ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 5/1 ojú ìwé 3-4
  • Iwa Ọdaran Ninu Aye Rúdurùdu Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iwa Ọdaran Ninu Aye Rúdurùdu Kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kikoju Iwa Ọdaran Ninu Ayé Rúdurùdu Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jíjìjàdù Láti Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn
    Jí!—1996
  • Ogun Àjàpàdánù Tí A Ń Bá Ìwà Ọ̀daràn Jà
    Jí!—1998
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ọlọ́pàá Lọ́jọ́ Iwájú?
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 5/1 ojú ìwé 3-4

Iwa Ọdaran Ninu Aye Rúdurùdu Kan

IWA ỌDARAN kii ṣe iṣẹlẹ ode oni kan. Ipaniyan akọkọ ṣelẹ ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹhin nigba ti Kaini pa arakunrin rẹ Abẹli. Ifipabanilopọ ati ìbẹ́yà kanna lòpọ̀ ni a mẹnukan ninu Iwe Mimọ lede Heberu ti igbaani. (Jẹnẹsisi 4:8; 19:4, 5; 34:1-4) Awọn eniyan ni a fipa jàlólè ninu ọgọrun-un ọdun kìn-ínní ti Sanmani Tiwa, gẹgẹ bi àkàwé ti ara Samaria rere ti fi han. (Luuku 10:29-37) Ṣugbọn iyatọ kan wà lonii.

Imọlara awọn eniyan ninu ọpọ awọn ilu nla aye, ìbáà ṣe New York, London, Calcutta, tabi Bogotá, ni pe iwa ọdaran tubọ ngbodekan ti o si tubọ ńkó ipaya bani. Irohin kan lati inu iwe irohin India Today ti o gbé akọle naa jade “Iwa ailofin di aṣa ti o gbajumọ” wipe: “Idagbasoke ayọnilẹnu ti nhalẹ lati fa ohun ẹlẹgẹ́ iwarere ati aṣọ ẹgbẹ oun ọgba ya tí ó so orilẹ ede pọ ni ilọsoke iwa ipa, àìlẹ́kọ̀ọ́ tí ó mú àìbọ̀wọ̀ funni dani ati iwa ailofin ti o di gbajumọ.” Ninu ijakadi wọn lodi si iwa-ọdaran, awọn ọlọpa paapaa ni a dẹwo lati rekọja aala fifi ipa mofinṣẹ, ti wọn si nlo ọna iwa ọdaran funraawọn. Irohin iṣaaju lati India wipe: “Awọn ti wọn ńkú sinu ahamọ ọlọpa ni wọn tubọ npọ sii.” Eyi si jẹ otitọ ni awọn ilẹ miiran pẹlu.

Ṣiṣeeṣe lati di ojiya iwa ọdaran ni o tubọ nburu sii. Irohin kan lati United States wipe: “Ẹyọkan ninu mẹrin awọn agbo ile ni America ni iriri iwa-ọdaran oniwa ipa tabi ijanilole ni 1988.” Pẹlupẹlu, awọn eniyan nisinsinyi nhuwa ọdaran oniwa ipa lati kekere. Iwe irohin Latin America naa Visión wipe “mẹsan ninu gbogbo sicarios [awọn apaniyan ti a nsanwo fun] mẹwaa jẹ ọmọde. [Wọn jẹ] ‘awọn ọmọde’ bi a ba nsọrọ nipa idagbasoke wọn si wa labẹ idaabobo ofin.” Siwaju sii, kari aye ni awọn ọmọde ti nhuwa ọdaran oniwa ipa.

Bibeli sọ asọtẹlẹ ni nnkan bii 2,000 ọdun sẹhin pe: “Ṣugbọn eyi ni ki o mọ, pe ni ikẹhin ọjọ igba ewu yoo de. Nitori awọn eniyan yoo jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, . . . aláìmọ́. Alainifẹ, . . . alaile kora wọn ni ijanu, onroro, alainifẹ ohun rere, onikupani, alagidi, ọlọkan giga. . . . Awọn eniyan buburu ati awọn ẹlẹtan yoo maa gbilẹ siwaju sii, wọn o maa tan eniyan jẹ, eniyan yoo si maa tan wọn jẹ.”—2 Timoti 3:1-4, 13.

Lati 1914, ẹ̀rí han gbangba pe awa ti ngbe ni awọn akoko lilekoko wọnni. Lẹhin iriri ogun agbaye meji ati awọn iforigbari ṣiṣe pataki miiran, ni ọpọlọpọ ọna ayé ti di rúdurùdu laiṣee ṣakoso. Iwa ọdaran gbilẹ. Ni ọpọ awọn agbegbe ilu nla, awọn ọdaran ti gba akoso, ti wọn si nyi aṣa igbesi-aye ọpọjulọ awọn ti npa ofin mọ pada. Gẹgẹ bi gbajumọ aṣofin U.S. kan ti wi: “Awọn ohun pupọ ni o wà lati daamu le lori nisinsinyi, awọn ohun ti a kii bẹru rẹ̀ tẹlẹ. Lọpọ igba ni a maa ndi ẹlẹwọn nitori ibẹru, nigba ti awọn ti o yẹ ki a timọle nrin kiri lominira.”

Nitori idi eyi, ọpọ awọn eniyan lonii ni wọn nlo iṣọra ti ko fi bẹẹ pọndandan ni 20 tabi 30 ọdun sẹhin. Awọn ilẹkun ni a nfi kọkọrọ meji tabi mẹta tì tí a si nfi irin tubọ mu wọn lagbara. Awọn eniyan ni ọpọ ibi ngbe owo ti o pọ to dani lati tẹ ọlọṣa lọrun pẹlu ireti ki a maa ba lù wọn nitori airi ohun fun ole. Ọpọ awọn opopona ni a nkọ silẹ lọwọ irọlẹ, ti o jẹ kiki awọn alaimọkan, olori kunkun, ati awọn ti ipo wọn mu pọndandan fun, ni o saba maa nrin nibẹ—ti wọn a si di ijẹ ti o rọrun fun awọn arẹnijẹ ti wọn ńwọ́ igboro ká.

Ki ni ohun ti a lè ṣe lati yẹra fun dídì ojiya iwa ọdaran ninu aye rúdurùdu alailofin yii? Bawo ni a ṣe le koju rẹ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́