Orílẹ̀-èdè Wo Ni Kò Ti Sí Ìwà Ọ̀daràn?
Ayẹyẹ ìsìnkú rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó tóbi jù lọ tí a tí ì rí ní Moscow láàárín ọ̀pọ̀ ọdún. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tò sí etí títì láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn wọn fún ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tí ọta ìbọn àwọn alágbàpa fòpin sí ìgbésí ayé rẹ̀ lójijì ní March 1, 1995. Vladislav Listyev, tí a mọ̀ sí akọ̀ròyìn títayọ jù lọ fún ọdún 1994, tí a yìnbọn pa ní ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ gan-an, jẹ́ gbajúmọ̀ òṣìṣẹ́ orí tẹlifíṣọ̀n.
KÒ PÉ ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní March 20, àwọn ènìyàn ń dà gììrì níbi ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ Tokyo ní kùtùkùtù òwúrọ̀, nígbà tí ìkọlù gáàsì olóró kan ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ló kú; ọ̀pọ̀ míràn sí i sì fara pa yánnayànna.
Lẹ́yìn náà, ní April 19, Ìlú Ńlá Oklahoma di ibi tí a ń gbé sórí tẹlifíṣọ̀n fún gbogbo olùwòran lágbàáyé wò. Pẹ̀lú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni wọ́n ń wo bí àwọn òṣìṣẹ́ agbẹ̀mílà ṣe ń fa àwọn òkú tí ó ti rún kùtù jáde láti inú àwókù ilé ìjọba àpapọ̀ kan tí bọ́m̀bù apániláyà kan ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ di òkìtì àlàpà. Ènìyàn 168 ni ó kú.
Nígbà tí oṣù June ọdún yìí ń parí lọ, irú ìkọlù bẹ́ẹ̀ míràn, nítòsí Dhahran, Saudi Arabia, pa àwọn ará America 19, ó sì pa nǹkan bí 400 lára.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́rin wọ̀nyí ṣàpèjúwe pé ìwà ọ̀daràn ń tàn kálẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. A ń fi àwọn ìṣe ìpániláyà rírorò kún ìwà ọ̀daràn “wíwọ́pọ̀.” Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin—tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà tirẹ̀—ń fi bí gbogbo ènìyàn kò ṣe pamọ́ lọ́wọ́ ìkọlù ìwà ọ̀daràn tó hàn. Yálà o wà nínú ilé, níbi iṣẹ́, tàbí ní títì, ìwà ọ̀daràn lè nawọ́ gán ọ, kí o sì di ọ̀kan lára àwọn tí ó kàgbákò rẹ̀. Ní gidi, ìwádìí kan ní ilẹ̀ Britain fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn ọmọ ilẹ̀ Britain tí wọ́n rò pé àwọ́n lè kàgbákò ìwà ọ̀daràn nísinsìnyí ju bí àwọ́n ti lè ṣe ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn lọ. Ó ṣeé ṣe kí ipò náà jọra níbi tí o wà.
Àwọn ará ìlú tí ń pòfin mọ́ ń fọkàn fẹ́ ìjọba kan tí yóò ṣe ju wíwulẹ̀ káwọ́ ìwà ọ̀daràn kò lọ. Wọ́n ń fẹ́ ìjọba kan tí yóò fòpin sí i ní gidi. Nígbà tí ìfiwéra ìwọ̀n ìwà ọ̀daràn sì lè fi hàn pé àwọn ìjọba kan gbéṣẹ́ ju àwọn mìíràn lọ ní ṣíṣèdíwọ́ fún ìwà ọ̀daràn, ipò náà ní gbogbogbòò fi hàn pé ìjọba ẹ̀dá ènìyàn ń pàdánù ìjàkadì rẹ̀ lòdì sí ìwà ọ̀daràn. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe tàbí Ipò Asunwọ̀ntán Má Ṣeé Ṣe láti gbà gbọ́ pé ìjọba yóò fòpin sí ìwà ọ̀daràn láìpẹ́. Ṣùgbọ́n ìjọba wo ni? Nígbà wo sì ni?
[Àpótí/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
AYÉ TÍ Ó KÚN FÚN ÌWÀ Ọ̀DARÀN
EUROPE: Ìwé kan láti ilẹ̀ Ítálì (“Àǹfààní àti Olè”) sọ pé láàárín sáà kúkúrú kan, iye ìwà ọ̀daràn tí ó kan ohun ìní ní Ítálì ti “ga dé ògógóró tí a ti fìgbà kan kà sí èyí tí kò lè ṣẹlẹ̀.” Ilẹ̀ Ukraine, ilẹ̀ olómìnira kan ní Soviet Union àtijọ́, ròyìn 490 ìwà ọ̀daràn láàárín ọ̀kọ̀ọ̀kan 100,000 ènìyàn ìlú ní 1985, ó sì ròyìn 922 ní 1992. Iye náà ń pọ̀ sí i. Abájọ tí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Rọ́ṣíà (“Àwọn Àlàyé àti Òkodoro Òtítọ́”) fi sọ pé: “Ète ìlépa tí ó wọ̀ wá lọ́kàn jù lọ ni gbígbé ayé—wíwà láàyè—líla sáà oníbẹ̀rù yìí já . . . ìbẹ̀rù wíwọ ọkọ̀ ojú irin—a lè yẹ̀ ẹ́ gẹ̀rẹ̀ kúrò lórì ọ̀nà ìrin tàbí kí a bà jẹ́; ìbẹ̀rù wíwọ ọkọ̀ òfuurufú—fífipá já a gbà ń ṣe lemọ́lemọ́ tàbí kí ọkọ̀ òfuurufú náà já bọ́; ìbẹ̀rù wíwọ ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀—nítorí ìforígbárí tàbí ìbúgbàù; ìbẹ̀rù rírìn ní òpópónà—o lè kó sáàárín àwọn tí ń yìnbọn lura wọn, tàbí kí a jà ọ́ lólè, kí a fipá bá ọ lò pọ̀, kí a lù ọ́ bolẹ̀, tàbí kí a pa ọ́; ìbẹ̀rù wíwọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́—a lè dáná sun ún, a lè fi ìbúgbàù fọ́ ọ yángá, tàbí kí a jí i gbé; ìbẹ̀rù wíwọ ọ̀dẹ̀dẹ̀ ilé ibùgbé, ilé àrójẹ, tàbí ilé ìtajà—a lè pa ọ́ lára tàbí pa ọ́ ní èyíkéyìí nínú wọn.” Ìwé ìròyìn HVG ilẹ̀ Hungary sì fi ìlú ńlá kan tí oòrùn ti ń mú hanhan ní Hungary wé “olú ilé iṣẹ́ Ẹgbẹ́ Awo Ìwà Ọ̀daràn,” ní sísọ pé láàárín ọdún mẹ́ta tí ó kọjá, ó ti jẹ́ “ibi orísun onírúurú ìwà ọ̀daràn tuntun . . . Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbẹ̀rù tí wọ́n so kọ́ra ń pọ̀ sí i bí àwọn ènìyàn ṣe ń rí i pé àwọn ọlọ́pàá kò gbara dì láti kógun ti àwọn Ẹgbẹ́ Awo Ìwà Ọ̀daràn náà.”
ÁFÍRÍKÀ: Ìwé agbéròyìnjáde Daily Times ti Nàìjíríà ròyìn pé “àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga” ní orílẹ̀-èdè kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ń fojú winá “àyalù ìpániláyà, tí àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ awo ń dá sílẹ̀: tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé orí kókó ìṣèdíwọ́ fún ìlépa ìgbòkègbodò ẹ̀kọ́ ìwé tí ó nítumọ̀ kankan.” Ó ń bá a lọ pé: “Àyalù náà ń gbilẹ̀ sí i, pẹ̀lú ìpàdánù ẹ̀mí àti ohun ìní tí ń bá a rìn.” Ìwé agbéròyìnjáde The Star ti Gúúsù Áfíríkà ròyìn nípa orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfíríkà míràn pé: “Oríṣi ìwà ipá méjì ló wà: ìforígbárí láàárín àwùjọ, àti ìwà ipá tí àwọn ọ̀daràn ń hù lásán. Ti àkọ́kọ́ ti dín kù gidigidi, èkejì sì ti lọ sókè.”
OCEANIA: Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Ìwà Ọ̀daràn ní Ilẹ̀ Australia ṣe ìdíyelé pé ìwà ọ̀daràn níbẹ̀ ń náni ní “ó kéré tán, bílíọ́nù 27 dọ́là ilẹ̀ Australia lọ́dọọdún, tàbí iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1600 dọ́là fún ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé kọ̀ọ̀kan.” Èyí jẹ́ “nǹkan bí ìpín 7.2 nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ ohun tí a ń ṣe jáde lábẹ́lé.”
ILẸ̀ AMERICA: Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail ti Kánádà ròyìn bí ìwà ọ̀daràn oníwà ipá ṣe lọ sókè ní Kánádà láàárín sáà ọdún 12 léraléra láìpẹ́ yìí, tí gbogbo wọn sì jẹ́ “ara ìtẹ̀sí tí ó ti mú ìbísí ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún wá nínú ìwà ipá láàárín ẹ̀wádún tí ó kọjá.” Láàárín àkókò náà, ìwé agbéròyìnjáde El Tiempo ti Colombia ròyìn pé ní Colombia, 1,714 ìṣẹ̀lẹ̀ ìjọ́mọgbé wáyé ní ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ kan, “iye tí ó lé ní ìlọ́po méjì àpapọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjọ́mọgbé tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní gbogbo ibi yòó kù lágbàáyé láàárín sáà kan náà.” Gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀ka Ìdájọ́ ilẹ̀ Mexico ṣe sọ, ní ọdún kan láìpẹ́ yìí, a ń hu ìwà ọ̀daràn ìbálòpọ̀ kan láàárín wákàtí mẹ́rin ní olú ìlú rẹ̀. Obìnrin agbẹnusọ kan tọ́ka sí i pé, ìdínkù nínú ìníyelórí àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan ti sàmì sí ọ̀rúndún ogún. Ó parí ọ̀rọ̀ pé: “A ń gbé nínú ìran lò ó, kí o sì jù ú nù.”
KÁRÍ AYÉ: Ìwé The United Nations and Crime Prevention ṣàkíyèsí “ìwà ọ̀daràn tí ń pọ̀ sí i láìdábọ̀ kárí ayé láàárín àwọn ọdún 1970 àti 1980.” Ó sọ pé: “Iye ìwà ọ̀daràn tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ pọ̀ sí i láti nǹkan bí 330 mílíọ̀nù ní 1975 sí iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 400 mílíọ̀nù ní 1980, a sì díwọ̀n pé ó ti dé ìdajì bílíọ̀nù ní 1990.”
[Àwòrán Credit Line]
Àwòrán ilẹ̀ àti àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Ilẹ̀ ayé ní ojú ìwé 3, 6, àti 9: Fọ́tò NASA