Fífa Gbòǹgbò Ìsọdèérí Tu—Kuro Ninu Ọkan-aya ati Ero-inu
JEHOFA kò fun awọn eniyan ni ìyánhànhàn fun èérí tabi aiwaletoleto. Planẹti ile wọn ni a ṣe lati jẹ́ paradise imọtoto, eto, ati ẹwà. Ọlọrun kò pete pe ki o bajẹ dori didi àkìtàn alaibojumu kan.—Genesisi 2:8, 9.
Bi o ti wu ki o ri, lẹhin ti awọn eniyan kọ itọsọna atọrunwa silẹ, wọn bẹrẹ sii kọ́ iru eto ayé tiwọn funraawọn. Laisi anfaani ọgbọn atọrunwa ti wọn sì ti ṣaini iriri, awọn ni a fi agbara mú lati kẹkọọ nipa igbidanwo boya a-jẹ-bọsii. Ìtàn ayé jẹrii si otitọ Bibeli pe awọn eniyan kò lè ṣakoso araawọn lọna aṣeyọrisirere; fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun “ẹnikan ń ṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.” (Oniwasu 8:9; Jeremiah 10:23) Iṣoro igbalode ti ìsọdèérí, ninu gbogbo ẹ̀ka rẹ̀, jẹ́ abajade iṣakoso eniyan lọna aitọ.
Gbigba Oju-iwoye Ọlọrun Lò
Awọn eniyan ti wọn fẹ́ lati wu Ọlọrun ń gbiyanju kárakára lati maa gbé ni ibamu pẹlu awọn ọpa-idiwọn imọtoto Ẹlẹdaa. Nipa bayii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dojukọ iṣoro kan nigba ti wọn wewee lati ṣe apejọpọ agbaye ni Prague, Czechoslovakia, ni aarin ọdun 1991.a Nǹkan bi 75,000 eniyan ni yoo pesẹ sibẹ, awujọ awọn eniyan kan ti Gbọngan-iṣere Strahov lè fi tirọruntirọrun gbà. Ṣugbọn Gbọngan-iṣere naa ni a kò ti lò fun ọdun marun-un. Ó ti di júujùu, o ti di ibikan ti oju-ọjọ ti sọ di játijàti. Nǹkan bii 1,500 awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lo eyi ti o ju 65,000 wakati lati tun un ṣe ti wọn sì tun un kùn. Nigba ti ó maa fi di akoko apejọpọ igbetaasi pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ yii ti mú ki gbọngan-isere naa di ibi ti ó yẹ ninu eyi ti a ti lè jọsin Ọlọrun tootọ naa, Jehofa.
Ki ni ó sún awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati jẹ́ ẹni ti ó yatọ, nigba ti ayé ni gbogbogboo ń fi imọriri ti o kere tobẹẹ hàn fun imọtoto ati iwaletoleto? Imọriri fun imọran Bibeli pe awọn Kristian nilati fa gbòǹgbò awọn animọ alaibarade tu, awọn bii imọtara-ẹninikan, aigbatẹniro, iwọra, ati aisi ifẹ. “Bọ́ ogbologboo ọkunrin nì [“animọ-iwa,” NW] silẹ pẹlu iṣe rẹ̀,” ni Bibeli sọ. Fi “ọkunrin titun nì . . . eyi ti a sọ di titun si ìmọ̀ gẹgẹ bi aworan ẹni ti ó dá a” rọ́pò rẹ̀. Animọ-iwa kan ti a mọ̀ fun ifẹ fun imọtoto, eto, ati ẹwà kò fààyè gba awọn itẹsi sísọ nǹkan deléèérí.—Kolosse 3:9, 10; 2 Korinti 7:1; Filippi 4:8; Titu 2:14.
Animọ-iwa titun naa ń beere pe ki awọn Kristian ṣaniyan nipa ìsọdèérí, kìí ṣe pe ki wọn maa mọ̀ọ́mọ̀ sọ ayika deléèérí tabi fi aigbọran fojutín-ín-rín awọn ofin ti ó gbógun ti ìsọdèérí ti awọn ijọba gbekalẹ. Ó ràn wọ́n lọwọ lati yẹra fun níní iṣarasihuwa ifiṣofo, onimọtara-ẹni-nikan, ati ọ̀lẹ eyi ti ń ṣamọna si dídọ̀tí ayika. Nipa gbigbe ọ̀wọ̀ fun ohun-ìní awọn ẹlomiran larugẹ, eyi ń wọ́gilé lilo awọn aworan ara ogiri gẹgẹ bi ọ̀nà isọrọ jade kan, gẹgẹ bi eré alaimọwọ-mẹsẹ kan, tabi gẹgẹ bi iru oriṣi iṣẹ́ aworan yíyà kan. Ó ń beere pe ki a pa awọn ile, ọkọ̀ ayọkẹlẹ, aṣọ, ati ara wà mọ́ ni mímọ́ tonitoni.—Fiwe Jakọbu 1:21.
Niti awọn eniyan ti wọn kò muratan lati gbé animọ-iwa titun yii wọ̀, ǹjẹ́ a lè dá Ọlọrun lẹbi fun ṣiṣaijẹ ki wọn ni ìyè ninu Paradise rẹ̀ ti ń bọ̀ bi? Ki a ma ri. Ẹnikẹni ti ó bá ṣì ní itẹsi sisọ nǹkan deléèrí ninu kọ́lọ́fín ọkan-aya tabi ero-inu rẹ̀ yoo wu ẹwà paradise ti planẹti Ilẹ̀-ayé wa ti a mupadabọsipo naa léwu, ni fifa ibanujẹ fun awọn wọnni ti wọn ni ìfẹ́-ọkàn lati pa á mọ́. Ipinnu Ọlọrun “lati run awọn ti ń pa ayé run” jẹ́ olododo ati onifẹẹ pẹlu.—Ìfihàn 11:18; 21:8.
Awa Ha Gbọdọ Fi Taratara Lọwọ Ninu Rẹ̀ Bi?
Bi o ti wu ki o ri eyi ha tumọ si pe awọn Kristian ni a reti pe ki wọn gbé eto igbogun ti ìsọdèérí tabi igbesẹ pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ larugẹ bi?
Ìsọdèérí léwu fun ilera ati aabo gbogbogboo lọna ti o ṣe kedere. Jehofa ní idaniyan ti ó bojumu nipa iru awọn ọ̀ràn bẹẹ, gẹgẹ bi a ṣe lè ri i lati inu awọn ofin ti ó fifun awọn ọmọ Israeli. (Eksodu 21:28-34; Deuteronomi 22:8; 23:12-14) Ṣugbọn kò si ìgbà kan rí ti oun dari wọn lati yi awọn eniyan miiran lọkan pada lori awọn ọ̀ràn ti o jẹmọ aabo gbogbogboo; bẹẹ ni a kò si sọ fun awọn Kristian ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní ri lati ṣe bẹẹ.
Lonii, awọn ọ̀ràn ayika lè fi irọrun di ariyanjiyan ti oṣelu. Niti tootọ, awọn ẹgbẹ́ oṣelu kan ni a ti dá silẹ ni pàtó fun ète yiyanju awọn iṣoro ayika. Kristian kan ti o bá gba araarẹ láàyè lati di ẹni ti a nipa lé lori ni ọna ti oṣelu ni kìí tun ṣe alaidasi tọtun-tosi niti iṣelu mọ́. Jesu fi ilana naa lélẹ̀ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Wọn kìí ṣe ti ayé, gẹgẹ bi emi kìí tii ṣe ti ayé.” Kristian kan ti ó bá ṣaika ohun abeerefun yẹn sí ń fi araarẹ sinu ewu gbígbè lẹhin ‘awọn olori ayé yii, ti wọn yoo di asán.’—Johannu 17:16; 1 Korinti 2:6.
Jesu kò gbiyanju lati yanju gbogbo iṣoro awujọ eniyan ti ọjọ rẹ̀; bẹẹ ni kò sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati ṣe bẹẹ. Àṣẹ rẹ̀ fun wọn ni pe: “Nitori naa ẹ lọ, ẹ maa kọ́ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ sì maa baptisi wọn . . . , ki ẹ maa kọ́ wọn lati maa kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa ni àṣẹ fun yin.” Oun kò paṣẹ fun wọn nipa awọn ìlànà-ètò ayika.—Matteu 28:19, 20.
Ni ṣiṣalaye ohun ti ó nilati gba ipo kìn-ín-ní ninu igbesi-aye Kristian kan, Kristi sọ pe: “Ṣugbọn ẹ tete maa wa ijọba Ọlọrun ná, ati ododo rẹ̀.” (Matteu 6:33) Nigba ti Jehofa, nipasẹ Ijọba Messia, bá mu ki awọn ilana ododo rẹ̀ di eyi ti a muṣẹ jakejado agbaye, awọn iṣoro ayika ni a o yanju titilae ati si itẹlọrun gbogbo eniyan.
Nipa bayii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa di ipo ti o ṣe deedee kan mú. Ni oju-iwoye Romu 13:1-7, ó jẹ́ aigbọdọmaṣe pe ki wọn fi ẹ̀rí-ọkàn ṣegbọran si awọn ofin ijọba eyi ti ń ṣabojuto ayika. Ni afikun, ifẹ bii ti Ọlọrun fun aladuugbo ń sún wọn lati fi ọ̀wọ̀ hàn fun ohun-ìní awọn ẹlomiran—ti gbogbogboo tabi ti àdáni—nipa ṣiṣai bà a jẹ́ ati nipa ṣiṣai kó pantiri danu láìdábìkan sí. Ṣugbọn awọn ni a kò dari ni kedere lati ṣe òléwájú ninu awọn igbesẹ ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ ti ayé. Wọn fi ẹ̀tọ́ fi wiwaasu ihin-iṣẹ Ijọba Ọlọrun siwaju, ni mímọ̀ pe eyi ni ọ̀nà naa ti wọn lè gbà ṣeni lanfaani ti ó wà pẹtiti julọ.
Ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ Nipa Ti Ẹmi Kan
Awọn ọmọ Israeli igbaani ni a kilọ fun lemọlemọ nipa awọn abajade bi wọn bá sọ ilẹ̀-ayé deléèérí nipa tita ẹ̀jẹ̀ silẹ, nipa gbigba ọ̀nà igbesi-aye oniwapalapala mọra, tabi nipa fifi ailọwọ hàn fun awọn ohun mímọ́. (Numeri 35:33; Jeremiah 3:1, 2; Malaki 1:7, 8) Ni ọ̀nà ti ó ṣe pataki, awọn ni a dá lẹbi fun ìsọdèérí tẹmi yii, kìí ṣe fun ìsọdèérí ti ara eyikeyii nipasẹ eyi ti wọn ti lè jẹbi pẹlu.b
Nitori naa, ìsọdèérí tabi iwa-eeri tẹmi ni Kristian kan lonii ń lakaka lati yẹra fun nipo akọkọ. Eyi ni oun ń ṣe nipa gbígbé “ọkunrin titun” nì wọ̀, eyi ti ó fa gbòǹgbò itẹsi ìsọdèérí tu kuro ninu ọkan-aya ati ero-inu. Eyi ti ó ju million mẹrin awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ ń janfaani lati inu ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ nipa ti ẹmi yii, ni jijere imọtoto nipa ti isin ati ti iwarere laaarin awọn ojugba wọn, bẹẹ naa sì ni imọtoto nipa ti ara ti ó farahan gbangba.—Efesu 4:22-24.
Sanmani ti a wà yii ni akoko naa fun igbetaasi pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ nipa tẹmi kan. Igbetaasi ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ nipa ti ara kaakiri agbaye ni yoo tẹle e ni akoko rẹ̀ ti yoo sì gba ile wa là kuro lọwọ didi àkìtàn kari-aye kan nipa fifun un ni ayika ti ó bọ́ lọwọ ìsọdèérí ti ó lẹtọọsi.—Oniwasu 3:1.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun irohin lẹkun-un rẹrẹ lori ọ̀wọ́ awọn apejọpọ yii ni iha Ila-oorun Europe, wo Ji! ti May 22, 1992.
b Awọn ọmọ Israeli jẹ ojulumọ pẹlu ọ̀nà ti a gbà ń yọ́ ohun kan. Àṣẹ́kù ni a ti ri ninu diẹ lara awọn ìwakùṣà bàbà wọn, bàbà ni a sì yọ́ lati pese awọn ohun eelo fun tẹmpili. (Fiwe 1 Ọba 7:14-46.) Ó dabi ohun ti kò ṣeeṣe pe ọ̀nà ti a gbà ń yọ́ nǹkan yii ni a ti lè maa baa lọ láìdá iwọn ìsọdèérí kan silẹ bi eefin, ìdàrọ́, ati èérí ìdàrọ́, pẹlu boya awọn iyọrisi abẹ́gbẹ̀ẹ́yọ miiran. Sibẹ, Jehofa lọna ti o ṣe kedere muratan lati fààyè gba iwọn aimọtonitoni adugbo ti kò pọ̀ ni ayika gátagàta ti ó sì dádó yii.