Nígbẹ̀yìngbẹ́yín—Ìjọba Kan Tí Yóò Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn
BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé ní ọjọ́ wa, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀-òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (Tímótì Kejì 3:2, 3) Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní ń hùwà ọ̀daràn.
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn ènìyàn ní ń hùwà ọ̀daràn, ìwà ọ̀daràn yóò dín kù dé ìwọ̀n tí wọ́n bá yí padà sí rere. Ṣùgbọ́n kò tí ì fìgbà kankan rọrùn rí fún àwọn ènìyàn láti yí padà sí rere. Ó túbọ̀ ṣòro lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ, nítorí pé láti 1914, déètì kan tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ Bíbélì fìdí rẹ̀ múlẹ̀, a ti ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, sáà yí ní àmì “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò.” Sátánì Èṣù, ọ̀daràn tí ó ju gbogbo ọ̀daràn lọ, tí ó ní “ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní,” ni ó dá àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí sílẹ̀.—Tímótì Kejì 3:1; Ìṣípayá 12:12.
Ìyẹn ṣàlàyé èrèdí ìlọsókè ìwà ọ̀daràn lóde òní. Sátánì mọ̀ pé òun àti ètò ìgbékalẹ̀ òun yóò pa run láìpẹ́. Láàárín ìwọ̀nba àkókò kúkúrú tí ó ṣẹ́ kù, ó ń wá gbogbo ọ̀nà tí ó bá ṣeé ṣe láti gbin àwọn àdámọ́ ìwà búburú tí a mẹ́nu bà nínú Tímótì Kejì, orí 3 sí àwọn ènìyàn lọ́kàn. Nípa bẹ́ẹ̀, fún ìjọba kan láti fòpin sí ìwà ọ̀daràn, ó gbọdọ̀ kásẹ̀ ipá Sátánì nílẹ̀, kí ó sì ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti yí padà, kí wọ́n yéé hùwà lọ́nà tí a júwe lókè yìí. Ṣùgbọ́n ìjọba kankan ha tóótun láti ṣàṣeparí iṣẹ́ tàkàntakan tí ó ré kọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn yìí bí?
Kò sí ìjọba ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó tóó ṣe èyí. J. Vaskovich, olùkọ́ ìmọ̀ òfin kan ní Ukraine, dábàá àìní náà fún “àjọ àjùmọ̀ní títóótun kan, tí yóò so gbogbo ìsapá ìjọba àti àwọn ètò àjọ aráàlú pọ̀, tí yóò sì máa ṣe kòkárí wọn.” Ààrẹ Fidel Ramos ti Philippines si sọ níbi àpérò àgbáyé kan lórí ìwà ọ̀daràn pé: “Nítorí pé imọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé ti sọ ayé wa di kóńkóló, ìwà ọ̀daràn ti láǹfààní láti ré kọjá àwọn ààlà ilẹ̀, ó sì ti di ìṣòro tí ó kó àwọn orílẹ̀-èdè pọ̀. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, àwọn ojútùú pẹ̀lú gbọ́dọ̀ kó àwọn orílẹ̀-èdè pọ̀.”
“Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Kárí Ayé”
Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jẹ́ àjọ (àgbáyé) kan tí ó kó àwọn orílẹ̀-èdè pọ̀. Láti ìgbà ìdásílẹ̀ rẹ̀ ni ó ti ń wá ọ̀nà láti gbéjà ko ìwà ọ̀daràn. Ṣùgbọ́n kò ní ojútùú kankan ju èyí tí àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè ní lọ. Ìwé The United Nations and Crime Prevention ṣàkíyèsí pé: “Ìwà ọ̀daràn abẹ́lé ti ré kọjá apá ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, ìwà ọ̀daràn tí ó kó àwọn orílẹ̀-èdè pọ̀ sì ti lọ sókè ju ohun tí apá àwọn orílẹ̀-èdè alájọṣepọ̀ ká lọ. . . . Ìwà ọ̀daràn àwọn ọ̀daràn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ti gbòòrò dé ìwọ̀n tí ń dáni níjì, pẹ̀lú àwọn àbájáde rírinlẹ̀ ní ti ìwà ipá gidi, ìkójìnnìjìnnì báni, àti ìwà ìbàjẹ́ àwọn lọ́gàálọ́gàá iṣẹ́ ìjọba, ní pàtàkì. Ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ti kú nítorí ìpániláyà. Kíkó oògùn olóró tí ń di bárakú kiri lọ́nà ìkónífà nítorí èrè ara ẹni ti di ọ̀ràn ìbànújẹ́ kárí ayé.”
James Madison, ààrẹ kẹrin ilẹ̀ United States, sọ nígbà kan pé: “Ìṣòro tí ó wà nínú gbígbé ìjọba kan, nínú èyí tí ènìyàn ń ṣàkóso àwọn ènìyàn, kalẹ̀ ni èyí: o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fún ìjọba náà lágbára láti kápá àwọn tí ó ń ṣàkóso lé lórí; lẹ́yìn náà, fi ṣe iṣẹ́ àìgbọdọ̀ má ṣe rẹ̀ láti kápá ara rẹ̀.” (Fi wé Oníwàásù 8:9.) Nítorí náà, ojútùú pípé pérépéré yóò jẹ́ láti fi ìgbékalẹ̀ kan, nínú èyí tí Ọlọ́run ti ń ṣàkóso, rọ́pò àwọn ìjọba, “nínú èyí tí ènìyàn ń ṣàkóso àwọn ènìyàn.” Ṣùgbọ́n ọwọ́ ha lè tẹ irú ojútùú bẹ́ẹ̀ bí?
Ìjọba Tí Yóò Fòpin sí Ìwà Ọ̀daràn
Àwọn Kristẹni tòótọ́ gba ohun tí Bíbélì sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run gbọ́.a Ìjọba gidi ni. Bí Ijọba náà kò tilẹ̀ ṣeé fojú rí nítorí pé ọ̀run ni ó wà, a ń fojú rí àwọn àṣeyọrí rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9, 10) Àwọn tí ó para pọ̀ wà nínú rẹ̀ ni Kristi Jésù àti àwọn 144,000 ènìyàn tí a mú wá “láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè . . . [láti] ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìjọba alágbára yìí yóò ṣàkóso lórí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn ọmọ abẹ́ tí wọ́n wá “lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n.” (Ìṣípayá 5:9, 10; 7:9) Nípa bẹ́ẹ̀, àti àwọn olùṣàkóso, àti àwọn ọmọ abẹ́, wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àgbáyé, àwọn ènìyàn tí a so pọ̀ ní ìṣọ̀kan ní tòótọ́ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè, tí wọ́n ní ìtìlẹ́yìn àtọ̀runwá.
Ní fífara mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti borí ìṣòro ìwà ọ̀daràn láàárín ẹgbẹ́ wọn dé àyè kan. Báwo? Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ láti mọrírì àwọn ìlànà Bíbélì, nípa lílò wọ́n nínú ìgbésí ayé wọn, àti nípa jíjẹ́ kí ipá tí ó lágbára jù lọ lágbàáyé, ẹ̀mí Ọlọ́run, àti èso rẹ̀—ìfẹ́, máa sún wọn ṣiṣẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Ní orílẹ̀-èdè tí ó lé ní 230, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan yìí dàṣà, ní fífi bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìwà ọ̀daràn hàn.
Àbájáde ìwádìí kan tí àwọn 145,958 Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Germany kópa nínú rẹ̀ ní 1994 lè ṣàpèjúwe èyí. Púpọ̀ lára wọn gbà pé àwọn ti ní láti ṣẹ́pá àwọn ìwà àìtọ́ líle koko kí àwọn lè di Ẹlẹ́rìí. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ láti inú Bíbélì sún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, 30,060 ṣẹ́pá lílo tábà tàbí ìjoògùnyó; 1,437 ṣíwọ́ tẹ́tẹ́ títa; 4,362 ṣàtúnṣe ìwà ipá tàbí ìwà ọ̀daràn; 11,149 ṣẹ́pá àwọn ànímọ́ bí owú tàbí ìkórìíra; 12,820 sì dá ìtòòrò minimini padà sínú ìgbésí ayé ìdílé tí ó ti lọ́ tín-ínrín.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àwárí wọ̀nyí jẹ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo, wọ́n ṣàpẹẹrẹ ipò àwọn Ẹlẹ́rìí kárí ayé. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn ọ̀dọ́ ará Ukraine tí ń jẹ́ Yuri. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, jáwójáwó ni. Ó tilẹ̀ ti rin ìrìn àjò lọ sí Moscow, níbi tí ó mọ̀ pé, ọ̀pọ̀ èrò yóò mú kí “iṣẹ́” òun rọrùn.
Ní 1993, Yuri tún wà láàárín ọ̀pọ̀ èrò lẹ́ẹ̀kan sí i ní Moscow. Ṣùgbọ́n ọ̀kankan lára iye ènìyàn tí ó lé ní 23,000 tí ó wà ní Pápá Ìṣiré Locomotive ní Friday, July 23, kò bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní báyìí. Àní, Yuri tilẹ̀ wà lórí pèpéle níbi tí ó ti ń kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí a ṣe fún àwọn olùgbọ́ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè náà. Bí ó ti yí padà sí rere, ó ń ṣègbọràn sí ìtọ́ni Bíbélì pé: “Kí ẹni tí ń jalè máṣe jalè mọ́.”—Éfésù 4:28.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn mìíràn bíi Yuri ti pa ìgbésí ayé ìwà ọ̀daràn tì, kí wọ́n lè tóótun fún ìyè nínú ayé titun òdodo Ọlọ́run. Èyí tẹnu mọ́ ìjóòótọ́ ọ̀rọ̀ Alàgbà Peter Imbert, ọ̀gá ọlọ́pàá látijọ́ ní Britain, tí ó wí pé: “A lè kápá ìwà ọ̀daràn ní kíámọ́sá bí gbogbo ènìyàn bá ṣe tán láti sapá.” Ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí ìjọba Ọlọ́run ń fúnni, ń pèsè ìsúnniṣe tí àwọn olóòótọ́ ọkàn ń fẹ́ fún wọn “láti sapá.”
Ayé Tí Kò Ti Sí Ìwà Ọ̀daràn
Oríṣikóríṣi ìwà ọ̀daràn ń fi àìní ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn hàn. Àwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, tí ó wí pé: “Ìwọ́ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” Àti pé: “Ìwọ́ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Mátíù 22:37-39.
Ìjọba kan ṣoṣo tí ó fara jin fífòpin sí ìwà ọ̀daràn nípa kíkọ́ àwọn ènìyàn láti ṣègbọràn sí àwọn òfin àṣẹ méjì wọ̀nyí ni Ìjọba Ọlọ́run. Lónìí, ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń jàǹfààní ìtọ́ni yìí. Wọ́n ti pinnu láti má ṣe jẹ́ kí ìtẹ̀sí ìwà ọ̀daràn fìdí múlẹ̀ nínú ọkàn àyà wọn, wọ́n sì múra tán láti ṣe ìsapá ara ẹni èyíkéyìí tí ó pọn dandan láti ṣàlékún sí ayé tí ó bọ́ lọwọ́ ìwà ọ̀daràn. Ohun tí Ọlọ́run tí ṣàṣeyọrí rẹ nínú ìgbésí ayé wọn wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò ṣáájú ní ti ohun tí yóò ṣe nínú ayé tuntun rẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba rẹ̀ ọ̀run. Finú wòye ayé kan tí a kò ti nílò àwọn ọlọ́pàá, adájọ́, amòfin, tàbí ọgbà ẹ̀wọ̀n!
Ṣíṣàṣeparí èyí kárí ayé yóò ní rúkèrúdò ìṣèjọba títóbi jù lọ nínú ìtàn nínú, tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò mú wá. Dáníẹ́lì 2:44 sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyí [tí ó wá lónìí] ni Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba [ti ọ̀run] kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè pa run títí láé: a kì yóò sì fi ìjọba náà lé orílẹ̀-èdè míràn lọ́wọ́, yóò sì fọ́ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.” Ọlọ́run yóò tún fọ́ Sátánì túútúú, ní fífòpin sí ipá búburú rẹ̀.—Róòmù 16:20.
Ní gbàrà tí a bá ti fi ìjọba ọ̀run Ọlọ́run rọ́pò àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn, àwọn ẹ̀dá ènìyàn kì yóò tún ṣàkóso lórí ẹnì kínní kejì mọ́ láéláé. Àwọn ọba ọ̀run—àwọn ọba tí wọ́n ju àwọn áńgẹ́lì pàápàá lọ—yóò máa kọ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn ní ipa ọ̀nà òdodo. Nígbà náà, kì yóò sí ìgbànìyànpa, ìkọlù gáàsì olóró, tàbí àwọn bọ́m̀bù àwọn apániláyà mọ́! Kì yóò sí àìṣèdájọ́ òdodo tí ń fa ìwà ọ̀daràn mọ́! Kì yóò sí ìsọ̀wọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn aláìní mọ́!
Ọ̀jọ̀gbọ́n S. A. Àlùkò, ti Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní Nàìjíríà, sọ pé: “Àwọn tálákà kò lè sùn lóru nítorí ebi ń pa wọ́n; àwọn ọlọ́rọ̀ kò lè sùn nítorí pé àwọn tálákà kò lóorun lójú.” Ṣùgbọ́n láìpẹ́, gbogbo ènìyàn yóò lè sùn nara ní mímọ̀ pé ìjọba—ìjọba Ọlọ́run—ti fòpin sí ìwà ọ̀daràn nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àti bí yóò ṣe ṣe ẹ̀dá ènìyàn onígbàgbọ́ láǹfààní, jọ̀wọ́ ka ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Olè kan látijọ́ àti ẹni tó jà lólè, tí wọ́n wà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí Kristẹni arákùnrin nísinsìnyí