Mo Rí Itẹlọrun Ninu Ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun
BI JOSHUA THONGOANA ṢE SỌ Ọ
Lẹhin lọhun-un ni 1942, ọkàn mi dàrú gidigidi. Mo ń kẹkọọ iwe ti awọn onisin Seventh-Day Adventist tẹjade ati iwe ti Watch Tower Society tẹjade. Gẹgẹ bi awọn ọmọ Israeli igbaani, mo ń “ṣiyemeji.”—1 Awọn Ọba 18:21.
AWỌN Seventh-Day Adventist ń fi iwe ẹkọ ti a tẹ̀ ti a ń pè ni “Ohùn Isọtẹlẹ” ranṣẹ si mi. Mo gbadun didahun awọn ibeere wọn, wọ́n sì ṣeleri lati fun mi ni iwe-ẹri ti o rẹwa kan bi mo bá yege ninu gbogbo idanwo mi. Ṣugbọn mo ṣakiyesi pe ati “Ohùn Isọtẹlẹ” ati awọn itẹjade Watch Tower Society ni a ń fi ranṣẹ lati ilu Cape Town ti South Africa. Mo ṣe kayeefi pe: ‘Ǹjẹ́ awọn eto-ajọ wọnyi mọ araawọn bayii? Awọn ẹkọ wọn ha fohunṣọkan bi? Bi kìí ba ṣe bẹẹ, ewo lo tọna?’
Lati yanju ọ̀ràn naa, mo kọ lẹta ti o jọra si eto-ajọ kọọkan. Fun apẹẹrẹ, mo kọwe si Watch Tower Society pe: “Ẹyin ha mọ awọn eniyan ti wọn ni isopọ pẹlu ‘Ohùn Isọtẹlẹ’ bi, bi ẹ bá sì mọ̀ wọn, ki ni ẹyin yoo sọ nipa awọn ẹkọ ti wọn fi ń kọni?” Bi akoko ti ń lọ mo ri èsì gbà lati ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ mejeeji. Lẹta ti o wá lati ọ̀dọ̀ Watch Tower Society sọ pe awọn mọ̀ nipa “Ohùn Asọtẹlẹ” ṣugbọn wọn ṣalaye pe awọn ẹkọ rẹ̀ gẹgẹ bii Mẹtalọkan ati ipadabọ Kristi sori ilẹ̀-ayé ninu ẹran ara, jẹ́ eyi ti kò ba iwe mimọ mu. Lẹta wọn ni awọn ẹsẹ iwe mimọ ti o dá awọn ẹkọ-igbagbọ wọnyi lẹbi ninu.—Johannu 14:19, 28.
Idahun lati ọdọ “Ohùn Isọtẹlẹ” kàn wulẹ sọ pe awọn mọ “awọn Watch Tower,” ṣugbọn awọn kò fohunṣọkan pẹlu ẹkọ ti wọn fi ń kọni. Kò si idi kankan ti a fifunni. Nitori naa mo pinnu ni itilẹhin Watch Tower Society, eyi ti o jẹ́ ẹgbẹ́ aṣojufunni ti o bá ofin mu ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń lo. Lonii, lẹhin 50 ọdun ikẹgbẹpọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí naa, bawo ni mo ti layọ tó pe mo ṣe ipinnu ti o tọ́!
Ipò Àtilẹ̀wá Niti Isin
A bí mi ni 1912 ni igberiko kan ti a ń pe ni Makanye, ni ila-oorun ilu Pietersburg ti South Africa. Makanye nigba naa wà labẹ idari isin Ṣọọṣi Anglika, nitori naa mo di mẹmba ṣọọṣi yẹn. Nigba ti mo jẹ́ ọmọ ọdun mẹwaa, idile wa ṣi lọ si agbegbe miiran tí awọn Ṣọọṣi Lutheran Berlin Mission jẹgaba lé lori, awọn òbí mi sì darapọ mọ ṣọọṣi yẹn. Mo tootun laipẹ lati lọ sibi isin gbígba Ara Oluwa ati lati bu ìṣù burẹdi kan ati ìdágẹ̀ẹ́ waini, ṣugbọn kò tẹ́ aini mi nipa tẹmi lọrun.
Lẹhin pipari ọdun mẹjọ ile-ẹkọ, baba mi rán mi lọ si ile-ẹkọ Kilnerton Training Institution, ati ni 1935, mo gba Iwe-ẹri Olukọ Ọlọdun Kẹta. Ọ̀kan ninu awọn olukọ ti mo bá ṣiṣẹ jẹ́ ọdọmọbinrin kan, Caroline. A fẹ́raawa, ati lẹhin naa Caroline bí ọmọbinrin jojolo kan ti a sọ orukọ rẹ̀ ni Damaris. Ọdun diẹ lẹhin naa, mo di ọ̀gá olukọ ni Ile-ẹkọ Sehlale ni abuleko Mamatsha. Niwọn bi a ti ń dari ile-ẹkọ naa lati ọwọ́ Ṣọọṣi Alatun-unṣe ti Dutch, a darapọ mọ ṣọọṣi yẹn, ni lilọ si awọn ipade isin rẹ̀ deedee. A ṣe eyi nitori pe o jẹ́ ohun kan ti o gbayì lati ṣe. Ṣugbọn kò mú itẹlọrun wá fun mi.
Ikorita Iyipada Kan
Ni ọjọ Sunday kan ni 1942, a ń kọ́ awọn orin isin idanrawo ninu ṣọọṣi nigba ti ọkunrin ọ̀dọ́ alawọ funfun kan farahan ni ẹnu ọ̀nà pẹlu iwe mẹta ti a tẹjade lati ọwọ́ Watch Tower Society—Creation, Vindication, ati Preparation. Mo ronu pe awọn iwe naa yoo dara lori pẹpẹ ikoweesi mi, nitori naa mo gbà wọn ni ṣílè mẹta. Lẹhin naa mo gbọ pe ọkunrin naa, Tienie Bezuidenhout, jẹ́ ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ọkanṣoṣo ti o wà ni adugbo naa. Nigba ibẹwo Tienie ti o tẹle e, ó gbé ẹ̀rọ rẹ́kọ́ọ̀dù kan wá ó sì gbé awọn ọ̀rọ̀ asọye diẹ jade lati ẹnu Judge Rutherford. Mo gbadun eyi ti a mọ si “Idẹkun ati Wàyó,” latokedelẹ, ṣugbọn Caroline ati arabinrin mi Priscilla, ti o ń gbé pẹlu wa kò ṣe bẹẹ. Nigba ibẹwo Tienie kẹta, ó fun mi ni ẹ̀rọ rẹ́kọ́ọ̀dù naa ki ń baa lè gbe rẹ́kọ́ọ̀dù naa si i fun awọn ọ̀rẹ́.
Ni ọjọ kan mo ń yára ṣí awọn oju-iwe Creation wò mo si ṣalabaapade akori naa “Where are the Dead?” [Nibo ni Awọn Oku Wa?] Mo bẹrẹ sii kà á pẹlu ireti kíkọ́ nipa ayọ ti awọn ọkàn ti o ti lọ ń niriiri rẹ̀ ni ọrun. Ṣugbọn ni odikeji si ifojusọna mi, iwe naa sọ pe awọn oku wà ninu sàréè wọn ti wọn kò sì mọ ohunkohun. Awọn ẹsẹ lati inu Bibeli, bi Oniwasu 9:5, 10, ni a fàyọ ni itilẹhin rẹ̀. Akori miiran ni a fun ni àkọlé naa “Awakening the Dead” [Jiji Awọn Oku Dide], Johannu 5:28, 29 ni a sì fàyọ gẹgẹ bi ẹ̀rí pe awọn oku jẹ alaimọkan ti wọn sì ń duro de ajinde. Eyi mọgbọndani. O tẹnilọrun.
Akoko yẹn, ni 1942, ni mo já ibatan mi pẹlu “Ohùn Isọtẹlẹ” mo sì bẹrẹ sii sọ fun awọn ẹlomiran nipa awọn nǹkan ti mo ń kọ́ lati inu awọn itẹjade Watch Tower Society. Ẹni akọkọ ti o dahunpada jẹ́ ọ̀rẹ́ kan, Judah Letsoalo, ẹni ti o ti jẹ ọ̀kan ninu awọn ọmọ kilaasi ẹlẹgbẹ mi tẹlẹri ni ile-ẹkọ Kilnerton Training Institution.
Emi ati Judah ń gun kẹkẹ rin kilomita 51 lati pesẹ si apejọpọ awọn Ẹlẹ́rìí ará Africa ni Pietersburg. Lẹhin naa, awọn ọ̀rẹ́ lati Pietersburg sábà maa ń wa lati iyànníyàn Mamatsha lati ràn mi lọwọ lati gbé ihin-iṣẹ Ijọba naa kalẹ fun awọn aladuugbo mi. Lẹhin-ọ-rẹhin, ni apejọpọ miiran ni Pietersburg, ni December 1944, a ṣeribọmi fun mi ní apẹẹrẹ iyasimimọ mi fun Jehofa.
Idile mi ati Awọn Miiran Dahunpada
Caroline, Priscilla, ati ọmọbinrin mi Damaris, ń baa lọ lati maa lọ si Ṣọọṣi Alatun-unṣe Dutch. Nigba naa ni ìjábá ṣẹlẹ. Caroline bi ọmọ wa keji—ọmọkunrin jojolo ti o jọ ẹni ti o lera ti a sọ orukọ rẹ̀ ni Samuel. Ṣugbọn lojiji o ṣaisan o sì kú. Awọn ọ̀rẹ́ Caroline ni ṣọọṣi kò nawọ itunu kankan, ni sisọ pe Ọlọrun fẹ ki ọmọkunrin wa wà pẹlu oun ni ọrun ni. Bi o ti ní isorikọ, Caroline ń baa lọ lati beere pe: “Eeṣe ti Ọlọrun yoo fi gba ọmọ wa lọ?”
Nigba ti ọ̀rọ̀ ìjábá wa de ọ̀dọ̀ awọn Ẹlẹ́rìí ni Pietersburg, wọn wá wọn sì fun wa ni ojulowo ìtùnú ti a gbekari Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Caroline sọ lẹhin naa pe: “Ohun ti Bibeli sọ nipa okunfa iku, nipa ipo awọn oku, ati nipa ireti ajinde lọgbọn-ninu, ara sì tù mi lọpọlọpọ. Mo fẹ lati wà ninu ayé titun naa ki n sì gba ọmọkunrin mi pada kuro ninu sàréè.”
Caroline dawọ lilọ si ṣọọṣi duro, ni 1946 oun, Priscilla, ati Judah ni a sì baptisi. Gẹ́rẹ́ lẹhin iribọmi rẹ̀, Judah fi wá silẹ lati bẹrẹ iṣẹ iwaasu naa ni agbegbe oko kan ti a ń pe ni Mamahlola, ó sì duro gẹgẹ bi oluṣotitọ titi di ìgbà iku rẹ̀ ni 1991.
Nigba ti Judah lọ, emi ni ọkunrin kanṣoṣo ti o kù lati bojuto ijọ wa, eyi ti a ń pe ni Boyne. Nigba naa ni Gracely Mahlatji kó wá si ipinlẹ wa, lẹhin-ọ-rẹhin ó gbé arabinrin mi, Priscilla, niyawo. Ni ọsẹ kọọkan, emi ati Gracely ń pin ọrọ-asọye fun gbogbo eniyan sọ ni Sepedi, èdè adugbo ti awọn ará Africa. Lati mu ki iwe ikẹkọọ Bibeli wà larọọwọto fun awọn eniyan, Society wi fun mi pe ki ń ṣetumọ iwe ikẹkọọ si èdè Sepedi. O fun mi ni itẹlọrun ti o ga lati ri awọn eniyan ti ń jere lati inu iwe ikẹkọọ yii.
Lati mu ki igbetaasi ipade fun gbogbo eniyan wa fẹjú sii, a ra ẹ̀rọ rẹ́kọ́ọ́dù kan pẹlu apoti gbohungbohun nla ki o baa lè gbé awọn ọrọ-asọye Bibeli jade jakejado ipinlẹ wa. A yá ọmọlanke kan ti a ń fi kẹtẹkẹtẹ fà lati maa gbe ohun-eelo wiwuwo yii lati ibikan si omiran. Gẹgẹ bi abajade, awọn aladuugbo wa sọ wa ni orukọ inagijẹ naa “Awọn Eniyan Ṣọọṣi Oníkẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Laaarin akoko yii, ijọ wa kekere ń baa lọ lati maa gbèrú. Lẹhin-ọ-ọrẹhin awọn ẹgbọn mi obinrin meji ati ọkọ wọn di Ẹlẹ́rìí gbogbo wọn sì ń fi iduroṣinṣin baa lọ titi di ìgbà iku wọn. Bakan naa, ọpọ lati ijọ Boyne (eyi ti a ń pe ni Mphogodiba nisinsinyii) bẹrẹ iṣẹ́ ajihinrere alakooko kikun, awọn ti o pọ̀ ṣì wà ninu iṣẹ-isin naa sibẹ. Nisinsinyi, ijọ meji ni o wà ni ayika awọn abule oko ti o ṣe gatagata gbigbooro yii, apapọ iye ti o ju 70 akede lọ ni wọn sì jẹ́ ogboṣaṣa ninu iṣẹ wiwaasu.
Igbesi-aye Titun Kan
Ni 1949, mo dawọ ṣiṣe olukọ ni ile-ẹkọ duro mo sì di ojiṣẹ aṣaaju-ọna deedee kan. Iṣẹ-ayanfunni mi akọkọ ni lati ṣe ikesini si ọ̀dọ̀ awọn lébìrà alawọ dudu ti wọn ń gbe ni awọn oko ti awọn alawọ funfun ní layiika Vaalwater ni Transvaal. Diẹ ninu awọn ti o ni oko naa ṣagbẹnusọ fun aṣa kẹlẹyamẹya ti a ṣẹṣẹ tẹwọgba ti wọn sì pinnu pe awọn eniyan dudu gbọdọ tẹwọgba ipo jíjẹ́ ẹni ti o rẹlẹ si awọn alawọ funfun ti wọn sì gbọdọ ṣiṣẹ sin awọn ọ̀gá wọn alawọ funfun. Nitori naa nigba ti mo waasu fun awọn oṣiṣẹ alawọ dudu, awọn alawọ funfun diẹ fi aṣiṣe pe mi ni oniwaasu atàpá-sí-àṣẹ. Awọn diẹ tilẹ fẹsun jíjẹ́ Kọmunisti kàn mi paapaa ti wọn sì halẹ lati ta mi ni ibọn.
Mo rohin ipo naa fun ẹ̀ka ọfiisi Watch Tower Society, ko sì pẹ́ ti wọn fi gbe mi kuro nibẹ lọ sibi iṣẹ-ayanfunni miiran ni àrọ́ko kan ti a ń pe ni Duiwelskloof. Ni deedee akoko yii iyawo mi pẹlu pa iṣẹ olukọni rẹ̀ tì ó sì darapọ mọ́ mi ninu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna. Ni ọsan ọjọ kan ni 1950, a pada de lati ẹnu iṣẹ-isin papa lati ri apoowe nla kan lati ọ̀dọ̀ Society. Si iyalẹnu wa, o ni ikesini ninu fun mi lati gba idanilẹkọọ gẹgẹ bi alaboojuto arinrin-ajo kan. Fun ọdun mẹta, a bẹ awọn ijọ wò ni South Africa, ati lẹhin naa ni 1953 a yàn wá si Lesotho, orilẹ-ede kan ti ilẹ yipo ni aarin gbungbun South Africa.
Iṣẹ-ojiṣẹ ni Lesotho ati Botswana
Nigba ti a bẹrẹ sii ṣiṣẹsin ni Lesotho, ọpọlọpọ ahesọ ni o wà pe awọn ajeji jẹ ayansọju ifirubọ. Emi ati iyawo mi ni a ṣaniyan, ṣugbọn ifẹ wa fun awọn ará ni Lesotho ati ifẹ alejoṣiṣe wọn ràn wá lọwọ laipẹ lati gbagbe gbogbo awọn ibẹru bẹẹ.
Lati ṣiṣẹsin awọn ijọ ni awọn Oke Maluti ti Lesotho, mo maa ń wọ ọkọ̀ ofuurufu, ni fifi aya mi silẹ ni ilẹ pẹrẹsẹ naa nibi ti oun ti ń ba iṣẹ-isin aṣaaju-ọna lọ titi di ìgbà ti mo bá dé. Awọn ọ̀rẹ́ fi inurere sin mi lati ijọ kan si omiran lati ràn mi lọwọ ki n maṣe sọnu ni awọn oke naa.
Lẹẹkan ri a sọ fun mi pe lati lè dé ijọ ti o tẹle e, a nilati sọdá Odò Orange lori ẹṣin. A mú un dá mi loju pe ẹṣin mi jẹ oniwa pẹlẹ ṣugbọn a kilọ fun mi pe nigba ti omi ba di eyi ti o lagbara jù, awọn ẹṣin sábà maa ń gbiyanju lati yọ araawọn kuro labẹ ẹrù ti a di rù wọn. Mo páyà nitori pe emi kìí ṣe ọ̀gẹṣin daradara bẹẹ ni emi kìí si ṣe òmùwẹ̀ daradara kan. Laipẹ a wà ninu odò naa, ti omi naa sì ru de ibi gàárì. Ẹ̀rù bà mi debi pe mo ju okun ijanu ẹṣin naa silẹ ti mo si wà mọ́ gọ̀gọ̀ ẹṣin naa pinpinpin. Iru itura wo ni o jẹ nigba ti a gunlẹ si odikeji bèbè odò naa laisewu!
Ni alẹ ọjọ yẹn agbarakaka ni mo fi lè sùn nitori pe ara kan mi gógó nitori gigun ẹṣin naa. Ṣugbọn gbogbo inira wọnyẹn tobẹẹ o si jù bẹẹ lọ, nitori pe awọn ọ̀rẹ́ fi imọriri ti o ga hàn fun ibẹwo wa. Nigba ti mo bẹrẹ iṣẹ ayika ni Lesotho, gongo awọn akede 113 ni o wà. Lonii, iye yẹn ti roke de 1,649.
Ni ọdun 1956 iṣẹ-ayanfunni iwaasu wa ni a yipada si Bechuanaland Àgbókèèrè-ṣàkóso, eyi ti a ń pe ni Botswana nisinsinyi. Botswana jẹ orilẹ-ede kan ti o tobi lọpọlọpọ, ọ̀nà ti o si tubọ jìnnàréré ni a nilati kari lati de ọ̀dọ̀ gbogbo awọn akede. A rinrin-ajo ninu ọkọ̀ oju-irin tabi ninu ọkọ̀ akérò alainilelori. Kò si ijokoo kankan, nitori naa a nilati jokoo nilẹ pẹlu awọn ẹrù irin-ajo wa. A sábà maa ń de ebute wa pẹlu ekuru táútáú ti yoo sì ti rẹ̀ wá. Awọn Kristian ará wa maa ń kí wa kaabọ ni gbogbo ìgbà, oju wọn ti o layọ si ń tù wa lara.
Ni akoko yẹn, awọn itẹjade Society wà labẹ ifofinde ni Botswana, nitori naa iwaasu ile-de-ile wa ni a ṣe tiṣọratiṣọra lailo iwe ikẹkọọ Society. Nigba kan a ká wa mọ́ ibi ti a ti ń ṣiṣẹ lẹgbẹẹ abule Maphashalala ti a si faṣẹ ọba mú wa. Lati gbèjà araawa a kà lati inu Bibeli, ni titọkasi iṣẹ-aṣẹ wa gẹgẹ bi a ṣe kọsilẹ ninu Matteu 28:19, 20. Bi o tilẹ jẹ pe diẹ ninu awọn káńsẹ́lọ̀ ni eyi wọ̀ lọ́kàn, olóyè naa paṣẹ pe ki a fi ọrẹ́ na awọn Ẹlẹ́rìí adugbo. Nigba naa, si iyalẹnu wa, alufaa ṣọọṣi rọ oloye naa lati ṣe oju aanu ki o si dariji wa. Oloye naa fohunṣọkan, a sì dá wa silẹ.
Ni oju inunibini ati ifofinde lori iwe-ikẹkọọ wa, iṣẹ Ijọba naa ń baa lọ lati maa tẹsiwaju. Nigba ti mo de Botswana, gongo 154 akede ni o wà. Ọdun mẹta lẹhin naa nigba ti a mu ifofinde naa kuro, iye yẹn ti roke de 192. Lonii, 777 awọn Ẹlẹ́rìí fun Jehofa ni o wà ti ń waasu ni ilẹ yẹn.
Kikọni ati Titumọ
Bi akoko ti ń lọ, a lò mi gẹgẹ bi olukọni ni Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Ijọba fun awọn Kristian alagba. Lẹhin naa mo gbadun anfaani jijẹ olukọni ni Ile-ẹkọ Iṣẹ-isin Aṣaaju-ọna. Emi ati aya mi tun ṣiṣẹsin loorekoore ni ẹ̀ka South Africa. Ni iru awọn akoko bẹẹ mo ń ṣeranlọwọ pẹlu ṣiṣetumọ, ti Caroline si ń ṣiṣẹ ni ile idana.
Ni ọjọ kan ni 1969, alaboojuto ẹ̀ka, Frans Muller, tọ̀ mi wa, ó sì sọ pe: “Arakunrin Thongoana, emi yoo fẹ lati ri iwọ ati aya rẹ ni ọfiisi mi.” Nibẹ ni o ti ṣalaye pe a ti wà lara awọn wọnni ti a yàn gẹgẹ bi ayanṣaṣoju si Apejọpọ “Alaafia Lori Ilẹ-aye” ti 1969 ni London. A gbadun iwa alejoṣiṣe onifẹẹ ti awọn ará wa ni England ati Scotland, o sì mu ki imọriri wa ga sii lọpọlọpọ fun ẹgbẹ́ ará kari-aye.
Fun ẹwadun mẹrin ti o ti kọja, Caroline ti jẹ aduroṣinṣin alabaakẹgbẹ mi ninu iṣẹ igbesi-aye wa gẹgẹ bi ajihinrere alakooko kikun. A ti ṣajọpin ọpọlọpọ ayọ ati awọn ibanujẹ diẹ papọ. Bi o tilẹ jẹ pe a padanu meji ninu awọn ọmọ wa ninu iku, ọmọbinrin wa, Damaris, dagba lati jẹ Ẹlẹ́rìí rere o si ṣajọpin ninu iṣẹ itumọ ni ẹ̀ka South Africa.
Ilera wa kò yọnda fun wa mọ́ lati ṣajọpin ninu iṣẹ arinrin-ajo, nitori naa fun awọn ọdun diẹ ti o ti kọja, a ti jẹ aṣaaju-ọna akanṣe ni ijọ kan ni Seshego, ilu awọn ara Africa kan lẹbaa Pietersburg. Mo ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto oluṣalaga. Bibeli sọ pe “ni iwaju rẹ [Jehofa] ni ẹ̀kún ayọ wa,” mo si ti ri ayọ ati itẹlọrun nitootọ ninu ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun ni iha guusu Africa.—Orin Dafidi 16:11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Jijẹrii ni ilu Seshego, South Africa