Ibùdókọ̀ Òfuurufú “Kanku”—A Rí i, Àmọ́ A Kì í Gbúròó rẹ̀
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ JAPAN
BÍ Ẹ ti ń sún mọ́ Ibùdókọ̀ Òfuurufú Ńlá Kansai láti òkè, ìwọ óò rí erékùṣù kan tí ó ní àkọlé kan “Kansai” ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.a Erékùṣù Japan yìí fi nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún jìnnà sí etíkun Ìyawọlẹ̀ Omi Osaka. Kìkì ibùdókọ̀ òfuurufú náà àti àwọn ohun èèlò tí ó tan mọ ọn nìkan ni o lè rí. Ní ti gidi, a ṣe erékùṣù náà fún ète pàtàkì ti lílò ó gẹ́gẹ́ bí ibùdókọ̀ òfuurufú. Nígbà tí a ṣí ibùdókọ̀ òfuurufú náà ní September 1994, a fún un ní orúkọ àpèjẹ́ náà, Kanku, ìkékúrú orúkọ rẹ̀ lédè Japan, Kansai Kokusai Kuko.
Afárá títì márosẹ̀ kan, tí ó gùn ní 3.75 kìlómítà, já erékùṣù ibùdókọ̀ òfuurufú náà pọ̀ mọ́ orí ilẹ̀, tí èyí sì mú kí mọ́tò àti ọkọ̀ ojú irin lè dé ibẹ̀. Erékùṣù náà ní àwọn ohun èèlò ibùdókọ̀ fún ọkọ̀ òkun àti ọkọ̀ òbèlè lílò. Ṣùgbọ́n, kí lò dé tí wọ́n kọ́ odindi erékùṣù tuntun fún ibùdókọ̀ òfuurufú?
Ibùdókọ̀ Òfuurufú Tí A Kì í Gbúròó Rẹ̀
Àwọn arìnrìn àjò afẹ́ àti àwọn àlejò tí ń wá sí Kansai tí ń pọ̀ sí i ń mú kí ariwo àwọn ọkọ̀ òfuurufú túbọ̀ rinlẹ̀ ní agbègbè tí àwọn ènìyàn ń gbé láyìíká Ibùdókọ̀ Òfuurufú Ńlá Osaka. Láti gba àwọn olùgbé ibẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdíwọ́ ariwo, wọ́n gbé òfin kónílégbélé láàárín agogo mẹ́sàn-án alẹ́ sí méje òwúrọ̀ dìde. Wọn kò fọwọ́ sí mímú kí iye àwọn ọkọ̀ òfuurufú tí ń wọ ibẹ̀ pọ̀ sí i láti 1974. Nípa bẹ́ẹ̀, ó di àìní kánjúkánjú láti ní ibùdókọ̀ òfuurufú tí yóò máa bójú tó ọ̀ràn àwọn èrò ọkọ̀ àti ẹrù tí ń pọ̀ sí i láìsí pé a gbọ́ ọ ní orí ilẹ̀.
Ibùdókọ̀ òfuurufú tí a lè máa lò tọ̀sántòru láìsí pé ó ń fa ìdíwọ́—tí ó jẹ́ ìpèníjà ńlá fún àwọn tí ọ̀ràn ìwéwèédáwọ́lé náà kàn. Ojútùú kan ṣoṣo tí ó yọjú ni láti kọ́ erékùṣù kan tí ó jìnnà sí ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé, kí a sì fi ṣe ibùdókọ̀ òfuurufú. Ìwéwèédáwọ́lé ńlá gbáà ni!
Ìjọba àpapọ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn oníṣòwò tí wọ́n wà ládùúgbò pèsè owó fún ìwéwèédáwọ́lé oníbílíọ̀nù 15 dọ́là náà, ní gbígbé ilé iṣẹ́ àdáni kan kalẹ̀ láti kọ́ ibùdókọ̀ tuntun náà, kí ó sì máa ṣàbójútó rẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Keisuke Kimura, igbákejì ààrẹ àgbà Ilé Iṣẹ́ Ibùdókọ̀ Òfuurufú Àwọn Ńlá Kansai, wí fún Jí! pé: “Nítorí pé, ó jẹ́ ilé iṣẹ́ àdáni, agbára wa kò gbé àtilo àkókò púpọ̀ lẹ́nu ṣíṣẹ̀dá erékùṣù náà. A gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ náà kíákíá.”
“Ṣíṣẹ̀dá Erékùṣù Náà”
Láti rí ilẹ̀ nítòsí etíkun jẹ́ ìṣòro kan, àmọ́ ṣíṣẹ̀dá erékùṣù kan tí ó fi kìlómítà márùn-ún jìnnà sí etikun tilẹ̀ túbọ̀ ṣòro. Láti lè ṣẹ̀dá erékùṣù ibùdókọ̀ òfuurufú tí ó jẹ́ hẹ́kítà 511, wọ́n fi yanrìn àti iyẹ̀pẹ̀ tí ó jẹ́ 180 mílíọ̀nù mítà níwọ̀n ìbú, òró òun fífẹ̀ kún ilẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Kimura ṣàlàyé pé: “Ìyẹn dọ́gba pẹ̀lú òkìtì aboríṣóńṣó 73—ìyẹn jẹ́ lára àwọn èyí tí ó tóbi jù lọ tí Ọba Khufu ṣe.”
Ìpele alámọ̀ rírọ̀ kan tí a ní láti gbẹ omi kúrò nínú rẹ̀ wà láàárín ilẹ̀ òkun náà, tí ó fi ìpíndọ́gba mítà 18 jìn. Ọ̀gbẹ́ni Kenichiro Minami, tí ń bójú tó iṣẹ́ fífi yanrìn dí ilẹ̀ náà ṣàlàyé pé: “Òkìtì yanrìn mílíọ̀nù kan, ní ìwọ̀n ìdábùú òbírí 40 sẹ̀ǹtímítà [íǹṣì 16], ni a wà lọ sórí ìpele yẹn láti gbẹ omi inú rẹ̀, kí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lè dúró gbọn-in. Ìtẹ̀wọ̀n yanrìn náà ti omi jáde láti inú ìpele iyẹ̀pẹ̀ rírọ̀ ológún mítà [ẹsẹ̀ bàtà 66] náà, ní mímú kí ó lọ sílẹ̀ sí mítà 14 [ẹsẹ̀ bàtà 46]. Ìsẹ̀gẹ̀dẹ̀ àwọn iyẹ̀pẹ̀ ìpele abẹ́ ilẹ̀ tí kò dọ́gbà ni a bẹ̀rù jù lọ. A lo kọ̀m̀pútà láti ṣírò ibi tí ó yẹ kí a da yanrìn dí gan-an, kí ìsẹ̀gẹ̀dẹ̀ náà ba lè tẹ́jú.”
Lápapọ̀, iyanrìn tí a fi dí i náà jìn tó mítà 33, tí ó dọ́gba pẹ̀lú ilé alájà 10. Bí ó ti wù kí ó rí, lábẹ́ ìtẹ̀wọ̀n iyanrìn náà, ilẹ̀ òkun náà ti rì, ó sì ń rì lọ. A ṣírò rẹ̀ pé, ilẹ̀ òkun náà yóò tún fi mítà 1.5 rì sí i láàárín 50 ọdún, tí yóò sì jẹ́ kí erékùṣù náà fi mítà 4 yọrí sókè ìtẹ́jú òkun.
Ní 1991, kódà, kí á tó ṣẹ̀dá gbogbo erékùṣù náà, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu lórí ilé èbúté èrò àti ilé gogoro ìṣàkóso ọkọ̀ òfuurufú. Lẹ́yìn ohun tí ó lé ní ọdún méje ni iṣẹ́ àṣelàágùn, kíkọ́ erékùṣù, ibùdókọ̀ òfuurufú, àti àwọn ohun èèlò tí ó tan mọ́n ọn tó parí.
Ó Tóbi Ṣùgbọ́n, Ó Wà Pa Pọ̀
Ìyàlẹ́nu ńlá ni ó jẹ́ fún àwọn èrò ọkọ̀ tí ń dé. Arìnrìn àjò kan láti United States sọ pé: “Nígbà tí a óò fi dé ibi ìgbẹrù, àwọn àpótí ẹrù wa ti ṣáájú wa débẹ̀.” Kí ló mú kí gbogbo rẹ̀ lọ geerege bẹ́ẹ̀? Ọ̀gbẹ́ni Kazuhito Arao, tí ń bójú tó ilé èbúté èrò náà, sọ pé: “Ilé èbúté èrò náà tóbi ṣùgbọ́n, ó wà pa pọ̀. Àwọn èrò ọkọ̀ kò ní láti máa lọ́rí káàkiri, bí ó ti máa ń rí ní àwọn ibùdókọ̀ òfuurufú ńlá.”
Bí wọ́n ṣe kọ́ ilé èbúté èrò náà kò le, ṣùgbọ́n ó ṣàrà ọ̀tọ̀. A kọ́ lájorí ilé náà lọ́nà tí yóò dín lílọ bíbọ̀ tí kò pọn dandan kù fún àwọn èrò ọkọ̀. Àwọn èrò ọkọ̀ tí a gbé láàárín orílẹ̀-èdè náà lè kọrí sí ibi tí wọn óò ti gbé ẹrù wọn sílẹ̀ láti ibùdókọ̀ ojú irin, lẹ́yìn náà, kí wọ́n sì lọ sí ibodè tí wọn óò gbà wọnú ọkọ̀ òfuurufú láìsí pé wọ́n ń rìn lọ rìn bọ̀ lórí àkàsọ̀ kankan.
Láti inú lájorí ilé náà, níbi tí wọn óò ti gbé ẹrù wọn sílẹ̀, tí àwọn aṣọ́bodè, àti àwọn agbowó ibodè wà, àwọn àkọ́kún ilé onímítà 700 méjì gbòòrò lọ síhà àríwá àti gúúsù, wọ́n sì darí sí àwọn ibodè 33 tí wọ́n ń gbà wọnú ọkọ̀ òfuurufú. Àwọn èrò ọkọ̀, tí wọ́n ń gba àwọn ibodè tí kò so pọ̀ mọ́ ara ilé náà, lè gba orí ẹ̀rọ ìgbénikiri oníná tí ń dá ṣiṣẹ́, tí a ń pè ní Ẹ̀rọ Ìgbénikiri Àkọ́kún Ilé. Ó máa ń gbé àwọn èrò ọkọ̀ lọ sí ẹnu ibodè tí wọ́n bá fẹ́ láti lọ láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún—èyí sì ní àkókò tí wọ́n fi ń dúró de ẹ̀rọ ìgbénikiri náà nínú.
Ibùdókọ̀ Òfuurufú Tí Ó Yẹ Ní Rírí
Ọ̀gbẹ́ni Arao sọ pé: “Nítorí pé ó jẹ́ ibùdókọ̀ òfuurufú tí ó wà lórí òkun pátápátá, ó bọ́ lọ́wọ́ ìdíwọ́ èyíkéyìí.” Ọ̀gbẹ́ni Kimura gbà pẹ̀lú rẹ̀ nípa sísọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, a ń gbọ́ tí àwọn awakọ̀ òfuurufú ń sọ pé, ó jẹ́ ibùdókọ̀ òfuurufú tí ó rọrùn láti balẹ̀ sí.”
Àwọn mìíràn tún fẹ́ràn bí o ṣe rí. Iṣẹ́ ọnà ilé èbúté èrò náà tí ó ní ìrísí apá ọkọ̀ òfuurufú ti gbé ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn àjò afẹ́ wá sí Kanku. Wọ́n tún gbádùn wíwo bí àwọn ọkọ̀ òfuurufú ti ń gbéra, tí wọ́n sì ń balẹ̀ sórí ibùdókọ̀ òfuurufú erékùṣù ṣíṣàjèjì náà. Ọ̀gbẹ́ni Kimura sọ pé: “A ti ní láti kọ́ ibi ìwòran kan sókè ibùdó ìṣàtúnṣe fún àwọn tí ń rìnrìn àjò afẹ́ wá sí ibùdókọ̀ òfuurufú náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò pète láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” Ìpíndọ́gba 30,000 ènìyàn ní ó máa ń bẹ ibùdókọ̀ òfuurufú náà wò lóòjọ́, kìkì láti wo ibẹ̀.
Bí o bá ṣèbẹ̀wò sí Japan nítòsí agbègbè Kansai, kí ló ṣe tí o kò gba Kanku—ibùdókọ̀ òfuurufú tí àwọn alámùúlégbè rẹ̀ ń rí, àmọ́ tí wọn kì í gbúròó rẹ̀—wọlé tàbí kí o gbabẹ̀ jáde.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kansai ni agbègbè fífẹ̀ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Japan tí ó ní nínú, àwọn ìlú ńlá olówò ní Osaka àti Kobe àti àwọn ìlú ńlá àtayébáyé Kyoto àti Nara. Kokusai koko túmọ̀ sí “ibùdókọ̀ òfuurufú ńlá.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Kansai International Airport Co., Ltd.