ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 10/15 ojú ìwé 8-11
  • Ìṣòro Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Dúró

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣòro Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Dúró
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọgbọ́n tí Ó Wà Nínú Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Dúró
  • Fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀, Ìpèníjà Titun Kan
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ẹlòmíràn
  • Jíja Ìjà Rere Náà
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Dúró ní Ọ̀nà Gbogbo
  • Ṣé Wàá Lè Fi Sùúrù Dúró De Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ṣé Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Táwọn Olówó Àtàwọn Tálákà Máa Ní Nǹkan Lọ́gbọọgba?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Wíwà Láìlọ́kọ Láìláya Ní Àkókò Tí Ọrọ̀-Ajé Kò Rọgbọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ṣé Wàá Dúró De Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 10/15 ojú ìwé 8-11

Ìṣòro Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Dúró

KÍKẸ́KỌ̀Ọ́ láti dúró de àwọn ohun tí a ń fẹ́ ni ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ lílekoko jùlọ tí a tíì béèrè lọ́wọ́ àwa ènìyàn rí láti tẹ́wọ́gbà. Àwọn ọmọdé jẹ́ aláìnísùúrù níti àdánidá. Ohunkóhun tí ó bá ti fà wọ́n mọ́ra, ni wọ́n ń fẹ́, wọ́n sì ń fẹ́ ẹ nísinsìnyí! Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí o ti lè mọ̀ láti inú ìrírí, ó jẹ́ ohun tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ pé kìí ṣe ohun gbogbo ni ó ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbàkigbà tí a bá béèrè fún un. Àní nínú ọ̀ràn àwọn ìfẹ́-ọkàn yíyẹ pàápàá, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ láti dúró de àkókò tí ó bójúmu láti tẹ́ wọn lọ́rùn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti kọ́ ẹ̀kọ́ yìí; àwọn mìíràn kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fẹ́ láti jèrè ìtẹ́wọ́gbà àtọ̀runwá ní àwọn ìdí pàtàkì fún kíkẹ́kọ̀ọ́ láti dúró. Jeremiah, ìráńṣẹ́ Jehofa ṣáájú àkókò àwọn Kristian, tẹnumọ́ èyí: “Ó dára tí à bá máa [dúró, NW] ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fún ìgbàlà Oluwa.” Lẹ́yìn náà, Kristian ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu sọ pé: “Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di [ìgbà wíwàníhìn-ín, NW] Oluwa.”—Ẹkun Jeremiah 3:26; Jakọbu 5:7.

Jehofa ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò tirẹ̀ fún ìṣiṣẹ́yọrí àwọn ète àtọ̀runwá. Bí a kò bá lè dúró títí di àkókò yíyẹ rẹ̀ fún ṣíṣe àwọn ohun kan, àwa yóò di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti aláìlẹ́mìí ìtẹ́lọ́rùn, èyí tí yóò fún ayọ̀ pa. Láìsí ayọ̀ ìráńṣẹ́ Ọlọrun kan yóò di aláìlera nípa tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí Nehemiah ti sọ fún àwọn ará ìlú rẹ̀: “Ayọ̀ nínú OLUWA ni okun yín.”—Nehemiah 8:10, The New English Bible.

Ọgbọ́n tí Ó Wà Nínú Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Dúró

Ó jẹ́ ìfẹ́-ọkàn àdánidá fún àwọn kò-lọ́kọ-kò-láya láti fẹ́ láti ṣègbéyàwó tàbí fún tọkọtaya aláìlọ́mọ kan láti fẹ́ kí wọ́n bí àwọn ọmọ. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò sí ohun tí ó ṣàìtọ́ nínú pé kí a fẹ́ láti tẹ́ àwọn àìní ti ara tàbí ìfẹ́-ọkàn wa tí ó yẹ lọ́rùn. Síbẹ̀, nítorí gbígbàgbọ́ pé àwọn ọjọ́ ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí yóò dópin láìpẹ́ àti pé nínú ètò-ìgbékalẹ̀ titun tí ń bọ̀ Ọlọrun yóò ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀ yóò sì tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn,’ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristian ti pinnu láti dúró láti mú díẹ̀ nínú àwọn ìfẹ́-ọkàn wọ̀nyí ṣẹ ní àkókò kan tí ó túbọ̀ wọ̀.—Orin Dafidi 145:16.

Àwọn ènìyàn tí kò ní ìrètí Kristian tí ó fìdímúlẹ̀ gbọnyingbọnyin yìí, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò rí ìdí tí ó pọ̀ tó fún ìsúnsíwájú. Bí wọ́n ti kùnà láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jehofa, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé” ti ń wá, wọ́n gbé ìbéèrè dìde sí ọgbọ́n tí ó wà nínú sísọ àwọn nǹkan dìgbàmíì ní ọjọ́-iwájú tí wọ́n ṣiyèméjì pé yóò dé láé. Wọ́n ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ náà pé: “Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ, ẹ jẹ́ kí á máa mu; ọ̀la ni àwa ó ṣáà kú.”—Jakọbu 1:17; 1 Korinti 15:32; Isaiah 22:13.

Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti lajú iṣẹ́-ajé ìpolówó-ọjà ń lo àǹfààní ìtẹ̀sí tí kò ní àṣìmú fún ìtẹ́lọ́rùn ojú-ẹsẹ̀. Àwọn ènìyàn ni a fún níṣìírí láti kẹ́ araawọn bàjẹ́. Ètò ìṣòwò yóò mú kí á gbàgbọ́ pé àwọn àǹfààní ìtẹ́lọ́rùn àti ìdẹ̀ra òde-òní jẹ́ kòṣeémánìí lójú méjéèjì. Èéṣe tí ìwọ kò fi lè ní wọn, ni a sọ, ní pàtàkì nígbà tí áwọn káàdì ìrajà láwìn, ìwéwèé san-án-díẹ̀díẹ̀, àti “rà nísinsìnyí—sanwó nígbà tí ó bá yá” mú kí ó ṣeéṣe láti ní gbogbo rẹ̀ àti láti ní i nísinsìnyí? Yàtọ̀ sí ìyẹn, ‘O lẹ́tọ̀ọ́sí ohun tí ó dára jùlọ kẹ̀; ṣàánú araàrẹ! Rántí, yálà kí o gbádùn rẹ̀ nísinsìnyí tàbí bóyá kí o má ṣe bẹ́ẹ̀ láé!’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú tí ó gbajúmọ̀ sọ.

Ní àkókò yìí ná, àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́wàá-mẹ́wàá àwọn ènìyàn ní àwọn ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà wulẹ̀ ní kìkì ohun tí ó tó wọn láti wá ohun tẹ́nu ó jẹ ni—tàbí kí wọ́n má tilẹ̀ ní èyí tí ó tó. Ohun mìíràn ha lè tẹnumọ́ àìpé àti àìsí ìdájọ́-òdodo ètò-ìgbékalẹ̀ ìṣèlú àti ọrọ̀-ajé ènìyàn lọ́nà híhàn ketekete ju èyí bí?

Ọgbọ́n tí ó wà nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ láti dúró ni a rí níti pé àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọn kò múratán láti ṣe bẹ́ẹ̀—tàbí ó kérétán tí wọn kò rí ìdí láti ṣe bẹ́ẹ̀—ti wọko gbèsè ńlá láti tẹ́ àwọn ìfẹ́-ọkàn ojú-ẹsẹ̀ lọ́rùn. Àwọn ipò tí a kò rí tẹ́lẹ̀, irú bí àìsàn tàbí àìníṣẹ́ lọ́wọ́, lè túmọ̀sí ìjábá. Ìwé-ìròyìn Germany náà Frankfurter Allgemeine Zeitung ṣàlàyé ìdí tí àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí a ròyìn ní Germany fi jẹ́ aláìrílégbé: “Ní ọ̀nà tí ó wọ́pọ̀, àìnílélórí ni àìníṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí gbèsè tí ó pọ̀ jù sábà máa ń ṣáájú rẹ̀.”

Bí wọn kò ti lè sanwó ìwé gbèsè wọn, ọ̀pọ̀ nínú irú àwọn aláìrìnnàkore bẹ́ẹ̀ ń jìyà àdánù bíbaninínújẹ́ níti ilé àti àwọn ohun-ìní. Ní gbogbo ìgbà ṣáá, másùnmáwo tí ń pọ̀ síi ń mú ìgalára ìdílé wá. Àwọn ìgbéyàwó tí kò fìdímúlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí túká. Àwọn sáà àkókò ìkárísọ àti àwọn ìṣòro ìlera mìíràn di ohun tí ó wà níbi gbogbo. Nínú ọ̀ràn ti àwọn Kristian, ipò-tẹ̀mí lè forífá a, tí yóò sì wá jálẹ̀ sí ìrònú òdì àti ìwà tí kò bójúmu lẹ́yìnwá ìgbà náà. Àwọn ènìyàn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ nípa fífi àìlọ́gbọ́n fẹ́ ohun gbogbo ń parí rẹ̀ sí ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ṣíṣàìní ohunkóhun.

Fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀, Ìpèníjà Titun Kan

Jesu mú un ṣe kedere pé a níláti ṣọ́ra kí ‘àníyàn ayé, àti ìtànjẹ ọrọ̀, àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ohun mìíràn má baà bọ́ sínú ọ̀rọ̀ náà kí ó sì fún wọn pa.’ (Marku 4:19) A níláti pa á mọ́ sọ́kàn pé kò sí ètò-ìgbékalẹ̀ òṣèlú tí ó tíì fi àṣeyọrí mú àwọn àníyàn, títíkan ti ìṣúnná-owó, èyí ti Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kúrò.

Ètò Kọmunisti tí àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìlà-Oòrùn Europe ti kọ̀ sílẹ̀ nísinsìnyí gbìyànjú láti mú àwọn nǹkan dọ́gba nípasẹ̀ ọrọ̀-ajé tí Orílẹ̀-èdè ń darí rẹ̀. Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra pẹ̀lú ètò-ìgbékalẹ̀ òwò-àdáṣe olómìnira, àwọn ètò-ìgbékalẹ̀ tẹ́lẹ̀rí náà pèsè ààbò ìṣúnná-owó kan fún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn tí ètò ìṣòwò ìjọba oníṣòwò bòḿbàtà kùnà láti fifúnni. Síbẹ̀, àwọn àníyàn tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ wà lọ́nà ti àwọn ọjà àràlò tí kò tó àti òmìnira ara-ẹni tí a dínkù.

Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì ń nawọ́ àǹfààní káràkátà síni wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ gbé ìpèníjà titun kalẹ̀ fún àwọn ará-ìlú wọn. Ìròyìn ẹnu àìpẹ́ yìí kan sọ pé: “Ànímọ́ àìnírìírí ni a dàpọ̀ mọ́ ìfẹ́-ọkàn náà láti bá ọ̀pá-ìdiwọ̀n lílo nǹkan bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè ìwọ̀-oòrùn dọ́gba ní kíákíá.” Kí ọwọ́ lè tẹ èyí “iye àwọn ènìyàn tí ń ga síi ní Länder titun tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn Germany ni wọ́n ń súlọ sínú gbèsè tí wọ́n lè má bọ̀ọ́ nínú rẹ̀.” Ìròyìn náà fikún un pé: “Lẹ́yìn ayọ̀ ṣìnkìn tí ó kọ́kọ́ wáyé lórí òmìnira ìṣúnná-owó titun ìbẹ̀rù àti àìnírètí ń tànkálẹ̀ nísinsìnyí.” Nísinsìnyí wọ́n ti da aṣọ ètò-ìgbékalẹ̀ ìjọba oníṣòwò bòḿbàtà bora, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ṣì wà.

Òmìnira òṣèlú àti ti ìṣúnná-owó gíga síi ti ṣí àwọn ṣíṣeéṣe titun sílẹ̀ fún ìmúsunwọ̀n síi ọrọ̀-ajé. Fún ìdí yìí, ọ̀pọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan ni a lè dánwò láti fún èrò bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ajé tiwọn fúnraawọn tàbí ṣíṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn tí ó ní àǹfààní ìgbanisíṣẹ́ tí ó sàn jù ní àgbéyẹ̀wò pàtàkì.

Àwọn ìpinnu bí ìwọ̀nyí jẹ́ ọ̀ràn ti ara-ẹni. Kò lòdì fún Kristian kan láti fẹ́ láti mú ipò ìṣúnná-owó rẹ̀ sunwọ̀n síi. Òun ni a lè sún nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn láti bójútó ìdílé rẹ̀, ní mímọ̀ pé “bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.”—1 Timoteu 5:8.

Nítorí náà, kò bójúmu láti ṣe lámèyítọ́ ìpinnu tí àwọn ẹlòmíràn ṣe. Lákòókò kan-náà, àwọn Kristian níláti rántí pé kò bọ́gbọ́nmu láti wá ìtura ìṣúnná-owó nípa jíjẹ gbèsè àjẹpajúdé tí ó lè dẹkùn mú wọn. Kò ní tọ̀nà bákan náà láti wá ìtura ìṣúnná-owó ní ọ̀nà kan tí ó wémọ́ pípa àwọn iṣẹ́-àìgbọ́dọ̀máṣe àti ire tẹ̀mí tì sápákan.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ẹlòmíràn

Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀lé Ogun Àgbáyé Kejì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Germany ni wọ́n ṣí kúrò ní Europe ti ogun ti fọ́bàjẹ́ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ní pàtàkì Australia àti Canada. Ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣeéṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti mú ipò ìṣúnná-owó wọn sunwọ̀n síi, ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kankan nínú wọn tí ó lè bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àníyàn ìṣúnná-owó tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Yíyanjú àwọn ìṣòro ìṣúnná-owó nígbà mìíràn ń dá àwọn ìṣòro titun sílẹ̀—ṣíṣàárò-ilé, èdè àjèjì, mímú ara-ẹni bá oúnjẹ titun, àṣà ọ̀tọ̀, mímú ọwọ́-wọ-ọwọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ titun, tàbí kíkojú àwọn ìṣarasíhùwà tí ó yàtọ̀.

Díẹ̀ lára àwọn olùṣíkúrò wọ̀nyí jẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Lọ́nà tí ó yẹ fún ìgbóríyìn, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú wọn kọ̀ láti fààyè gba àwọn ìṣòro tí ó jẹ mọ́ ìṣíkúrò láti fún ipò-tẹ̀mí wọn pa. Ṣùgbọ́n àwọn àfi díẹ̀ wà. Àwọn kan ṣubú sọ́wọ́ agbára ìtànjẹ ọrọ̀. Ìtẹ̀síwájú wọn níti ìṣàkóso Ọlọrun ni kò lọ ní ìṣísẹ̀rìn kan-náà pẹ̀lú ìsunwọ̀n ìṣúnná-owó wọn.

Dájúdájú èyí ṣàkàwé ọgbọ́n ṣíṣàyẹ̀wò ipo wa tìṣọ́ra-tìṣọ́ra ṣáájú kí á tó ṣe àwọn ìpinnu tí ó ṣeéṣe kí ó má bá ọ́gbọ́n mu. Àwọn ìtẹ̀sí ti ọrọ̀-àlùmọ́nì yóò mú iṣẹ́ sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn tí a kò tún ní túnṣe mọ́ láé náà tí a yàn fún àwọn Kristian láti ṣe jórẹ̀yìn. Èyí jẹ́ òtítọ́ láìka ibi yòówù tí a ń gbé sí, níwọ̀n bí kò ti sí orílẹ̀-èdè tí àwọn ọlọ̀tọ̀ rẹ̀ wà lómìnira kúro lọ́wọ́ àníyàn ìṣúnná-owó.

Jíja Ìjà Rere Náà

Paulu fún Timoteu ní ìṣílétí pé: “Máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, sùúrù, ìwàtútù. Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a gbé pè ọ́ sí.” Fún àwọn Kristian ní Korinti ó sọ pé: “Ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ síi ní iṣẹ́ Oluwa nígbà gbogbo.”—1 Timoteu 6:11, 12; 1 Korinti 15:58.

Títẹ̀lé ìmọ̀ràn rere yìí ni ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti borí ìfẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́nì lọ́nà àṣeyọrísírere, ọ̀pọ̀ yanturu sì wà fún Kristian kan láti ṣe dájúdájú! Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan níbi tí iye àwọn oníwàásù Ìjọba kò ti pọ̀, ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ni àǹfààní wọn láti rí òtítọ́ kò pọ̀ tó. Jesu sọtẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó péye pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan.”—Matteu 9:37.

Dípò fífààyè gba àwọn àníyàn ìṣúnná-owó ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí láti pa wọ́n léte dà kúrò nínú iṣẹ́ tẹ̀mí tí ó wà lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń lo àǹfààní ipò náà nípa lílo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Nígbà tí a kò bá gbà wọ́n síṣẹ́ fún àkókò díẹ̀ kan, ọ̀pọ̀ nínú wọn ń mú ìgbòkègbodò wọn gbòòrò síi. Iṣẹ́-ìsìn wọn, yàtọ̀ sí mímú tí ó ń mú igbe ìyìn sí Jehofa ga síi, ń fún wọn ní ayọ̀ tí wọ́n nílò láti kojú ìṣòro ìṣúnná-owó tiwọn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ń fi iṣẹ́ wíwàásù sí ipò kìn-ín-ní tí wọ́n sì fi àwọn ìnira ìṣúnná-owó sí ipò kejì, èyí tí ó fihàn fún ẹgbẹ́ àwọn ará kárí-ayé pé wọ́n fi tọkàntọkàn ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa láti bójútó wọn. Ìlérí rẹ̀ ni pé: “Ẹ tètè máa wá ìjọba Ọlọrun ná, àti òdodo rẹ̀; gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Matteu 6:33.

Láti ìgbà ìmúpadàbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́ ní 1919, Jehofa kò tíì yọ̀ǹda fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti pàdánù okun. Ó ti dáàbòbò wọ́n la inúnibíni mímúná já àti ní àwọn ibì kan la àwọn ẹ̀wádún ìgbòkègbodò abẹ́lẹ̀ já. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wà ní ìmúratán pé ohun tí ọwọ́ Èṣù kùnà láti tẹ̀ nípasẹ̀ inúnibíni, ni òun kò ní ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́nì tí ó túbọ̀ jẹ́ ti àrékérekè!

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Dúró ní Ọ̀nà Gbogbo

Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó fẹ̀, ohun-èèlò agbóhùnjáde olówó gọbọi, àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àwọn ilé Beteli tí ó fanimọ́ra ń mú ògo wá fún Ọlọrun ó sì ń fúnni ní ìjẹ́rìí abẹ́lẹ̀ pé ó ń bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí a ti fòfinde iṣẹ́ náà tipẹ́ lè nímọ̀lára pé ní ọ̀nà yìí àwọn ní ohun púpọ̀ láti ṣe láti lé ọ̀pá-ìdiwọ̀n kan-náà bá. Ṣùgbọ́n ohun tí ó gba ipò-iwájú jùlọ níti ìjẹ́pàtàkì ni pé wọ́n ń tẹ̀síwájú nìṣó nípa tẹ̀mí. Ìfihàn ìbùkún Ọlọrun tí ó hàn gbangba ní ọ̀nà ti ara yóò tẹ̀lé e ní àkókò yíyẹ.

Àwọn olùṣèyàsímímọ́ ìráńṣẹ́ Jehofa níláti wà lójúfò kí ó má baà jẹ́ pé, nínú ìlépa ire ti ara-ẹni, wọ́n a bẹ̀rẹ̀ síí nímọ̀lára pé ó tó gẹ́ẹ́ fún ṣíṣàìní àwọn ohun tí ara kan láti ìgbà yìí wá. Yíyánhànhàn fún ìtura kúrò nínú ségesège ìṣúnná-owó àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ni a lè lóye rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Jehofa kò gbójúfò ó dá pé gbogbo àwọn ìráńṣẹ́ Ọlọrun ń yánhànhàn fún ìtura. Àwọn afọ́jú ń yánhànhàn láti ríran lẹ́ẹ̀kan síi, àwọn fòníkú-fọ̀ladìde ń yánhànhàn fún ìlera tí a mú padà bọ̀ sípò, awọn tí wọ́n ní ìsoríkọ́ ń yánhànhàn fún ìrísí ojú mímọ́lẹ̀yòò, àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ sì ń yánhànhàn láti rí àwọn olólùfẹ́ wọn tí ó ti kú lẹ́ẹ̀kan síi.

Nítorí àwọn ipò àyíká, olúkúlùkù Kristian ni a fipá mú ní àwọn ọ̀nà kan láti dúró fún ayé titun Jehofa láti yanjú àwọn ìṣòro rẹ̀. Èyí níláti mú wa béèrè lọ́wọ́ araawa pé, ‘Bí mo bá ní oúnjẹ àti ìbora, kò ha yẹ kí n ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun wọ̀nyí kí n sì wà ní ìmúratán láti dúró de ìtura kúrò nínú àwọn ìṣòro ìṣúnná-owó bí?’—1 Timoteu 6:8.

Àwọn Kristian tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Jehofa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ ni a lè mú un dá lójú pé bí wọ́n bá wulẹ̀ múratán láti dúró, gbogbo ìfẹ́-ọkàn yíyẹ àti àìní wọn ni a óò tẹ́lọ́rùn láìpẹ́. Kò sí ẹni tí ìdúró rẹ̀ yóò ti jásí asán. A tún àwọn ọ̀rọ̀ Paulu sọ pé: “Ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ Oluwa nígbà gbogbo, níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yín kìí ṣe asán nínú Oluwa.”—1 Korinti 15:58.

Nítorí náà kíkẹ́kọ̀ọ́ láti dúró níti gidi ha lè jẹ́ ìṣòro títóbi bí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kíkẹ́kọ̀ọ́ láti dúró lè gba ìwàláàyè rẹ là

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́