Ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, Ibi Táwọn Olè Kan Fojú Sí, Ọ̀nà Ò Gbabẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí Eunice Ebuh ti sọ ọ́
“Àwọn adigunjalè fẹ́ wá jà wá lólè lọ́jọ́ tí a sábà máa ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nílé wa. Ní irú ọjọ́ yìí, ṣíṣí ni géètì wa máa ń wà nítorí àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn olùfìfẹ́hàn. Ó jọ pé àwọn olè náà mọ ìṣe wa àti àkókò ìpàdé wa. A mọ̀ dájú pé wọ́n ti jí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan gbé níbì kan, wọ́n sì wá dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ géètì wa lọ́jọ́ yẹn, ní àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ.
“Ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká ni ìgbà tí wọ́n wá lọ bọ́ sí. Dípò kí a ṣèpàdé nílé wa, Gbọ̀ngàn Ìjọba ni a ti ṣèpàdé. Lẹ́yìn ìpàdé, ìpàdé àwọn alàgbà wà. Bó bá ṣe pé tẹ́lẹ̀ ni, èmi àti àwọn ọmọ ì bá ti lọọlé, ṣùgbọ́n ọkọ mi, tí í ṣe alàgbà, ní ká dúró de òun. Ó lóun ò ní pẹ́. Báa ṣe dúró nìyẹn.
“Nígbà tí wọ́n ṣe tán, ló bá tún di pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa kọ̀ tí kò ṣiṣẹ́. Ọkọ mi àti alábòójútó àyíká tún un ṣe tì. Mẹ́káníìkì alára tí a pè pé kó wá ṣe é, ó ṣe é tì.
“Ó di dandan kí àwọn ọmọ fẹsẹ̀ rìn lọọlé. Kó pẹ́ sígbà yẹn lèmi náà lọọlé. Mo délé ní nǹkan bí aago mẹ́wàá alẹ́. Àtèmi àti àtàwọn ọmọ, kò sẹ́nì kankan nínú wa tó gbé ọkọ̀ wọlé, ìyẹn ni ò jẹ́ ká ṣí géètì ńlá.
“Nígbà tí mo wọ yàrá mi, mo gbọ́ ìró ìbọn, gbùà. Mi ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Mo fẹ́ fóònù ọlọ́pàá, ṣùgbọ́n fóònù ò ṣiṣẹ́. Mo sáré bàràbàrà sọ̀ kalẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, mo ti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé onírin, mo tún sáré lọ ti ilẹ̀kùn àárín. Mo pa gbogbo iná. Jìnnìjìnnì ti bá àwọn ọmọ mi, nítorí náà mo sọ pé kí wọn ó sinmẹ̀dọ̀. A jùmọ̀ gbàdúrà fún ààbò Jèhófà. Di bí a ti ń wí yìí, ọkọ mi ṣì wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ń tiraka láti rí i pé ọkọ̀ wa ṣiṣẹ́.
“Mo yọjú wòta lójú fèrèsé, mo rí ọkùnrin kan tó sùn sórí títì lẹ́gbẹ̀ẹ́ géètì. Ó jọ pé àwọn olè náà ti lọ, nítorí náà mo gbé ọkùnrin tó ṣèṣe náà sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tèmi, mo sì sáré gbé e lọ sí ọsibítù. Bí ẹní fikú ṣeré ni, ṣùgbọ́n mo ní láti ṣe nǹkan kan. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ọkùnrin náà kú lọ́jọ́ kejì.
“Yàtọ̀ sí tẹni tó kú, ṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́, torí ì bá burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká ni kò jẹ́ ká ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ nílé wa. Ọkọ̀ tó kọṣẹ́ ni kò jẹ́ kí gbogbo ìdílé wa wọ mọ́tò wálé. Ọkọ mi, tí ọwọ́ ṣìnkún àwọn olè wọ̀nyẹn ì bá tẹ̀, tòrutòru ló fi wọlé. Ìwọ̀nyí àti àwọn nǹkan mìíràn wà lára ohun tó kó wa yọ lálẹ́ ọjọ́ yẹn.
“Jèhófà ni odi agbára wa àti ìsádi wa. Bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ti wí, bẹ́ẹ̀ gan-an ló rí: ‘Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá ṣọ́ ìlú ńlá náà, lásán ni ẹ̀ṣọ́ wà lójúfò.’”—Sáàmù 127:1.