Wíwà Láìlọ́kọ Láìláya Ní Àkókò Tí Ọrọ̀-Ajé Kò Rọgbọ
CHUKS, tí ń gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn Africa, sọ pé: “Mo fẹ́ láti gbéyàwó nígbà tí mo wà ní ẹni ọdún 25. Mo ní ọmọbìnrin kan lọ́kàn, òun pẹ̀lú sì ní ọkàn-ìfẹ́ sí mi. Owó ni ìṣòro. Bàbá mi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin kò ní iṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn àbúrò mi ọkùnrin àti obìnrin sì wà ní ilé-ẹ̀kọ́. Gbogbo wọn gbáralé mi láti gbọ́ bùkátà ìdílé. Nígbà náà, láti mú ọ̀ràn burú síi, àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ àìsàn, ìyẹn sì túmọ̀ sí wíwá àlékún owó láti san owó ìtọ́jú ìṣègùn.”
Chuks, Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, kò fẹ́ láti kówọ inú ìgbéyàwó láìlè gbọ́ bùkátà ìyàwó. Ó fi ọ̀rọ̀ Paulu tí a rí nínú 1 Timoteu 5:8 sọ́kàn pé: “Dájúdájú bí ẹni kan kò bá pèsè fún awọn wọnnì tí [wọ́n] jẹ́ tirẹ̀, ati ní pàtàkì fún awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, oun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”
Chuks tẹ̀síwájú pé: “Mo ṣiṣẹ́ kára, ṣùgbọ́n owó kò fìgbà kan tó rí. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ìwéwèé ìgbéyàwó wa ni a níláti dá dúró ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Paríparí rẹ̀, mo gba lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin náà tí ń sọ pé ẹlòmíràn ti bá bàbá òun sọ̀rọ̀ láti fẹ́ òun. Bàbá náà gbà. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí lẹ́tà rẹ̀ dé, àwọn ẹbí ṣe ayẹyẹ àdéhùn ìgbéyàwó náà.”
Gẹ́gẹ́ bíi Chuks, ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristian ọkùnrin ni ìwéwèé ìgbéyàwó wọn ti foríṣánpọ́n tàbí tí a ti dá dúró nítorí ipò ọrọ̀-ajé tí kò dára. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ìfòsókè owó-ọjà ti rékọjá ààlà. Fún àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan ní àárín gbùngbùn Africa, owó-ọjà lọ sókè ní ìpín 8,319 nínú ọgọ́rùn-ún ní ọdún kan! Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan iṣẹ́ ṣòro láti rí. Bákan náà, owó-ọ̀yà ń kéré lemọ́lemọ́ débi pé ó ṣòro fún ọkùnrin kan láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, áḿbọ̀sìbọ́sí ìyàwó àti àwọn ọmọ. Ọkùnrin ọ̀dọ́ kan ní Nigeria dárò pé ilé-iṣẹ́ kan san $17 (U.S.) péré lóṣù fún iṣẹ́ alákòókò-kíkún tí a fún òun—iye tí ó kéré sí owó ọkọ̀ àlọ àti àbọ̀ sí ibi iṣẹ náà lóṣooṣù!
Ọ̀pọ̀ àwọn Kristian obìnrin tí wọn kò lọ́kọ ń rí i pé ìṣòro ọrọ̀-ajé ń mú ìjákulẹ̀ wá bá ìwéwèé ìgbéyàwó wọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà wọ́n níláti ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn. Àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n jẹ́ àpọ́n, ní rírí ipò náà, ń ṣetìkọ̀, níti pé wọ́n mọ̀ pé ọkùnrin tí ó bá gbéyàwó lábẹ́ àyíká-ipò bẹ́ẹ̀ yóò níláti ṣiṣẹ́-gbowó tí ó pọ̀ tó láti gbọ́ bùkátà tí kì í ṣe ti ìyàwó nìkan ṣùgbọ́n ti ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú. Ayọ, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́gboyè ní yunifásítì, ń tiraka láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, ìyá rẹ̀, àti àwọn àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ó ń dárò pé: “Mo fẹ́ láti lọ́kọ, ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn mìíràn bá wá tí wọ́n sì rí bùkátà mi rẹpẹtẹ [ẹrù-iṣẹ́ níti ọ̀ràn-ìnáwó], wọ́n a fẹsẹ̀ fẹ́ẹ.”
Láìka ìṣòro ọ̀ràn-ìnáwó sí, ọ̀pọ̀ àwọn Kristian tí kò tí ì lọ́kọ tàbí láya ń rí i pé àwọn ìbátan àti àwọn mìíràn ń fúngun mọ́ wọn láti gbéyàwó tàbí lọ́kọ kí wọ́n sì bímọ. Nígbà mìíràn ìfúngunmọ́ yìí ń wáyé ní ọ̀nà ìfiniṣẹlẹ́yà. Fún àpẹẹrẹ, ni àwọn apákan Africa, ó jẹ́ àṣà láti béèrè ìyàwó tàbí ọkọ àti àwọn ọmọ nígbà tí a bá ń kí ẹni tí ó ti dàgbà. Nígbà mìíràn, irú ìkíni bẹ́ẹ̀ ni a máa ń lò láti fi àwọn tí wọn kò bá tí ì gbéyàwó tàbí lọ́kọ ṣe yẹ̀yẹ́. John, ẹni tí ó ti lé dáradára ní 40 ọdún, sọ pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn bá yọ́milóhùn tí wọ́n sì sọ pé, ‘Ìyàwó rẹ ń kọ́?,’ màá dáhùn pé, ‘Ó ń bọ̀.’ Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, báwo ni n óò ṣe ní ìyàwó tí n kò bá lè gbọ́ bùkátà rẹ̀?”
Níti John àti àìmọye àwọn ẹlòmíràn bíi tirẹ̀, ipò náà ni a kó pọ̀ nínú òwe Yorùbá kan tí ó sọ pé: “Àti gbéyàwó kò tó pọ́n; owó ọbẹ̀ ló ṣòro.”
Lo Àǹfààní Ipò Rẹ Lọ́nà Tí Ó Dára Jùlọ
Ẹ wo bí ó ti rọrùn tó láti di ẹni tí a kó wàhálà ọkàn bá nígbà tí a bá yánhànhàn fún ohun kan ṣùgbọ́n tí kò bọ́ síi. Owe 13:12 sọ pé: “Ìrètí pípẹ́ mú ọkàn ṣàìsàn.” Bóyá irú ìmọ̀lára tí o ní nìyí bí o bá ń yánhànhàn láti gbéyàwó ṣùgbọ́n tí ọ̀ràn-ìnáwó kò jẹ́ kí o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí lè jẹ́ tòótọ́ ní pàtàkì bí o bá wà lára àwọn tí aposteli Paulu ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n ní “ìfẹ́ onígbòónára.”—1 Korinti 7:9.
Bíborí àwọn ìṣòro náà lè jẹ́ ohun tí kò rọrùn, ṣùgbọ́n àwọn ohun tí o lè ṣe wà láti faradà á àti pàápàá láti rí ìdùnnú-ayọ̀ nínú ipò rẹ. Jesu Kristi, ọkùnrin kan tí kò gbéyàwó, fi ìlànà Bibeli tí ó gbéṣẹ́ lélẹ̀ tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí ìjákulẹ̀ tí ń wá láti inú ìrètí pípẹ́. Ó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà ninu fífúnni ju èyí tí ó wà ninu rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
O lè fi èyí sílò nípa ṣíṣe ohun tí ó dára fún ìdílé rẹ àti fún àwọn mìíràn nínú ìjọ. Bóyá o tilẹ̀ lè fi kún ìgbòkègbodò rẹ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian. Bí o bá mú kí ọwọ́ rẹ dí púpọ̀ nínú ìfúnni aláìmọtara-ẹni-nìkan, o lè rí i pé o ‘pinnu tán ninu ọkàn-àyà rẹ, tí o ní ọlá-àṣẹ lórí ìfẹ́-inú ara rẹ.’—1 Korinti 7:37.
Aposteli Paulu, ọkùnrin mìíràn tí kò gbéyàwó, kọ ìmọ̀ràn tí ó wúlò yìí pé: “Ẹ máa ṣọ́ra láìgbagbẹ̀rẹ́ pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nitori pé awọn ọjọ́ burú pin.” (Efesu 5:15, 16) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristian tí kò gbéyàwó tàbí lọ́kọ ti rí ‘ìtura fún ọkàn wọn’ nípa lílo àkókò wọn láti túbọ̀ súnmọ́ Jehofa nípasẹ̀ àdúrà, ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, àti kíkópa nínú àwọn ìpàdé Kristian. (Matteu 11:28-30) Bí o bá ṣe èyí, ìwọ yóò lè kojú ipò ìṣúnná-owó tí ó ṣòro pẹ̀lú àṣeyọrí. Yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàfihàn ohun ti ẹ̀mí tí ó tilẹ̀ ga síi, yóò sọ ọ́ di ọkọ tàbí ìyàwó tí ó dára síi bí o bá gbéyàwó tàbí lọ́kọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.
Máṣe gbàgbé láé pé Jehofa bìkítà nípa gbogbo àwọn tí ń ṣiṣẹ́sìn-ín. Ó mọ àwọn ìṣòro àti ìnira tí o ń jìyà rẹ̀. Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ tún mọ ohun tí ó dára jùlọ fún ọ ní ọjọ́-ọ̀la, nípa ti ẹ̀mí àti nípa ti èrò-ìmọ̀lára. Bí o bá fi pẹ̀lú sùúrù fi àwọn ìlànà Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò nínú ìgbésí-ayé rẹ ojoojúmọ́, jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé òun yóò mú ìtura wá láìpẹ́ yóò sì tẹ́ àìní àti ìfẹ́-ọkàn rẹ lọ́rùn ní ọ̀nà tí yóò jẹ́ fún ire rẹ títí láé. Bibeli mú un dáni lójú pé: “Jehofa fúnra rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohun rere kankan sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn láìlálèébù.”—Orin Dafidi 84:11, NW.
Máa Wo Ohun Rere Tí Ó Wà Nínú Àwọn Nǹkan
Bakan náà, fi í sọ́kàn pé àwọn àǹfààní pàtó wà nínú wíwà láìlọ́kọ láìláya. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹni . . . tí ó fi ipò wúńdíá rẹ̀ fúnni ninu ìgbéyàwó ṣe dáadáa, ṣugbọn ẹni naa tí kò fi í fúnni ninu ìgbéyàwó yoo ṣe dáadáa jù.”—1 Korinti 7:38.
Èéṣe tí wíwà láìlọ́kọ láìláya fi ‘sàn ju’ gbígbéyàwó tàbí lílọ́kọ lọ? Paulu ṣàlàyé pé: “Ọkùnrin tí kò gbéyàwó ń ṣàníyàn fún awọn ohun ti Oluwa, bí oun ṣe lè jèrè ojúrere ìtẹ́wọ́gbà Oluwa. Ṣugbọn ọkùnrin tí ó gbéyàwó ń ṣàníyàn fún awọn ohun ti ayé, bí oun ṣe lè jèrè ojúrere ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀, ó sì pínyà lọ́kàn. Síwájú sí i, obìnrin tí kò lọ́kọ, ati wúńdíá, ń ṣàníyàn fún awọn ohun ti Oluwa, pé kí oun lè jẹ́ mímọ́ ninu ara rẹ̀ ati ninu ẹ̀mí rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, obìnrin tí a ti gbéníyàwó ń ṣàníyàn fún awọn ohun ti ayé, bí oun ṣe lè jèrè ojúrere ìtẹ́wọ́gbà ọkọ rẹ̀.”—1 Korinti 7:32-34.
Ní èdè mìíràn, àwọn Kristian tí wọ́n gbéyàwó tàbí lọ́kọ dàníyàn lọ́nà tí ó tọ́ nípa àwọn ohun tí ẹnìkejì wọn nínú ìgbéyàwó nílò, àwọn ohun tí ó nífẹ̀ẹ́ sí, àti àwọn ohun tí kò nífẹ̀ẹ́ sí. Ṣùgbọ́n àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ kòlọ́kọ kòláya lè tẹjúmọ́ iṣẹ́-ìsìn Jehofa pẹ̀lú ìpọkànpọ̀ tí ó ga. Bí a bá fi wọ́n wé àwọn tí wọ́n gbéyàwó tàbí lọ́kọ, ó rọrùn fún àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ kòlọ́kọ kòláya láti “ṣiṣẹ́sin Oluwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn.”—1 Korinti 7:35.
Paulu kò sọ pé Kristian tí ó jẹ́ kòlọ́kọ kòláya kò ní ìpínyà-ọkàn. Bí ìṣòro ọrọ̀-ajé bá di ẹrù-ìnira rù ọ́, o lè nímọ̀lára pé ohun púpọ̀ wà tí ń halẹ̀ láti pín ọkàn rẹ níyà kúrò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, òmìnira ara-ẹni láti sin Ọlọrun sábà máa ń pọ̀ jù fún ọkùnrin tàbí obìnrin tí kò gbéyàwó tàbí lọ́kọ ju bí ó ti rí fún àwọn tí wọ́n ti gbéyàwó tàbí lọ́kọ.
Nígbà tí ó ń dámọ̀ràn wíwà láìlọ́kọ láìláya gẹ́gẹ́ bí ipa-ọ̀nà tí ó sàn jù, aposteli Paulu kò sọ pé ó lòdì láti gbéyàwó tàbí lọ́kọ. Ó kọ̀wé pé: “Bí iwọ bá tilẹ̀ gbéyàwó, iwọ kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” Síbẹ̀, ó kìlọ̀ pé: “Awọn wọnnì tí wọ́n [gbéyàwó tàbí lọ́kọ] yoo ní ìpọ́njú ninu ẹran-ara wọn.”—1 Korinti 7:28.
Kí ni ó ní lọ́kàn pẹ̀lú ìyẹn? Ìgbéyàwó máa ń mú àwọn àníyàn kan wá. Ní àwọn àkókò tí ọrọ̀-ajé kò rọgbọ, irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ lè ní nínú àníyàn bàbá kan nípa pípèsè fún ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀. Àìsàn pẹ̀lú lè mú àlékún ẹrù-ìnira nípa ti ìṣúnná-owó àti ti èrò-ìmọ̀lára wá fún ìdílé náà.
Nítorí náà nígbà tí ipò rẹ lè má jẹ́ ohun tí o yàn láàyò, o lè wà ní ipò tí ó dára ju bí ìwọ ìbá ti wà lọ bí ó bá jẹ́ pé o gbéyàwó tí o sì ní ẹrù-iṣẹ́ láti pèsè fún àwọn ọmọ. Àwọn ìṣòro tí o ń dojúkọ nísinsìnyí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀; wọn yóò dópin nínú ètò-ìgbékalẹ̀ titun Ọlọrun—àwọn mìíràn pàápàá sì tilẹ̀ lè jẹ́ láìpẹ́.—Fiwé Orin Dafidi 145:16.
O Ha Lè Mú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Síi Bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan láti kówọnú iṣẹ́-ìsìn alákòókò-kíkún láìka àwọn ìṣòro ti ọ̀ràn-ìnáwó sí. Chuks, tí a mẹ́nu kàn ṣáájú, ń ra ìwé fún títà láti gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Ní nǹkan bí àsìkò kan náà tí ìwéwèé ìgbéyàwó rẹ̀ foríṣánpọ́n, ó rí lẹ́tà kan gbà tí ń késí i láti ṣiṣẹ́ ìkọ́lé fún ìgbà díẹ̀ ní ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ti àdúgbò. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, nítorí àníyàn nípa owó. Bí ó ti wù kí ó rí, Chuks ronú pé Jehofa ti ran òun lọ́wọ́ láti dá okòwò ìwé títà sílẹ̀, nítorí náà òun níláti fi ire Ìjọba sí ipò kìn-ínní kí òun sì gbẹ́kẹ̀lé agbára Ọlọrun láti pèsè. (Matteu 6:25-34) Yàtọ̀ sí èyí, ó ronú pé, ṣebí kìkì fún oṣù mẹ́ta péré ni.
Chuks tẹ́wọ́gba ìkésíni náà ó sì gbé okòwò náà fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, Chuks ṣì wà nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún, ó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ Kristian, níti ọ̀ràn-ìnáwó sì nìyí ó ti ṣetán láti gbéyàwó. Òun ha kábàámọ̀ nípa bí nǹkan ti yọrí sí nínú ìgbésí-ayé rẹ̀ bí? Chuks sọ pé: “Ó dùn mí nígbà tí n kò lè gbéyàwó nígbà tí mo fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n nítòótọ́ nǹkan yọrí sí rere fún mi. Mo ti ní ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdùnnú-ayọ̀ àti àǹfààní iṣẹ́-ìsìn tí ó ṣeé ṣe kí n má ti gbádùn bí ó bá jẹ́ pé mo ti gbéyàwó nígbà yẹn lọ́hùn ún tí mo sì ti ní ìdílé.”
Àìléwu fún Ọjọ́-Ọ̀la
Ní àwọn ìgbà tí ó lekoko ọ̀pọ̀ ń wá àìléwu ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ààbò fún ìṣòro ọ̀ràn-ìnáwó ọjọ́-ọ̀la. Àwọn orílẹ̀-èdè kan, tí gbèsè ti dẹrùpa, kì í lè pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn àgbàlagbà. Nítorí náà ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn òbí máa ń gbọ́kànlé àwọn ìdílé wọn, àti ní pàtàkì lé àwọn ọmọ wọn, láti gbọ́ bùkátà wọn nígbà ọjọ́-ogbó. Nítorí ìdí èyí, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ kòlọ́kọ kòláya ni a sábà máa ń fúngun mọ́ láti gbéyàwó tàbí lọ́kọ kí wọ́n sì bímọ, àní bí ipò ọ̀ràn-ìnáwó wọn bá tilẹ̀ wà ní ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́-ewu.
Ṣùgbọ́n ìgbéyàwó àti ọmọ bíbí kò mú ìdánilójú àìléwu wá. Àwọn ọmọ kan nínú ayé kò ṣetán láti bìkítà fún àwọn òbí tí wọ́n ti dàgbà, àwọn mìíràn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà tí àwọn mìíràn sì ń kú ṣáájú àwọn òbí wọn. Àwọn Kristian ń wo ibòmíràn ní pàtàkì fún àìléwu, níti pé wọ́n fi ohun tí ìlérí Ọlọrun sọ sọ́kàn pé: “Dájúdájú emi kì yoo fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tabi ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.”—Heberu 13:5.
Àwọn tí wọ́n ti sún ìgbéyàwó síwájú láti sin Jehofa ní àkókò-kíkún ni a kò ṣá tì. Christiana kò lọ́kọ ó sì jẹ́ ẹni ọdún 32. Ó ti ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà ní Nigeria láti ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Mo gbẹ́kẹ̀ mi lé Jehofa, ẹni tí ó fi dá wa lójú pé òun kì yóò pa àwọn ìránṣẹ́ òun tì. Ìlérí rẹ̀ ni ìgbọ́kànlé mi. Jehofa ń bójútó mi nípa ti ẹ̀mí àti nípa ti ara. Ó ti fi ẹ̀rí jíjẹ́ Bàbá ọlọ́làwọ́ hàn. Fún àpẹẹrẹ, mo ṣí lọ láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní àdúgbò kan níbi tí àìní fún àwọn Ẹlẹ́rìí ti pọ̀ gidigidi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun amáyédẹrùn díẹ̀ ni ó wà, mo ti kọ́ láti máa bá a yí. Nígbà tí a dá mi dúró sí ilé ìwòsàn nítorí àrùn typhus, àwọn arákùnrin tí wọ́n wà ní ìjọ ibi tí mo wà tẹ́lẹ̀ rọ̀gbà yí mi ká láti ṣàtìlẹyìn fún mi.
“Mo ní ìtẹ́lọ́rùn gidigidi pẹ̀lú iṣẹ́-ìsìn alákòókò-kíkún. Mo kà á sí àǹfààní tí ó kọyọyọ láti máa bá Ẹlẹ́dàá àgbáyé ṣiṣẹ́ papọ̀ àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ arákùnrin àti arábìnrin káàkiri ayé. Mo ń rí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ yí wọn ká ti já kulẹ̀ tí wọn kò sì ní ìrètí. Níti èmi, ìgbésí-ayé mi nítumọ̀; mo ń wo ọjọ́-ọ̀la pẹ̀lú ìgbọ́kànlé. Mo mọ̀ pé dídi ẹni tí ó súnmọ́ Jehofa ni ojútùú tí ó dára jùlọ sí àwọn ìṣòro tí a ń dojúkọ lónìí.”
Bí o bá ń yánhànhàn láti gbéyàwó tàbí lọ́kọ ṣùgbọ́n tí o kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìṣòro ètò ọrọ̀-ajé, mọ́kànle! O kò dáwà. Ọ̀pọ̀ wà tí ń farada àdánwò tí ó farajọ èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa. Lo àǹfààní ipò rẹ bí ó bá ti lè ṣee ṣe tó nípa fífi ara rẹ fún ṣíṣe nǹkan rere fún àwọn mìíràn àti nípa mímú ipò rẹ nípa ti ẹ̀mí sunwọ̀n síi. Fà súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọrun; òun yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nítorí ó bìkítà nípa rẹ.—1 Peteru 5:7.