ lati ṣe isapa ti o wa deedee, ti o si lọgbọn-ninu lati yẹra fun dídákún ibajẹ obirikiti ile-aye wa ti ń baa lọ lainidii lati ọwọ́ awọn eniyan. Bi o ti wu ki o ri, ṣakiyesi ọ̀rọ̀ naa ‘lọgbọn-ninu.’ . . . Awọn eniyan Ọlọrun kò gbọdọ jẹ́ alaimọkan nipa awọn ọ̀ràn ti o niiṣe pẹlu ibugbe awọn ohun alaaye. Jehofa beere lọwọ awọn eniyan rẹ̀ igbaani lati gbé awọn igbesẹ lati da awọn pantiri wọn nù, awọn igbesẹ ti wọn ni ijẹpataki ti o niiṣe pẹlu ibugbe awọn ohun alaaye ati pẹlu imọtoto. (Deuteronomi 23:9-14) Niwọn bi a si ti mọ oju-iwoye rẹ̀ nipa awọn wọnni ti wọn ń pa ayé run, awa dajudaju kò gbọdọ ṣaika awọn nǹkan ti a lè ṣe lati mu ki ayika wà ni mimọ tonitoni sí. . . . Bi o ti wu ki o ri, awọn ààyè tí Kristian kan yoo lọ de ni ìhà yii jẹ ọ̀ràn ara-ẹni ayafi ti a bá beere fun un nipasẹ ofin. . . . Awọn eniyan alaipe ń fi irọrun ṣubu sinu pakute jíjẹ́ alaṣeregee. . . . Awọn isapa eniyan lati gba ilẹ̀-ayé kuro lọwọ awọn iṣoro ti o ṣekoko nipa ibugbe awọn ohun alaaye, eyi ti o ni ninu ibayika jẹ, ni ki yoo kẹ́sẹjárí ni kikun. Awọn itẹsiwaju bii meloo kan le wa nihin-in ati lọhun-un, ṣugbọn ojutuu wiwapẹtiti kanṣoṣo beere fun idasi Ọlọrun. Fun idi yii a dari isapa ati awọn ohun-ìní wa sori ojutuu atọrunwa, dipo gbigbiyanju lati mu ki itura deba awọn ami-arun oréfèé.”

Àwọn Kristian wà déédéé bí wọ́n ti ń fiyè sí àwọn ìlànà Bibeli, ní fífi iṣẹ́ àṣẹ àtọ̀runwá tí wọ́n ti gbà sọ́kàn láti wàásù ìhìn Ìjọba Ọlọrun jákèjádò ayé. (Matteu 24:14) Kò sí ohun tí ó ṣe pàtàkì tàbí jẹ́ kánjúkánjú jù ú lọ! Bí àwọn ọ̀nà ìtibìkan-débìkan àti ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ òde òní bá lè ran àwọn Kristian lọ́wọ́ láti kúnjú iṣẹ́ àìgbọdọ̀ má ṣe yìí, ó bọ́gbọ́n mu fún wọn láti lò wọ́n. Nígbà kan náà, wọ́n ń yẹra fún mímọ̀ọ́mọ̀ bàyíká jẹ́ láìnídìí. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀rí ọkàn rere níwájú ènìyàn àti Ọlọrun.

Nítorí náà, bí àwa lónìí kò tilẹ̀ mọ bí a óò ṣe yanjú ìṣòro ìṣèbàjẹ́ àti ohun ìrìnnà nígbẹ̀yìngbẹ́yín ní gidi, a mọ̀ pé yóò yanjú ṣáá. Ní tòótọ́, ojútùú pípé náà ti dé tán.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Gbígbógun Ti Ìṣèbàjẹ́

• Rírìn tàbí gígun kẹ̀kẹ́ nígbà tí ó bá ṣeé ṣe

• Jíjùmọ̀ wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́

• Ṣíṣàtúnṣe àwọn ohun ìrìnnà déédéé

• Jíjẹ́ kí lílo epo mímọ́ gaara jẹni lọ́kàn

• Yíyẹra fún ìrìn àjò tí kò pọn dandan

• Wíwakọ̀ ní ìwọ̀n ìsáré oníwọ̀ntunwọ̀nsì tí ó lọ geere

• Wíwọ ọkọ̀ èrò nígbà tí ó bá ṣeé ṣe, tí ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó

• Pípaná ọkọ̀ dípò jíjẹ́ kí ó máa ṣiṣẹ́ dà nù nígbà tí ọkọ̀ bá wà lórí ìdúró fún àkókò gígùn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́