ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/8 ojú ìwé 3-5
  • Ayé Kan Láìsí Ohun Ìrìnnà Kẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé Kan Láìsí Ohun Ìrìnnà Kẹ̀?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìlọ́lùpọ̀ Kárí Ayé
  • Ewu Ìbàyíkájẹ́
  • Wíwá Ojútùú Ṣíṣètẹ́wọ́gbà
    Jí!—1996
  • Ojú Ọjọ́ Júujùu
    Jí!—1998
  • Rírí Ojútùú Pípéye
    Jí!—1996
  • Wíwá Ìgbésí Ayé Ìdẹ̀ra
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/8 ojú ìwé 3-5

Ayé Kan Láìsí Ohun Ìrìnnà Kẹ̀?

ǸJẸ́ o lè fojú inú wo ayé kan láìsí ọkọ̀ ìrìnnà? Tàbí o lè dárúkọ àwárí kan tí ó ti yí ọ̀nà ìgbé ayé àti ìhùwà àwọn ènìyàn padà délẹ̀délẹ̀ láàárín ọ̀rúndún tí ó kọjá tó bi ohun ìrìnnà ti ṣe? Láìsí ohun ìrìnnà, kì bá tí sí àwọn ilé àyàsùn, ilé àrójẹ, àti gbọ̀ngàn àyàwòran. Lékè gbogbo rẹ̀, bí kò bá sí bọ́ọ̀sì, takisí, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, tàbí ọkọ̀ akẹ́rù, báwo ni ò bá ṣe máa dé ibi iṣẹ́? dé ilé ẹ̀kọ́? Báwo ni àwọn àgbẹ̀ àti àwọn aṣọjàjáde ì bá ṣe máa kó ẹrù wọn dé ọjà?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ìdá mẹ́fà gbogbo iṣẹ́ okòwò ní United States gbára lé ìṣejáde, ìpínkiri, ìṣàtúnṣe, tàbí ìlò ọkọ̀ ìrìnnà,” ní fífi kún un pé: “Ọjà tí àwọn ilé iṣẹ́ ohun ìrìnnà ń tà àti èyí tí wọ́n ń gbà ju ìdá márùn-ún gbogbo òwò àtàpọ̀ ọjà tí orílẹ̀-èdè náà ń ṣe àti ìdá mẹ́rin ọjà àràtúntà rẹ̀ lọ. Ìpín yìí kéré bákan ṣáá ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, ṣùgbọ́n Japan àti àwọn orílẹ̀-èdè ìwọ̀ oòrùn Europe ti ń yára sún mọ́ ìpele ti United States.”

Láìka ìyẹn sí, àwọn ènìyàn kán sọ pé ayé kan láìsí ọkọ̀ ìrìnnà ì bá sàn jù. Wọ́n sọ èyí nítorí ìdí méjì.

Ìlọ́lùpọ̀ Kárí Ayé

Bí o bá ti wakọ̀ káàkiri òpópó láìrí àyè gbọ́kọ̀ sí rí, kò dìgbà tí ẹnì kán bá sọ fún ọ kí o tó mọ̀ pé, bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tilẹ̀ ṣàǹfààní, níní in lọ́pọ̀ ládùúgbò tí ó há gágá kò ṣàǹfààní. Tàbí bí o bá ti kó sínú ìlọ́lùpọ̀ ọkọ̀ kíkàmàmà rí, o mọ bí ó ti ń gọ́ni tó láti wà nínú ohun ìrìnnà kan tí a ṣe láti máa rìn lọ, ṣùgbọ́n tí ó di dandan fún láti dúró pa sójú kan.

Ní 1950, United States nìkan ni ó ní ìpíndọ́gba ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ 1 fún ènìyàn 4. Nígbà tí ó fi di 1974, Belgium, Faransé, Germany, Great Britain, Itali, Netherlands, àti Sweden ti dà bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà yẹn, iye ti United States ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọkọ̀ 1 fún ẹni 2. Ní báyìí, Germany àti Luxembourg ní nǹkan bí ọkọ̀ 1 fún ará ìlú 2. Belgium, Faransé, Great Britain, Itali, àti Netherlands kò gbẹ́yìn.

Ọ̀pọ̀ jù lọ ìlú ńlá—níbi yòówù kí wọ́n wà lágbàáyé—kún fọ́fọ́ bí ibi ìgbọ́kọ̀sí ńlá kan. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí India ń gbòmìnira ní 1947, New Delhi, olú ìlú rẹ̀, ní àròpọ̀ 11,000 ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ọkọ̀ akẹ́rù. Ní 1993, iye náà ti lé ní 2,200,000! Ìgasókè gígadabú—ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Time ti wí, ó jẹ́ “iye kan tí a retí kí ó di ìlọ́po méjì nígbà tí yóò bá fi di òpin ọ̀rúndún yìí.”

Ní báyìí ná, ní Ìlà Oòrùn Europe, tí ó ní kìkì ìdá mẹ́rin iye ọkọ̀ tí ó wà fún ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Europe, ó ṣeé ṣe kí nǹkan bí 400 mílíọ̀nù ènìyàn tún ra ọkọ̀ tiwọn. Láàárín ọdún mélòó sí i, ipò náà yóò ti yí padà ní China, tí ó gbajúmọ̀ pẹ̀lú 400 mílíọ̀nù kẹ̀kẹ́ rẹ̀ títí di báyìí. Gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn rẹ̀ ní 1994, “ìjọba ń wéwèé fún ìlọsókè yíyára kánkán nínú ìṣèmújáde ọkọ̀,” láti orí 1.3 mílíọ̀nù ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ́dọọdún sí mílíọ̀nù 3, nígbà tí ó bá fi di òpin ọ̀rúndún yìí.

Ewu Ìbàyíkájẹ́

Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Telegraph ti October 28, 1994, sọ pé: “Britain kò ní afẹ́fẹ́ mímọ́ gaara mọ́.” Èyí lè jẹ́ àsọdùn, ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, ó tó láti múni ṣàníyàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Stuart Penkett, ti Yunifásítì East Anglia, kìlọ̀ pé: “Àwọn ohun ìrìnnà ń yí àwọn ohun tí ó para pọ̀ di afẹ́fẹ́ àyíká àdánidá wa padà pátápátá.”

Ìwé 5000 Days to Save the Planet sọ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ afẹ́fẹ́ carbon monoxide tí ń bàyíká jẹ́ “ń fi afẹ́fẹ́ rere oxygen du ara, ó ń ṣàkóbá fún ìmọ̀lára àti ìrònú, ó ń mú ìhùwàpadà àdánidá ti ìmọ̀lára falẹ̀, ó sì ń fa ìtòògbé.” Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé sì sọ pé: “Nǹkan bí ìdajì gbogbo àwọn olùgbé ìlú ńlá ní Europe àti Àríwá America ṣíra payá sí ìwọ̀n ìpele afẹ́fẹ́ carbon monoxide tí ó pọ̀ ju ohun tí ó bára dé lọ.”

A díwọ̀n rẹ̀ pé ní àwọn ibì kan, afẹ́fẹ́ burúkú tí àwọn ọkọ̀ ń tú jáde ń pa ọ̀pọ̀ ènìyàn—ní àfikún sí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là tí ń náni lórí ìbàjẹ́ àyíká. Ní July 1995, ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n kan sọ pé nǹkan bí 11,000 ọmọ ilẹ̀ Britain ni ìbafẹ́fẹ́jẹ́ tí ọkọ̀ ń fà ń pa.

Ní 1995, Àpérò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ojú Ọjọ́ wáyé ní Berlin. Àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè 116 fohùn ṣọ̀kan pé ó yẹ láti wá nǹkan ṣe. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìjákulẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn pé, a sún gbígbé góńgó ìlépa gúnmọ́ kalẹ̀ àti lílapa ìlànà gúnmọ́ tàbí ṣíṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìgbésẹ̀ pàtó síwájú.

Ó ṣeé ṣe kí a ti máa retí ìfàsẹ́yìn yìí lójú ohun tí ìwé 5000 Days to Save the Planet sọ nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1990. Ó ṣàlàyé pé: “Ìrísí agbára ìṣèlú àti ti ètò ọrọ̀ ajé nínú àwùjọ oníṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní sọ ọ́ di dandan pé àwọn ìgbésẹ̀ láti gbógun ti ìbàyíkájẹ́ ṣeé tẹ́wọ́ gbà, kìkì bí wọn kò bá ṣèdíwọ́ fún ètò ìṣiṣẹ́ ọrọ̀ ajé.”

Nípa báyìí, ìwé ìròyìn Time kìlọ̀ láìpẹ́ yìí nípa “bí ó ṣe ṣeé ṣe kí ìkórajọpọ̀ afẹ́fẹ́ carbon dioxide àti àwọn gáàsì amúǹkangbóná mìíràn nínú afẹ́fẹ́ àyíká mú àgbáyé móoru ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti wí, àbájáde rẹ̀ lè jẹ́ ọ̀dá, ìyòrò ìkórajọ yìnyín, ìgasókè ìpele ìrugùdù omi òkun, àkúnya etídò, àwọn ìjì tí ń kó wàhálà báni àti àwọn ìjábá ojú ọjọ́ mìíràn.”

Bí ìṣòro ìbàyíkájẹ́ ti wúwo tó sọ ọ́ di dandan láti wá nǹkan ṣe. Ṣùgbọ́n kí ni ṣíṣe?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́