ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/8 ojú ìwé 11-14
  • Aláàbọ̀ Ara—Tí Ó Sì Tún Lè Wakọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aláàbọ̀ Ara—Tí Ó Sì Tún Lè Wakọ̀
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Rọrùn
  • Àwọn Ìdámọ̀ràn Tèmi
  • Láti Wakọ̀ Tàbí Láti Máṣe Wakọ̀ —Ìpinnu Tí Ó Mẹ́rù Iṣẹ́ Lọ́wọ́
  • Ọkọ̀ Mi àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Mi
  • “Aláìlera Ni Mí Báyìí, àmọ́ Mi Ò Ní Wà Bẹ́ẹ̀ Títí Láé!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?
    Jí!—2002
  • Bó O Ṣe Lè Dènà Ìjàǹbá Ọkọ̀
    Jí!—2011
  • Bí O Ṣe Lè Ra Àlòkù Ọkọ̀
    Jí!—1996
Jí!—1996
g96 5/8 ojú ìwé 11-14

Aláàbọ̀ Ara—Tí Ó Sì Tún Lè Wakọ̀

“MO LÈ wakọ̀!” Ọ̀rọ̀ yẹn lè má dà bí ohun bàbàrà létí rẹ, àmọ́ wọ́n ní ipa jíjinlẹ̀ lórí mi. Ọkùnrin ẹni 50 ọdún tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ká jọ sílẹ̀ẹ́lẹ̀ níwájú mi. Nítorí pé ó ní àrun rọpárọsẹ̀ nígbà tí ó wà ní ìkókó, àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ má yọ síta rárá. Níwọ̀n bí wọ́n ti tín-ínrín, tí wọn kò sì wúlò, ńṣe ni ó ká wọn sábẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn apá àti èjìká rẹ̀ ti taagun níwọ̀n bí ó ti ń fi ọwọ́ rìn káàkiri fún ọ̀pọ̀ ọdún. Gbígbé tí kò gbé ọ̀ràn náà sọ́kàn sì dójú tì mí—ní pàtàkì bí ó ṣe ń fi tayọ̀tayọ̀ yangàn nígbà tí ó bá ń sọ̀rọ̀ nípa wíwakọ̀ tí ó lè wakọ̀.

Ṣé ẹ rí i, èmi pẹ̀lú ní àrùn rọpárọsẹ̀ nígbà tí mo wà ní ẹni ọdún 28. Ìròyìn pé n kò lè rìn mọ́ láìlo igi àfirìn bà mí nínú jẹ́. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ọkùnrin yìí ń sọ lásán ràn mí lọ́wọ́ láti kojú ìsoríkọ́ mi. Mo rò nínú ara mi pé, bí òun tí àbùkù ara rẹ̀ ju tèmi lọ bá lè borí ìpọ́njú rẹ̀, nígbà náà kí ló dé tí èmi náà kò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀? Mo pinnu níbẹ̀ pé èmi pẹ̀lú yóò tún wa ọkọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i!

Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Rọrùn

Ìyẹ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 40 ọdún sẹ́yìn báyìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, kí aláàbọ̀ ara máa wakọ̀ béèrè ìgboyà. Ìhùmọ̀ àkànṣe gbáà ni ọkọ̀ tí wọ́n pilẹ̀ yípadà fún mi náà jẹ́! Wọ́n ṣe igi àfirìn kan sábẹ́ abíyá mi òsì, tí ó nà lọ sí orí kílọ́ọ̀ṣì. Mo máa ń tẹ kílọ́ọ̀ṣì náà nípa títi èjìká mi òsì síwájú. Ohun èèlò ìtẹná rẹ̀ jẹ́ ìkọ́ aláfọwọ́fà kan tí ó wá láti ara ohun ìrìnnà Ẹ̀ya T Ford àtijọ́ kan, ìkọ́ aláfọwọ́fà kan ni a tún fi ń kó bíréèkì rẹ̀. O ha lè finú yàwòrán mi níbi tí mo ti ń wakọ̀ bí? Èjìká mi ń lọ síwá-sẹ́yìn, ọwọ́ òsì mi ń yíwọ́ ọkọ̀, ó sì ń fa bíréèkì, ọwọ́ ọ̀tún mi ń ṣiṣẹ́ yíyíwọ́ ọkọ̀, títẹná, àti jíjuwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ọlọ́kọ̀ yòókù! (Apá òsì títì ni a ti ń wakọ̀ ní Australia.) Àwọn ọkọ̀ kì í ní iná tí ó máa ń ṣẹ́jú nígbà tí ọkọ̀ bá fẹ́ yà nígbà náà lọ́hùn-ún.

Mo ṣọpẹ́ pé àwọn ọjọ́ tí mo máa ń wakọ̀ pẹ̀lú ohun tí mo so kọ́ra jánganjàngan ti di ohun àtijọ́. Lónìí, pẹ̀lú ìṣètò ìṣiṣẹ́ gíà adáṣiṣẹ́ àti bọ́tìnì ìtanná tí ń ṣẹ́jú tí ọkọ̀ bá fẹ́ yà, tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ọkọ̀ wíwà ti rọrùn gidigidi. Ìtẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn aláàbọ̀ ara máa wakọ̀. A ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀rọ kan tí a sábà máa ń lò ní ojú ewé 14.

Àwọn Ìdámọ̀ràn Tèmi

Bí o bá jẹ́ aláàbọ̀ ara, tí o sì ń ronú nípa pé kí wọ́n pilẹ̀ yí ohun ìrìnnà kan padà fún ọ kí o baà lè máa wakọ̀, mo ń gbà ọ́ nímọ̀ràn gidigidi pé kí o tọ ẹni tí ó mọ̀ dáadáa nípa rẹ̀ lọ. Ó lè ṣètò láti jẹ́ kí wọ́n ṣàyẹ̀wò gbogbo ẹ̀rọ rẹ̀ láti dáàbò bo ìwọ tí o jẹ́ awakọ̀ àti àwọn èrò inú ọkọ̀ rẹ pẹ̀lú. Nítorí ìjàm̀bá ọkọ̀ lè ṣẹlẹ̀, ó ṣe pàtàkì láti ní ètò ìbánigbófò tí ó kún rẹ́rẹ́ lọ́dọ̀ ilé iṣẹ́ abánigbófò tí a mọ̀ dáradára.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè jẹ́ ìṣọ́ra tí ó bọ́gbọ́n mu láti máa gbé ẹnì kan dáni tí o bá ń wakọ̀. Òwe láéláé kan sọ lọ́nà ọgbọ́n pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ, nítorí pé wọ́n lè ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́. Bí ọ̀kan lára wọ́n bá ṣubú, èkejì lè ràn án lọ́wọ́ láti dìde. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan bá dá wà tí ó sì ṣubú, ó burú jáì, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò ràn án lọ́wọ́.” (Oniwasu 4:9, 10, Today’s English Version) Ẹnì kejì lè ṣèrànwọ́ ńláǹlà bí ìjàm̀bá bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, bí ọkọ̀ bá ní ìṣòro, tàbí tí táyà bá jò. Àwọn awakọ̀ aláàbọ̀ ara kan máa ń ní tẹlifóònù alágbèérìn nínú ọkọ̀. Nítorí èyí, bí ó bá pọn dandan, wọ́n lè dánìkan wakọ̀ pẹ̀lú ìgboyà ńláǹlà.

Ó tún lọ́gbọ́n nínú fún awakọ̀ aláàbọ̀ ara láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn atọ́kọ̀ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì kí wọ́n lè tètè máa dáhùn sí ìpè rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, lọ́sàn-án tàbí lóru. Owó tí wọ́n ń san lọ́dọọdún sábà máa ń mọ níwọ̀n—owó táṣẹ́rẹ́ kan tí a ń san fún ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ó lè fúnni.

Ó hàn kedere pé ó yẹ kí àwa awakọ̀ aláàbọ̀ ara mọ ààlà wa, kí a sì máa wakọ̀ pẹ̀lú èyí lọ́kàn. A kò ní láti máa fínràn tí a bá ń wakọ̀ láti fi hàn pé a lè wakọ̀ bíi ti àwọn mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn awakọ̀ aláàbọ̀ ara máa ń ní àkọlé tí ó kà pé: “Awakọ̀ Aláàbọ̀ Ara—Rọra O” lára ọkọ̀ wọn, tàbí irú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jọra. Èyí wulẹ̀ jẹ́ àkọlé kan tí ń fi han àwọn ènìyàn pé aláàbọ̀ ara náà lè máa rọra, ìwakọ̀ rẹ̀ sì lè máà yára tó ti àwọn mìíràn. Kò túmọ̀ sí pé àwọn mìíràn ní láti jìnnà réré sí ọkọ̀ rẹ̀. Ní tòótọ́, nínú ìrírí mi, aláàbọ̀ ara máa ń tètè fa bíréèkì ju awakọ̀ tí nǹkan kò ṣe lọ, ní pàtàkì láti ìgbà tí àwọn ohun àsokọ́ra ìgbàlódé ti dé.

Láti Wakọ̀ Tàbí Láti Máṣe Wakọ̀ —Ìpinnu Tí Ó Mẹ́rù Iṣẹ́ Lọ́wọ́

Bí o bá jẹ́ aláàbọ̀ ara, tí o sì fẹ́ láti wakọ̀, ó yẹ kí o fojú pàtàkì gan-an wo ọ̀ràn náà. Lákọ̀ọ́kọ́, bá dókítà àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ sọ̀rọ̀. O tún lè ronú nípa àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: Ó ha pọn dandan pé kí n máa wakọ̀ bí? Ǹjẹ́ mo lè kojú rẹ̀ bí ìjàm̀bá bá ṣẹlẹ̀ bí? Ǹjẹ́ mo lè ṣẹ́pá ìbẹ̀rù èyíkéyìí tí mo lè ní bí? Kí ni àwọn èrè ibẹ̀? Ǹjẹ́ ìtóótun mi láti wakọ̀ lè jẹ́ kí n padà sẹ́nu iṣẹ́ bí? Ó ha lè ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ fara mi fún àwọn ẹlòmíràn bí?

Mímọ ìgbà tí ó yẹ kí a ṣíwọ́ tún ṣe pàtàkì. Ọjọ́ náà lè dé sí awakọ̀ èyíkéyìí, yálà aláàbọ̀ ara tàbí ẹni tí ara rẹ̀ pé, tí agbára ìwòye àti àwọn iṣan ìmọ̀lára tí ń jórẹ̀yìn yóò mú kí ó pọn dandan láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Bí àkókò yẹn bá dé sí ọ, rántí pé o kò ní láti ronú nípa ara rẹ nìkan. Àwọn tí o nífẹ̀ẹ́—ìdílé rẹ àti aládùúgbò rẹ, ènìyàn bíi tìrẹ tí ń bẹ lórí títì ńkọ́? Ọ̀nà ìwakọ̀ rẹ tí kò dára mọ́ ha lè jẹ́ ojúlówó ewu fún un bí?

Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, bí ilẹ̀ ìbí mi, Australia, awakọ̀ aláàbọ̀ ara kọ̀ọ̀kan tí ó bá ti lé ní ẹni ọdún 65 ní àǹfààní lẹ́ẹ̀kan láti sọ ìwé àṣẹ ìwakọ̀ rẹ̀ dọ̀tun kìkì fún ọdún kan—èyí sì jẹ́ lẹ́yìn tí ó bá kọ́kọ́ gba ìwé ẹ̀rí lọ́dọ̀ dókítà kan tí ó sọ pé kò ní ìṣòro ìlera tí ó tún lè máa ṣèdíwọ́ fún agbára ìwakọ̀ rẹ̀ mọ́.

Ọkọ̀ Mi àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Mi

Nínú sànmánì tí ń yára tẹ̀ síwájú kánkán yìí, ohun ìrìnnà ti di ohun kòṣeémánìí gan-an fún àwọn Kristian ní àwọn ilẹ̀ kan. Ọkọ̀ ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun dé ọ̀dọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tàbí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn. (Matteu 24:14) Ní pàtàkì ni èyí rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn abirùn bíi tèmi. Ọkọ̀ mi, tí wọ́n pilẹ̀ yí padà fún mi, ń jẹ́ kí n lè sọ fún àwọn mìíràn nípa ìdálójú ìgbàgbọ́ mi pé ayé tuntun kan ń bọ̀ láìpẹ́ níbi tí kì yóò sí ìjàm̀bá, àìsàn, àti gbogbo àbùkù ara mọ́. (Isaiah 35:5, 6) Ó tilẹ̀ ti ṣeé ṣe fún àwọn aláàbọ̀ ara kan láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún.

Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a fún ní àga arọ ní Iowa, U.S.A., ti ń ṣe èyí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó sọ pé bọ́ọ̀sì òún ti ran òun lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀; Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan ni ó ṣe àwọn ìhùmọ̀ àkànṣe tí ó fi ń darí rẹ̀, irú bí ohun agbéniròkè tí ó máa ń gbé e sínú bọ́ọ̀sì náà. Bí ó bá ti dé inú rẹ̀, yóò kúrò lórí àga arọ lọ sórí àga awakọ̀. Ó wí pé: “Lọ́nà yìí, ó ti mú kí ó ṣeé ṣe fún mi láti jáde kí n sì máa ké sí àwọn ènìyàn déédéé ní ilé wọn, mo sì sábà máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bíi mélòó kan.”

Ní tèmi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lè ṣiṣẹ́ alákòókò kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ọkọ̀ mi tí wọ́n pilẹ̀ yí padà fún mi ti jẹ́ búrùjí tí kò láfiwé nínú iṣẹ́ ìwàásù. Mo ti ń lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà pẹ̀lú igi àfirìn fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ bí àkókò ti ń lọ, iṣẹ́ ń pá àwọn apá àti èjìká mi lọ́rùn. Nítorí náà, mo ṣẹ̀dá ọ̀nà kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ nira jù. Yálà mo ń ṣiṣẹ́ láàárín ìlú tàbí ní àwọn agbègbè ìgbèríko, mo máa ń yan àwọn ilé tí ó ní ọ̀nà ọkọ̀ tí yóò jẹ́ kí n lè wakọ̀ sún mọ́ ẹnu ọ̀nà.

Nígbà ìbẹ̀wò mi àkọ́kọ́, mo sábà máa ń jáde kúrò nínú ọkọ̀, n óò lo igi àfirìn dé ẹnu ọ̀nà ìta, n óò sì yára ṣàlàyé ìdí tí mo fi wá. Bí onílé náà bá fi ìfẹ́ hàn nínú ìhìn iṣẹ́ náà, n óò gbìyànjú láti bá a dọ́rẹ̀ẹ́ kí ó lè jẹ́ pé ní àwọn ìgbà tí mo bá tún padà wá, mo lè lo àǹfààní náà láti tẹ fèrè ọkọ̀ láti jẹ́ kí ó mọ̀ pé mo ti dé—nígbà náà, àwọn ló kàn láti jáde wá bá mi.

Ọ̀nà ìyọsíni yìí ṣiṣẹ́ dáradára. Láìjẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn onílé nímọ̀lára pé mo ń da àwọn láàmú, wọ́n máa ń gbà láti jókòó pẹ̀lú mi nínú ọkọ̀ fún ìgbà díẹ̀ kí a baà lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdẹ̀ra, kí a sì bọ́ lọ́wọ́ ojú ọjọ́ tí kò dára. Mo sábà máa ń ní àwọn onílé tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìkésíni mi, wọ́n sì máa ń fojú sọ́nà láti jíròrò ìhìn iṣẹ́ Bibeli tí ń runi sókè, àti láti gba ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! tí ó dé kẹ́yìn.

Dájúdájú, ipò tí aláàbọ̀ ara kọ̀ọ̀kan wà yàtọ̀. Àmọ́, bóyá wíwakọ̀ yóò fún ọ ní irú àǹfààní kan náà tí ó ti fún mi ní—àyà níní tí a sọ dọ̀tun, òmìnira, àǹfààní láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́, àti adùn púpọ̀ tí ń wá láti inú àtilèsọ pé, “Mo ń wakọ̀ jáde lọ!”—Gẹ́gẹ́ bí Cecil W. Bruhn ti sọ ọ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

Bí A Ṣe Ń Pilẹ̀ Yí Ọkọ̀ Padà fún Àwọn Aláàbọ̀ Ara

Ọ̀PỌ̀ jù lọ lára àwọn awakọ̀ aláàbọ̀ ara máa ń lo ọwọ́ wọn láti ṣe ohun tí ẹsẹ̀ wọn kò lè ṣe. Irú ohun àfọwọ́darí kan ni ó tilẹ̀ bára dé jù lọ. Òun ni ìkọ́ kan tí ó wọlé dáadáa sábẹ́ ìdarí ọkọ̀ náà, tí ó sì yọ síta láti ọrùn ìdarí ọkọ̀. Ọ̀pá irin kan lọ síbi bíréèkì láti ara ìkọ́ yìí. Títẹ ìkọ́ náà síwájú yóò mú kí o kó bíréèkì.

Láti ara ìhùmọ̀ yìí kan náà, wọ́n so wáyà kan mọ́ ara ìtẹná rẹ̀. Ìkọ́ náà máa ń ṣiṣẹ́ gba ìhà méjì: tí ó bá lọ síwájú, ó máa ń ṣiṣẹ́ fún kíkó bíréèkì, tí ó bá sì lọ sí òkè, ó máa ń ṣiṣẹ́ fún títẹná. Ìwọ̀nba agbára ló nílò. Àǹfààní pàtó tí irú èyí tí a ń fọwọ́ ṣàkóso yìí ní ni pé kì í dí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wa ọkọ̀ náà lọ́nà tí wọ́n ń gbà wakọ̀ ní gidi. Ní àfikún sí i, ó rọrùn láti gbé ẹ̀rọ àdọ́gbọ́nṣe náà kúrò lọ sínú ọkọ̀ míràn.

Ní ti àwọn tí ọwọ́ wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára, oríṣiríṣi àwọn ohun àfọwọ́darí yìí ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Bákan náà ló ṣe ń ṣiṣẹ́, nípa sísún un síwájú láti kó bíréèkì, àti nípa títẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ fún títẹná, kí ìwọ̀n ọ̀rìn ọwọ́ lásán baà lè tẹná.

Àwọn Àga Arọ ŃKọ́?

Àwọn awakọ̀ aláàbọ̀ ara tún dojú kọ ìṣòro mìíràn ní àfikún sí i: Báwo ni yóò ṣe ṣe àga arọ rẹ̀ sí? Ọ̀pọ̀ àwọn awakọ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ máa ń ra ohun ìrìnnà onílẹ̀kùn méjì tí ń jẹ́ kí wọ́n lè gbé àga arọ náà sí àlàfo tí ó wà lẹ́yìn àga awakọ̀. Dájúdájú, èyí béèrè pé kí apá àti èjìká lókun dáadáa. Àwọn tí wọn kò lágbára tó gbọ́dọ̀ dúró kí ẹni bí ọ̀rẹ́ kan tí ń kọjá lọ bá wọn gbé àga wọn sínú ọkọ̀.

Ọ̀nà míràn tún ni ohun àfidirù àga arọ, àpótí ńlá onígíláàsì tí a máa ń gbé sórí ọkọ̀. Bí a bá tẹ bọ́tìnì kan, ohun ayíbíríbírí kékeré kan yóò rọra gbé àpótí náà wálẹ̀ kí àgbá agbẹ́rù kan lè gbé àga arọ náà sínú rẹ̀. Bí ó bá ti dé inú àpótí náà, yóò tún nà gbalaja padà. Irú ohun àfidirù bẹ́ẹ̀ tí ó wà ní Australia ni a lè rọra kì bọ ibi ohun èlò ìtaná sìgá tí ó wà nínú ọkọ̀ náà.

Àbùkù kan tí ó wà nínú ohun àfidirù àga arọ náà ni pé ó máa ń mú kí ọkọ̀ fà lórí ìrìn, èyí tí ó máa ń jẹ́ kí epo tí ń lò fi ìwọ̀n ìpín 15 sí ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Ní àfikún sí i, owó ẹ̀rọ náà fúnra rẹ̀ lè ti pọ̀ jù. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn púpọ̀ ṣì ń ka àwọn ẹ̀rọ náà sí ohun tí ó tóyeyẹ fún òmìnira tí wọ́n ń pèsè. Obìnrin aláàbọ̀ ara kan sọ pé: “Nísinsìnyí, mo lè lọ sí ibikíbi fúnra mi láìsí pé ẹnì kankan wà pẹ̀lú mi tàbí kí ó máa dúró dè mí níbi tí mo ń lọ láti bá mi já àga arọ mi sílẹ̀.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Mo lè wàásù láti inú ọkọ̀ mi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́