ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb19 October ojú ìwé 8
  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Mímọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Mímọ́
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ́tótó—Kí Ló Túmọ̀ sí Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìmọ́tótó Báwo Ló Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Mọ́ Tónítóní
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Kí Nìdí Tí Ìmọ́tótó Fi Ṣe Pàtàkì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
mwb19 October ojú ìwé 8
Arákùnrin kan ń fọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Mímọ́

“Lọ fọ ọwọ́ ẹ̀. Lọ fọ abọ́ tó o fi jẹun. Rí i dájú pé o gbálẹ̀. Lọ dalẹ̀ nù.” Ọ̀pọ̀ òbí máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè fọwọ́ pàtàkì mú ìmọ́tótó. Àmọ́, àtọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run mímọ́ láwọn ìlànà tó ń jẹ́ ká wà ní mímọ́ ti wá. (Ẹk 30:​18-20; Di 23:14; 2Kọ 7:⁠1) Tá a bá ń jẹ́ kí ara wa àtàwọn nǹkan ìní wa wà ní mímọ́, ṣe là ń fògo fún Jèhófà. (1Pe 1:​14-16) Ilé wa àti àyíká wa ńkọ́? Kò yẹ ká fìwà jọ àwọn èèyàn tó máa ń ju ìdọ̀tí sójú títì tàbí síbikíbi tí wọ́n bá rí. Dípò bẹ́ẹ̀, àwa Kristẹni máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí ilẹ̀ ayé tí Jèhófà fi jíǹkí wa wà ní mímọ́. (Sm 115:16; Ifi 11:18) Kódà nínú àwọn nǹkan kéékèèké míì irú bí ibi tá a ju ọ̀rá súìtì sí, agolo ohun mímu tàbí ṣingọ́ọ̀mù lè fi irú ọwọ́ tá a fi mú ìmọ́tótó hàn. Nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa ló ti yẹ ká máa “dámọ̀ràn ara wa bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.”​—2Kọ 6:3, 4.

WO FÍDÍÒ NÁÀ ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN TÓ JẸ́ MÍMỌ́, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwáwí wo làwọn kan máa ń ṣe tí wọn kì í fi í bójú tó àwọn nǹkan ìní wọn?

  • Báwo ni Òfin Mósè ṣe jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó?

  • Báwo la ṣe lè fògo fún Jèhófà láìsọ ọ̀rọ̀ kan?

Bàbá kan fẹ́ wọnú ọkọ̀ ọmọ rẹ̀ tó ti dọ̀tí; bàbá àtọmọ jọ ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìlànà Jèhófà sọ nípa ìmọ́tótó; àlùfáà méjì nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nítòsí bàsíà tí wọ́n fi ń fọ nǹkan; àwọn ará tó ń lọ sóde bọ́lẹ̀ nínú mọ́tò ọmọ náà tó ti wà ní mímọ́ tónítóní báyìí

Báwo ni mo ṣe lè fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó bíi ti Jèhófà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́