Bí O Ṣe Lè Ra Àlòkù Ọkọ̀
TA NI inú rẹ̀ kò ní dùn láti ra ọkọ̀ kan ní ìdajì iye owó ọkọ̀ tuntun tàbí kí ó tilẹ̀ dín sí i? O lè béèrè pé, ‘Ìyẹn ha ṣeé ṣe ní tòótọ́ bí?’ Bẹ́ẹ̀ ni—bí ó bá jẹ́ ọkọ̀ ìrìnnà tí ó ti jẹ́ ti ẹnì kan tẹ́lẹ̀, tí a mọ̀ sí àlòkù ọkọ̀. Ìṣòro ibẹ̀ ni pé, àwọn ẹni púpọ̀ bẹ̀rù pé àlòkù ọkọ̀ kì í ṣe ọjà tí ó dára. Bíi ti àwọn ohun mìíràn tí ń lo ẹ́ńjìnì, ọkọ̀ máa ń bà jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ìdíyelé ọkọ̀ kan máa ń dín kù bí ó bá ti ń pẹ́ sí i, bí ìrìn tí ó ti rìn bá ti ń pọ̀ sí i, àti bí a ṣe ń lò ó.
Ṣé kí n sọ ẹni tí mo jẹ́ ? Mo ti jẹ́ atọ́kọ̀ṣe fún ohun tí ó ti lé ní ọdún 15. Nítorí náà, jẹ́ kí n sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tí mo ti kọ́ fún ọ. Àwọn ìbéèrè tí ó yẹ kí o bi ara rẹ kí ó tó ra àlòkù ọkọ̀ ni ó tẹ̀ lé e yìí.
Èló Ni Mo Lè Ná?
Lákọ̀ọ́kọ́, ṣírò iye tí owó tí ń wọlé fún ọ yóò jẹ́ kí o ná lórí ọkọ̀ kan. Nígbà náà, ìpolówó ọjà nínú àwọn ìwé agbéròyìnjáde lè jẹ́ kí o mọ̀ nípa ọdún tí wọ́n ṣe àwọn ọkọ̀ náà àti irú èyí tí owó rẹ lè ká. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ilé ìfowópamọ́, àwọn ẹ̀ka ìyánilówó, àti àwọn ilé ìkówèésíkà máa ń ní àwọn ìwé amọ̀nà olóṣooṣù tí ń ṣàkọsílẹ̀ iye owó àwọn àlòkù ọkọ̀. Rí i dájú pé kì í ṣe iye owó ọkọ̀ náà nìkan ni ó ṣírò, ṣùgbọ́n iye tí àwọn owó àbùfúnni, owó ìforúkọ̀sílẹ̀, àti owó ìbánigbófò yóò ná ọ. Tún wéwèé láti ní owó díẹ̀ lọ́wọ́ fún àwọn àtúnṣe àìròtẹ́lẹ̀ tí ọkọ̀ náà lè nílò lẹ́yìn tí o bá rà á tán.
Irú Ọkọ̀ Wo Ni Mo Fẹ́?
Nígbà tí o bá ń pinnu ohun tí o fẹ́, pinnu ohun tí ó ṣe pàtàkì sí ọ. Ronú nípa bí ìdílé rẹ ṣe tóbi tó àti àwọn ìgbòkègbodò tí ẹ óò máa lo ọkọ̀ náà fún, irú bíi wíwà á lọ síbi iṣẹ́, fífi gbé àwọn ọmọ rẹ lọ sí ilé ẹ̀kọ́, àti gbígbé e lọ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian. Ṣé ẹ óò máa lo ọkọ̀ náà ládùúgbò ni tàbí lọ sí ọ̀nà jíjìn? Má ṣe ronú lórí irú oríṣi ọkọ̀ kan tàbí irú ẹ̀yà pàtó kan; kàkà bẹ́ẹ̀, wá ọkọ̀ kan tí wọ́n lò dáradára, tí ó sì wà ní ipò tí ó dára. Ra ọkọ̀ tí ó rọrùn láti tún ṣe. Gbogbo ọkọ̀ ni yóò nílò ẹ̀ya ara ọkọ̀, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Olùtajà kan ha wà ní àdúgbò rẹ tí ń ta ẹ̀yà ara tí ọkọ̀ náà ń lò bí? Ẹ̀yà ara àwọn ọkọ̀ tí ó ti lé ní ọdún mẹ́wàá lè ṣòro láti rí. Bí owó tí ń wọlé fún ọ kò bá tó nǹkan, yẹra fún ríra àwọn ọkọ̀ aláfẹ́ tàbí àwọn àkànṣe tí a kó wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè, níwọ̀n bí ẹ̀yà ara wọn àti títún wọn ṣe yóò ti gbówó lórí jù láìsí àní-àní. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ọkọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣeé fọkàn tẹ̀ dáadáa, níní wọn tún máa ń náni lówó gan-an.
Ṣe Ọkọ̀ Náà Dára?
Ọkọ̀ tí a tún ṣe dáradára ni ọkọ̀ tí ó dára. Láìfa ọ̀rọ̀ gùn, ó dára láti yẹra fún àwọn ọkọ̀ tí iye kìlómítà tí wọ́n ti lò ti pọ̀ jù—ní pàtàkì bí ó bá jẹ́ pé láàárín ìlú ni wọ́n ti rìnrìn àjò yìí dípò ní òpópónà márosẹ̀. Ohun tí a lè pè ní iye kìlómítà tí ó pọ̀ jù lè yàtọ̀ láti ibì kan sí òmíràn. Kò sí àlòkù ọkọ̀ tí ó lè wà ní pípé pátápátá. Bí ó ti wù kí ó rí, agbára rẹ yóò ha ká àtúnṣe tí ọkọ̀ náà ń fẹ́ bí? Bí ó ti máa ń rí, àtúnṣe náà kò ní mú kí ìdíyelé ọkọ̀ náà sunwọ̀n sí i. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá ra ọkọ̀ kan ní 3,000 dọ́là, tí o sì ná 1,000 dọ́là sórí àwọn àtúnṣe tí ó ń fẹ́, ọkọ̀ náà lè ṣàìtó 4,000 dọ́là. Bí ó ti máa ń rí, ríra ọkọ̀ tí ó wà ní ipò dáradára kì í fi bẹ́ẹ̀ gbówó lórí tó bí ó ti rí láti ra ọkọ̀ tí kò sí ní ipò dáradára, kí a sì ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ tún un ṣe.
Àwọn ìsọfúnni díẹ̀ nìwọ̀nyí nípa yíyan ọkọ̀ tí ó dára:
• Yẹ ọkọ̀ náà wò dáradára kí o tó rà á. Láti lè mọ bí ó ṣe rí dáradára, yẹra fún yíyẹ ọkọ̀ kan wò ní alẹ́ tàbí nínú òjò. Yára rìn yíká ọkọ̀ náà. Kí ni èrò rẹ nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ inú àti òde rẹ̀ fi hàn pé ẹni tí ń lò ó tẹ́lẹ̀ tọ́jú rẹ̀ dáradára, tí ó sì lè fi yangàn bí? Ṣé ó lò wọ́n dáradára? Ṣé ẹni tí ó fẹ́ tà á lè pèsè àkọsílẹ̀ abójútó tí ó ti ṣe lórí ọkọ̀ náà? Bí kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé kò tọ́jú ọkọ̀ náà. O lè má dààmú ara rẹ lórí ọkọ̀ náà mọ́.
• Wa ọkọ̀ náà wò. Nígbà tí o bá ń wa ọkọ̀ náà wò, tẹ iná rẹ̀ gan-an bí ìgbà tí o wà ní òpópónà márosẹ̀. Bákan náà, wà á lọ díẹ̀, dúró díẹ̀ ní àwọn ọ̀nà olókè àti ní òpópónà títẹ́jú.
Ẹ́ńjìnì:
Ǹjẹ́ ẹ́ńjìnì rẹ̀ ń múná wá dáradára?
Ǹjẹ́ èéfín tí ń jáde lára rẹ̀ mọ níwọ̀n bí?
Ǹjẹ́ ẹ́ńjìnì rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ dáradára?
Ǹjẹ́ ó máa ń ṣiṣẹ́ geerege tí kò bá sí lórí ìrìn?
Ǹjẹ́ ẹ́ńjìnì rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ ariwo?
Ǹjẹ́ ẹ́ńjìnì rẹ̀ ní agbára tí ó tó fún títẹná gidi gan-an?
Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ rárá sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè òkè yìí, nígbà náà, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ẹ́ńjìnì náà ń fẹ́ iṣẹ́ àtúnṣe fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tàbí àtúnṣe tí ó pọ̀ gan-an. Àwọn ipò wọ̀nyí tún lè jẹ́ àmì pé ẹ́ńjìnì náà ti gbó. Ṣọ́ra gidigidi bí ẹni tí ó fẹ́ tà á bá sọ pé ó wulẹ̀ ń fẹ́ iṣẹ́ àtúnṣe fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ kan ni. Ó yẹ kí iṣẹ́ àtúnṣe fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ti jẹ́ apá kan àbójútó déédéé tí ó ń ṣe lórí ọkọ̀ náà.
Ìṣètò ìṣiṣẹ́ gíà:
Ǹjẹ́ ìṣètò ìṣiṣẹ́ gíà adáṣiṣẹ́ rẹ̀ máà ń yẹ̀ tàbí kí ó má wọlé tí a bá fi sí gíà bí?
Gíà rẹ̀ kì í ha rọra wọlé bí?
Ǹjẹ́ èyíkéyìí lára àwọn gíà náà máa ń pariwo bí?
Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìṣètò ìṣiṣẹ́ gíà rẹ̀ ń fẹ́ àtúnṣe.
Bíréèkì àti ìgbékalẹ̀ ẹ̀yà ìgbọ́kọ̀ró:
Ǹjẹ́ ọkọ̀ náà máa ń fawọ́ sí apá kan nígbà tí o bá ń wà á lọ tàbí tí o bá tẹ bíréèkì?
Ǹjẹ́ ọkọ̀ náà máa ń gbọ̀n tí ó bá sáré dé àyè kan tàbí nígbà tí o bá tẹ bíréèkì rẹ̀?
Ǹjẹ́ ó máa ń pariwo nígbà tí o bá tẹ bíréèkì rẹ̀ tàbí tí o bá yíwọ́ tàbí tí o bá kọjá lórí gegele kan bí?
Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ó ṣeé ṣe kí bíréèkì tàbí ìgbékalẹ̀ ẹ̀yà ìgbọ́kọ̀ró ọkọ̀ náà nílò àtúnṣe.
• Wá àwọn apá ibòmíràn tí ń fẹ́ àtúnṣe. Wọ aṣọ tí ó lè jẹ́ kí o wo tinú-tìta àti abẹ́ ọkọ̀ náà.
• Yẹ ara rẹ̀ wò bóyá ó ti ń dógùn-ún. Yẹra fún àwọn ọkọ̀ tí ó ti dógùn-ún. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọkọ̀ tuntun-tuntun ni a kò ṣe ara wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn apá ara ọkọ̀ náà ni a ń lò láti ṣàgbéró àwọn ìhà mélòó kan lára rẹ̀. Bí àwọn apá wọ̀nyí bá ti dógùn-ún, ó sábà máa ń wọ́nwó láti ṣàtúnṣe wọn látòkèdélẹ̀. Tí ìbòrí táyà bá dógùn-ún, ó lè máà dógùn-ún wọnú, ṣùgbọ́n ó sábà máa ń jẹ́ àmì pé àwọn apá ìgbékalẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ti dógùn-ún. Wo abẹ́ ọkọ̀ náà wò bí ó bá dógùn-ún. Ṣọ́ra gidigidi bí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kun ọkọ̀ náà; ó ṣeé ṣe kí ọkọ̀ náà jẹ́ sàréè tí a kùn lẹ́fun.
• Wá ibi tí ó bà jẹ́ nítorí ìjàm̀bá ọkọ̀. Yẹ̀ abẹ́ ìdérí ẹ́ńjìnì ọkọ̀ náà àti inú ibi ìkẹ́rùsí rẹ̀ wò láti rí àwọn ibi tí ìjàm̀bá ọkọ̀ bà jẹ́ tí kò hàn síta. Ǹjẹ́ àwọn ilẹ̀kùn, ìdérí ẹ́ńjìnì, àti ibi ìkẹ́rùsí rẹ̀ tì dáadáa? O ha rí àpá ọ̀dà tí a fín níbi tí kò yẹ kí ó wà lára rẹ̀, irú bíi pàlàpálá ibi tí ilẹ̀kùn ń tì sí bí? Ǹjẹ́ àwọn ibì kan ń jò níbi ìkẹ́rùsí tàbí ní àwọn ibi tí wọ́n tẹ́ bí? Àwọn ibi tí ń jò yìí lè jẹ́ kí ó dógùn-ún.
• Yẹ ọ́ìlì ẹ́ńjìnì rẹ̀ wò. Wo ọ̀pá tí a fi ń wọn ọ́ìlì náà. Ọ́ìlì náà ha lọ sílẹ̀ bí? Èyí lè jẹ́ nítorí pé ó ń jẹ ọ́ìlì jù tàbí pé ó ń jò dànù. Ǹjẹ́ ọ́ìlì náà dọ̀tí jù tàbí pé ó dúdú? Ǹjẹ́ ó dà bíi pé ó ní òkúta nínú tí o bá fọwọ́ kàn án? Wò ó bí ọ́ìlì bá wà lára ìdérí àwọn ọ̀pá rẹ̀. Wọ inú ọkọ̀ náà, kí o sì ṣíná rẹ̀, ṣùgbọ́n máà kíìkì ọkọ̀ náà. Ǹjẹ́ iná adíwọ̀n ọ́ìlì ẹ́ńjìnì rẹ̀ tàn bí? Bí ọkọ̀ náà bá ní adíwọ̀n ọ́ìlì ẹ́ńjìnì, ó yẹ kí ó wà lórí òdo. Wá kíìkì rẹ̀, jẹ́ kí ẹ́ńjìnì rẹ̀ máa dá ṣiṣẹ́ díẹ̀díẹ̀, kí o sì ṣàkíyèsí bí yóò ṣe pẹ́ tó kí iná adíwọ̀n ọ́ìlì ẹ́ńjìnì náà tó kú tàbí kí adíwọ̀n ọ́ìlì ẹ́ńjìnì náà tó dé orí ìwọ̀n ọ́ìlì wíwà déédéé. Bí ó bá pẹ́ ju ìṣẹ́jú àáyá bíi mélòó kan lọ kí iná náà tó kú tàbí kí adíwọ̀n ọ́ìlì ẹ́ńjìnì náà tó dé orí ìwọ̀n wíwà déédéé, ó lè jẹ́ pé ẹ́ńjìnì ti gbó. Lórí àwọn ọkọ̀ tuntun kan ní United States, ó yẹ kí iná “Yẹ Ẹ́ńjìnì Wò” tàbí “Ṣàtúnṣe Ẹ́ńjìnì Láìpẹ́” kan tàn nígbà tí o bá ṣíná ọkọ̀ náà ṣùgbọ́n tí o kò kíìkì ẹ́ńjìnì rẹ̀. Ó yẹ kí iná náà kú nígbà tí ẹ́ńjìnì bá ń ṣiṣẹ́. Bí iná náà bá wà ní títàn nígbà tí ẹ́ńjìnì náà ń ṣiṣẹ́ lọ, èyí sábà máa ń jẹ́ àmi pé ẹ́ńjìnì náà ní ìṣòro, bóyá nínú ìṣètò tí ń darí ìtújáde afẹ́fẹ́ burúkú tàbí ìṣètò tí ń gbé epo kiri.
• Yẹ epo ìṣètò ìṣiṣẹ́ gíà adáṣiṣẹ́ wò. Ṣé ó ti lọ sílẹ̀ tàbí ó ti dúdú? Wò ó bóyá àwọn ibì kan dá lu lábẹ́ ìṣètò ìṣiṣẹ́ gíà náà. Àwọn ipò yìí lè jẹ́ àmì pé ìṣètò ìṣiṣẹ́ gíà náà ń fẹ́ àtúnṣe gidi. Bí ó bá jẹ́ pé àwọn táyà iwájú ọkọ̀ náà ló ń darí rẹ̀, wo abẹ́ rẹ̀ láti rí i bóyá àwọn ìdérí onírọ́bà tí a fi dé ibi tí agbára ìwọ̀n ìyára déédéé rẹ̀ ti forí kò ti fà ya. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè máa tú gíríìsì dànù, èyí sì lè tètè ba àwọn ibi ìforíkò yìí jẹ́, èyí tí ń náni lówó láti pààrọ̀.
• Yẹ gbogbo táyà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wò. Bí wọ́n bá ti bà jẹ́ gan-an, mọ̀ pé o ní láti pààrọ̀ wọn. Bí táyà náà kò bá bà jẹ́ bára mu, ó lè jẹ́ pé ó ń fẹ́ kí a mú àwọn ẹ̀yà ara ọ̀pá ìtọ́kọ̀ tọ́ ni tàbí kí a pààrọ̀ rẹ̀.
• Yẹ ìṣètò ọ̀pá ìtọ́kọ̀ náà wò. Ǹjẹ́ epo rẹ̀ jọ èyí tí ó ti jó tàbí tí ó ti lọ sílẹ̀ bí? Kíìkì ọkọ̀ náà, kí o sì yí ọwọ́ rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì fún ìgbà bíi mélòó kan. Agbára kan náà ló yẹ kí ó gbà láti yí i sọ́tùn ún tàbí sósì. Ó ha dà bí ẹni pé ó ń fawọ́ bí o ṣe ń yí i bí? Kò yẹ kí ọ̀pá ìtọ́kọ̀ náà pariwo púpọ̀ bí o bá ń yí i. Bí ìṣiṣẹ́ rẹ̀ bá ní ìṣòro èyíkéyìí, ó lè túmọ̀ sí àtúnṣe gbígbówó lórí.
• Àyẹ̀wò àwọn nǹkan mìíràn.
Yẹ ipò tí àwọn bẹ́líìtì àti àwọn ọ̀pá epo rẹ̀ wà wò.
Yẹ bí ìjánu àfọwọ́fà rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ wò lórí òkè.
Yẹ bí awakọ̀ ṣe ní láti tẹ ìjánu ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀ tó kí ó tó ṣíṣẹ́ wò.
Yẹ ipò tí ọ̀pá agbéèéfín jáde rẹ̀ wà wò. Ǹjẹ́ ó ń pariwo bí? Ǹjẹ́ ó dẹ̀ bí?
Yẹ àwọn ọ̀pá àti irin atapọ́n-ún ara ìgbékalẹ̀ ẹ̀yà ìgbọ́kọ̀ró wò. Ǹjẹ́ ọkọ̀ náà lọ sílẹ̀ gan-an, tàbí ṣé ó ta pọ́n-ún ju ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ nígbà tí o tẹ igun kọ̀ọ̀kan lọ sílẹ̀ bí?
Bí ó bá ní ọyẹ́ nínú, ó ha ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìyáraṣiṣẹ́ gbogbo abẹ̀bẹ̀ rẹ̀ bí?
Ǹjẹ́ àwọn iná, ọ̀pá ìnugíláàsì, fèrè, bẹ́líìtì ara ìjókòó, àti àwọn fèrèsé rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ bí?
Yẹ abẹ́ ọkọ̀ náà wò lápá ẹ̀yìn láti wò ó bóyá àwọn àmì èyíkéyìí tí ó hàn síta wà tí ń fi hàn pé wọ́n so ìhùmọ̀ ìsokọ́ra kan tí wọ́n fi ń wọ́ ọkọ̀ alágbèérìn kan mọ́ ọn. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò dára pé kí o ṣọ́ra, níwọ̀n bí wíwọ́ ọkọ̀ ti lè ti mú kí wọ́n lo iṣètò ìṣiṣẹ́ gíà rẹ̀ ju bí ó ṣe yẹ lọ.
Bí èyíkéyìí lára àwọn àyẹ̀wò tí a mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí kò bá dá ọ lójú, ó lè jẹ́ ohun tí ó bọ́gbọ́n mu láti jẹ́ kí mẹ́káníìkì amọṣẹ́dunjú kan ṣàyẹ̀wò rẹ̀ kí o tó rà á. Ní kí ó yẹ ọkọ̀ náà wò kí ó sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí:
1. Àtúnṣe tí ọ̀kọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ń fẹ́ lójú ẹsẹ̀ àti ìfojúdíwọ̀n iye tí ẹ̀yà ara ọkọ̀ àti owó iṣẹ́ yóò jẹ́.
2. Àtúnṣe tí ó ṣeé ṣe kí ọkọ̀ náà nílò ní ọdún tí ń bọ̀ àti ìfojúdíwọ̀n iye tí ẹ̀yà ara ọkọ̀ àti owó iṣẹ́ yóò jẹ́.
Kò yẹ kí àyẹ̀wò tí mẹ́káníìkì amọṣẹ́dunjú náà yóò ṣe ju wákàtí kan lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè ná ọ ní owó iṣẹ́ wákàtí kan, iye tí yóò ná ọ kéré sí iye tí o kò mọ̀ tí àtúnṣe tí ó ń fẹ́ yóò náà ọ. Wádìí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lórí ọkọ̀ náà láìpẹ́ yìí lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ tà á. Ní kí wọ́n fi àkọsílẹ̀ àtúnṣe rẹ̀ hàn ọ́. Ǹjẹ́ wọ́n ń pààrọ̀ ọ́ìlì ẹ́ńjìnì àti asẹ́ ọ́ìlì ẹ́ńjìnì rẹ̀ déédéé bí? Ǹjẹ́ wọ́n ti tún ìṣètò ìṣiṣẹ́ gíà adáṣiṣẹ́ rẹ̀ ṣe rí? Ìgbà wo ni wọ́n ṣàtúnṣe fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ọkọ̀ náà gbẹ̀yìn? Rántí pé ọkọ̀ tí a tún ṣe dáradára ni ọkọ̀ tí a lò dáradára, tí kò sì nílò iṣẹ́ púpọ̀.
Jókòó, kí o kọ́kọ́ ṣírò iye tí yóò ná ọ—pẹ̀lú gbogbo òkodoro òtítọ́ àti àkọsílẹ̀ ìṣirò tí ó wà nípa ọkọ̀ náà. Lẹ́yìn náà, wá pinnu bí ọkọ̀ náà bá pójú owó, bí o bá sì ti wéwèé owó tí ó pọ̀ tó láti ná, kì í ṣe kìkì lórí iye àtirà á nìkan àmọ́ lórí àwọn ìnáwó mìíràn.—Onímọ̀ nípa ohun ìrìnnà kan ló kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Báwo ni o ṣe lè ní ìdánilójú pé ọkọ̀ tí o rà dára? A yàwòrán díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí o yẹ̀ wò síhìn-ín
Jẹ́ kí onímọ̀ nípa ohun ìrìnnà kan yẹ ọkọ̀ náà wò kí o tó rà á
Ǹjẹ́ wọ́n ń pààrọ̀ ọ́ìlì ẹ́ńjìnì àti asẹ́ ọ́ìlì ẹ́ńjìnì rẹ̀ déédéé?
Wá ibi tí ó bà jẹ́ nítorí ìjàm̀bá ọkọ̀. Ǹjẹ́ àwọn ilẹ̀kùn, ìdérí ẹ́ńjìnì, àti ibi ìkẹ́rùsí rẹ̀ tì dáadáa bí?
Bí táyà kò bá bà jẹ́ bára mu, ó lè jẹ́ àmi pé ọ̀pá ìtọ́kọ̀ tàbí ọwọ́ ọkọ̀ náà ní ìṣòro gan-an