ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 5/1 ojú ìwé 4-7
  • Kikoju Iwa Ọdaran Ninu Ayé Rúdurùdu Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kikoju Iwa Ọdaran Ninu Ayé Rúdurùdu Kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ero Ori Ọdaran ati Idajọ-ododo
  • Ọgbọn Aṣeemulo ati Ori Pipe
  • Ki ni Bi A Ba Fipa Jà Ọ Lole?
  • Igba ti Iwa Ọdaran Yoo Dawọ Duro
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ọlọ́pàá Lọ́jọ́ Iwájú?
    Jí!—2002
  • Iwa Ọdaran Ninu Aye Rúdurùdu Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jíjìjàdù Láti Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn
    Jí!—1996
  • Ogun Àjàpàdánù Tí A Ń Bá Ìwà Ọ̀daràn Jà
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 5/1 ojú ìwé 4-7

Kikoju Iwa Ọdaran Ninu Ayé Rúdurùdu Kan

IWỌ ha nbẹru lati jade ni alẹ bi? O ha nilo kọkọrọ meji tabi mẹta si awọn ẹnu ilẹkun ati fèrèsé rẹ bi? A ha ti ji ọkọ̀ tabi kẹkẹ rẹ lọ ri bi? A ha ti ji redio inu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lọ bi? O ha ni imọlara ipaya ni awọn agbegbe kan bi?

Bi iwọ ba dahun bẹẹni si eyikeyi ninu awọn ibeere wọnyi, nigba naa iwọ ngbiyanju lati koju iwa ọdaran ninu aye rúdurùdu kan. Ki ni iwọ le ṣe nipa rẹ? Bibeli ha le ran ọ lọwọ lati koju rẹ bi?

Ero Ori Ọdaran ati Idajọ-ododo

Ninu aye ọdaran, awọn ohun mẹta pataki ni o wa: awọn ọdaran, awọn ọlọpaa ati awọn ojiya iwa ipa. Ki ni o pọndandan ki iwọ, ti o ṣeeṣe ki o jẹ ojiya ṣe ki o ba le koju iwa-ọdaran?. O ha le nipa lori eyikeyi ninu awọn ohun mẹta wọnyi bi? Fun apẹẹrẹ, o ha le yi awọn ọdaran pada bi?

Ọpọ awọn ọdaran ti mu iwa-ọdaran gẹgẹ bi iṣẹ igbesi-aye. Wọn ti yàn án gẹgẹ bi ọna igbesi aye ti o rọrun. ‘Eeṣe ti o fi nṣiṣẹ nigba ti o le jifa iṣẹ ọwọ awọn ẹlomiran?’ ni o jọ pe o jẹ ironu wọn. Awọn ọlọṣa mọ pe ọpọjulọ awọn ojiya iwa ipa ni yoo jọ̀wọ́ owo wọn láìjampata. Ati pẹlu iwọn ṣiṣeeṣe naa pe a o mu wọn ki a si ran wọn lọ sinu ọgba ẹwọn ti o kere gan an, fun wọn iwa ọdaran lere.

Siwaju sii, awọn ilana itolesẹẹsẹ ile ẹjọ díjú o si maa ngba akoko. Ni ọpọ awọn orilẹ ede, iwọnba awọn ile ẹjọ, adajọ ati ọgba ẹwọn ni o wa. Tí igbẹjọ awọn ọdaran si bo eto naa mọlẹ. Idajọ ni a fi nfalẹ ti ipo naa si ri bi Bibeli ti ṣapejuwe rẹ ni nnkan ti o ju ẹgbẹrun ọdun mẹta sẹhin pe: “Nitori a ko mu idajọ ṣe kánkán si iṣẹ buburu, nitori naa aya awọn ọmọ eniyan mura paapaa lati huwa ibi.” Gẹgẹ bi ilana Bibeli yii ṣe fihan, ireti diẹ ni o wa si ojutuu naa nipa didin iye awọn ọdaran kù tabi yiyi wọn lọkan pada.—Oniwaasu 8:11.

Ki ni nipa ohun keji, awọn ọlọpaa? Ireti kankan ha wa pe awọn ọlọpaa yoo ṣe ikawọ awọn ọran naa? Awọn funraawọn yoo dahun: Pẹlu awọn ofin ti nsaba nja fun ẹtọ awọn ọdaran, pẹlu awọn amofin aláìlẹ́rìí ọkan ti wọn yi ofin po ni mimu ki ọdaran lọ laijiya, pẹlu awọn ara ilu ti nlọtikọ lati pese owo fun kíkọ́ awọn ọgba ẹwọn ti o pọ ti o si tobi sii, ati pẹlu aito awọn ọlọpaa, iwọnba diẹ ni wọn le ṣe lati din iwa ọdaran ku.

O ku ohun kẹta, awọn ti o ṣeeṣe fun lati di ojiya iwa ọdaran: awa, ará ilu. Ohun kan ha wa ti a le ṣe lati fi ran ara wa lọwọ sii ni kikoju ipo oniwa ailofin yii?

Ọgbọn Aṣeemulo ati Ori Pipe

Iwe Bibeli naa Owe wipe: “Pa ọgbọn ti o yè ati imoye mọ, bẹẹ ni wọn o maa jẹ iye si ọkan rẹ, ati oore ọ̀fẹ́ si ọrùn rẹ. Nigba naa ni iwọ o maa rin ọna rẹ lailewu, ẹsẹ rẹ ki yoo si kọ.” Imọran yii le ṣee fisilo labẹ awọn ipo ti o le sọni di ojiya iwa ọdaran. Ki ni awọn ọna ti ọgbọn ṣiṣeemulo le gba ran wa lọwọ labẹ ipo yii?—Owe 3:21-23.

Awọn ọdaran dabi awọn ẹranko ẹhanna adọdẹ ounjẹ. Wọn nwa awọn ijẹ ti o rọrun julọ. Wọn ko fẹ dagbale ewu jija ijakadi ati didi ẹni ti o ṣeeṣe ki a mú bi wọn ba le ri ohun kan naa gba lọwọ ojiya ti o rọrun. Nitori naa wọn ndọdẹ awọn agbalagba, awọn alailera, awọn ti ọkan wọn dàrú ati awọn ti ko fura si ipo elewu naa. Awọn jàǹdùkú naa nyan awọn akoko ati ibi ti o rọrun fun wọn lati ta jàm̀bá. Nihin-in ni awọn ti o ṣeeṣe ki wọn di ojiya ọdaran ti le lo ọgbọn ti o ṣee mulo.

Gẹgẹbi Bibeli ti ṣapejuwe wọn, awọn olufẹ ibi saba maa nṣe awọn iṣẹ wọn labẹ ìbòjú okunkun. (Roomu 13:12; Efesu 5:11, 12) O jẹ otitọ lonii pe ọpọ awọn iwa ọdaran ti a ṣe lodisi awọn eniyan ati awọn ohun ìní ni a ṣe ni ọwọ́ alẹ́. (Fiwe Joobu 24:14; 1 Tẹsalonika 5:2.) Nitori naa, nibi ti o ba ṣeeṣe ọlọgbọn eniyan yoo yẹra fun wiwa ni awọn agbegbe elewu ni alẹ. Ni ilu nla New York nibi ti iwa ọdaran ti njọba, akọsilẹ ojoojumọ awọn ọlọpaa fihan pe awọn eniyan ni a nfipa jalole ni alẹ́, paapaa julọ lẹhin agogo mẹwaa alẹ, lọpọ igba bi wọn ti npada lọ si ibugbe wọn. Awọn adọdẹ ounjẹ naa maa ńwà ni awọn opopona ti ẹnikẹni ko gbà kọja ti wọn ndọdẹ awọn ojiya iwa ọdaran. Nitori naa, bi o ba nilati pinnu lati duro de ọkọ tabi takisi tabi ki o fẹsẹ rin la awọn agbegbe elewu kọja, ni suuru ki o si duro na. Bi bẹẹkọ iwọ lè ni iriri kikoro kan.

Kristian kan ni a lu ti a si jí ní ohun ìní lọ nigba ti, dipo ki o duro de bọọsi ni nnkan bi agogo mẹwaa alẹ, o rin irin ẹsẹ bata diẹ ninu okunkun fẹ́ẹ́rẹ́. Awọn eniyan miiran wa ni opopona naa, ṣugbọn awọn jaguda mẹta ti dẹ páńpẹ́ fun alaifura naa. Ọkan ninu wọn wawọ́ si awọn iyoku rẹ nigba ti ẹni ti o ṣeeṣe ki o di ojiya iwa ọdaran yọ ni okere opopona naa. Laisọ ohun kan, wọn rọlu ojiya iwa ọdaran naa wọn si ji ohun ìní rẹ̀ lọ. O dopin ni kiakia debi pe ko si àyè fun aladuugbo lati le dasi i. Ojiya iwa ọdaran naa gba lẹhin naa pe: “Ni ọjọ miiran emi yoo duro de bọọsi.”

“Artful Dodger,” jaguda ọdọ kan ninu iwe itan Dickens Oliver Twist, jẹ apẹẹrẹ fífararọ ni ifiwera si iwa ẹṣẹ ti awọn ọ̀dọ́ ńdá ni awọn opopona ni ode oni. Laidabi Artful Dodger, awọn ole ati ọlọṣa ti oni, laika ọjọ ori wọn si, ni o ṣeeṣe ki wọn gbe ibọn tabi ọbẹ, ki wọn si lo wọn. Awọn arinrin ajo ti wọn ti ṣìnà, awọn alejo ati awọn onírìn ìgbafẹ́ ni ilu-nla ti o kun fọ́fọ́ kan jẹ ijẹ ti o rọrun fun iru awọn ọdaran aláìlẹ́rìí ọkàn. Wọn ti ji gbogbo ohun ti o wa larọwọto ki o to ṣẹju pẹ́kẹ́! Ki ni o le wọ ole kan loju? Ẹ̀gbà ọrùn oniwura kan tabi awọn ohun ọṣọ olowo iyebiye miiran ti a wọ sode ara. Tabi Kamẹra kan ti nfi dirodiro lọrun arinrin ajo kan. Ṣe ni o dabi igba ti eniyan gbe ami kan sọrun ti o sọ pe, “Wa gbe mi!” Nitori naa, a nilo iṣọra tẹlẹ. Pa ohun ẹṣọ oniyebiye eyikeyii mọ, ki o si gbe Kamẹra naa ni ọna ti awọn eniyan ko ni tete ri i, boya ki o fi pamọ sinu apo àmúrọjà kan. Eyi jẹ ọgbọn ti o ṣee mulo.

Wiwa lojufo tun jẹ ọna miiran ti a le gba koju iwa ọdaran. Bibeli wipe: “Oju ọlọgbọn nbẹ ni ori rẹ; ṣugbọn aṣiwere nrin ni okunkun.” (Oniwaasu 2:14) Fifi ikilọ yii silo ninu iṣoro iwa ọdaran yoo sún ẹnikan lati ṣakiyesi awọn eniyan ti nrin gbéregbère lọna tí o ṣee fura si laini ete pato kan. Ṣọra fun awọn ole ti o le gba ẹhin já apo rẹ gbà bi o ti nrin ni ẹ̀bá ọna. Niwọn bi awọn kan ti nja ohun ìní awọn ẹlomiiran gbà bi wọn ti ngun kẹkẹ sare kọja lọ, maṣe rin ni igun ẹba ọna, paapaa julọ bi o ba gbe iru apoti ẹru tabi apo ifalọwọ eyikeyii dani. Yẹra fun awọn ọkọ ayọkẹlẹ oju ọna ti ko si ero ninu wọn. Aabo pupọ wà fun ọ nibiti ọgọọrọ awọn eniyan wa ati nibiti imọlẹ pọ si. Awọn ole kii fẹ ki a ṣakiyesi wọn ki a si da wọn mọ.

Ìfọ́lé jẹ iwa-ọdaran miiran ti o gbajumọ ti a le yẹra fun bi awọn eniyan ba tubọ wa lojufo nipa iwa ipa. Ni ọna ti o tọna Bibeli lo ifiwera naa: “Wọn gba oju ferese wọle bi ole.” (Joẹli 2:9) Ọgbọn ti o ṣee mulo beere pe ki o maṣe fi awọn ilẹkun tabi awọn ferese rẹ silẹ láìtì. O si maa nfi igbagbogbo jẹ otitọ pe ìṣèdènà arun san ju iwosan rẹ lọ. Inawo diẹ si lati fi daabobo ile rẹ nitootọ jẹ aabo lodisi ole jija ati ipalara ara.

Ki ni Bi A Ba Fipa Jà Ọ Lole?

Bẹẹni, pẹlu gbogbo awọn iṣọra tẹlẹ rẹ, ki ni bi ọlọṣa kan bá dá ọ duro? Gbiyanju lati maṣe foya tabi yara kankan lati gbe igbesẹ eyikeyi. Ranti pe ole naa le maa bẹru pẹlu o si le ṣi awọn igbesẹ rẹ tumọ. Gbiyanju lati sọrọ ki o si ba ẹni naa ronu papọ bi oun yálà lọkunrin tabi lobinrin ba yọnda fun un. (Bẹẹni, ẹni ti ngbeja kò ọ le jẹ obinrin.) Nigba miiran awọn ọlọṣa ni wọn maa nṣe wọ̀ọ̀ nigba ti wọn ba mọ pe ojulowo ati alailabosi Kristian ni awọn ngbeja kò. Laika ihuwa pada wọn si, maṣe gbiyanju lati kọju ija si wọn bi o ba jẹ pe owo rẹ tabi awọn ohun ìní rẹ ni wọn nfẹ. Fun wọn ni ohunkohun ti wọn ba beere fun. Bibeli kọni pe ẹmi eniyan san ju ohunkohun ti o le ni lọ.—Fiwe Maaku 8:36.

Laijẹki o dabi pe o nṣayẹwo rẹ fínnífínni, gbiyanju lati ṣakiyesi ami idanimọ ti o yatọ ti ọlọṣa naa le ni, boya niti aṣọ wiwọ tabi irisi ara. Bawo ni oun ṣe npe ọrọ? Gbogbo awọn kulẹkulẹ wọnyi le wulo nigba ti o ba nrohin iwa-ọdaran naa fun awọn ọlọpa, niwọnbi ọpọjulọ awọn ọdaran ni wọn jẹ oluṣedeedee ni ọna igbayọsini olukuluku wọn ti o si le tipa bayii mu ki o tubọ rọrun lati da wọn mọ.

Ki ni nipa nini ohun ija fun igbeja ara ẹni? Dajudaju ko ni jẹ ohun ti o bọgbọn mu fun Kristian kan lati ni ohun ija. Bi janduku kan ba ronu pe iwọ ńnàgà lati mu ohun ija kan, oun ki yoo fi ọ̀kan pe meji nipa ṣiṣe ọ leṣe tabi pipa ọ. Siwaju sii, bawo ni iwọ ṣe le tẹle ilana Bibeli naa lati “wà ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan” bi iwọ ba dihamọra lati doju ija kọ ẹni ti o doju ija kọ ọ́?—Roomu 12:18.

Laika awọn iṣọra tẹlẹ ti o le ṣe si, ko si idaniloju pe iwọ ki yoo di ojiya iwa ọdaran ni ọjọ kan. Ni awọn ilu nla ti o kun fun iwa ọdaran, yoo kàn iwọ naa bi o ba wa ni ibi ti ko yẹ ni akoko ti ko yẹ. Laipẹ yii ni New York, amofin kan fi ibi iṣẹ rẹ silẹ lati lọ ra ife Kọfi kan. Bi o ṣe wọ ile ìtajà naa, awọn ọdọ kan wa ọkọ kọja wọn si yinbọn sibẹ. Amofin naa ni a pa pẹlu ọta ibọn kan ti a yin lù u ni ori. Nitori “ìgbà ati èèṣì,” oun padanu iwalaaye rẹ. Iru ibanujẹ wo ni eyi! Ireti eyikeyii ha wà fun ojutuu wíwà títí fun ọpọ jáǹtì rẹrẹ iwa ọdaran ti lọọlọọ yii ti o bo aye mọlẹ?—Oniwaasu 9:11.

Igba ti Iwa Ọdaran Yoo Dawọ Duro

Ni nnkan ti o fẹrẹẹ to ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, Jesu sọ asọtẹlẹ pe iran kan yoo wà ti yoo ri awọn iṣẹlẹ ti nbani lẹru ju iran eyikeyi ti o ti wà ri lọ. Pẹlu ẹrọ amóhùn máwòrán ati ibanisọrọpọ lẹsẹkẹsẹ, araadọta ọkẹ, bẹẹkọ, araadọta ọkẹ lọna ẹgbẹgbẹrun, ni wọn nṣẹlẹrii awọn iwa buburu gan an bi a ti ńhù wọn ninu orisun irohin adugbo wọn. Aye ti di abule kan, irohin agbaye si ndi irohin adugbo lọgan. Nitori idi eyi, iṣẹlẹ otitọ ni nwọle wa ni ojoojumọ, ati gẹgẹbi Jesu ṣe sọ awọn asọtẹlẹ rẹ, awọn eniyan pupọ “yoo maa daku lati inu ibẹru ati ifojusọna fun awọn ohun ti nbọ wa sori ilẹ aye.”—Luuku 21:26, New World Translation.

Jesu ti ri awọn iṣẹlẹ ti o ti nṣẹlẹ bẹrẹ lati 1914 ṣaaju, awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣaaju “opin eto igbekalẹ awọn nnkan isinsinyi.” (Matiu 24:3-14) Ṣugbọn oun tun wipe: “nigba ti ẹyin ba ri awọn nnkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹyin ki o mọ pe ijọba Ọlọrun kù si dẹdẹ.” (Luuku 21:31) Eyi tumọ si pe iṣakoso ododo Ọlọrun laipẹ yoo nipa lori aye lọna ti o galọla.—Matiu 6:9, 10; Iṣipaya 21:1-4.

Labẹ iṣakoso yẹn, kiki awọn ọlọkan tutu, awọn olufẹ alaafia ati awọn ti wọn jẹ onigbọran si Ọlọrun ni yoo ṣajọpin awọn ipo Paradise ilẹ-aye. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ọdaran ati awọn oluṣe buburu? “Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bii koriko, wọn o si rọ bi eweko tutu. Nitori ti a o ke awọn oluṣe buburu kuro, ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa [“Jehofa,” NW] ni yoo jogun aye.” Labẹ iṣakoso ododo atọrunwa yẹn, ki yoo si yala ohun rúdurùdu tabi iwa ọdaran.—Saamu 37:2, 9.

Bi iwọ yoo ba fẹ mọ pùpọ si i nipa ireti ti a gbe kari Bibeli yii ti iṣakoso aye alalaafia ti yoo wa pẹ́ titi, tọ awọn Ẹlẹrii Jehofa ti wọn wa ni adugbo rẹ lọ tabi ni Gbọngan Ijọba wọn ti adugbo. Wọn yoo fi pẹlu inudidun ràn ọ lọwọ lati loye Bibeli, lọfẹẹ laigba kọbọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Nitori ti a o ké awọn oluṣe buburu kuro, ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa [“Jehofa,” NW] ni yoo jogun aye”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Artful Dodger, jaguda inu iwe Charles Dickens, jẹ ọgbẹri ni ifiwera pẹlu awọn ọlọṣa ode oni

[Credit Line]

Iṣẹ Aworan GEORGE CRUIKSHANK, lati ọwọ Richard A. Vogler, Awọn Itẹjade Dover, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́