Nígbà Wo Ni Ìbẹ̀rù Yóò Dópin?
YÓÒ ha yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé àìléwu tòótọ́ ní i ṣe pẹ̀lú ọkùnrin kan tí ó gbé ní 2,000 ọdún sẹ́yìn bí? Ní fífi ìdí tí ó fi yẹ́ láti ní ìfẹ́ hàn, Jesu Kristi pa òwe àkàwé kan tí ó pẹtẹrí pé: “Ọkùnrin kan bayii ń sọ̀kalẹ̀ lati Jerusalemu lọ sí Jeriko ó sì bọ́ sí àárín awọn ọlọ́ṣà, awọn tí wọ́n bọ́ ọ láṣọ tí wọ́n sì lù ú, wọ́n sì lọ, ní fífi í sílẹ̀ láìkú tán.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arìnrìn-àjò méjì ṣá òjìyà náà tì, onínúrere ará Samaria kan fi àánú hàn. Ṣùgbọ́n, ta ni ń bójútó àwọn òjìyà ìwà-ọ̀daràn lónìí? Ìtura wo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ni a lè máa retí?—Luku 10:30-37.
Bí wọ́n ti ń jẹ́wọ́ pé àwọn gba Ọlọrun gbọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò pé ènìyàn ni ó gbọ́dọ̀ mú òfin àti àṣẹ ṣẹ. Ṣùgbọ́n sáà ìfisẹ́wọ̀n púpọ̀ síi tàbí àwọn ọlọ́pàá tí owó wọn ga sókè síi yóò ha mú òpin dé bá ìwà-ọ̀daràn oníwà-ipá bí? O ha gbàgbọ́ níti gidi pé àwọn agbófinró, láìka ìsapá àfitọkàntọkànṣe láti pèsè àìléwu dé ìwọ̀n àyè kan, yóò mú irú àwọn nǹkan bí oògùn ìlòkulò, ìwà-ọ̀daràn tí a ṣètò, àti òṣì kúrò bí? Síbẹ̀, ebi tí ń pa wá àti òùngbẹ tí ń gbẹ wá fún òdodo kò yẹ kí ó jẹ́ lórí asán.—Matteu 5:6.
Orin Dafidi 46:1 sọ pé: “Ọlọrun ni ààbò wa àti agbára, lọ́wọ́lọ́wọ́ ìrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.” A óò rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kì í wulẹ̀ ṣe ewì tí ó dùn ún gbọ́ lásán nìkan.
Bí o ṣe mọ̀, àwọn ilé-iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń ròyìn ìpànìyàn tí ó ṣòro kápá nínú àwọn ogun abẹ́lé àti ìkọlù àwọn akópayàbáni. Àwọn apá ibì kan nínú ayé, ti di ibi tí a sábà ń lò láti pa àwọn ọ̀dọ́ tàbí olùfojúrí tí a kò fẹ́ run pátápátá. Èéṣe tí ìwàláàyè fi wá di èyí tí kò níyelórí tóbẹ́ẹ̀ mọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú okùnfà irú ìwà-ipá bẹ́ẹ̀ lè wà, ìdí kan ń bẹ tí a kò níláti gbójú fò dá.
Ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” (1 Johannu 5:19) Ní tòótọ́, Jesu Kristi fi Satani Èṣù hàn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí òpùrọ́ nìkan ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí “apànìyàn.” (Johannu 8:44) Nípa lílo agbára ìdarí lórí aráyé ní onírúurú ọ̀nà, ẹ̀dá ẹ̀mí tí ó lágbára yìí ń gbé ìwà-ipá tí ń peléke síi lónìí lárugẹ. Ìṣípayá 12:12 sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó dùnmọ́ni nínú pé, ètò-ìgbékalẹ̀ búburú yìí ni a óò rọ́pò pẹ̀lú “awọn ọ̀run titun ati ilẹ̀-ayé titun kan . . . , ninu awọn wọnyi ni òdodo yoo sì máa gbé.”—2 Peteru 3:13.
Ní àfikún sí ìrètí àgbàyanu ti ilẹ̀-ayé titun yìí, ìrànlọ́wọ́ wo ni a ní nísinsìnyí?
Ṣáájú wíwo ìdáhùn tí ó ṣe kedere sí ìyẹn, ó dára láti fi í sọ́kàn pé àwọn ojúlówó Kristian pàápàá kò ní ìdánilójú pé a óò dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ ìwà-ọ̀daràn. Aposteli Paulu ṣàpèjúwe àwọn ewu díẹ̀ tí òun fúnra rẹ̀ dojúkọ. Ó ti wà “ninu awọn ewu odò, ninu awọn ewu dánàdánà, ninu awọn ewu lati ọwọ́ ẹ̀yà-ìran [tirẹ̀] fúnra [rẹ̀], ninu awọn ewu lati ọwọ́ awọn orílẹ̀-èdè, ninu awọn ewu ninu ìlú-ńlá, ninu awọn ewu ninu aginjù, ninu awọn ewu lójú òkun.” (2 Korinti 11:26) Síbẹ̀síbẹ̀ Paulu la àwọn ewu wọ̀nyí já. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe rí lónìí pẹ̀lú; nípa ṣíṣọ́ra, a ṣì lè máa bá iṣẹ́ wa lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan díẹ̀ tí yóò ṣèrànwọ́.
Bí ẹnì kan bá ń gbé ní àdúgbò eléwu, ìwà rere lè jẹ́ ààbò, níwọ̀n bí àwọn ènìyàn ti máa ń ṣàkíyèsí àwọn ẹlòmíràn fínnífínní. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọ́ṣà ń wéwèé wọ́n sì ń hùwà ọ̀daràn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ka ara wọn sí olórí pípé. Yẹra fún ṣíṣe lámèyítọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe, má sì ṣe gbìyànjú láti wádìí ohun tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, o lè dín ṣíṣeéṣe náà láti di ẹni tí wọn yóò gbẹ̀san lára rẹ̀ kù. Fi sọ́kàn pé àwọn olè ń gbìyànjú láti wádìí ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ra nǹkan titun tàbí ẹni tí ń lọ fún àkókò ìsinmi tí kò sì ní sí nílé, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú ohun tí o ń ṣípayá fún àwọn ẹlòmíràn.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti rí i pé orúkọ rere wọn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ti fún wọn ní ààbò tí ó dá yàtọ̀ gédégédé dé ìwọ̀n àyè kan. Àwọn ọ̀daràn ti sábà máa ń fihàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún irú àwọn Kristian bẹ́ẹ̀, àwọn tí ń fi pẹ̀lú àìṣègbè yọ̀ọ̀da ara wọn ní ríran àwọn ènìyàn ní àwùjọ wọn lọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọn kì í ṣe òṣìkàpànìyàn tàbí olè, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe “olùyọjúràn sí ọ̀ràn awọn ẹlòmíràn,” nípa bẹ́ẹ̀ wọn kì í ṣe awuniléwu.—1 Peteru 4:15.
Àìléwu Nínú Ilẹ̀-Ayé Titun Ọlọrun
A kẹ́dùn “pípọ̀ sí i ìwà-àìlófin” tí Jesu Kristi sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kàkà tí a óò fi ṣe àníyàn jù, a lè ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọrun yóò pa ètò-ìgbékalẹ̀ búburú yìí run ṣẹ́ḿṣẹ́ḿ láìpẹ́. Yàtọ̀ sí sísọ tẹ́lẹ̀ nípa ìwàásù kárí-ayé ti “ìhìnrere ìjọba yii,” Jesu rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí pé: “Ẹni tí ó bá faradà á dé òpin ni ẹni tí a óò gbàlà.”—Matteu 24:12-14.
A lè ní ìdánilójú pé àwọn wọnnì tí ń fi àwọn mìíràn ṣe ìjẹ, nígbà mìíràn pẹ̀lú ìwà-ìkà tí ó ṣòro láti gbàgbọ́, ni a óò mú kúrò pátápátá. Owe 22:22, 23 (NW) sọ pé: “Máṣe ja ẹni rírẹlẹ̀ lólè nítorí pé ó rẹlẹ̀, má sì ṣe pa ẹni tí a pọ́n lójú run ní ẹnubodè. Nítorí pé Jehofa fúnra rẹ̀ yóò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ wọn, dájúdájú òun yóò sì pa ọkàn àwọn wọnnì tí ń jà wọ́n lólè rẹ́.” Jehofa yóò mu àwọn olùṣe búburú kúrò, irú àwọn bí olè, apànìyàn, àti àwọn abánilòpọ̀ lọ́nà tí a gbé gbòdì. Síwájú síi, òun kì yóò ṣá àwọn òjìyà irú ìwà-ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ tì. Òun yóò borí àwọn òfò wọn yóò sì mú ìlera wọn padà bọ̀ sípò.
Ní tòótọ́, àwọn wọnnì tí wọ́n bá ‘kúrò nínú ibi tí wọ́n sì ń ṣe rere’ yóò jèrè ìyè àìnípẹ̀kun yálà nípa líla ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀ já tàbí nípasẹ̀ jíjí wọn dìde láti inú òkú. “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” (Orin Dafidi 37:27-29) Irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó nítorí ẹbọ ìràpadà Jesu. (Johannu 3:16) Ṣùgbọ́n báwo ni ìgbésí-ayé yóò ṣe rí nínú Paradise tí a mú padà bọ̀ sípò náà?
Ìgbésí-ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun yóò jẹ́ ìgbádùn gidi. Jehofa sọtẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ibùgbé àlàáfíà, àti ní ibùgbé ìdánilójú, àti ní ibi ìsinmi ìparọ́rọ́.” (Isaiah 32:18) Gbogbo àwọn tí ó bá jèrè ìyè àìnípẹ̀kun yóò ti tún àkópọ̀ ìwà wọn ṣe. Kò sí ẹnì kan tí yóò jẹ́ ẹni ibi tàbí tí yóò jẹ́ alábòsí, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnì kan kì yóò sì ṣeé ṣe kí ó jẹ́ òjìyà lọ́wọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wòlíì Mika sọ pé: “Wọn óò jókòó olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀; ẹnì kan kì yóò sì dáyà fò wọ́n.” (Mika 4:4; Esekieli 34:28) Ẹ wo irú ìyàtọ̀ tí ó jẹ́ sí àdúgbò eléwu ti òde-oní!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
ṢỌ́RA
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀daràn ń ṣiṣẹ́ ní àkókò kíkún, ní sísọ ìwà-ọ̀daràn di iṣẹ́ àjókòótì. Wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ ẹlẹ́ni méjì tàbí mẹ́ta, àní bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kan ni ó na ìbọn sí ọ. Ó ṣe kedere lọ́nà tí ń pọ̀ síi pé bí ọ̀daràn náà bá ti kéré tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe léwu tó. Kí ni o lè ṣe bí o bá di òjìyà?
Dúró jẹ́ẹ́ kí o má baà mú kí ojora mú olè náà—àìní ìrírí rẹ̀ lè ṣekúpa ọ́. Bí o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, fi ara rẹ hàn bí ọ̀kan. Síbẹ̀, ṣetán láti fún olè náà ní ohun tí ó bá ń fẹ́. Bí o bá jáfara, ewu náà yóò peléke síi. Lẹ́yìn náà, o lè nímọ̀lára pé kò léwu láti bèèrè pé kí a dá káàdì ìdánimọ̀ tàbí owó bọ́ọ̀sì padà.
Lọ́pọ̀ ìgbà o kò lè sọ pé ẹni báyìí jẹ́ ọ̀daràn. Àwọn olè kan jẹ́ alòògùn nílòkulò tàbí afìwà-ọ̀daràn ṣiṣẹ́ àjókòótì, oúnjẹ lásán ni àwọn mìíràn ń fẹ́. Bí ó ti wù kí ọ̀ràn náà rí, máṣe gbé owó púpọ̀ dáni. Yẹra fún ṣíṣàfihàn ohun-ọ̀ṣọ́, òrùka wúrà, tàbí aago olówó gọbọi. Rìn kí o sì rin ìrìn-àjò lọ́nà tí ó wàdéédéé, máṣe fi ìbẹ̀rù kankan hàn. Máṣe tẹjúmọ́ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹni pé o ń fura sí wọn. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a ń yìnbọn ní òpópónà, da àyà délẹ̀; a lè fọ aṣọ lẹ́yìn náà.—Ọlọ́pàá kan tẹ́lẹ̀rí ní Rio de Janeiro.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Dákẹ́ jẹ́ẹ́ kí o sì fún olè náà ní ohun tí ń fẹ́. Bí o bá jáfara, ewu náà yóò peléke síi