ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/8 ojú ìwé 19-23
  • Mo Ń Ráre Kiri àmọ́ Mo Rí Ète Kan Nínú Ìgbésí Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Ń Ráre Kiri àmọ́ Mo Rí Ète Kan Nínú Ìgbésí Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìyọrísí Bíbani Nínú Jẹ́ Ìwà Àìtọ́
  • Ìsapá Láti Ṣàtúnṣe
  • Ìráre Kiri Mi Ń Bá A Lọ
  • Ìgbésí Ayé Lójú Omi Gẹ́gẹ́ Bí Ajaguntà
  • Ìkófìrí Ohun Tí Ìgbésí Ayé Túmọ̀ Sí
  • Dídarí Sílé Pẹ̀lú Ìjákulẹ̀
  • England àti Ilé Ẹ̀kọ́ Eré Orí Ìtàgé
  • Ìráre Kiri Ń Lọ Sópin Níkẹyìn
  • Dídarí Sílé Lọ́nà Yíyàtọ̀
  • “Ọ̀tọ̀ Ni Nọ́ńbà Tí O Fẹ́ Pè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Mo Rí Itẹlọrun Ninu Ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ayọ̀ Mi Ò Lópin Bí Mo Ti Ń Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 1/8 ojú ìwé 19-23

Mo Ń Ráre Kiri àmọ́ Mo Rí Ète Kan Nínú Ìgbésí Ayé

FINÚ wòye ìdààmú àti ìnira tí mo ní ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kan tí àwọn ọkùnrin títaagun méjì, tí ń tú iyàrá, jí mi sílẹ̀ lójijì. Ìyá mi ń wò bọ̀ọ̀, láìlólùrànlọ́wọ́, ó sì hàn pé ó wà nínú ìjayà. Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ni àwọn ọkùnrin náà.

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo ti mọ ohun tí wọ́n ń wá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo lejú koko, tí mo sì díbọ́n bíi pé n kò bẹ̀rù, nínú mi lọ́hùn-ún, ẹ̀rù ń bà mí. Mo mọ̀ pé ọwọ́ ṣìnkún àwọn ọlọ́pàá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ba agbo màjèṣí jalèjalè wa ní New Jersey, U.S.A. Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyé náà jágbe mọ́ mi pé kí n múra, wọ́n sì gbé mi lọ sí orílé-iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.

Báwo ni mo ṣe dénú ipò aburú yìí? Ó bẹ̀rẹ̀ ní kùtùkùtù ìgbésí ayé mi. Nígbà tí mo ṣì wà láàárín àwọn ọdún ọ̀dọ́langba mi, mo ti ka ara mi sí pòkíì màjèṣí. Láàárín àwọn ọdún 1960, ọ̀pọ̀ àwọn èwe kà á sí “àṣà tó layé” láti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ láìsí ìdí kan, mo sì fi gbogbo ara tẹ́wọ́ gbà á. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí mo di ọmọ ọdún 16, mo bá ara mi níbi tí mo ti ń fẹsẹ̀ palẹ̀ ní ilé tẹ́tẹ́ kan ládùúgbò, nítorí wọ́n ti lé mi kúrò ní ilé ẹ̀kọ́. Níhìn-ín ni mo ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn èwe kan tí ń fọ́lé. Lẹ́yìn tí mo ti bá wọn fọ́lé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lọ́nà bíi mélòó kan tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ìmóríyá àti ìháragàgà amóríyá, ìrírí kọ̀ọ̀kan sì máa ń ru mí sókè.

Bí ìbẹ́sílẹ̀ ìwọ́de ìfọ́lé àti olè jíjà olóṣù mẹ́sàn-án ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, a máa ń kó àfiyèsí jọ sórí àwọn ọ́fíìsì àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, níbi tí wọ́n sábà máa ń tọ́jú owó gọbọi sí. Bí a bá ṣe fọ́lé láìsí pé wọ́n mú wa tó, bẹ́ẹ̀ ni àyà ṣe máa ń kò wá tó. Níkẹyìn, a pinnu láti ja ẹ̀ka báǹkì àrọko kan lólè.

Fún ìgbà àkọ́kọ́, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í dojú rú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a wọnú báǹkì náà láìsí ìṣòro kankan, a lo odindi alẹ́ kan tí ń pinni lẹ́mìí nínú ilé, nítorí pé àpótí àwọn asanwó nìkan ni a rí fọ́. Ìṣòro tí ó túbọ̀ le koko kan ni pé fífọ́ tí a fọ́ ibẹ̀ mu kí Ọ́fíìsì Ìwádìí ní Orílẹ̀-Èdè [Federal Bureau of Investigation] (FBI) dá sí ọ̀ràn náà. Nítorí pé FBI ní ń ṣèwádìí ọ̀ràn wa, kò pẹ́ tí wọ́n fi rí gbogbo wa kó.

Àwọn Ìyọrísí Bíbani Nínú Jẹ́ Ìwà Àìtọ́

Wọ́n fẹ̀sùn ìfọ́lé nígbà 78 kan èmi nìkan, ojú sì tì mí pé wọ́n ka kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn síta ketekete ní kóòtù. Ní àfikún sí gbígbé tí wọ́n gbé àwọn ìwà ọ̀daràn wa yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò, èyí ní ipa amúnibanújẹ́ lórí àwọn òbí mi. Ṣùgbọ́n n kò ṣàníyàn kankan nípa ìtẹ́nilógo àti ìmójútìbáni tí mo ń fà fún wọn ní àkókò yẹn. Wọ́n dájọ́ fífi mí sí ilé àwọn ọmọ aláìgbọràn ti orílẹ̀-èdè fún àkókò tí kò lọ́jọ́ fún mi, tí ì bá ti yọrí sí pé n óò wà nínú àhámọ́ títí tí n óò fi pé ọmọ ọdún 21. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí ìsapá agbẹjọ́rò kan tí ó dángájíá, wọ́n gbé mi lọ sí àkànṣe ilé ẹ̀kọ́ alátùn-únṣe kan.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lọ ṣẹ̀wọ̀n, ìpinnu kan ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ mú mi kúrò ní agbègbè náà, kí wọ́n sì mú mi kúrò ní sàkáání àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ mi àtijọ́. Nítorí èyí, wọ́n forúkọ mi sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ àdáni kan ní Newark, èyí tí ń bójú tó àwọn ọmọ líle bíi tèmi. Ní àfikún, wọ́n sọ pé kí n máa rí afìṣemọ̀rònú kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí n lè máa rí ìrànlọ́wọ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ gbà. Àwọn òbí mi ṣe gbogbo ìwọ̀nyí—pẹ̀lú owó gọbọi láti àpò ara wọn.

Ìsapá Láti Ṣàtúnṣe

Láìṣe àní-àní, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ẹjọ́ wa tí wọ́n pòkìkí dáadáa, àkọlé ẹ̀yìn ìwé agbéròyìnjáde kan kà pé, “Àkẹ́jù Ló Ń Bọmọ Jẹ́.” Àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ lòdì sí ìbáwí yọ̀bọ́kẹ́ tí a fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìí. Fún ìgbà àkọ́kọ́, àwọn ọ̀rọ̀ abẹ́ àkọlé yìí mú mi lọ́kàn. Nítorí náà mo gé abala náà kúrò nínú ìwé agbéròyìnjáde náà, mo sì jẹ́jẹ̀ẹ́ nínú ara mi pé, lọ́jọ́ kan, lọ́nà kan, n óò san gbogbo ìjìyà, ìtìjú àti ìnáwó tí mo kó bá àwọn òbí mi padà.

Mo ronú pé, ọ̀nà kan tí mo lè gbà fi ẹ̀rí hàn fún àwọn òbí mi pé mo lè yí padà yóò jẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga pẹ̀lú àwọn ọmọ kíláàsì tí a wọlé pa pọ̀ nígbà kan náà tẹ́lẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé bí n kò ti ṣe rí ní ìgbésí ayé mi. Àbájáde rẹ̀ ni pé, lópin ọdún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, òṣìṣẹ́ tí ń bójú tó ọ̀ràn mi wà níbẹ̀ nígbà tí mo tún fara hàn níwájú adájọ́ tí ó ṣèdájọ́ mi, ojú rẹ̀ tí ó ṣì kọ́rẹ́ lọ́wọ́ yí dà sí ẹ̀rín músẹ́ nígbà tí ó ṣàkíyèsí pé mo gba ìpíndọ́gba ìpele gíga ipò kejì ní sáà kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, ní báyìí, ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fún mi láti padà lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí mo wà tẹ́lẹ̀, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e.

Ìráre Kiri Mi Ń Bá A Lọ

Ní báyìí, ó ti di 1966, nígbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tí a jùmọ̀ wà ní kíláàsì sì kọrí sójú ogun ní Vietnam, mo kọrí sí Kọ́lẹ́ẹ̀jì Concord ní West Virginia. Ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, wọ́n fà mí sí oògùn líle, àwọn ìwọ́de àlàáfíà, àti àwọn àṣà tuntun tí ó jẹ́ kí n máa pe àwọn ìníyelórí tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ níjà. Mo ń wá ohun kan, àmọ́ n kò mọ ohun tí ó jẹ́. Nígbà tí àkókò họlidé ìgbà Ìdúpẹ́ dé, dípò kí n lọ sí ilé, mo wọkọ̀ ọ̀fẹ́ lọ síhà gúúsù ní ìsọdá Òkè Ńlá Blue Ridge sí Florida.

N kò tí ì rìnrìn àjò tí ó jìnnà tó bẹ́ẹ̀ rí, ó sì dùn mọ́ mi bí mo ti ń rí àwọn ibi tuntun púpọ̀, tí ó sì yàtọ̀ síra—ìyẹn jẹ́ títí fi di Ọjọ́ Ìdúpẹ́, nígbà tí mo bá ara mi ní ìtìmọ́lé Daytona Beach nítorí ẹ̀sùn ìréde. Ojú tì mí gan-an débi tí n kò fi lè kàn sí àwọn òbí mi, ṣùgbọ́n àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n kàn sí wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, bàbá mi ṣètò láti san owó ìtanràn gọbọi dípò kí ó jẹ́ kí n lọ ṣẹ̀wọ̀n.

N kò dúró ní kọ́lẹ́ẹ̀jì lẹ́yìn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú àpótí aṣọ kan ṣoṣo àti ìyánhànhàn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ní fún ìrìn àjò, mo tún mọ́nà pọ̀n, ní wíwọ ọkọ̀ ọ̀fẹ́ káàkiri etíkun ìhà ìlà oòrùn United States láìsí ète kan, mo sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò báradé láti gbọ́ bùkátà mi. Àwọn òbí mi kò fìgbà kan rí mọ ibi tí mo wà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń bẹ̀ wọ́n wò láti ìgbà dé ìgbà. Ó yà mí lẹ́nu pé, ó sábà máa ń jọ pé inú wọn máa ń dùn láti rí mi, àmọ́, n kò lè fi ibì kan ṣelé.

Ní báyìí tí n kò sí ní kọ́lẹ́ẹ̀jì mọ́, mo pàdánù wíwà tí mo wà ní ìsọ̀rí akẹ́kọ̀ọ́, tí ń sún àkókò ìwọṣẹ́ ológun síwájú. Ipò àtiyanni-síṣẹ́-ológun tí mo wà ní báyìí ti di ìpele 1-A, ìgbà díẹ̀ péré ni ó sì kù tí wọn óò fi pè mí láti wá wọṣẹ́ ológun. Èrò sísún ìwọṣẹ́ ológun síwájú àti pípàdánù òmìnira mi tuntun kò bára dé. Nítorí náà, mo pinnu láti bá ọkọ̀ òkun fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. Lákòókò náà ni àǹfààní iṣẹ́ tuntun kan ṣí sílẹ̀ fún mi. Èyí ha lè jẹ́ ète ìgbésí ayé mi tòótọ́ bí?

Ìgbésí Ayé Lójú Omi Gẹ́gẹ́ Bí Ajaguntà

Ọ̀rẹ́ ìdílé wa àtijọ́ kan jẹ́ ọ̀gákọ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi ológun ilẹ̀ United States. Ó sọ fún mi nípa ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ fún àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ọkọ̀ ojú omi. Kíá ni wọ́n tẹ́wọ́ gbà mí fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́dún méjì tí ó gbóná janjan kan, tí ó ní àǹfààní alápá méjì ti sísún àkókò ìwọṣẹ́ ológun síwájú àti ìfojúsọ́nà fún gbígba oyè ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ọkọ̀ ojú omi. Mo kẹ́kọ̀ọ́ gba oyè diploma ní 1969, mo sì kiwọ́ bọ ìwé ìwọṣẹ́ mi àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí amojú ẹ̀rọ onípele kẹta nínú ọkọ̀ òkun ní San Francisco. Kíá ni a kọrí sí Vietnam pẹ̀lú ẹrù ohun ìjà ogun. Ìrìn àjò náà kò fara rọ, mo sì kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ òkun náà nígbà tí a dé Singapore.

Ní Singapore, mo fọwọ́ sí ìwé ìwọṣẹ́ nínú ọkọ̀ balogun awáre-kiri kan, tí a ń pè bẹ́ẹ̀ nítorí pé, ó háyà gbogbo àwọn tí kì í ṣe mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, tí wọ́n ń wá iṣẹ́ ní pèpéle ìdíkọ̀. Ọkọ̀ òkun yìí ni a lò láti kiri àwọn etíkun ní Vietnam, láti Ìyawọlẹ̀ Omi Cam Ranh ní ìhà gúúsù lọ sí Da Nang ní ìhà àríwá, nítòsí ibùdó ológun tí a ti tú ká. Ariwo rírinlẹ̀ bọ́m̀bù tí a ń jù síhìn-ín kò dáwọ́ dúró rí. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ti ìṣúnná owó, ipa ọ̀nà yìí ṣàǹfààní, owó tí a ń san lọ́tọ̀ nítorí ewu àti ìkọluni ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú sì máa ń gbé fúkẹ́ sí i nígbàkígbà tí a bá fojú kojú pẹ̀lú ìyìnbọn, mo rí i tí mo ń gba iye tí ó lé ní 35,000 dọ́là lọ́dún gẹ́gẹ́ bí ajaguntà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní aásìkí tuntun yìí, mo ṣì ń nímọ̀lára ìráre, mo sì ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìgbésí ayé jẹ́—ibo ni mo forí lé?

Ìkófìrí Ohun Tí Ìgbésí Ayé Túmọ̀ Sí

Lẹ́yìn ìkọluni bíbani lẹ́rù kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá, Albert, ẹni tí ń bójú tó ẹ̀rọ apèsè-ooru-gbígbóná mi, bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún mi nípa bí Ọlọrun yóò ṣe mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kan láìpẹ́. Mo la etí mi sílẹ̀ sí ìsọfúnni ṣíṣàjèjì yìí. Nígbà tí a tún tukọ̀ padà sí Singapore, Albert wí fún mi pé òún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ṣùgbọ́n òun kò tún ṣe dáádáa mọ́. Nítorí náà, a jùmọ̀ gbìyànjú láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà ládùúgbò kàn ní Singapore. Ó jọ pé kò sí ẹni tí ó lè ràn wá lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ní alẹ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí a óò gbéra gan-an, Albert rí ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà kan ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ hòtẹ́ẹ̀lì kan. Ó ní àdírẹ́sì kan tí a lù sẹ́yìn rẹ̀. A kò ní àkókò láti wá ẹni náà rí, àmọ́, ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, a tukọ̀ lọ sí Sasebo, Japan, níbi tí a ti ṣètò fún ọkọ̀ òkun náà láti lọ fún àtúnṣe fún ọ̀sẹ̀ méjì.

Níbẹ̀ ni a ti sanwó fún àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀, Albert sì fiṣẹ́ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọ̀sẹ̀ méjì péré lẹ́yìn náà, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi láti gba tẹ́lígíráàmù kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, tí ó fi ń sọ fún mi pé, wọn óò ṣe àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ní Sasebo ní òpin ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Mo pinnu láti lọ, kí n sì wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní àpéjọpọ̀ náà.

Ọjọ́ yẹn—August 8, 1970—yóò máa wà lọ́kàn mi títí ayé. Ọkọ̀ takisí ni ó gbé mi dé ilẹ̀ àpéjọpọ̀ náà, tí mo sì kó sí àárín ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará Japan, tí gbogbo wọn múra nigínnigín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò lè sọ Gẹ̀ẹ́sì rárá, ó jọ pé gbogbo wọ́n fẹ́ láti bọ̀ mí lọ́wọ́. N kò tí ì rí irú nǹkan báyìí rí, bí n kò sì tilẹ̀ lóye ọ̀rọ̀ kankan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, tí ó jẹ́ ní èdè Japan, mo pinnu pé n óò tún lọ ní ọjọ́ kejì—kìkì láti wò ó bí n óò bá tún nírìírí irú ìkínikáàbọ̀ kan náà. Mo ṣe bẹ́ẹ̀!

A gba àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn, a sì tún padà sójú omi ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, ní títukọ̀ lọ sí Singapore. Ohun tí mo kọ́kọ́ ṣe nígbà tí a gúnlẹ̀ ni pé, mo wọ takisí lọ sí àdírẹ́sì tí wọ́n lù sẹ́yìn ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà. Obìnrin kan tí ó jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́ jáde láti inú ilé náà, ó sì béèrè bí ìrànwọ́ kankan bá wà tí òún lè ṣe fún mi. Mo fi àdírẹ́sì tí ó wà lára Ilé-Ìṣọ́nà hàn án, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó sì jẹ́ kí n wọlé. Mo rí ọkọ rẹ̀, mo sì wá mọ̀ lẹ́yìn náà pé, míṣọ́nnárì ni wọ́n láti Australia, Norman àti Gladys Bellotti. Mo ṣàlàyé bí mo ṣe rí àdírẹ́sì wọn. Wọ́n jẹ́ kí n nímọ̀lára pé àwọ́n gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì dáhùn púpọ̀ lára àwọn ìbéèrè mi, mo sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú láílọ̀ọ̀nù ìrajà tí ó kún fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Láàárín àwọn oṣù bíi mélòó kan tí ó tẹ̀ lé e, bí a ti ń wakọ̀ lọ sí etíkun ní Vietnam, mo ka púpọ̀ lára àwọn ìwé wọ̀nyẹn, títí kan Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye.

Nísinsìnyí, fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi, mo ní ìmọ̀lára ète gidi àti ìtọ́sọ́nà kan. Nínú ìrìn àjò tí ó tẹ̀ lé e padà lọ sí Singapore, mo fi iṣẹ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ òkun náà.

Dídarí Sílé Pẹ̀lú Ìjákulẹ̀

Fún ìgbà àkọ́kọ́ pẹ̀lú, mo nímọ̀lára àtilọ sí ilé. Nítorí náà, ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, mo darí sílé pẹ̀lú ayọ̀, ní fífẹ́ láti sọ gbogbo ohun tí mo mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọn kò ṣàjọpín ìtara ọkàn mi. Mo lóye èyí, nítorí pé ìhùwà mi kò ṣèrànwọ́. Ìwọ̀nba ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ni mo ti fi wà nílé nígbà tí ìrunú mi bú jáde, tí mo sì da ilé ijó kan ládùúgbò rú. Inú àhámọ́ ni mo jí sí.

Ní àkókò yìí, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́ pé kò sí ìrètí gidi pé mo lè yí padà, kí n sì lè ṣàkóso ìbínú gbígbóná janjan mi. Bóyá n óò lè máa bá a lọ láti jẹ́ aṣọ̀tẹ̀ láìsí ìdí kan. N kò lérò pé mo tún lè jókòó sílé mọ́. Mo ní láti fi ilé sílẹ̀. Nítorí náà, láàárín ọjọ́ bíi mélòó kan, mo forúkọ sílẹ̀ láti bá ọkọ̀ òkun akẹ́rù ilẹ̀ Norway, tí ń lọ sí England rìn.

England àti Ilé Ẹ̀kọ́ Eré Orí Ìtàgé

Mo gbádùn gbígbé ní England, àmọ́, iṣẹ́ ni ìṣòro ibẹ̀. Nítorí náà, mo pinnu láti gbìyànjú àwọn ilé ẹ̀kọ́ eléré orí ìtàgé, sí ìyàlẹ́nu mi, wọ́n gbà mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Eré Orí Ìtàgé ti London. Mo lo ọdún méjèèjì tí mo fi wà ní London ní mímú ọtí àmujù, lílọ sí òde ìgbádùn, àti, gẹ́gẹ́ bí o ṣe lè retí, mímu oríṣiríṣi oògùn líle.

Lójijì ni mo pinnu pé n óò fẹ́ láti tún lọ bẹ ìdílé mi wò ní United States. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o lè finú wòye bí ìrísí mi tí ó jọ ti òṣèré yóò ti mú wọn ta gìrì tó lọ́tẹ̀ yìí? Mo wọ ẹ̀wù dúdú kan, tí ó ní orí kìnnìún onígóòlù méjì, tí wọ́n fi ẹ̀gbà onígóòlù so pọ̀ ní ọrùn, ẹ̀wù aláràn-án àwọ́lékè péńpé, àti ṣòkòtò aláràn-án dúdú, tí ó ní awọ tí wọ́n fi ṣọ̀ṣọ́ sí i lára, tí mo tẹ̀ bọnú bàtà àmùtán tí ó gùn dé orúnkún. Ó ha yani lẹ́nu pé kò tilẹ̀ wú àwọn òbí mi lórí àti pé mo nímọ̀lára yíyàtọ̀ pátápátá ní àyíká wọn tí wọ́n ti ń ṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì! Nítorí náà, mo padà sí England, níbí tí mo ti gba oyè diploma nínú eré orí ìtàgé ní 1972. Ní báyìí, mo ti ṣàṣeparí góńgó mìíràn. Ṣùgbọ́n ìbéèrè ayọnilẹ́nu, tí ń wá léraléra náà ṣì wà síbẹ̀ pé, Ibo ni n óò kọrí sí báyìí? Mo ṣì nímọ̀lára àìní fún ète gidi nínú ìgbésí ayé.

Ìráre Kiri Ń Lọ Sópin Níkẹyìn

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára pé ìgbésí ayé mi ti ń lójú nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú aládùúgbò mi, Caroline. Ó jẹ́ olùkọ́ láti Australia, ó sì jẹ́ ẹni tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí ó níwà gidi—ìdà kejì irú ohun tí mo yà. A ti ń bá ọ̀rẹ́ wa bọ̀ fún ọdún méjì láìsí àjọṣepọ̀ eléré ìfẹ́ kankan. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, Caroline lọ sí America fún oṣù mẹ́ta, nítorí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ dáradára wa, mo ṣètò fún un láti wà lọ́dọ̀ àwọn òbí mi fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣe kàyéfì nípa ìdí tí yóò fi ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú oníwà wíwọ́ bíi tèmi.

Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Caroline lọ, mo wí fún àwọn ọ̀rẹ́ mi pé èmi pẹ̀lú ń lọ sílé, wọ́n sì ṣe ayẹyẹ ìdágbére ńlá kan fún mi. Ṣùgbọ́n dípò kí n padà lọ sí America, mo wulẹ̀ lọ sí ìhà Gúúsù Kensington, London, níbi tí mo ti háyà ilé ilẹ̀ gbéetán kan, mo sì tẹlifóònù ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní London. Mo ti mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí ìgbésí ayé mi dorí kọ. Láàárín ọ̀sẹ̀ kan, àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n kún fún inú dídùn wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé pẹ̀lú mi. Nítorí àwọn ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí tí mo ti kà tẹ́lẹ̀, mo ń yánhànhàn gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ nísinsìnyí, mo sì sọ pé kí wọ́n máa bá mi kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Nígbà tí Bob rí ìtara ọkàn mi, ó tètè rọ̀ mí láti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé tí a ń ṣe lọ́sẹ̀.

Nígbà tí mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kì í mu sìgá, mo pinnu láti jáwọ́ nínú àṣà náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn ti ìrísí mi ńkọ́? N kò fẹ́ láti dá yàtọ̀ gedegbe mọ́, nítorí náà, mo ra ṣẹ́ẹ̀tì kan, táì kan, àti tòkètilẹ̀ kóòtù kan. Kò pẹ́ tí mo fi tóótun láti ṣàjọpín nínú ìgbòkègbodò ìwàásù láti ilé dé ilé—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní ojora níbẹ̀rẹ̀, nígbà tí ó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn rẹ̀.

Mo ronú pé ẹnu ní láti ya Caroline gan-an nígbà tí ó bá padà dé. Ìyẹn kò tilẹ̀ wá tó ohun tí ó ṣẹlẹ̀! Kò lè gbà gbọ́ láti rí ìyípadà tí ó ti ṣẹlẹ̀ lára mi níwọ̀nba àkókò kúkúrú bẹ́ẹ̀—nínú ìmúra àti ìrísí mi àti ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀nà míràn. Mo ṣàlàyé bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mi ṣe ràn mí lọ́wọ́, mo sì ké sí òun pẹ̀lú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó lọ́ra lákọ̀ọ́kọ́, ó wá gbà níkẹyìn, ní sísọ pé, èmi nìkan ni òun yóò bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Inú mi dùn láti rí bí ó ṣe tètè gbà, kò sì pẹ́ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ sí í mọrírì òtítọ́ Bibeli.

Lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan, Caroline pinnu láti padà sí Australia, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ ní Sydney. Mo wà ní London títí di ìgbà tí ń óò ṣèrìbọmi, oṣù méje lẹ́yìn náà ni mo sì ṣe é. Wàyí o, mo tún fẹ́ láti lọ sílé ní United States láti lọ wo gbogbo ìdílé mi. Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, mo pinnu láti ṣàṣeparí góńgó ìlépa mi!

Dídarí Sílé Lọ́nà Yíyàtọ̀

Àwọn òbí mi tí ìdàrúdàpọ̀ ọkàn ti bá ń fẹ́ láti mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí—mo dà bí ẹni tí ọ̀wọ̀ tọ́ sí gan-an! Ṣùgbọ́n inú mi dùn lọ́tẹ̀ yìí láti fara mọ́lé ní ti gidi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi wulẹ̀ ṣe kàyéfì nípa ìyípadà tí ó dé sí mi bí idán, wọ́n lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, wọ́n sì hùwà pẹ̀lú inú rere àti ìráragba-nǹkan-sí wọn bíi ti tẹ́lẹ̀. Ní àwọn oṣù tí ó tẹ̀ lé e, mo ní àǹfààní ṣíṣàjọpín ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan pẹ̀lú wọn. Mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin méjì, tí ó dájú pé, ọ̀nà ìgbésí ayé mi tí ó ti yí padà ní ipa lórí wọn. Bẹ́ẹ̀ ni, dídarí sílé gidi ni èyí!

Ní August 1973, mo bá Caroline lọ sí Australia, níbi tí ó ti jẹ́ ìdùnnú mi láti rí i tí a ṣèrìbọmi fún un ní àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní 1973, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn 1,200 míràn. A ṣègbéyàwó ní òpin ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e ní Canberra, olú ìlú orílẹ̀-èdè Australia. Mo ti ń ṣiṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún níhìn-ín fún 20 ọdún tí ó ti kọjá, àti gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ àdúgbò fún ọdún 14.

Ọpẹ́ ni fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ aya mi, a ti tọ́ ọmọ mẹ́ta—Toby, Amber àti Jonathan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ń kojú àwọn ìṣòro ìdílé tí ó wọ́pọ̀, mo ṣì ń yí i mọ́ ọ́n ní nínípìn-ín nínú ìṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, bákan náà ni mo sì ń bójú tó àwọn àìní ìdílé wa nípa ti ara.

Lónìí, ní United States, àwọn òbí mi jẹ́ ìránṣẹ́ Jehofa tí ó ti ṣèyàsímímọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì ti lé ní ẹni 80 ọdún báyìí, wọ́n ṣì ń nípìn-ín nínú ìwàásù Ìjọba náà ní gbangba. Bàbá mi ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ìjọ àdúgbò. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin méjèèjì pẹ̀lú ní ìtara fún iṣẹ́ ìsìn Jehofa.

Ẹ wo bí ọpẹ́ mi sí Jehofa Ọlọrun ti jinlẹ̀ tó pé, ọ̀pọ̀ ọdún tí mo ti ń ráre káàkiri nígbà kan rí ti wá di ọ̀rọ̀ ìtàn báyìí! Kì í ṣe pé ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà dídára jù lọ láti lo ìgbésí ayé mi nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ti fi ìdílé tí ó ṣọ̀kan tí ó sì bìkítà bù kún mi.—Gẹ́gẹ́ bí David Zug Partrick ti sọ ọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

David àti aya rẹ̀, Caroline

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́