ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 1/1 ojú ìwé 31
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Rírí Ojútùú Pípéye
    Jí!—1996
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ọ̀ràn Àtúnṣe Ilẹ̀ Ayé?
    Jí!—2008
  • Ṣé Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Fífa Gbòǹgbò Ìsọdèérí Tu—Kuro Ninu Ọkan-aya ati Ero-inu
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 1/1 ojú ìwé 31

Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Ẹrù-iṣẹ́ wo ni awọn Kristian ni fun mimu kí bíba ayika wa—ilẹ, okun, ati afẹfẹ jẹ́ di eyi ti ó rọlẹ̀?

Gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí Jehofa, awa daniyan jinlẹjinlẹ nipa ọpọlọpọ awọn iṣoro nipa ibugbe awọn alaaye eyi ti o kan ile wa ori ilẹ̀-ayé nisinsinyi. Ju pupọ awọn eniyan lọ, a mọriri pe ilẹ̀-ayé ni a dá lati jẹ́ ile mimọgaara, ti o sì kun run ilera fun idile ẹ̀dá eniyan pipe kan. (Genesisi 1:31; 2:15-17; Isaiah 45:18) A tun ni idaniloju ọ̀rọ̀ Ọlọrun pe oun yoo “run awọn ti ń pa ayé run.” (Ìfihàn 11:18) Nipa bayii o tọ́ lati ṣe isapa ti o wa deedee, ti o si lọgbọn-ninu lati yẹra fun dídákún ibajẹ obirikiti ile-aye wa ti ń baa lọ lainidii lati ọwọ́ awọn eniyan. Bi o ti wu ki o ri, ṣakiyesi ọ̀rọ̀ naa “lọgbọn-ninu.” O tun yẹ lọna ti o bá Iwe Mimọ mu lati ṣọra fun jijẹ ki awọn ọ̀rọ̀ ati ìṣe-àṣà ti o nii ṣe pẹlu ibugbe awọn alaaye di idaniyan ti o bò wa mọlẹ patapata.

Koda ìgbé-ayé eniyan ti o wà deede paapaa ń mú pantiri jade. Fun apẹẹrẹ, gbigbin, ṣise, ati jíjẹ awọn ounjẹ amujade maa ń figba gbogbo fa pantiri, bi o tilẹ jẹ pe pupọ ninu rẹ̀ le jẹràmọ́lẹ̀. (Orin Dafidi 1:4; Luku 3:17) Ounjẹ ẹja yíyan tí Jesu ti a ji dide ṣe fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni o ṣeeṣe ki o yọrisi eefin diẹ, eérú, ati pantiri awọn eegun ẹja. (Johannu 21:9-13) Ṣugbọn awọn eto igbekalẹ tabi iyipoyipo ilẹ̀-ayé ẹlẹmii ati alailẹmii ni a ṣeto lati gba iru awọn nǹkan bẹẹ mọra.

Awọn eniyan Ọlọrun kò gbọdọ jẹ́ alaimọkan nipa awọn ọ̀ràn ti o niise pẹlu ibugbe awọn ohun alaaye. Jehofa beere lọwọ awọn eniyan rẹ̀ igbaani lati gbé awọn igbesẹ lati da awọn pantiri wọn nù, awọn igbesẹ ti wọn ni ijẹpataki ti o niiṣe pẹlu ibugbe awọn ohun alaaye ati pẹlu imọtoto. (Deuteronomi 23:9-14) Niwọn bi a si ti mọ oju-iwoye rẹ̀ nipa awọn wọnni ti wọn ń pa ayé run, awa dajudaju kò gbọdọ ṣaika awọn nǹkan ti a lè ṣe lati mu ki ayika wà ni mimọ tonitoni sí. A le fi eyi hàn ninu kiko pantiri ati idọti danu lọna ti o yẹ, paapaa julọ awọn nǹkan olóró. A ń fi tọkantọkan fọwọsowọpọ pẹlu awọn isapa alayiipoyipo, ti a si ni afikun ìdí lati ṣe bẹẹ bi o bá jẹ pe Kesari ni o sọ wọn di ọ̀ranyàn. (Romu 13:1, 5) Awọn eniyan bii meloo kan si ń ri itẹlọrun ninu gbigbe awọn afikun igbesẹ, iru bii yíyàn lati lo awọn ohun amujade ti o lè jẹràmọ́lẹ̀ dipo iwọnyi ti o lè fikun òkìtì pantiri lori ilẹ ati labẹ awọn okun.

Bi o ti wu ki o ri, awọn ààyè tí Kristian kan yoo lọ de ni ìhà yii jẹ ọ̀ràn ara-ẹni ayafi ti a bá beere fun un nipasẹ ofin. O ṣe kedere lati ọ̀dọ̀ awọn ajọ akọrohin pe awọn eniyan alaipe ń fi irọrun ṣubu sinu pakute jíjẹ́ alaṣeregee. Imọran Jesu ni o tan mọ ọn dajudaju pe: “Ẹ maṣe dani ni ẹjọ, ki a ma baa da yin ni ẹjọ . . . Eesitiṣe ti iwọ si ń wo ẹ̀rún igi ti ń bẹ ni oju arakunrin rẹ, ṣugbọn ti iwọ kò kiyesi ìtí igi ti ń bẹ ni oju araarẹ?” (Matteu 7:1, 3) Fifi eyi sọkan lè ràn wá lọwọ lati maṣe gbojufo awọn koko ṣiṣe pataki miiran.

Wolii Jeremiah kọwe pe: “Oluwa! emi mọ pe, ọ̀nà eniyan kò si ni ipa araarẹ: kò si ni ipa eniyan ti ń rin, lati tọ iṣisẹ rẹ̀.” (Jeremiah 10:23) Ṣiṣaika ilana yii si ti mu iran eniyan wa si ojukoju pẹlu “igba ewu,” gẹgẹ bi a ṣe fihàn ni 2 Timoteu 3:1-5. Oun ti Ọlọrun si ti kọsilẹ ninu Ìfihàn 11:18 fi ẹ̀rí hàn pe awọn isapa eniyan lati gba ilẹ̀-ayé kuro lọwọ awọn iṣoro ti o ṣekoko nipa ibugbe awọn ohun alaaye, eyi ti o ni ninu ibayika jẹ, ni ki yoo kẹ́sẹjárí ni kikun. Awọn itẹsiwaju bii meloo kan le wa nihin-in ati lọhun-un, ṣugbọn ojutuu wiwapẹtiti kanṣoṣo beere fun idasi Ọlọrun.

Fun idi yii a dari isapa ati awọn ohun-ìní wa sori ojutuu atọrunwa, dipo gbigbiyanju lati mu ki itura deba awọn ami-arun oréfèé. Ninu eyi ni a tẹle apẹẹrẹ Jesu, ẹni ti o lo eyi ti o pọ julọ ninu iṣẹ-isin rẹ̀ ‘ni jijẹrii si otitọ.’ (Johannu 18:37) Dipo ṣiṣetilẹhin fun ayé tabi mimu idẹra bá awọn ipo aibarade ẹgbẹ-oun-ọgba kaakiri agbaye—titikan biba ayika jẹ́—Jesu ṣalaye ojutuu patapata si awọn iṣoro ti o gbogun ti iran eniyan.—Johannu 6:10-15; 18:36.

Nigba ti ifẹ fun awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa ń sun wa lati yẹra fun biba ilẹ, ayika, tabi ipese omi jẹ́ lainidii, a ń baa lọ lati maa jẹrii si otitọ. Eyi ni ninu kíkọ́ awọn eniyan lati fi otitọ Bibeli silo ati nipa bẹẹ ki wọn yẹra fun rírun araawọn pẹlu siga mimu, apọju ọti lile, tabi awọn oogun lile ti ń ba ara jẹ́. Bi araadọta-ọkẹ awọn ẹni titun ti ń di ọmọ-ẹhin, wọn ti kọ́ ẹkọ iwa imọtonitoni ati igbatẹniro fun awọn ẹlomiran. Nitori naa iṣẹ́ iwaasu ti fi itilẹhin gidi fun dídín iṣoro gbogbogboo ti biba ayika jẹ́ kù lonii. Ṣugbọn eyi ti o tubọ ṣe pataki sii, awọn Kristian ọmọlẹhin ń lakaka lati tun akopọ animọ ati iwa wọn ṣe nisinsinyi ki wọn baa lè mu ara wọn bá Paradise mimọ tonitoni ti ori ilẹ̀-ayé eyi ti Ọlọrun yoo pese fun awọn olujọsin rẹ̀ tootọ laipẹ mu.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́