ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 2/15 ojú ìwé 7
  • Ẹ Yọ̀ Ninu Ilẹ̀-ayé mímọ́ Tonitoni Ti Ó Wà Niwaju!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Yọ̀ Ninu Ilẹ̀-ayé mímọ́ Tonitoni Ti Ó Wà Niwaju!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Paradise Tabi Àkìtàn—Ewo Ni Iwọ Fẹ́ Jù?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Fífa Gbòǹgbò Ìsọdèérí Tu—Kuro Ninu Ọkan-aya ati Ero-inu
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Mímọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Ìmọ́tótó—Kí Ló Túmọ̀ sí Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 2/15 ojú ìwé 7

Ẹ Yọ̀ Ninu Ilẹ̀-ayé mímọ́ Tonitoni Ti Ó Wà Niwaju!

ATI kún fun ayọ tó pe Jehofa, Ọlọrun eto ati imọtoto, yoo mú ète rẹ̀ ipilẹṣẹ lati sọ ilẹ̀-ayé di paradise agbaye kan ṣẹ! (Isaiah 11:6-9) Ó ṣeleri pe: “Bẹẹ ni ọ̀rọ̀ mi ti ó ti ẹnu mi jade . . . kì yoo pada sọdọ mi lófo, ṣugbọn yoo ṣe eyi ti ó wù mí, yoo sì maa ṣe rere ninu ohun ti mo rán an.” “Kò lè ṣeeṣe fun Ọlọrun lati ṣèké,” nitori naa iwọnyi kìí ṣe òfìfo ọ̀rọ̀.—Isaiah 55:11; Heberu 6:18.

Ara lè tù wá pe Jehofa yoo fi ifẹ dá sí i ki awọn eniyan tó fa ìsọdèérí pupọ tobẹẹ gẹẹ debii pe iwolulẹ ibugbe ohun alaaye patapata ni a kì yoo lè dá duro!—Ìfihàn 11:18.

Jehofa yoo mú awọn olùsọ-nǹkàn-deléèérí alaironupiwada, alailakooso ati awọn eniyan ti wọn fi iṣọtẹ ṣaika awọn itọni eto ati imọtoto rẹ̀ sí kuro. Kò sí ẹni ti a o gbà láàyè lati fi Paradise ti a mupadabọsipo naa sinu ewu.—Owe 2:20-22.

Nigba iṣakoso Ijọba Ọlọrun, labẹ itọsọna Kristi Jesu, awọn eniyan ni a ó kọ́ ni bi a ṣe lè fa gbòǹgbò awọn okunfa ìsọdèérí nipa ti ara tí ó kù tu. Nigba naa—kìí ṣe nisinsinyi—ni yoo jẹ́ akoko ti ó bojumu pe ki gbogbo iranṣẹ Ọlọrun fi taratara lọwọ ninu iṣeto ti ara-ẹni ati ti apapọ eyi ti yoo fikun ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ kari ayé alailafiwe kan.—Fiwe Esekieli 39:8-16.

Awọn olula opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan buburu isinsinyi já yoo ṣetilẹhin fun itolẹsẹẹsẹ pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ niti ara yii pẹlu ifọkansin ati ìtara kan-naa ti wọn fi lọwọ ninu igbetaasi pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ tẹmi ti sanmani ti a wà yii.—Orin Dafidi 110:3.

Ilẹ̀-ayé kan ti o mọ́ tonitoni ni ó daju pe yoo dé, ṣaaju eyi ti igbetaasi pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ giga julọ ti a tii rí rí, ti Ijọba Ọlọrun ṣe aṣepari rẹ̀ yoo waye. Gbogbo ami ìsọdèérí ni a o mú kuro. Kò ni sí aworan ara ogiri nibikibi mọ́. Kò sí awọn àfọ́kù ìgò, agolo, àpò ọlọ́ràá, bébà ṣingọọmu ati ti ipapanu olóyinmọmọ, iwe agberohinjade ati iwe-irohin mọ́ lati sọ etikun tabi agbegbe oniparadise eyikeyii di onipantiri.

Ẹ yọ̀ ninu ilẹ̀-ayé mímọ́ tonitoni ti ó wà niwaju!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Iwọ yoo ha lọwọ ninu ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ kari-aye ti ń bọ̀ bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́