Paradise Tabi Àkìtàn—Ewo Ni Iwọ Fẹ́ Jù?
KÒ SÍ ẹni ti ìbá ti fi í pe ẹlomiran yatọ si ẹni ti ó jẹ́: oluṣebẹwo ará Europe kan ti o nilo isinmi ti ó sì ń haragaga lati gbadun ìtànṣán oòrùn ni erékùṣù kan ti o dabi paradise. Ni sísọdá ori àgbájọ iyanrìn ti ó tẹ́ rẹrẹ lẹbaa etikun naa, ó fi pẹlẹpẹlẹ wá ọ̀nà gba kọja ibi ìdọ̀tí awọn ìgò, agolo, àpò ọlọ́ràá, bébà ṣingọọmu ati ipapanu, awọn iwe-agberohinjade ati iwe-irohin. Ó hàn kedere pe oun ni a kó niriira, ó ṣe kayefi bi eyi bá jẹ paradise naa ti oun ti rinrin-ajo lati dé.
Iwọ ha ti ni iru iriri ti ó rí bakan naa bi? Eeṣe ti awọn eniyan maa ń fi lilo akoko isinmi ni awọn ibi paradise kan lálàá, ṣugbọn gbàrà ti wọn bá ti dé ibẹ̀, ti ó ń dabii pe wọn kìí ní ẹ̀rí-ọkàn ti yoo dí wọn lọwọ lati maṣe yí i pada si àkìtàn gidi kan?
Kìí Wulẹ Ṣe ni “Paradise”
Àìka ẹwà, imọfonifoni, ati imọtonitoni sí ti o ṣe kedere yii kò mọ sí “awọn paradise” tí awọn oluṣebẹwo maa ń rọ́ lọ. O fẹrẹ jẹ́ pe nibi gbogbo ni a ti ń yọ awujọ eniyan odeoni lẹnu lọna gígadabú nipa ìsọdèérí. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn iṣẹ́-ajé ń sọ ayika deléèérí gan-an nipa ṣiṣemujade ọpọ tọọnu pantiri. Awọn pantiri ti a kò bojuto lọna yiyẹ ati ìṣẹ́dànù epo lọna èèṣì ń halẹ iparun mọ́ ayika ti o tobi lori ilẹ̀-ayé wa, ni mimu ki wọn jẹ́ ibi ti kò yẹ fun iwalaaye.
Awọn ogun pẹlu ń ba ayika jẹ́. Bi ayé ṣe ń woran tẹ̀rùtẹ̀rù, ogun Persian Gulf ti 1991 fi apá ìha titun kan kun un. Awọn ọmọ-ogun Iraqi mọ̀ọ́mọ̀ fi ipá dáná sinu 600 kòtò epo, ni yiyi Kuwait pada di “iran ina àjóòkú ti inu iṣipaya,” gẹgẹ bi iwe-irohin awọn ará Europe kan ṣe ṣapejuwe rẹ̀. Iwe-irohin awọn ará Germany naa Geo pe ìjórọrọ-iná naa ni “ajalu-ibi ayika ti o galọla julọ ti a tíì fi ọwọ́ eniyan fà rí.”
Ni opin ogun naa, iṣẹ pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ ni a bẹrẹ lọ́gán. Wiwulẹ paná awọn kòtò epo ti ń jó naa gba iṣẹ aṣekara ọlọ́pọ̀ oṣù. Eto-ajọ Ilera Agbaye rohin pe ìsọdèérí ti o lọ soke ni Kuwait lè jẹ ki iye ìwọ̀n iku nibẹ fi ipin 10 ninu ọgọrun-un lọ soke.
Kò Fi Bẹẹ Léwu Ṣugbọn Ó Ń Rínilára
Fun gbogbo apẹẹrẹ ìbàyíkájẹ́ oniwọn-nla ti ó pafiyesi julọ ti kò sì bojumu, ẹgbẹẹgbẹrun awọn apẹẹrẹ oniwọn keekeeke wà. Awọn ti ń sọ ayika di onipantiri ati “awọn ayaworan” ara ogiri lè má fi bẹẹ jẹ́ abàyíkájẹ́ ti ó léwu, ṣugbọn bi o tilẹ ri bẹẹ wọn ń ṣetilẹhin fun jíja Ilẹ̀-ayé lólè agbara ti o ni lati jẹ́ paradise kan.
Ni awọn ibi kan aworan ara ogiri ti di eyi ti o wọpọ debi pe awọn ará ilu ti di “ẹni ti aworan ara ogiri kò jọ loju mọ” ti wọn fẹrẹ má lè ṣakiyesi wọn mọ́. Wọn wà lara awọn ọkọ̀ abẹ́lẹ̀, lara awọn ogiri ile, ati lara awọn àtíbàbà tẹlifoonu. Aworan ara ogiri ni a kò fi mọ sára kìkì ogiri ile-igbọnsẹ gbogbogboo nikan mọ́.
Awọn ilu kan kún fọ́fọ́ fun awọn ẹgẹrẹmìtì ile ti o sì ti dahoro. Awọn adugbo ile gbigbe ni a sọ di alabawọn nipa awọn ile ati agbala wuruwuru. Awọn ọkọ̀ ti o ti wógbá, awọn ẹ̀rọ ti a kó dànù, ati awọn àkójọ wòsìwósì sọ awọn ọgbà oko tí kì bá ti jẹ́ eyi ti o fanimọra lọna ti ń tẹnilọrun di jákujàku.
Ni awọn agbegbe kan pato awọn eniyan dabi ẹni ti kò bikita nipa ara dídọ̀tí, ti o sì ri wúruwùru. Fifi irisi wúruwùru hàn ninu aṣọ ati imura ni kò lè jẹ́ pe a tẹwọgba nikan ṣugbọn ó tun jẹ́ eyi ti o lode paapaa. Awọn wọnni ti wọn mọriri imọfonifoni ati imọtonitoni ni a ń foju wo gẹgẹ bi alaibagbamu paraku.
Iru Iṣẹ Gigadabu Wo Ni Eyi Jẹ!
Igbetaasi pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ gígadabú wo ni yoo pọndandan lati yí awọn etikun, igbó-ẹgàn, ati awọn òkè ti wọn wà lori ilẹ̀-ayé wa yii pada si awọn Paradise ti a ya ni aworan si ẹhin awọn iwe-irohin ẹlẹhin dídán bọ̀rọ́bọ̀rọ́ ti awọn oluṣebẹwo—ki a má ṣẹṣẹ mẹnukan ohun ti a o nilati ṣe si awọn ilu-nla, ilu ati oko ati si awọn eniyan funraawọn!
Oluṣebẹwo ti a mẹnukan ni iṣaaju ni inu rẹ̀ dun lati ri ìsọ̀wọ́ awọn olupàlẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ kan ti ń gba adugbo naa kọja nigba ti ó ya ni ọjọ naa ni mimu awọn ẹyọ-ẹyọ pantiri tìrìgàngàn naa kuro. Bi o ti wu ki o ri, wọn fi awọn àfọ́kù ìgò, ideri ìgò, akọ́rọ́ agolo, ati àmukù siga pupọ rẹpẹtẹ silẹ sẹhin ju eyi ti a lè kà lọ. Nitori naa lẹhin ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ kan paapaa, ẹ̀rí ti ó daju ṣì wà sibẹ pe oju ilẹ naa ni o tubọ farajọ àkìtàn ju paradise kan lọ.
Ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ kari-aye lati daabobo planẹti Ilẹ̀-ayé kuro lọwọ didi àkìtàn agbaye kan yoo beere fun ṣiṣe ìmúkúrò gbogbo iru àṣẹ́kù awọn ohun ibajẹ wọnyi. Ifojusọna kankan ha wà pe iru ìpamọ́-ìdọ̀tí-mọ́ bẹẹ yoo ṣẹlẹ bi? Bi o bá ri bẹẹ, bawo? Ta ni yoo ṣe e? Nigba wo?