ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 12/15 ojú ìwé 21-25
  • Nígbà Tí Àwọn Adigunjalè Bá Ṣọṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Àwọn Adigunjalè Bá Ṣọṣẹ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ààbò àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
  • Dídín Ewu Olè Jíjà Kù
  • Nígbà Tí Àwọn Adigunjalè Bá Dé
  • Sinmẹ̀dọ̀
  • Ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, Ibi Táwọn Olè Kan Fojú Sí, Ọ̀nà Ò Gbabẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Nígbà Wo Ni Ìbẹ̀rù Yóò Dópin?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ayé kan Láìsí Àwọn Olè
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 12/15 ojú ìwé 21-25

Nígbà Tí Àwọn Adigunjalè Bá Ṣọṣẹ́

NÍ Ìkòyí, àdúgbò àwọn olówó nílùú Èkó, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, àwọn ilé gbígbé ti di ilé olódi. Ọ̀pọ̀ ilé ló ní ọ̀gbà gìrìwò tó ga tó mítà mẹ́ta, tí a to àwọn irin ṣóńṣó-ṣóńṣó, tàbí àwọn àfọ́kù ìgò, tàbí àwọn wáyà ẹlẹ́gùn-ún lára sí lórí. Àwọn mègáàdì kì í kúrò lẹ́nu àwọn géètì gàgàrà tí a fi irin gbọọrọ há lẹ́yìn, tí a fi ẹ̀wọ̀n irin dè, tí a sì fi àgádágodo tì pa. Gbogbo ojú fèrèsé ni a rọ irin sí kítikìti. Àwọn ilẹ̀kùn onírin ló tún wà lẹ́nu ọ̀nà àwọn yàrá, ìwọ̀nyí ló pààlà sáàárín yàrá àti ibòmíràn nínú ilé. Lóru, àwọn ajá àkòtagìrì—àwọn ajá gìdìgbà olójú ẹkùn tí a fi ń ṣọ́lé—ni a máa ń tú síta. Àwọn iná mímọ́lẹ̀ yòò tí ń mú kí òkùnkùn para dà yóò wà ní títàn, bó bá sì jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́gírí kò sí ní tòsí, ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tí ń ṣọ́ gbogbo àyíká yóò rọra máa dún pin-in pin-in.

Kò sẹ́ni tó lè sọ pé ọ̀ràn eré lọ̀ràn ààbò ilé. Àwọn àkọlé ìwé ìròyìn ti figbe ta pé: “Àwọn Adigunjalè Kó Gbogbo Àdúgbò Lẹ́rù Lọ”; “Àwọn Màjèṣí Ìgárá Ọlọ́ṣà Gboró”; àti “Òde Kan Bóbó, bí Àwọn Ọmọ Ìta Ṣe Ń Ṣọṣẹ́.” Ohun tójú àwọn èèyàn ń rí lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè nìyí. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀, àkókò líle koko là ń gbé lóòótọ́.—2 Tímótì 3:1.

Kárí ayé, ìwà ọ̀daràn, títí kan ìdigunjalè, kàn ń pọ̀ sí i ni. Lójoojúmọ́ ló ń di pé ọwọ́ ìjọba kò ká dídáàbò bo àwọn èèyàn wọn, tàbí kí wọ́n má tilẹ̀ ṣújá dídáàbò bò wọ́n. Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn ọlọ́pàá kéré níye, ìbọn ò tó, wọn kì í sì í rí ohun ìjà láti fi dira dáadáa tí wọ́n bá fẹ́ lọ gba àwọn tó ń kígbe gbàmí-gbàmí. Ṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní tòsí sì máa ń ta kété bí ẹni pé ohun tó ṣẹlẹ̀ kò kàn wọ́n.

Yóò wá di kí àwọn èèyàn wá nǹkan ṣe sọ́ràn ara wọn, níwọ̀n bí ìrànlọ́wọ́ kò ti tọ̀dọ̀ ọlọ́pàá tàbí àwọn aráàlú wá. Kristẹni alàgbà kan ní ilẹ̀ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè ọ̀làjú sọ pé: “Bóo bá pariwo pẹ́nrẹ́n, àwọn olè á ṣe ẹ́ léṣe tàbí kí wọ́n pa ẹ́. Gbàgbé nípa pé ẹnì kan ń bọ̀ wá gbà ẹ́. Bí ẹnì kan bá wá, ó fi dáa náà ni, ṣùgbọ́n má fọkàn sí i, má wulẹ̀ kígbe gbàmí-gbàmí, nítorí pé wíwá ìrànlọ́wọ́ lè yọrí sí wíwá wàhálà púpọ̀ sí i.”

Ààbò àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kì í ṣe apá kan ayé, inú ayé ni wọ́n ń gbé. (Jòhánù 17:11, 16) Nítorí náà, bí ti gbogbo èèyàn, wọ́n ń ṣètò ààbò tó yẹ. Síbẹ̀, láìdàbí ọ̀pọ̀ tí kò sin Jèhófà, àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń wá ààbò láìtẹ àwọn ìlànà Kristẹni lójú.

Láìdàbí wọn, àwọn èèyàn ní àwọn ilẹ̀ kan ní Áfíríkà máa ń ṣoògùn nítorí àwọn olè. Babaláwo lè sín gbẹ́rẹ́ sí ẹnì kan lọ́rùn ọwọ́, tàbí sí igbá àyà rẹ̀, tàbí sí ẹ̀yìn rẹ̀. Á wá fi oògùn kan pa ojú gbẹ́rẹ́ yẹn, á pògèdè sí i, á wá sọ pé onítọ̀hún ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn olè. Àwọn mìíràn máa ń ṣoògùn sílé tàbí kí wọ́n so àsorọ̀ mọ́lé, wọ́n lérò pé irú “ààbò” bẹ́ẹ̀ yóò mú kí àwọn olè fi àwọn sílẹ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣoògùn. Bíbélì lòdì sí gbogbo ìbẹ́mìílò, bẹ́ẹ̀ ló sì yẹ kó rí, nítorí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí èèyàn ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù, àwọn ẹni náà gan-an tí ń ṣe agbátẹrù ìwà ipá lórí ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 6:2, 4, 11.

Àwọn kan ń wá ààbò lọ́nàkọnà nípa níní ìbọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni kò fi ọ̀rọ̀ Jésù ṣeré rárá, pé: “Àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Àwọn ènìyàn Ọlọ́run ti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,” wọn kì í sì í ra ìbọn láti fi dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ olè tàbí ìkọluni.—Míkà 4:3.

Ṣíṣètò àwọn mègáàdì adìhámọ́ra ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn yìí o, ọ̀ràn ìpinnu ara ẹni ni, síbẹ̀ rántí pé irúfẹ́ ìṣètò bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ fi ìbọn náà lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ ni. Kí ni ẹni tó gba irú mègáàdì bẹ́ẹ̀ síṣẹ́ retí pé kó ṣe bí olè bá dé? Yóò ha retí pé bó bá di dandan kí mègáàdì yin olè níbọn, láti dáàbò bo àwọn èèyàn àti ohun ìní tó ń ṣọ́?

Kíkọ̀ tí àwọn Kristẹni ń kọ̀ láti máa fi oògùn àti ohun ìjà dáàbò bo ara wọn lè dà bí ìwà ẹ̀gọ̀ lójú àwọn tí kò mọ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.” (Òwe 29:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń dáàbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀ lápapọ̀, kì í ṣe ìgbà gbogbo ló máa ń gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olè. Jóòbù jẹ́ olùṣòtítọ́ lọ́nà tó ta yọ, síbẹ̀ Ọlọ́run gba àwọn onísùnmọ̀mí láyè láti kó àwọn ohun ọ̀sìn Jóòbù lọ, wọ́n tilẹ̀ gbẹ̀mí àwọn darandaran. (Jóòbù 1:14, 15, 17) Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run jẹ́ kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ìrírí “ewu dánàdánà.” (2 Kọ́ríńtì 11:26) Síbẹ̀, Ọlọ́run ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí yóò dín ewu gbígbàlejò olè kù. Ó tún ń fún wọn ní ìsọfúnni tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tí wọn yóò gbà hùwà nígbà tí olè bá jà, kí èṣe tó lè wáyé lè dín kù.

Dídín Ewu Olè Jíjà Kù

Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà sọ tipẹ́tipẹ́ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.” (Oníwàásù 5:12) Lédè mìíràn, àwọn tó ní nǹkan púpọ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn nípa pípàdánù nǹkan ìní wọn dépò tí wọn kò fi ní róorun sùn mọ́ nítorí ìdààmú.

Fún ìdí yìí, ọ̀nà kan láti gbà dín àníyàn àti ewu olè jíjà kù ni láti yàgò fún kíkó àwọn nǹkan ìní olówó ńlá jọ. Àpọ́sítélì náà tí a mí sí kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.” (1 Jòhánù 2:16) Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó ń sún àwọn èèyàn láti ra àwọn nǹkan olówó gọbọi ló ń sún àwọn ẹlòmíràn láti jalè. “Fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími” sì lè jẹ́ kíké sí àwọn tó bá fẹ́ jalè láti wá jalè.

Ní àfikún sí yíyẹra fún ṣekárími, ààbò mìíràn kúrò lọ́wọ́ olè jíjà ni láti fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni ọ́. Bí o bá ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn, tí o ń ṣòótọ́ sáwọn èèyàn, tí o sì ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni déédéé, a lè wá mọ̀ ọ́ sí ẹni rere láwùjọ, ẹni àyẹ́sí. (Gálátíà 5:19-23) Irú ìfùsì Kristẹni bẹ́ẹ̀ lè dáàbò boni lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ohun ìjà.

Nígbà Tí Àwọn Adigunjalè Bá Dé

Ṣùgbọ́n o, kí ni ṣíṣe bí àwọn olè bá rọ́nà bá wọ ilé rẹ, tí wọ́n sì kò ọ́ lójú? Rántí pé ẹ̀mí rẹ ṣe pàtàkì ju nǹkan ìní. Kristi Jésù sọ pé: “Má ṣe dúró tiiri lòdì sí ẹni burúkú; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí èkejì sí i pẹ̀lú. Bí ẹnì kan bá sì fẹ́ . . . gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ pẹ̀lú lọ sọ́wọ́ rẹ̀.”—Mátíù 5:39, 40.

Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n nìyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe dandan fún àwọn Kristẹni láti fún àwọn ọ̀daràn ní ìsọfúnni nípa dúkìá, ó jọ pé àwọn olè tètè máa ń yọwọ́ ìjà bí wọ́n bá rí i pé ẹnì kan ń ṣagídí, tí kò gbọ́rọ̀ sáwọn lẹ́nu, tàbí tó ń tàn wọ́n. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló tètè máa ń fìbínú hanni léèmọ̀, “níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.”—Éfésù 4:19.

Ilé fúláàtì ni Samuel ń gbé. Àwọn olè dí gbogbo ọ̀nà àbáwọ ilé náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti fúláàtì dé fúláàtì, wọ́n ń kẹ́rù. Samuel gbọ́ ìró ìbọn, ó gbọ́ ìró fífọ́ ilẹ̀kùn, ó sì gbọ́ tí àwọn èèyàn ń kígbe, tí wọ́n ń sunkún, tí wọ́n sì ń pohùnréré ẹkún. Ọ̀nà àjàbọ́ ò sí. Samuel sọ fún ìyàwó àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé kí wọ́n kúnlẹ̀, kí wọ́n káwọ́ sókè, kí wọ́n dijú, kí wọ́n sì máa retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Nígbà tí àwọn olè náà já wọlé, Samuel doríkodò bá wọn sọ̀rọ̀, ó mọ̀ pé bí òun bá wò wọ́n lójú, wọ́n lè rò pé òun yóò dá wọn mọ̀ lẹ́yìn náà. Ó sọ pé: “Ẹ wọlé. Ẹ kó gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́. Ẹ lè kó ohun tó bá wù yín. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a ò ní ṣagídí.” Ó ya àwọn olè náà lẹ́nu. Fún nǹkan bí wákàtí kan ni àwọn ọkùnrin méjìlá tó dira fi wọlé wá ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti owó àti àwọn ohun abánáṣiṣẹ́, wọn kò lu ìdílé náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣá wọn ládàá, bí wọ́n ti ṣe fún àwọn yòókù nínú ilé náà. Ìdílé Samuel dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀mí wọn.

Èyí fi hàn pé tó bá ti dọ̀ràn owó àti àwọn nǹkan ti ara, àwọn tí kò bá ṣagídí nígbà tí olè ń jà wọ́n lè dín èṣe tó lè wáyé kù.a

Nígbà mìíràn jíjẹ́rìí tí Kristẹni kan bá jẹ́rìí lè gbà á lọ́wọ́ èṣe. Nígbà tí àwọn olè wá jà nílé Adé, ó sọ fún wọn pé: “Mo mọ̀ pé nǹkan le fún yín, èyí ló jẹ́ kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ yìí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé lọ́jọ́ kan olúkúlùkù yóò ní oúnjẹ tí ó tó òun àti ìdílé rẹ̀. Olúkúlùkù yóò máa gbé ní àlàáfíà àti ayọ̀ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.” Gbogbo gìràgìrà àwọn olè náà rọlẹ̀. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Máà bínú pé a wá sílé ẹ, ṣùgbọ́n ó yẹ kóo mọ̀ pé ebi ló ń pa wá.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kó gbogbo ẹrù Adé lọ, wọn ò fọwọ́ kan òun àti ìdílé rẹ̀.

Sinmẹ̀dọ̀

Kò rọrùn láti sinmẹ̀dọ̀ nígbà téèyàn wà nínú ewu, pàápàá tó jẹ́ pé olórí góńgó àwọn olè ni láti kóni láyà jẹ. Àdúrà yóò ràn wá lọ́wọ́. Bí igbe wa fún ìrànwọ́ tilẹ̀ jẹ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tó sì ṣe ṣókí, Jèhófà ń gbọ́. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” (Sáàmù 34:15) Jèhófà ń gbọ́ wa, ó sì lè fún wa ní ọgbọ́n láti sinmẹ̀dọ̀ láti lè kojú ipò èyíkéyìí.—Jákọ́bù 1:5.

Yàtọ̀ sí àdúrà, ìrànlọ́wọ́ mìíràn tí yóò múni sinmẹ̀dọ̀ ni láti pinnu ṣáájú nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe àti ohun tí o kò ní ṣe bí olè bá jà ọ́. A gbà pé ṣáájú àkókò, kò ṣeé ṣe láti mọ ipò tí olè lè ká ọ mọ́. Síbẹ̀, ó dára láti ní àwọn ìlànà kan lọ́kàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bọ́gbọ́n mu láti ní àwọn ọ̀nà ààbò kan lọ́kàn bí ilé bá ṣèèṣì gbiná. Ríronú nípa rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sinmẹ̀dọ̀, láìbẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n jìnnìjìnnì, a ó sì lè yẹra fún èṣe.

Ọlọ́run sọ ojú ìwòye rẹ̀ nípa ìjanilólè ní kedere, pé: “Èmi, Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, mo kórìíra ìjanilólè pa pọ̀ pẹ̀lú àìṣòdodo.” (Aísáyà 61:8) Jèhófà mí sí Ìsíkíẹ́lì wòlíì rẹ̀ láti ka olè jíjà mọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo. (Ìsíkíẹ́lì 18:18) Síbẹ̀, ìwé Bíbélì kan náà tún fi hàn pé Ọlọ́run yóò fi tàánútàánú dárí ji ẹni tó bá ronú pìwà dà, tó sì dá ohun tó jí padà.—Ìsíkíẹ́lì 33:14-16.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbé nínú ayé tó kún fún ìwà ọ̀daràn, àwọn Kristẹni ń yọ̀ nínú ìrètí ìwàláàyè lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, nígbà tí olè jíjà kò ní sí mọ́. Nípa àkókò yẹn, Bíbélì ṣèlérí pé: “[Àwọn ènìyàn Ọlọ́run] yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”—Míkà 4:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ṣùgbọ́n o, ó ní ibi tí a lè gbọ́rọ̀ sí wọn lẹ́nu mọ. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kì í bá ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó bá rú òfin Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, Kristẹni kan kò kàn ní fínnúfíndọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún ìfipábánilòpọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́