ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/8 ojú ìwé 6-8
  • Jíjìjàdù Láti Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjìjàdù Láti Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú Ìwòye Yìí Ha Lòdì Jù Bí?
  • Àwọn Ìjọba Ń Gbìyànjú
  • Àìní Ìgbẹkẹ̀lé
  • Ogun Àjàpàdánù Tí A Ń Bá Ìwà Ọ̀daràn Jà
    Jí!—1998
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ọlọ́pàá Lọ́jọ́ Iwájú?
    Jí!—2002
  • Orílẹ̀-èdè Wo Ni Kò Ti Sí Ìwà Ọ̀daràn?
    Jí!—1996
  • Ìgbà Kan Tí Ìwà Ọ̀daràn Kò Sí
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 10/8 ojú ìwé 6-8

Jíjìjàdù Láti Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn

ÀKÒRÍ ọ̀rọ̀ kan nínú ìwé agbéròyìnjáde kan tí ó lókìkí ní ilẹ̀ Britain sọ pé: “Àwọn Ọ̀dọ́ Wí Pé Àárẹ̀ Ni Olórí Okùnfà Ìwà Ọ̀daràn Àwọn Màjèṣín.” Òmíràn sọ pé: “A Dẹ̀bi Ìbísí Ìwà Ọ̀daràn Ru Gbọ́nmisi-Omi-Òto Inú Ilé.” Ẹ̀kẹ́ta sì sọ pé: “Ìsọdibárakú ‘Ń Ṣokùnfà Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ìwà Ọ̀daràn.’” Ìwé ìròyìn Philippine Panorama fojú bù ú pé àwọn tí ń lo oògùn líle nílòkulò ní ń hu ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ìwà ọ̀daràn oníwà ipá ní Manila.

Àwọn kókó abájọ mìíràn tún lè máa kópa nínú títanná ran ìwà ọ̀daràn. Ọ̀kan tí ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ilẹ̀ Nàìjíríà mẹ́nu kàn ni “ipò òṣì ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ọrọ̀ kíkàmàmà.” A tún mẹ́nu ba ìkìmọ́lẹ̀ ojúgbà àti àǹfààní iṣẹ́ ṣíṣe tí kò dán mọ́rán, àìsí àwọn òfin ìdènà lílágbára, ìwólulẹ̀ níbi gbogbo nínú àwọn ànímọ́ ìdílé, àìsí ọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ àti òfin, àti ìwà ipá lílé kenkà nínú àwọn fíìmù àti fídíò.

Kókó abájọ mìíràn ni pé ọ̀pọ̀ ènìyàn kò gbà pé ìwà ọ̀daràn kò pé mọ́. Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ láàárín àwùjọ kan ní Yunifásítì Bologna ní Ítálì ṣàkíyèsí pé láàárín sáà ọ̀pọ̀ ọdún kan, “iye ìṣẹ̀lẹ̀ olè jíjà tí a fi sùn pọ̀ púpọ̀, nígbà tí iye àwọn ènìyàn tí a dá lẹ́bi nítorí wọn sì kéré púpọ̀.” Ó ṣàkìyèsí pé “iye ìdálẹ́bi náà ní ìpíndọ́gba pẹ̀lú iye ẹjọ́ olè jíjà tí a fi sùn ti wá sílẹ̀ láti orí ìpín 50 sí ìpín 0.7 nínú ọgọ́rùn-ún.”

Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bani nínú jẹ́, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ òtítọ́ ni ti ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica tí ó wí pé: “Ó jọ pé ìwà ọ̀daràn tí ń pọ̀ sí i ni àbùdá gbogbo àwọn àwùjọ oníṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní, kò sì sí ìgbékalẹ̀ òfin tàbí ìjẹni níyà kankan tí ó ṣeé tọ́ka sí pé ó ti nípa gúnmọ́ kan lórí ìṣòro náà. . . . Nínú ẹgbẹ́ àwùjọ ìgboro òde òní, tí a ti ka ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé àti àṣeyọrí ara ẹni sí ànímọ́ tí ó gborí jù lọ, kò sí ìdí láti rò pé ìwà ọ̀daràn kò níí máa pọ̀ sí i.”

Ojú Ìwòye Yìí Ha Lòdì Jù Bí?

Ipò náà ha burú tó bẹ́ẹ̀ ní ti gidi bí? Àwọn àdúgbò kan kò ha ń ròyìn pé ìwà ọ̀daràn ti dín kù bí? Òtítọ́ ni pé àwọn kan ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ oníṣirò lè ṣini lọ́nà. Fún àpẹẹrẹ, a ròyìn pé ìwà ọ̀daràn ní Philippines dín kù ní ìwọ̀n ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lẹ́yìn tí a ṣe òfin tí ó gbẹ́sẹ̀ lé ìbọn. Ṣùgbọ́n ìwé ìròyìn Asiaweek ṣàlàyé pé òṣìṣẹ́ onípò gíga kan gbà gbọ́ pé àwọn olè ajímọ́tò àti àwọn afọ́báńkì ti ṣíwọ́ jíjí mọ́tò àti fífọ́ báńkì, wọ́n sì ti “yí sí jíjí ọmọ gbé.” Fífọ́ báńkì àti jíjí mọ́tò gbé tí ó lọ sílẹ̀ díẹ̀ ti yọrí sí ìdínkù nínú iye àpapọ̀ ìwà ọ̀daràn, ṣùgbọ́n ìdínkù yìí pàdánù ọ̀pọ̀ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ lójú ìbísí onílọ̀ọ́po mẹ́rin nínú jíjí ọmọ gbé!

Nígbà tí ìwé ìròyìn HVG ń ròyìn nípa Hungary, ó kọ ọ́ pé: “Ní ìfiwéra pẹ̀lú iye ti apá ìdajì àkọ́kọ́ ọdún 1993, iye ìwà ọ̀daràn ti fi ìpín 6.2 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sílẹ̀. Ohun tí àwọn ọlọ́pàá gbàgbé láti mẹ́nu bà ni pé, ìdínkù náà . . . jẹ́ nítorí àwọn ìyípadà ètò ìṣàkóso ní pàtàkì.” Ní ti ìṣirò owó, fífi ẹ̀sùn olè jíjà, jìbìtì, àti ìmọ̀ọ́mọ̀ ba nǹkan jẹ́ sùn ti lọ sókè pẹ̀lú ìpín 250 nínú ọgọ́rùn-ún sí ti tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, a kì í ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìwà ọ̀daràn tí ó níí ṣe pẹ̀lú ohun ìní tí kò lówó lórí tó báyìí mọ́. Níwọ̀n bí àwọn ìwà ọ̀daràn tí ó níí ṣe pẹ̀lú ohun ìní sì ti jẹ́ ìpín mẹ́ta nínú mẹ́rin gbogbo ìwà ọ̀daràn ní orílẹ̀-èdè náà, ó ṣòro láti gbà gbọ́ pé ìdínkù náà jẹ́ òtítọ́ pọ́nńbélé.

A gbà pé mímọ iye tí ìwà ọ̀daràn jẹ́ gẹ́lẹ́ ṣòro. Ìdí kan ni pé, ọ̀pọ̀ ìwà ọ̀daràn—tí ó ṣeé ṣe kí ó tó ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún nínú àwọn ìsọ̀rí kan—ni a kì í fi sùn rárá. Ṣùgbọ́n jíjiyàn lórí bóyá ìwà ọ̀daràn ti dín kù tàbí pọ̀ sí i kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan. Àwọn ènìyàn ń hára gàgà láti rí i pé a mú ìwà ọ̀daràn kúrò, kì í ṣe wíwulẹ̀ dín in kù.

Àwọn Ìjọba Ń Gbìyànjú

Ìwádìí kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe ní 1990 fi hàn pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà ń ná ìpíndọ́gba ìpín 2 sí 3 nínú ọgọ́rùn-ún ìwéwèé ìṣúnná owó wọn ọdọọdún sórí kíkápá ìwà ọ̀daràn, nígbà tí àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ń ná jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìpíndọ́gba ìpín 9 sí 14 nínú ọgọ́rùn-ún. Ṣíṣe àfikún iye ọlọ́pàá, àti pípèsè ohun èèlò iṣẹ́ tí ó sàn jù fún wọn ń di ohun àkọ́múṣe ní àwọn àdúgbò kan. Àbájáde rẹ̀ kò dọ́gba. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Hungary mélòó kan ráhùn pé: “Àwọn ọlọ́pàá kò pọ̀ tó rí láti mú àwọn ọ̀daràn, ṣùgbọ́n nígbà gbogbo, wọ́n pọ̀ tó láti mú àwọn tí ń rú òfin ìrìnnà.”

Àwọn ìjọba púpọ̀ tí rí i pé ó pọn dandan láti ṣe àwọn òfin tí ó túbọ̀ fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lórí ìwà ọ̀daràn ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Fún àpẹẹrẹ, níwọ̀n bí “jíjí ọmọ gbé ti ń pọ̀ sí i jákèjádò Latin America,” ìwé ìròyìn Time sọ pé, àwọn ìjọba níbẹ̀ ti hùwà padà nípa ṣíṣe àwọn òfin tí “ó le koko tí kò sì gbéṣẹ́ nígbà kan náà.” Ó gbà pé: “Kò ṣòro láti ṣe òfin, ohun tó ṣòro ni lílò wọ́n.”

A fojú bù ú pé, ní Britain, ó lé ní 100,000 ìgbékalẹ̀ ẹ̀ṣọ́ àdúgbò, tí ó kárí igba ọ̀kẹ́ ilé, ó kéré tán, ní 1992. Wọ́n ṣe irú ìgbékalẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní Australia ní agbedeméjì àwọn ọdún 1980. Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Ìwà Ọ̀daràn ní Ilẹ̀ Australia sọ pé ète wọn ni láti dín ìwà ọ̀daràn kù “nípa mímú ìwàlójúfò àwọn aráàlú sí ààbò àwùjọ sunwọ̀n sí i, mímú ìṣesí àti ìhùwàsí àwọn olùgbé nípa fífi ìwà ọ̀daràn àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ afuni lára ládùúgbò sùn sunwọ̀n sí i, àti dídín àìpamọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn kù nípa sísàmì sí ohun ìní ẹni àti ṣíṣàgbékalẹ̀ àwọn ìhùmọ̀ ààbò gbígbéṣẹ́.”

A ń lo tẹlifíṣọ̀n aríléróde abẹ́lé láti so àwọn àgọ́ ọlọ́pàá pọ̀ mọ́ àwọn àdúgbò ìṣòwò ní àwọn ibì kan. Àwọn ọlọ́pàá, báńkì, àti ibi ìtajà ń lo àwọn kámẹ́rà fídíò bí adènà ìwà ọ̀daràn àti bí ohun èèlò iṣẹ́ fún dídá àwọn arúfin mọ̀.

Ní Nàìjíríà, àwọn ọlọ́pàá ní àwọn ibùdó ìṣàyẹ̀wò lójú títì nínú ìsapá láti rọ́wọ́ tó àwọn olè àti àwọn tí ń já mọ́tò gbà. Ìjọba ti gbé ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe kan kalẹ̀ lórí ìwàkiwà nínú ìṣòwò láti gbógun ti ìwà jìbìtì. Àwọn ìgbìmọ̀ alárinà ìbáṣepọ̀ ọlọ́pàá àti ará ìlú, tí ó ní àwọn aṣáájú ìlú nínú, ń sọ fún àwọn ọlọ́pàá nípa ìgbòkègbodò ìwà ọ̀daràn àti àwọn ènìyàn tí ìwà wọn ń funi lára.

Àwọn aṣèbẹ̀wò sí ilẹ̀ Philippines ṣàkíyèsí pé a kì í sábà fi ilé kan sílẹ̀ láìsí olùṣọ́, àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ajá tí ń ṣọ́lé. Àwọn oníṣòwò ń gba àwọn ẹ̀ṣọ́ àdáni láti máa dáàbò bo okòwò wọn. Àwọn ìhùmọ̀ ìgbóguntolè nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ń tà gan-an. Àwọn ènìyàn tí wọ́n lágbára rẹ̀ ń gbé ní àwọn agbègbè ibùgbé tí ó ní ààbò híhá gádígádí tàbí agbègbè ọlọ́pọ̀ ilé.

Ìwé agbéròyìnjáde The Independent ti London wí pé: “Bí ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìgbékalẹ̀ òfin ṣe ń dín kù, iye àwọn ará ìlú tí ń ṣètò ààbò àwùjọ wọn fúnra wọn ń pọ̀ sí i.” Àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ń dìhámọ́ra. Fún àpẹẹrẹ, ní United States, a fojú bù ú pé ìdajì gbogbo ará ilé kọ̀ọ̀kan ní ìbọn kan, ó kéré tán.

Àwọn ìjọba ń ṣàgbékalẹ̀ àwọn ọ̀nà tuntun láti gbógun ti ìwà ọ̀daràn láìdáwọ́ dúró. Ṣùgbọ́n, V. Vsevolodov, ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Abẹ́lé ní Ukraine fi hàn pé, gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ àjọ UN ṣe wí, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ẹ̀bùn àdánidá ń ṣàwárí “àwọn ọ̀nà aláìlẹ́gbẹ́ láti máa bá ìgbòkègbodò ìwà ọ̀daràn nìṣó” èyí tí “ìdálẹ́kọ̀ọ́ àwọn agbófinró” kò lè lé bá láé. Àwọn ọ̀daràn tí wọ́n gbọ́n féfé ń mú kí owó ibi wọ́n jọ alálùbáríkà nípa níná an sórí okòwò àti àwọn ìpèsè ohun àmúlò àwùjọ, wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ àwùjọ, wọ́n sì “ń gba ipò kàǹkàkàǹkà láwùjọ fún ara wọn.”

Àìní Ìgbẹkẹ̀lé

Iye àwọn ènìyàn tí ń gbà pé ìjọba fúnra rẹ̀ jẹ́ apá kan ìṣòro náà ń pọ̀ sí i ní àwọn orílẹ̀-èdè kan. Ìwé ìròyìn Asiaweek fa ọ̀rọ̀ olórí ẹgbẹ́ kan tí ń gbógun ti ìwà ọ̀daràn yọ pé: “Nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ẹni tí a fura sí, tí a ń rí mú, jẹ́ ọlọ́pàá tàbí ológun.” Ó rí bẹ́ẹ̀, kò rí bẹ́ẹ̀, irú àwọn ìròyìn báyìí ti mú kí aṣòfin kan sọ pé: “Bí àwọn tí wọ́n búra láti máa gbé òfin lárugẹ fúnra wọn bá jẹ́ arúfin, àwùjọ wá wà nínú ewu.”

Ìwà ìbàjẹ́ tí ń tini lójú, tí ó kan àwọn lọ́gàálọ́gàá, ti gbo àwọn ìjọba jìgìjìgì ní onírúurú ilẹ̀ lágbàáyé, tí ó túbọ̀ ń jin ìgbọ́kànlé àwọn aráàlú lẹ́sẹ̀. Yàtọ̀ sí pípàdánù ìgbọ́kànlé nínú agbára ìjọba láti kápá ìwà ọ̀daràn, awọn ènìyàn ń ṣàríwísí ìpinnu ìjọba láti ṣe bẹ́ẹ̀. Olùkọ́ kan béèrè pé: “Báwo ni àwọn aláṣẹ wọ̀nyí ṣe lè gbéjà ko ìwà ọ̀daràn nísinsìnyí nígbà tí ẹrẹ̀ ìwà ọ̀daràn mu àwọn náà dé ọrùn dẹ́múdẹ́mú?”

Àwọn ìjọba ń wá, wọ́n sì ń lọ, ṣùgbọ́n ìwà ọ̀daràn kò rebì kan. Síbẹ̀, ìgbà kan ń bọ̀ láìpẹ́ tí ìwà ọ̀daràn kì yóò sí mọ́!

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn ìhùmọ̀ ìdènà ìwà ọ̀daràn: Kámẹ́rà àti gọgọwú tẹlifíṣọ̀n aríléróde abẹ́lé, ilẹ̀kùn onírin àyíwálẹ̀, àti ẹ̀ṣọ́ pẹ̀lú ajá tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ìwà ọ̀daràn ń sọ àwọn ènìyàn di ẹlẹ́wọ̀n nínú ilé àwọn fúnra wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́