ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 5/1 ojú ìwé 25-29
  • Ẹ Maa Baa Lọ ni Fífúnrúgbìn—Jehofa Yoo Si Mu Ibisi Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Maa Baa Lọ ni Fífúnrúgbìn—Jehofa Yoo Si Mu Ibisi Wa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apẹẹrẹ Rere Òbí ati Idalẹkọọ
  • Sinu Iṣẹ-isin Aṣaaju-ọna
  • Iṣẹ-ayanfunni—Ireland
  • Iwa-ipa Awọn Eniyankeniyan
  • Awọn Èso Otitọ Hù Jade
  • Awọn Iṣarasihuwa Ti Nyipada
  • Idalẹkọọ Akanṣe ni Ile-ẹkọ Gilead
  • Ibukun Jehofa Nbaa Lọ
  • Ohun Dídára Jùlọ Tí Mo Lè Lo Ìgbésí-Ayé Mi Fún
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • “Áńgẹ́lì Jèhófà Dó Yí Àwọn Tí ó Bẹ̀rù Rẹ̀ Ká”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Mo Rí Itẹlọrun Ninu Ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 5/1 ojú ìwé 25-29

Ẹ Maa Baa Lọ ni Fífúnrúgbìn—Jehofa Yoo Si Mu Ibisi Wa

GẸGẸ BI FRED METCALFE TI SỌ Ọ

NI KUTUKUTU ni 1948, lẹnu iṣẹ ojiṣẹ ile-de-ile mi, Mo ṣebẹwo si oko kekere kan ni ẹhin ode Cork ni guusu Ireland. Nigba ti mo ṣalaye fun àgbẹ̀ naa ẹni ti mo jẹ, oju rẹ̀ pọ́n. O gbanájẹ o kígbe pe emi jẹ Kọmunist, ti o sì salọ lati lọ mu àmúga ìroko nla. Lai sì ro o wo lẹẹmeji, mo bẹ́ gìjà jade kuro ninu àgbàlá oko naa ti mo sì fò sori kẹ̀kẹ́ naa ti mo ti fisilẹ lẹba ọna. Òkè naa ti o wa nibẹ ṣe gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gan-an ṣugbọn mo nwa kẹ̀kẹ́ sọkalẹ pẹlu ìyárakankan bi mo ti le ṣe to laiboju wẹhin, bi mo ṣe wòye pe àgbẹ̀ naa ti ju àmúga ìroko naa tẹle mi lẹhin bi ẹni ju ẹ̀ṣín.

MO TI di ojulumọ daradara si iru awọn ihuwapada bawọnyi ni awọn ọdun meji ti mo ti de si orilẹ ede Ireland lati England gẹgẹ bi aṣaaju ọna akanṣe ni 1946. Awujọ kekere awọn oniwaasu Ijọba naa ti mo darapọ mọ́, kiki nnkan bii 24 niye, ti niriiri ẹmi ikóguntini ati ọ̀rọ̀ ìyọṣùtì. Ṣugbọn mo ni igbọkanle pe ẹ̀mí Jehofa nigbẹhin gbẹhin yoo mu awọn eso jade.—Galatia 6:8, 9.

Ṣaaju ki nto rohin bi awọn nnkan ṣe jẹyọ jade, bi o ti wu ki o ri, ẹ jẹ ki nsọ fun yin diẹ nipa ibẹrẹ igbesi aye mi ati idalẹkọọ naa ti o ran mi lọwọ labẹ iru awọn ipo ti ndanniwo bawọnyi.

Apẹẹrẹ Rere Òbí ati Idalẹkọọ

Baba mi ṣe alabaapade otitọ ni kutukutu 1914. Nigba ti o nrinrin ajo lọ sile lati ibi eré ìje bọọlu kan ni Sheffield, England, oun ka iwe àṣàrò kukuru Bibeli kan, ti o ṣalaye ipò awọn oku. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ oun ti ṣebẹwo si ọpọlọpọ awọn ṣọọṣi ninu iwakiri fun awọn idahun si awọn ibeere rẹ̀ ṣugbọn pẹlu aṣeyọri diẹ. Ohun ti o ka nisinsinyi ninu iwe àṣàrò kukuru yẹn, bi o ti wu ki o ri, ru ú lọkan soke. Oun ranṣẹ beere fun awọn idipọ mẹfa ti Studies in the Scriptures tí iwe àṣàrò kukuru naa polowo, ti o sì nka wọn pẹlu iharagaga, titi di awọn wakati kutukutu owurọ. Ni kiakia Baba mọ pé otitọ ni.

Laipẹ, oun bẹrẹ sii darapọ mọ ijọ adugbo ti awọn Ẹlẹrii Jehofa, idarapọ ti nba a lọ fun eyi ti o ju 40 ọdun, ọpọ ninu ọdun wọnyi ni o fi nṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto oluṣalaga. Si idunnu baba mi, meji ninu awọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo awọn arabinrin rẹ̀ mẹtẹẹta tẹwọgba otitọ. Ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀ jẹrii fun ọ̀dọ́ alaboojuto ile itaja kan, oun ati arabinrin rẹ̀ di Kristian oluṣeyasimimọ ati ẹni ami ororo. Baba mi ati arakunrin rẹ̀ gbe awọn ọ̀dọ́bìnrin meji wọnyi niyawo.

Ninu idile mi, mo jẹ ọkan ninu awọn ọmọdekunrin mẹrin ti a tọ dagba ninu “ẹkọ ati ikilọ Oluwa.” (Efesu 6:4) Mo layọ pe awọn òbí mi lo gbogbo isapa ninu gbigbin otitọ sinu wa. Ni saa akoko naa kò si awọn itẹjade paapaa julọ ti a ṣeto lati fi ran awọn òbí lọwọ lati kọ́ awọn ọmọ wọn ni otitọ Bibeli; ṣugbọn a ni ikẹkọọ Bibeli idile deedee lẹẹmeji lọsẹ ni lilo iwe naa Duru Ọlọrun, ati bakan naa pẹlu ijiroro ti o ṣe deedee ti ọ̀rọ̀ ẹsẹ ìwé ojoojumọ fun ọjọ naa.—Deuteronomi 6:6, 7; 2 Timoti 3:14, 15.

Iya mi ati baba mi pẹlu jẹ apẹẹrẹ agbayanu ninu imọriri wọn fun awọn ipade ati itara wọn fun iṣẹ isin. Ni afikun si awọn animọ rere rẹ̀ nipa tẹ̀mí, baba mi tun mọ bi a ti ńṣàwàdà daradara, eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ wá jogun. Iṣẹ àṣekára awọn òbí mi ṣamọna si awọn iyọrisi rere. Gbogbo awọn ọmọkunrin wọn mẹrẹẹrin, ti wọn wa ni ọjọ ori ọgọta siwaju bayii, ṣì nfi pẹlu ayọ ṣiṣẹsin Jehofa sibẹsibẹ.

Sinu Iṣẹ-isin Aṣaaju-ọna

Ni April 1939, ni ọjọ́ ori 16, mo pari ile-ẹkọ ti mo sì di aṣaaju-ọna deedee. Baba mi darapọ pẹlu mi ninu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna naa ti o sì fun mi idalẹkọọ ti o tayọ julọ. Ni ririn irin ajo nipasẹ kẹ̀kẹ́, awa kari gbogbo ipinlẹ naa ti o wà laaarin ibusọ meje ni ayika ile wa jalẹjalẹ. Ni ọjọ kọọkan awa mejeeji yoo mu 50 awọn iwe pẹlẹbẹ, ti awa ki yoo sì pada wa si ile titi di igba ti a ba ti fi gbogbo wọn sode.

Ọdun meji lẹhin naa, mo ni anfaani lati jẹ ọkan ninu awọn aṣaaju-ọna akanṣe akọkọ ti a yànsípò ni Britain. O jẹ idunnu lati tẹwọgba ibukun yii, ṣugbọn o jẹ iriri alaibarade lati fi ibugbe alayọ ti o laabo ti o jẹ ti iṣakoso Ọlọrun silẹ lọ. Bi akoko ti nlọ ati pẹlu iranlọwọ Jehofa, mo ṣatunṣebọsipo.

Iṣẹ-isin aṣaaju-ọna mi ni a dilọwọ ni akoko Ogun Agbaye Keji nigba ti, pẹlu awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹrii miiran, a rán mi ni ẹ̀wọ̀n lori ọran aidasi tọtun tosi. Ni Ọgbà ẹ̀wọ̀n Durham, a dá mi yà sọtọ gẹgẹ bi YP (Young Prisoner [Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́wọ̀n]). Eyi tumọsi pe mo nilati wọ ṣokoto péńpé—iyatọ kan ti ko ṣanfaani ni ipo oju-ọjọ ti o tutù. Wulẹ woye Wilf Gooch (ti o jẹ oluṣekokaari Igbimọ Ẹka ni Britain bayii), Peter Ellis (ọkan ninu mẹmba Igbimọ Ẹka ti Britain), Fred Adams, ati emi—ti gbogbo wa jẹ nnkan bii ẹsẹ bata mẹfa ni giga—ti a duro papọ ti a sì wọ̀ ṣokoto penpe gẹgẹ bi awọn ọmọdekunrin ti nlọ si ile-ẹkọ!

Iṣẹ-ayanfunni—Ireland

Tẹle itusilẹ mi kuro ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo ṣe aṣaaju-ọna ni oriṣiriṣi awọn apa England fun ọdun mẹta. Nigba naa mo gba iṣẹ-ayanfunni kan ti yoo jẹ eyi ti ndanniwo ti o si ntẹnilọrun lọna jijinlẹ—orilẹ ede Ireland. Gbogbo ohun ti mo mọ̀ nipa apa guusu Ireland ni pe o fẹrẹẹ jẹ gbogbo eniyan ti o wà nibẹ ni wọn jẹ onisin Roman Katoliki. Ṣugbọn emi kò kọbiara si awọn ọ̀rọ̀ alaigbeniro ti awọn diẹ sọ ti emi kò sì lọ́tìkọ̀ lati tẹwọgba iṣẹ naa. Eyi jẹ akoko naa fun imugbooro ijọsin tootọ, o sì da mi loju pe Jehofa, nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, yoo ran mi lọwọ.

Eyi ti o pọ julọ ninu awọn Ẹlẹrii ni orilẹ-ede Ireland wà ni olú-ìlú, Dublin, pẹlu kiki ẹyọkan tabi meji ti wọn wà nibi ọtọọtọ ni apa ibomiran. Nipa bayii, awọn eniyan ti o pọ̀ julọ kò tii fi ìgbà kan rí rí ọkan ninu awọn Ẹlẹrii Jehofa. Papọ pẹlu awọn aṣaaju-ọna akanṣe mẹta miiran, mo bẹrẹ iṣẹ ni ilu Cork. Ko rọrun lati ri olufetisilẹ kan. Ni akoko Isin Mass wọn, awọn alufaa nfi ìgbà gbogbo kilọ lodisi wa, ni pipe wa ni “awọn elèṣù Kọmunist.” Awọn iwe irohin pẹlu kilọ lodisi awọn igbokegbodo wa.

Ni ọjọ kan onígbàjámọ̀ kan gẹ irun mi ni lilo abẹfẹ́lẹ́ gbọọrọ (amú bí abẹ). Bi a ṣe nba ijiroro lọ, o beere ohun ti mo nṣe ni Cork. Nigba ti mo sọ fun un, o gbinájẹ ti o sì ńṣépè fun mi. Ọwọ́ rẹ̀ ńgbọ̀npẹ̀pẹ̀ pẹlu ibinu, mo sì ri ìran pe mo nrin jade ninu ṣọọbu naa pẹlu orí mi ti mo kibọ abiya mi! Iru itura wo ni o jẹ́ lati jade kuro ninu ṣọọbu rẹ̀ laifarapa!

Iwa-ipa Awọn Eniyankeniyan

Ni awọn ìgbà miiran a dojukọ iwa-ipa awọn eniyankeniyan. Fun apẹẹrẹ, ni ọjọ́ kan ni March 1948, ọwọ́ wa dí ninu iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile nigba ti awujọ eniyankeniyan fipa kọlu alabaaṣiṣẹpọ mi, Fred Chaffin. Bi awọn awujọ ti ńlé e lọ, Fred salọ si ibùdókọ̀ bọ́ọ̀sì kan ti o sì pàrọwà si awakọ bọ́ọ̀sì kan ati agbèrò kan fun iranlọwọ. Kaka bẹẹ, wọn darapọ ninu igbejako naa. Fred tubọ salọ siwaju sapa oke ọna naa ti o sì gbiyanju fi ara pamọ́ lẹhin ògiri gíga ti o fi ààlà si ile alufaa.

Laaarin akoko naa, mo ti lọ gbe kẹ̀kẹ́ mi. Lati pada si aarin ilu-nla naa, mo gba ti ẹ̀gbẹ́ ọna kan, ṣugbọn nigba ti mo yọ si opopo ọna naa, awujọ eniyan keniyan naa ti nduro. Ọkunrin meji gbá apoti mi mu, wọn sì ju awọn nnkan ti o wà ninu rẹ̀ sinu afẹ́fẹ́. Nigba naa wọn bẹrẹ sii lù mi ni ikuuku ti wọn sì ńgbá mi. Lojiji ọkunrin kan farahan. Oun jẹ ọlọpaa ṣugbọn kò wọ aṣọ ọlọpaa, o sì da igbejako naa duro, o mú emi ati awọn naa lọ si àgọ́ ọlọpaa.

Igbejako yii pese ipilẹ fun ‘gbigbeja ati fifi ihinrere naa mulẹ lọna ofin.’ (Filipi 1:7, NW) Nigba ti ẹjọ naa de ile ìgbẹ́jọ́, ọlọpaa naa ti o ti gbà mi là, oun fúnraarẹ̀ onisin Roman Katoliki kan, pese ẹri, a si da awọn eniyan mẹfa lẹbi fun igbeja koni. Ẹjọ naa fihan pe awa ni ẹ̀tọ́ lati lọ lati ẹnu ọna de ẹnu ọna ti eyi sì jẹ idena fun awọn miiran ti wọn le ronu lati yiju si iwa-ipa.

Ni akọkọ a gbé e yẹwo pe o lewu pupọ ju lati ran awọn arabinrin gẹgẹ bi awọn aṣaaju-ọna sinu awọn ilu gẹgẹ bi Cork. Bi o ti wu ki o ri, lọpọ ìgbà o dabi ẹni pe yoo dara ju fun awọn arabinrin lati ṣe ikesini sọdọ awọn olufifẹhan obinrin. Nitori naa, kete ṣaaju gbejakoni yii, Society ti pinṣẹyan fun awọn arabinrin aṣaaju-ọna daradara meji fun Cork. Ọkan ninu wọn, Evelyn MacFarlane, lẹhin naa di ojiṣẹ Ọlọrun ni ilẹ̀ ajeji ti o sì ṣe iṣẹ titayọ ni Chile. Ẹni keji, Caroline Francis, ẹni ti o ti ta ibugbe rẹ̀ ni London ki o ba le ṣeeṣe fun un lati ṣe aṣaaju-ọna ni Ireland, di iyawo mi.

Awọn Èso Otitọ Hù Jade

Ìbá ti jẹ ohun ti o rọrun lati ronu pe awa nfi akoko naa ṣofo ni gbigbin awọn eso otitọ Ijọba naa labẹ iru awọn ipo wọnni. Riri otitọ naa ti nhu jade, nitori naa, gbe igbẹkẹle wa ró ninu agbara Jehofa lati mu ki awọn nnkan dagba. Fun apẹẹrẹ, Society nigba kan ti fi orukọ ati adirẹsi ọkunrin kan ranṣẹ ti o ti kọwe beere fun ẹ̀dà iwe naa Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ. Adirẹsi naa naa jẹ ní Fermoy, ilu kekere kan ni nnkan bii 22 ibusọ si ilu nla Cork. Nitori naa mo gbéra lati lọ pẹlu kẹ̀kẹ́ mi ni owurọ Sunday kan lati wa ẹni yii rí.

Nigba ti mo de Fermoy, mo beere lọwọ ọkunrin kan fun itọsọna. Oun wipe: “Óò, iyẹn jẹ ibusọ mẹsan-an miiran ni oju ọna naa.” Mo gbéra lati lọ lẹẹkan sii nigbẹhin gbẹhin mo de oko kan nisalẹ ọna igberiko kekere kan. Ọ̀dọ́ ọkunrin ti o ti beere fun iwe naa ti nduro ni ẹnu abawọle oko naa. Nigba ti mo sọ ẹni ti mo jẹ fun un, oun wipe: “Iwe yẹn tootun fun iwọn iwuwo rẹ̀ ni wúrà!” Awa ni ijumọsọrọpọ ti o dara, agbárakáká ni mo fi ṣakiyesi gígùn kẹ̀kẹ́ ni 30 ibusọ pada si ile. Koda nisinsinyi, lẹhin eyi ti o ti ju 40 ọdun, mo ṣi nri idunnu ti o pọ̀ nigba ti mo ba pade “ọ̀dọ́” ọkunrin yẹn, Charles Rinn, lọdọọdun ni awọn apejọpọ. Lonii, ijọ mẹwaa ni o wà ni agbegbe Cork.

Laaarin awọn ọdun 1950, emi ati Caroline fọ́n awọn irugbin otitọ kaakiri ni awọn ilẹ aarin gbungbun ti Ireland. Iṣiri lati foriti wá ni 1951 nigba ti awọn eniyan ọlọkan tutu gẹgẹ bi “Ìyá àgbà” Hamilton ati ọdọmọbinrin àna rẹ̀ dahunpada ni kiakia. “Ìyá àgbà” Hamilton di akede akọkọ ti o ṣe iribọmi ni Ìgbèríko Longford.—1 Tẹsalonika 2:13.

Awọn ibugbe jẹ iṣoro. Ni gbara ti wọn ba ti fòòró awọn onílé de gongo, wọn yoo sọ fun wa pe ki a jade. Nitori naa, lẹhin ti a ti padanu awọn ibi ìbùwọ̀ mẹta ọtọọtọ, wéréwéré ni itotẹlera, a ra àtíbàbà kan, aṣọ nínípọn ti a lè tẹ́ silẹ, ati awọn àpò àtẹ́sùn ti a sì gbé kaakiri ninu mọto Ford onímódẹ́ẹ̀lì Y. Awa yoo gbe àtíbàbà naa kalẹ nibikibi ti a ba a le ri lẹhin ijẹrii ọjọ kọọkan. Lẹhin naa, awa ra ile àgbérìn ti o gùn ni 13 ẹsẹ bata. O jẹ ọkan tí o kere pupọ pẹlu awọn ohun eelo amáyédẹrùn ode oni diẹ—awa nilati rìn ni idamẹrin ibusọ kan fun omi mimu—ti kò sì sí ohun idena ooru, ṣugbọn fun wa o dabi fàájì. Jijẹ tí mo jẹ́ aláwàdà ni a fi sabẹ idanwo ni ọjọ kan nigba ti mo yọ́tẹ̀rẹ́ lori gbòǹgbò igi ti o ti rẹ kan ti mo sì takiti sẹhin sinu kanga gígùn, fífún, ṣugbọn ti kò jìn pupọ. Sibẹsibẹ, awa pese ibugbe fun alaboojuto ayika ati iyawo rẹ̀ ninu ile àgbérìn yẹn nigba ti wọn bẹ̀ wá wò.

Ni awọn ìgbà miiran awọn eniyan ọlọkan rere maa nfi inurere ti a kò reti tẹlẹ hàn. Fun apẹẹrẹ, awa lọ si Sligo ni iwọ-oorun Ireland ni 1958, ọdun mẹjọ lẹhin ti wọn lé tọkọtaya aṣaaju-ọna miiran jade kuro ninu ilu. Awa gbadura si Jehofa fun iranlọwọ lati fun wa ni ibi aaye fun ile àgbérìn naa, lẹhin iwakiri fun awọn wakati pupọ, awa ṣe alabaapade ibi ti wọn ti nfọ okuta nla ràpàtà kan ti a kò lò mọ́. Ọkunrin kan ti ndari agbo maluu nisalẹ ọna naa sọ fun wa pe idile oun ni o ni ibi ti wọn ti nfọ okuta si wẹ́wẹ́ naa. “Njẹ awa lè lò ó?” ni awa beere, ni sisọ fun un pe awa jẹ aṣoju fun ẹgbẹ Bibeli kan. Oun sọ pe iyẹn yoo dara.

Kete lẹhin naa o ṣe iwadii: “Iru Ẹgbẹ Bibeli wo ti yin?” O jẹ akoko oniharagaga kan. A sọ fun un pe awa jẹ Ẹlẹrii Jehofa. Si itura wa gigalọla, oun nbaa lọ gẹgẹ bi ọ̀rẹ́. Awọn ọsẹ diẹ lẹhin naa, oun fi iwe ẹ̀rí isanwo le wa lọwọ fun híháyà ibi àyè naa fun ọdun kan. “Awa kò fẹ́ owó eyikeyii,” ni oun wi. “Ṣugbọn awa mọ̀ atako ti ẹyin eniyan wọnyi dojukọ, nitori naa bi ẹnikẹni ba beere fun ẹ̀tọ́ yin lati wà lori ibi aye yii, ẹ̀rí yin niyẹn.”

Nigba ti a ṣì wà ni Sligo, a gbọ́ nipa ọkunrin kan, olutọju ile itaja ati agbá bọọlu tí ó gbajumọ, ẹni ti o fi ifẹ diẹ hàn nigba ti awọn aṣaaju-ọna akọkọ ṣì wà ninu ilu naa sibẹsibẹ. Iwọnba ijumọsọrọpọ diẹ ni oun ní fun ọdun mẹjọ, bi o ti wu ki o ri, nitori naa awa ṣe kayefi bi oun ṣe wà bayii. Ẹ̀rín abúyẹ̀rì naa ti o wà loju Mattie Burn nigba ti mo sọ ẹni ti emi jẹ pese idahun naa. Irugbin otitọ naa ti a ti gbìn ni ọpọ ọdun ṣaaju kò tii kú. Oun sibẹsibẹ ṣì jẹ́ mẹmba ijọ kekere alakitiyan naa ni Sligo.

Awọn Iṣarasihuwa Ti Nyipada

Ibi kan ti o ṣakopọ ni ṣókí iwa idojuujakọni ọpọlọpọ si wa jẹ ni ilu Athlone. Nigba ti a bẹrẹ iṣẹ ijẹrii nibẹ ni pẹrẹwu ni awọn ọdun 1950, awọn alufaa ṣeto fun gbogbo awọn ti ngbe ni apakan ilu naa lati fọwọsi iwe kotẹmilọrun kan ti nsọ pe awọn kò fẹ́ ki awọn Ẹlẹrii Jehofa ṣe ikesini si ẹnu ọna wọn. Wọn fi eyi ranṣẹ si ijọba, ni mimu ki iṣẹ́ ni Athlone ṣoro gan-an fun ọpọlọpọ ọdun. Ni igbakan ti awujọ awọn ọ̀dọ́ kan dá mi mọ gẹgẹ bi Ẹlẹrii kan wọn bẹrẹ sii sọ okuta. Nigba ti mo duro ni iwaju fèrèsé oníjígí ilé ìtajà kan, onile ìtajà naa késí mi wọle sinu ilé ìtajà rẹ̀—o fẹ́ lati daabobo fèrèsé jíígí rẹ̀ ju didaabobo mi lọ—ti o sì jẹ́ ki njade lẹnu ọn abajade ẹhin.

Laipẹ yii, bi o ti wu ki o ri, ni August 1989, nigba ti mo dari isinku kan ni Athlone fun arakunrin oluṣotitọ kan, o kan ṣa nyanilẹnu ni lati rí bi Jehofa ṣe mu ki awọn nnkan dàgbà nibẹ. Yatọ si awọn mẹmba ijọ naa, nnkan bii 50 awọn eniyan adugbo fetisilẹ tọwọtọwọ si ọ̀rọ̀ isinku naa ninu Gbọngan Ijọba daradara ti awọn arakunrin ti kọ́.

Idalẹkọọ Akanṣe ni Ile-ẹkọ Gilead

Ni 1961, a késí mi fun idalẹkọọ oloṣu mẹwaa ni Ile-ẹkọ Bibeli ti Watchtower ni Gilead. Idalẹkọọ akanṣe yii wà fun kìkì awọn arakunrin nikan, nitori naa Caroline ati emi nilati fun ikesini naa ni igbeyẹwo taduratadura. A ko tii pin wa níyà rí fun 12 ọdun. Ju bẹẹ lọ, niwọnbi iyawo mi pẹlu ti ni ifẹ ọkan jijinlẹ lati lọ si Ile-ẹkọ Gilead ati lati di ojihin iṣẹ Ọlọrun, oun ni a jákulẹ̀ ni pataki julọ bi a kò ṣe fun un ni ikesini. Ṣugbọn, ni jijẹ ọmọluwabi, oun fi ire Ijọba naa si ipo àkọ́kọ́ ti o sì fohunṣọkan pe mo nilati lọ. Idalẹkọọ naa jẹ anfaani agbayanu kan. Ṣugbọn o jẹ idunnu lati pada sile ati lati kowọnu iṣẹ́ ni ọfiisi ẹka ile iṣẹ Society, ni fifun 200 awọn Ẹlẹrii tabi ju bẹẹ lọ ni iṣiri awọn ti ńgbìn ti wọn sì nbominrin ni Ireland ni ibẹrẹ awọn ọdun 1960.

Awọn ọdun diẹ lẹhin naa, ni 1979, Caroline nilati lọ si orile-iṣẹ agbaye ti awọn Ẹlẹrii Jehofa ni New York nigba ti a késí mi si idalẹkọọ akanṣe Gilead kan fun awọn mẹmba Igbimọ Ẹka. O jẹ koko pataki ohun ti o wa yọrisi apa ikẹhin ninu igbesi aye rẹ̀. Ọdun meji lẹhin naa oun kú. Ni gbogbo 32 ọdun ti a fi ṣiṣẹsin papọ ninu iṣẹ isin alakooko kikun, Caroline kò fi ìgbà kan ri padanu itara fun iṣẹ isin Jehofa tabi igbẹkẹle rẹ̀ pe oun yoo mu ki awọn nnkan dàgbà.

Mo padanu rẹ̀ lọna titobi. Ohun kan ti o ran mi lọwọ lati koju rẹ̀ jẹ́ ọrọ ẹkọ kan ninu iwe-irohin Ji! ti akoko naa, ti a fun ni akori naa “Kikẹkọọ lati Gbe Laisi Ololufẹ Rẹ.” (April 8, 1982) Omije wa si ojú mi nigbakigba ti mo ba ronu nipa alabaakẹgbẹpọ mi ti mo padanu, ṣugbọn mo ṣe ohun ti ọrọ ẹkọ yẹn damọran ti mo sì jẹ ki ọwọ́ mi dí ninu iṣẹ-isin Jehofa.

Ibukun Jehofa Nbaa Lọ

Ọdun kan ṣaaju eyi, ni April 1980, mo wa nibẹ nigba ti Arakunrin Lyman Swingle ti Ẹgbẹ Oluṣakoso ya ẹka ile iṣẹ titun ni Dublin si mimọ. Ẹ wo irumọlara soke ti o jẹ lati ri awọn akede 1,854 ninu papa naa, eyi ti o ni ninu apá Ariwa Ireland pẹlu nigba naa! Ati bayii, ọdun mẹwaa lẹhin naa, Yearbook rohin gongo 3,451 fun 1990!

Bi akoko ti nlọ mo ni afikun ibukun kan. Nigba ti mo nṣiṣẹsin gẹgẹ bi oludanilẹkọọ Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Ijọba, mo pade Evelyn Halford, arabinrin kan ti o fanimọra ti o sì ni itara ẹni ti o ti ṣikuro lọ si Ireland lati ṣiṣẹsin nibi ti aini ti pọ ju. A ṣe igbeyawo ni May 1986, oun sì ti jẹ iranlọwọ gidi fun mi ninu gbogbo igbokegbodo iṣakoso Ọlọrun mi.

Ninu 51 ọdun iṣẹ isin alakooko kikun mi lati igba ti mo ti fi ile-ẹkọ silẹ, 44 ni mo ti lò ni Ireland. O jẹ ohun ti ńmọ́kànyọ̀ lati ri ọpọlọpọ ti mo ran lọwọ ti wọn ṣì nṣiṣẹsin Jehofa sibẹsibẹ, awọn diẹ gẹgẹ bi awọn alàgbà ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ. Emi lè sọ laisi ilọtikọ pe idunnu titobi julọ ti ẹni kan lè ní ni lati ran ẹlomiran lọwọ si oju ọna si ìyè.

O ti jẹ ohun ti nfun igbagbọ lokun lati rí ijọsin tootọ ti ntankalẹ ni ibi kan tẹle omiran ni Ireland, laika atako gbigbona janjan si. Bayii, nnkan bii 3,500 awọn akede ni wọn nkẹgbẹpọ pẹlu awọn ijọ ti o ju 90 jakejado orilẹ-ede naa. Nitootọ, ko si aala si ohun ti Jehofa lè ṣe. Oun yoo mu ki awọn nnkan dàgbà bi awa farabalẹ gbìn ti a sì bominrin. (1 Kọrinti 3:6, 7) Mo mọ eyi pe o jẹ otitọ. Mo ti ríi ti o ṣẹlẹ ni Ireland.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́