Ayé kan Láìsí Àwọn Olè
Ó YÁRA ṣẹlẹ̀ gan-an ni. Ọkùnrin kan tí ó múra dáradára kọ ẹnu ìbọn sí orí Antônioa ní iwájú ilé rẹ̀ ní São Paulo, Brazil, ó béèrè fún kọ́kọ́rọ́ àti àwọn ìwé ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, ó sì yára wakọ̀ lọ.
Ní Rio de Janeiro, níṣojú ọmọbìnrin rẹ̀ ẹni ọdún mẹ́wàá, àwọn ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n dìhámọ́ra dáradára borí ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Paulo. Wàyí o, lẹ́yìn wíwakọ̀ lọ sí ilé rẹ̀, àwọn adigunjalè náà jáwọlé wọ́n sì jí ohun tí wọ́n ń fẹ́, ní dídi àwọn ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ Paulo méjèèjì kún bámú. Ní fífi ikú halẹ̀mọ́ ìyàwó Paulo, wọ́n mú òun àti ẹnìkan tí wọ́n gbà síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àmúdá lọ sí ilé-ìtajà ọ̀ṣọ́ iyebíye ti Paulo tí ó wà ní àárín-ìlú, èyí tí wọ́n kó gbogbo ohun tí ó ṣeyebíye nínú rẹ̀. Láìròtẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó rí, àwọn olè náà ṣe ìkésíni lorí tẹlifóònù nígbà tí ó yá, ní sísọ ibi tí wọ́n gbé àwọn ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ náà sí.
Ó ti ń mú ìbànújẹ́ wá tó pé kí á janilólè owó àti ọjà tí a fi òógùn-ojú kójọ! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Antônio àti Paulo kò ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn máa ń dá hùwà láìfi ti òfin pè. Wọ́n lè ṣe olè náà lọ́ṣẹ́, bí bẹ́ẹ̀kọ́ wọ́n lè pàdánù ìwàláàyè tiwọn fúnraawọn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀dọ́langba kan já aago ọrùn-ọwọ́ rẹ̀ gbà, obìnrin ọmọ ilẹ̀ Brazil kan tí inú bí gidigidi fa ìbọn kan jáde nínú àpò rẹ̀ ó sì yìn ín lu olè náà, tí ó sì pa á. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? O Estado de S. Paulo ròyìn pé: “Àwọn ènìyàn tí ọ̀ràn náà ṣojú wọn sọ̀rọ̀ rere nípa ìṣarasíhùwà obìnrin tí a kò mọ̀ yìí, kò sì sí ẹnìkankan tí ó fẹ́ láti ran àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ láti fi í hàn.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yánhànhàn fún ayé kan láìsí àwọn olè, àwọn Kristian kìí gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí obìnrin yẹn ti ṣe. Níwọ̀n bí ẹ̀san ti jẹ́ ti Ọlọrun, wọ́n kọbiara sí ọ̀rọ̀ inú Owe 24:19, 20: “Máṣe ìlara sí àwọn ènìyàn búburú, má sì ṣe jowú ènìyàn búburú. Nítorí pé, [ẹ̀yìn-ọ̀la, NW] kì yóò sí fún ènìyàn ibi.”
Ṣùgbọ́n bí a bá gbéjàkò ọ́, kí ni ìwọ lè ṣe? Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ni Rio de Janeiro fi bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti gbéjẹ́ẹ́ hàn. Kristian kan, Heloísa ń wọ mọ́tò lọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan. Àwọn ọkùnrin méjì bẹ̀rẹ̀ síí fipá ja àwọn èrò inú ọkọ̀ náà lólè. Nígbà tí ó dé ibi tí yóò ti bọ́ sílẹ̀, Heloísa sọ fún wọn pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti pé òun ń lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan ni. Ó fi Bibeli àti àwọn àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ hàn. Láì fipá jà á lólè, àwọn olè náà yọ̀ǹda fún un láti bọ́ sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, èrò mìíràn ni a kò fún láàyè láti lọ. Awakọ̀ náà sọ lẹ́yìn náà pé òun kò tíì rí irú rẹ̀ rí.
Regina pẹ̀lú gbéjẹ́ẹ́ nígbà tí àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n dìhámọ́ra pàṣẹ fún un láti wọnú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀. Ní fífi ẹ̀dà ìwé-ìròyìn Jí! tirẹ̀ hàn, Regina jẹ́rìí fún wọn. Níwọ̀n bí ojora ti mú àwọn adigunjalè náà, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣí ààyè tí a ń kó nǹkan sí ní iwájú ọkọ̀ níbi tí ó tọ́jú àwọn mindin-mín-ìn-dìn díẹ̀ pamọ́ sí. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti rí àwọn kásẹ́ẹ̀tì Kingdom Melodies, wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí tẹ́tísílẹ̀ sí ohùn-orin yẹn. Bí àyíká náà ti wá túbọ̀ di ti ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́, àwọn adingunjalè náà pinnu láti fi Regina sílẹ̀ láìṣe é níbi lójú ọ̀nà márosẹ̀ náà, ní mímú un dá a lójú pé yóò rí onínúure kan láti ràn án lọ́wọ́. Lẹ́yìn rírìn fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá, ó rí ilé kan, ṣùgbọ́n ó ṣòro fún onílé náà láti gba ohun tí ó sọ gbọ́, ní wíwí pé: “Ìwọ kò farahàn bí ẹni tí a gbéjàkò; araàrẹ balẹ̀ gan-an.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tí nǹkan ṣẹlẹ̀ sí náà ni a lè má palára níti ara-ìyára, irú ìrírí adánniwò kan bẹ́ẹ̀ lè ṣokùnfà àbájáde líléwu. ‘Ẹni tí nǹkan ṣẹlẹ̀ sí náà lè di aláìláàbò, kí ó kún fún ìkanra sí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tàbí àwọn wọnnì tí wọ́n gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́, kí ó má lè fọkàntán àwọn ẹlòmíràn, ṣíṣàkójọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ lè gbà á lọ́kàn, ó lè nímọ̀lára pé ayé kò nídàájọ́-òdodo,’ ni ìwé-ìròyìn O Estado de S. Paulo sọ. Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, ẹni tí ọ̀ràn ṣẹlẹ̀ sí kan tí ó nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa Ọlọrun ni ó ṣeéṣe kí ó la ìrírí náà já láìní ìpalára ti ara-ìyára àti ti èrò-ìmọ̀lára. Síbẹ̀, ìwọ kì yóò ha gbà pé yóò jẹ́ ìbùkún bí kò bá sí ìwà-ọ̀daràn tàbí ohunkóhun tí ń fa ìbẹ̀rù mọ́ bí?
“Kí Ẹni tí Ń Jalè Maṣe Jalè Mọ́”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀nà ìgbésí-ayé oníwọra wọn, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti ran àwọn olè lọ́wọ́ láti yí ìfẹ́-ọkàn wọn àti àkópọ̀ ànímọ́-ìwà wọn padà. (Efesu 4:23) Bí wọ́n ti ní ète gidi, tí a gbékarí Bibeli, wọ́n fi àwọn ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn pé: “Díẹ̀ pẹ̀lú òdodo, ó sàn ju ọrọ̀ ńlá lọ láìsí ẹ̀tọ́.” (Owe 16:8) Cláudio sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ìdílé mi ni wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí, ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ fetísílẹ̀ sí ohun tí wọ́n ní láti sọ nípa Jehofa àti àwọn ète rẹ̀. Ní pípadà láti ìrìn-àjò kan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá kìlómítà nínú ọkọ̀ akẹ́rù kan tí mo jígbé, mo níláti kọjá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi àyẹ̀wò àwọn ọlọ́pàá. Nígbà tí èyí ń ṣẹlẹ̀ mo rí i pé mo níláti yí ìgbésí-ayé mi padà. Mo ti gbìyànjú láti ṣe ìyẹn tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n láìsí àṣeyọrí. Lọ́tẹ̀ yìí mo bẹ̀rẹ̀ síí ronú nípa àwọn ìbátan mi tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa àti bí wọ́n ṣe yàtọ̀ tó, bí wọ́n ṣe ní ìdùnnú, ayọ̀, àti àlàáfíà.” Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, Cláudio bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ó pa oògùn olóró àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tì, ó sì di Kristian òjíṣẹ́ kan.
Àwọn mìíràn tún ń kọbiara sí àwọn ọ̀rọ̀ náà nísinsìnyí pé: “Máṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, kí o má sì ṣe gbéraga ní olè jíjà.” (Orin Dafidi 62:10) Lẹ́yìn ìdájọ́ ìjìyà ọgbà-ẹ̀wọ̀n fún ìpànìyàn tí a gbìdánwò rẹ̀ lákòókò ìdigunjalè kan, José, ajòògùnyó àti onífàyàwọ́ oògùn kan, jàǹfààní láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan pẹ̀lú arákùnrin aya rẹ̀. Ó dáwọ́ oògùn dúró ó sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí onítara kan nísinsìnyí.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àkópọ̀ ànímọ́-ìwà titun kìí wáyé lójú-ẹsẹ̀ tàbí lọ́nà ìyanu. Oscar, ẹni tí ó ti lọ́wọ́ nínú oògùn àti olè jíjà gidigidi, sọ pé: “Mo gbàdúrà lọ́nà tí ó gbóná janjan tóbẹ́ẹ̀ sí Jehofa débi pé ilẹ̀ sábà máa ń dàbí adágún omi kékeré kan fún ọ̀pọ̀ omijé mi.” Bẹ́ẹ̀ni, yàtọ̀ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun taápọn-taápọn, àdúrà lemọ́lemọ́, tọkàn-tọkàn ni a béèrè fún. Ṣàkíyèsí ọgbọ́n tí ó wà nínú ojú-ìwòye tí ó kún fún àdúrà yìí: “Máṣe fún mi ní òṣì, máṣe fún mi ní ọrọ̀; fi oúnjẹ tí ó tó fún mi bọ́ mi. Kí èmi kí ó má baà yó jù, kí èmi kí ó má sì sẹ́ ọ, pé ta ni Oluwa? tàbí kí èmi má baà tòṣì, kí èmi sì jalè, kí èmi sì ṣẹ̀ sí orúkọ Ọlọrun mi.”—Owe 30:8, 9.
Ọkàn-ìfẹ́ ara-ẹni ni a níláti fi ojúlówó ìfẹ́ rọ́pò: “Kí ẹni tí ń jalè máṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun kí ó lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.” (Efesu 4:28) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ti rí nípa àwọn Kristian ọgọ́rùn-ún ọdún kìn-ín-ní tí wọ́n ti jẹ́ ‘olè tàbí olójúkòkòrò’ tẹ́lẹ̀rí, Jehofa, nípasẹ̀ ìràpadà Jesu Kristi, fi tàánú-tàánú dáríji àwọn wọnnì tí wọ́n ronúpìwàdà. (1 Korinti 6:9-11) Ó ti tuninínú tó pé ohun yòówù kí ìgbà wa àtijọ́ ti jẹ́, a lè yí ọ̀nà ìgbésí-ayé wa padà kí á sì rí ojúrere Ọlọrun gbà!—Johannu 3:16.
Àìléwu Nínú Ayé Titun ti Ọlọrun
Ronú nípa ilẹ̀-ayé kan láìsí àwọn olè. Ìwọ kò ní nílò ètò-ìgbékalẹ̀ amófinṣẹ ti àwọn adájọ́, agbẹjọ́rò, ọlọ́pàá, àti ọgbà-ẹ̀wọ̀n tí ó gbówólórí! Yóò jẹ́ ayé aláásìkí kan nínú èyí tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ti bọ̀wọ̀ fún àwọn mìíràn àti ohun-ìní wọn! Ìyẹn ha dàbí ohun tí kò ṣeégbàgbọ́ bí? Ọlọrun yóò ha dásí àwọn àlàámọ̀rí ènìyàn kí ó sì fòpin sí ìwà-àìlófin níti tòótọ́ bí? A rọ̀ ọ́ láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí náà pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣeégbáralé. Ìwọ yóò rí ìpìlẹ̀ tí ó fìdímúlẹ̀ fún ìgbọ́kànlé pé ìyípadà wà níwájú. Kò sí ẹni tí ó lè dí Ọlọrun lọ́wọ́ láti mú ìtura tí a ṣèlérí fún gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òdodo wá pé: “Máṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ kí ó máṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí tí a óò ké wọn lulẹ̀ láìpẹ́ bíi koríko, wọn ó sì rọ bí ewéko tútù.” (Orin Dafidi 37:1, 2) Àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì tí a kọ tipẹ́ sẹ́yìn ni yóò ní ìmúṣẹ pátápátá láìpẹ́.
Ìjọba Ọlọrun yóò fòpin sí ìbànújẹ́ àti àìṣòdodo, tí ń ṣokùnfà àìnírètí àti àìdánilójú púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀. Kò sí ẹni tí yóò ṣaláìní mọ́, pẹ̀lú ìmọ̀lára wíwà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ láti jalè. A mú un dá wa lójú nínú àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀, lórí àwọn òkè ńlá ni èso rẹ̀ yóò máa mì bíi Lebanoni [ìgbàanì]: àti àwọn ti inú ìlú yóò sì máa gbá bíi koríko ilẹ̀.” (Orin Dafidi 72:16) Níti gidi, nínú Paradise tí a mú padàbọ̀sípò, kò sí ohun tí yóò dí àlàáfíà àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Ọlọrun òtítọ́ tí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀ lọ́wọ́.—Isaiah 32:18.
Èrè ńlá wo ni ìyẹn yóò jẹ́ fún kíkọ̀ tí a kọ àwọn ọ̀nà ayé oníwọra yìí! Owe 11:19 sọ pé: “Bí ẹni tí ó dúró nínú òdodo ti í ní ìyè, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lépa ibi, ó ń lé e sí ikú araarẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ni, lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti ké àwọn olùṣe búburú kúrò, kò sí ẹni tí yóò ní ìdí láti bẹ̀rù fún ìwàláàyè rẹ̀ tàbí ohun-ìní rẹ̀ mọ́. Orin Dafidi 37:11 fún wa ní ìlérí yìí pé: “Àwọn ọlọ́kàn-tútù ni yóò jogún ayé; wọn ó sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Díẹ̀ lára àwọn orúkọ náà ni a ti yípadà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Kíkojú Ìwà Olè-Jíjà Gidi
NÍNÚ ILÉ—Níwọ̀n ìgbà tí àwọn olè lè ya wọlé yálà o wà nílé tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, jẹ́ kí àwọn ilẹ̀kùn wà ní pípadé àti títìpa. Àwọn ògbógi dámọ̀ràn níní aago ìdágìrì tàbí ajá tí a fi ń ṣọ́lé. Fi ìgbà tí ìwọ kò ní sí nílé tó aládùúgbò tí ó ṣeégbáralé kan létí. Gbéjẹ́ẹ́—àwọn adigunjalè máa ń yára ṣiṣẹ́, láìròtẹ́lẹ̀, wọ́n sì lè yí ìwéwèé padà lójú-ẹsẹ̀ bí ojora bá mú wọn. Bí ìwọ bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, fi araàrẹ hàn kí o sì gbìyànjú láti jẹ́rìí. Ó lè ṣeéṣe fún ọ láti múni hùwà bí-ọ̀rẹ́ tàbí fi ojú-àánú hàn. Máṣe ṣàtakò àyàfi bí a bá gbéjàkò ọ́ níti ara-ìyára.
NÍ GBANGBA—Wà lójúfò láti kíyèsí i bí ẹnìkan bá ń tẹ̀lé ọ lẹ́yìn. Rìn láàárín ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀. Yẹra fún àwọn ojú-ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn tàbí tí ó dá. Tọ́jú àpamọ́wọ́ tàbí ohun ṣíṣeyebíye rẹ pamọ́. Rìn kánmọ́-kánmọ́ bí ẹni pé o ń lọ sí ibìkan. Yẹra fún wíwọ aṣọ olówó-ńlá tàbí ohun-ọ̀ṣọ́ dídán yanranyanran. Lọ ra ọjà pẹ̀lú ọ̀rẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ kan nígbà tí ipò nǹkan bá béèrè fún un. Mú kìkì owó tí o nílò dání, kí o pín in káàkiri inú àpò tàbí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
NÍNÚ ỌKỌ̀—Bí “jíjá ọkọ̀ gbà” bá ti di ohun tí ó wọ́pọ̀ ní àgbègbè rẹ, máṣe jókòó sínú ọkọ̀ rẹ tí o gbé síbi ìgbọ́kọ̀sí. Yí ọ̀nà rẹ lọ sí ibi iṣẹ́ àti láti ibi iṣẹ́ lọ sílé padà. Máa gba ibi tí ewu ti dínkù jùlọ, àní bí ó bá dàbí èyí tí ó jìn jù pàápàá. Ṣáájú kí o tó páàkì ọkọ̀, wò yíká láti rí i bi ohunkóhun bá jọ bi èyí tí ó ṣeéfura sí. Yẹra fún ṣíṣí búùtù ní agbègbè ibi tí èrò ti dá. Máṣe fi àwọn ohun tí ó níyelórí sílẹ̀ síbi tí ojú ti lè tó o nínú ọkọ̀. Ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tí a tìpa tí ó ṣeérí tàbí ìhùmọ̀ tí ń dí olè lọ́wọ́ mìíràn lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn olè arebipa.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
“Ẹ máṣe to ìṣúra jọ fún ara yín ní ayé, níbi tí kòkòrò àti ìpáàrà íbà á jẹ́, àti níbi tí àwọn olè í rúnlẹ̀ tí wọ́n sì í jalè: Ṣùgbọ́n ẹ to ìṣúra jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò àti ìpáàrà kò lè bà á jẹ́, àti níbi tí àwọn olè kò lè rúnlẹ̀ kí wọ́n sì jalè.”—Matteu 6:19, 20