Àgbàyanu Àgbáálá Ayé
Ó Ṣàràmàǹdà Gan-an Síbẹ̀, Ó Lẹ́wà Púpọ̀
NÍ ÀKÓKÒ yìí láàárín ọdún, òfuurufú alẹ́ ń gbé ògo ẹwà rẹ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì yọ. Orion ńlá, tí a tètè máa ń rí láti Anchorage, Alaska, títí dé Cape Town, South Africa, ní àwọn ìrọ̀lẹ́ nínú oṣù January ń bẹ́ gìjàgìjà lọ lókè lọ́hùn-ún. Ìwọ́ ha ti fara balẹ̀ wo àwọn ìṣúra ọ̀run, tí a lè rí nínú àwọn ìdìpọ̀ ìràwọ̀ tí a mọ̀ dáradára, bí Orion, lẹ́nu àìpẹ́ yìí bí? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà wò ó gààrà láìpẹ́ yìí, ní lílo Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú Hubble tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe.
Idà Orion ń jù fìrìfìrì láti inú ìràwọ̀ mẹ́ta ara ìgbànú rẹ̀. Ìràwọ̀ tí ó rí bàìbàì tí ó wà láàárín idà náà kì í ṣe ìràwọ̀ gidi rárá, ṣùgbọ́n Orion Nebula ni, ohun kan tí ó ní ẹwà gbígbàfiyèsí, kódà bí a bá fi awò awọ̀nàjíjìn kékeré kan wò ó. Bí ó ti wù kí ó rí, ti ìrànyòò rẹ̀ lápá òkè gbalasa òfuurufú kọ́ ni ìdí tí ó fi fa àwọn amọṣẹ́dunjú onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà mọ́ra.
Jean-Pierre Caillault sọ nínú ìwé ìròyìn Astronomy pé: “Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ṣèwádìí nípa Orion Nebula àti àwọn ìràwọ̀ rẹ̀ kéékèèké púpọ̀ jaburata nítorí pé, ó jẹ́ agbègbè ìràwọ̀ tí ó gbéṣẹ́ jù lọ ní apá ibi tí a wà nínú Ètò Ìgbékalẹ̀ Ìṣùpọ̀ Ìràwọ̀.” Nebula fara hàn bí ibùdó ìbísí ìràwọ̀! Nígbà tí awò awọ̀nàjíjìn Hubble ya fọ́tò Orion Nebula, tí ó kó àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí a kò tí ì rí tẹ́lẹ̀ rí jọ, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kò rí kìkì àwọn ìràwọ̀ àti gáàsì tí ń ràn yòò nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n rí ohun tí Caillault ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “àwọn pọ̀kọ́ bàìbàì kéékèèké. Àwọn pọ̀kọ́ náà jẹ́ àbàwọ́n iná olómi ọsàn. Wọ́n fara jọ èérún oúnjẹ ẹnì kan, tí ó ṣèèṣì já bọ́ sínú fọ́tò náà.” Bí ó ti wù kí ó rí, dípò kí ó jẹ́ àṣìṣe tí ó wáyé nígbà fífọ fọ́tò náà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà gbọ́ pé àwọn pọ̀kọ́ bàìbàì wọ̀nyí jẹ́ “ègé tí ń ṣẹ̀dá pílánẹ́ẹ̀tì ìkórajọpọ̀ ètò ìgbékalẹ̀ ayé tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kóra jọ tí a rí láti ibi tí ó jìnnà tó 1,500 ọdún ìmọ́lẹ̀.” A ha ń ṣẹ̀dá àwọn ìràwọ̀—ní ti gidi, ètò ìgbékalẹ̀ ayé lódindi—ní àkókò yìí nínú Orion Nebula bí? Púpọ̀ lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà gbà gbọ́ bẹ́ẹ̀.
Láti Ibùdó Ìbísí Ìràwọ̀ sí Ibojì Ìràwọ̀
Bí Orion ti ń bẹ́ gìjàgìjà lọ, pẹ̀lú ọfà lọ́wọ́, ó jọ pé ó dojú kọ ìdìpọ̀ ìràwọ̀ Taurus, akọ màlúù. Awò awọ̀nàjíjìn kékeré kan lẹ́bàá etí ìwo ìhà gúúsù akọ màlúù náà yóò fi àbùlẹ̀ iná fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ kan hàn. A ń pè é ní Crab Nebula, tí a bá sì wò ó nínú awò awọ̀nàjíjìn, ó dà bí ìbúgbàù tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn ní ojú ewé 9. Bí Orion Nebula bá jẹ́ ibi ìṣọlọ́jọ̀jọ̀ ìràwọ̀, nígbà náà Crab Nebula, tí ó wà nítòsí, lè jẹ́ ibojì ìràwọ̀ tí ìbúgbàù tí a kò lè lóye ṣekú pa.
Ó lè jẹ́ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ará China tí wọ́n ṣàpèjúwe “Ìràwọ̀ Àjèjì” kan nínú Taurus, tí ó yọ lójijì ní July 4, 1054, tí ó sì mọ́lẹ̀ gan-an débi pé a ṣì ń rí i ní ojú mọmọ fún ọjọ́ 23, ni wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìjábá òjijì yẹn. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, Robert Burnham, sọ pé: “Fún ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ìràwọ̀ náà ń jó wòwò pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ nǹkan bí 400 mílíọ̀nù oòrùn.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà pe iru ìṣekúpara-ẹni àwọn ìràwọ̀ lọ́nà agbàfiyèsí bẹ́ẹ̀ ní ìbúgbàù àwọn ìràwọ̀ bàǹbà. Kódà nísinsìnyí, tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn àkíyèsí náà, àwọn èérún àfọ́kù tí ìbúgbàù yẹn fọ́n ká ń sá kiri ní gbalasa òfuurufú pẹ̀lú ìwọ̀n ìyára tí a fojú díwọ̀n sí 80 mílíọ̀nù kìlómítà lóòjọ́.
Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú Hubble ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọ̀ràn yìí pẹ̀lú, ní wíwo àárín gbùngbùn inú nebula, ó sì ń ṣàwárí ohun tí ìwé ìròyìn Astronomy pè ní, “àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀, nínú Crab, tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kò fìgbà kan retí.” Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, Paul Scowen, sọ pé, àwọn àwárí wọ̀nyẹn “yẹ kí ó sún àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà alábàá èrò orí lásán láti máa ronú jinlẹ̀ títí lọ fún ìgbà díẹ̀.”
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, bíi Robert Kirshner láti Harvard, gbà gbọ́ pé lílóye àṣẹ́kù àwọn ìbúgbàù àwọn ìràwọ̀ bàǹbà bíi Crab Nebula ṣe pàtàkì nítorí pé, a lè lò wọ́n láti wọn bí àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ míràn ṣe jìnnà tó, tí ó jẹ́ apá tí a ń ṣe ìwádìí kíkankíkan lé lórí ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, àìfohùnṣọ̀kan lórí bí ó ti jìnnà sí àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ míràn ti dá àríyànjiyàn kan sílẹ̀ láìpẹ́ yìí lórí àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá àwọn ìṣẹ̀dá tí ó wà nínú àgbáálá ayé.
Ìrànyòò fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ kan tí ó wà nínú ìdìpọ̀ ìràwọ̀ Andromeda wà lókè Taurus, ṣùgbọ́n tí a ṣì ń rí ní Àríwá Ìlàjì Ayé lójú òfuurufú ìhà ìwọ̀ oòrùn ní January. Ìrànyòò yẹn ni ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Andromeda, ohun àfojúrí tí ó jìnnà jù lọ tí a lè fojú rí. Àwọn àràmàǹdà Orion àti Taurus sún mọ́ àgbáálá ayé wa díẹ̀—láàárín ẹgbẹ̀rún ọdún ìmọ́lẹ̀ díẹ̀ sí Ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, a ń wò ré kọjá àyípoyípo ńláǹlà àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n dà bíi ti ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tiwa, Milky Way, pẹ̀lú ìfojúdíwọ̀n mílíọ̀nù méjì ọdún ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá—nǹkan bí 180,000 ọdún ìmọ́lẹ̀ láti ìkángun kan sí èkejì. Bí o ti ń wo ìrànyòò fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ Andromeda náà, ojú rẹ wà lára ìmọ́lẹ̀ tí ó ṣeé ṣe kí ó ti lé ní mílíọ̀nù méjì ọdún!
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, Margaret Geller àti àwọn yòókù ti dáwọ́ lé àwọn ètò ìnàgà láti yàwòrán gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ó wà nítòsí wa lọ́nà ìwọ̀n onípele mẹ́ta ti ìbú, òró àti fífẹ̀, àbáyọrí rẹ̀ sì ti gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì dìde fún àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá náà. Dípò rírí ìpín lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ní ìhà gbogbo, àwọn ayàwòrán àgbáálá ayé náà ṣàwárí “ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí a hun jìngbìnnì bí aṣọ” nínú ìṣètò kan tí ó nasẹ̀ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọdún ìmọ́lẹ̀. Ìròyìn kan nínú ìwé àtìgbàdégbà tí a ń gbédìí fún náà, Science, sọ pé: “Bí a ṣe hun ayé jìngbìnnì yẹn láti ara àwọn ìṣètò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bára mu délẹ̀ nínú àgbáálá ayé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè líle jù lọ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà.”
A bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ yìí nípa wíwo òfuurufú alẹ́ January wa, kì í sì í ṣe pé a tètè ṣàwárí ẹwà àrímálèlọ nìkan ni, ṣùgbọ́n a tún ṣàwárí àwọn ìbéèrè àti àwọn nǹkan àràmàǹdà tí ó jẹ mọ́ àbùdá àti orísun àgbáálá ayé fúnra rẹ̀. Báwo ni ó ṣe bẹ̀rẹ̀? Báwo ni ó ṣe dé ipò ìdíjúpọ̀ tí ó wà ní báyìí? Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn nǹkan àràmàǹdà ojú ọ̀run tí ó yí wa ká? Ta ló lè dáhùn? Ẹ jẹ́ kí a wò ó.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Báwo Ni Wọ́n Ṣe Mọ Bí Ó Ṣe Jìnnà Tó?
Nígbà tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà wí fún wa pé, ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Andromeda fi mílíọ̀nù méjì ọdún ìmọ́lẹ̀ jìnnà, wọ́n ń fún wa ní ìfojúdíwọ̀n ti a gbé karí ìrònú lọ́ọ́lọ́ọ́ ni. Kò sí ẹni tí ó tí ì hùmọ̀ ọ̀nà ìṣèdíwọ̀n nípa bí irú ohun amúniṣekàyééfì bẹ́ẹ̀ ṣe jìnnà tó. Àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n sún mọ́ ìtòsí jù lọ, àwọn tí wọ́n fi nǹkan bí 200 ọdún ìmọ́lẹ̀, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ jìnnà, ni a lè wọ̀n tààràtà nípa jíjìnnà ìràwọ̀ láti ìhà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èyí yóò béèrè fún ìmọ̀ ránpẹ́ nínú ìṣirò nípa àwọn nǹkan onígun mẹ́ta. Àmọ́, nínú ọ̀ràn àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n sún mọ́ ilẹ̀ ayé dáadáa débi tí wọ́n fi fara hàn bí ẹni pé wọ́n ń yíra díẹ̀díẹ̀ bí ayé ti ń yí oòrùn nìkan po ni èyí ti ń ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìràwọ̀, àti gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, jìnnà púpọ̀ gan-an. Ibẹ̀ yẹn gan-an ni iṣẹ́ ìméfò náà ti bẹ̀rẹ̀. Kódà àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n sún mọ́ wa dáadáa, bí òmìrán pupa tí ó lókìkí náà Betelgeuse tí ó wà nínú Orion, wà lábẹ́ ìméfò, pẹ̀lú ìwọ̀n jíjìnnà rẹ̀ tí a fojú díwọ̀n láti orí nǹkan bí 300 sí ohun tí ó lé ní 1,000 ọdún ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu láti rí àìfohùnṣọ̀kan láàárín àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà lórí bí àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, tí wọ́n fi àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìgbà ju bẹ́ẹ̀ lọ, ṣe jìnnà tó.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìbúgbàù Àwọn Ìràwọ̀ Bàǹbà, Ìgbì Ìmọ́lẹ̀, Àti Àwọn Ihò Dúdú
Ọ̀kan lára àwọn ohun ṣíṣàjèjì jù lọ tí a mọ̀ lágbàáyé wà ní àárín gbùngbùn Crab Nebula. Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti sọ, àfọ́kù tín-ń-tín ìràwọ̀ kan, tí ó tẹ̀ pẹ̀nrẹ́n sí ìwọ̀n yíyani lẹ́nu kan, tí ń yí nínú sàréè rẹ̀ ní ìgbà 30 láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan, tí ó sì ń gbé ìgbì rédíò, tí a kọ́kọ́ ṣàwárí ní ilẹ̀ ayé ní 1968, jáde. A pè é ní ìgbì ìmọ́lẹ̀, tí a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ́kù ìràwọ̀ bàm̀bà abúgbàù tí ń yí, tí a tẹ̀ pẹ̀nrẹ́n débi pé àwọn electron àti proton tí ó wà nínú àwọn átọ́ọ̀mù ògidì ìràwọ̀ náà ni a ti tẹ̀ pa pọ̀ láti ṣèmújáde àwọn neutron. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé, ó ti fìgbà kan jẹ́ àárín gbùngbùn títóbi ti ìràwọ̀ bàm̀bà kan bíi Betelgeuse tàbí Rigel tí ó wà nínú Orion. Nígbà tí ìràwọ̀ náà bú gbàù, tí àwọn ìpele ara rẹ̀ sì fọ́n ká sínú gbalasa òfuurufú, kìkì àárín gbùngbùn tí ó sún kì náà ni ó ṣẹ́ kù, èédú arànyòò tí ń ṣèéfín funfun, tí ó jẹ́ iná ọ̀gbálẹ̀gbáràwé rẹ̀ ti kú tipẹ́tipẹ́.
Finú wòye mímú àwọn ìràwọ̀ méjì tí ó ṣe bàm̀bà tó méjì lára àwọn oòrùn wa, kí a sì tẹ̀ ẹ́ pọ̀ di ohun rogodo tí ó jẹ́ kìlómítà 15 sí 20 ní ìwọ̀n òbìrí! Finú wòye mímú pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé, kí a sì tẹ̀ ẹ́ pọ̀ sí 120 mítà. Sẹ̀ǹtímítà 16 níbùú lóròó àti òbìrí èyí yóò tẹ̀wọ̀n ju tọ́ọ̀nu bílíọ̀nù 16 lọ.
Kódà, kò dà bíi pé, ìparí gbogbo rẹ̀ nìyẹn nípa àwọn ohun tí a tẹ̀ pẹ̀nrẹ́n náà. Bí a bá ní láti fún ilẹ̀ ayé pọ̀ sí ìwọ̀n ègé mábìlì tí a ń fọwọ́ jù, àgbègbè òòfà ilẹ̀ ayé yóò wá lágbára gan-an débi pé, ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú kò ní lè jáde. Ibí yìí ni ilẹ̀ ayé wa tín-ń-tín yóò ti dà bí èyí tí ó pòórá sínú ohun tí a pè ní ihò dúdú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà gbà gbọ́ nínú àwọn ihò dúdú, a kò tí ì fi ẹ̀rí hàn síbẹ̀ pé wọ́n wà, kò sì dà bíi pé wọ́n wọ́pọ̀ tó bí a ṣe fi wọ́n kọ́ni ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Àwọ̀ Wọ̀nyẹn Ha Jẹ́ Gidi bí?
Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fi awò-awọ̀nàjíjìn kéékèèké tan òfuurufú wò sábà máa ń nímọ̀lára ìjákulẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan tí ó lókìkí tàbí nebula. Ibo ni àwọn àwọ̀ rírẹwà tí wọ́n ti rí nínú àwọn fọ́tò wà? Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, tí ó tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, Timothy Ferris, sọ pé: “A kò lè fi ojúyòójú rí àwọn àwọ̀ tí àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ní ní ti gidi, kódà pẹ̀lú àwọn awò awọ̀nàjíjìn títóbi jù lọ tí ó tí ì wà rí, nítorí pé wọn kò mọ́lẹ̀ dáradára tó tí ojú fi lè gba àwọ̀ náà mọ́ra nínú rẹ̀tínà ojú.” Èyí ti sún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti parí èrò sí pé àwọn àwọ̀ rírẹwà tí a ti rí nínú àwọn fọ́tò tí a yà láti inú sánmà jẹ́ ṣàgbẹ̀lójúyòyò, tí wọ́n wulẹ̀ fi kún un lọ́nà kan ṣáá nígbà tí wọ́n ń fọ fọ́tò náà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí ọ̀ràn ti rí kọ́ nìyẹn. Ferris kọ̀wé pé: “Àwọn àwọ̀ náà fúnra wọn jẹ́ gidi, àwọn fọ́tò náà sì dúró fún àwọn ìsapá dídára jù lọ ti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà láti gbé wọn jáde pérépéré.”
Ferris ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀, Galaxies, pé, fọ́tò àwọn ohun jíjìnnà tí kò mọ́lẹ̀ dáradára, bí àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tàbí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn nebula, “jẹ́ ìṣípayá fíìmù fọ́tò tí a mú jáde nípa fífi awò awọ̀nàjíjìn kan wo ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan, tí a óò sì ṣí ègé awò fọ́tò pẹlẹbẹ kan payá fún wákàtí bíi mélòó kan bí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ ti ń kọjá wọnú fíìmù fọ́tò náà. Lákòókò yìí, ìhùmọ̀ ayíbírí kan kì í jẹ́ kí àyípoyípo ayé ní ipa lórí fọ́tò náà, ó sì ń mú kí awò awọ̀nàjíjìn náà fojú sun ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ náà, nígbà tí ó sì jẹ́ pé onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, tàbí nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìhùmọ̀ adáṣiṣẹ́ kan tí ń darí rẹ̀, yóò máa ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
1 Ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Orion, tí a máa ń rí dáradára lójú òfuurufú káàkiri àgbáyé ní January
2 Orion Nebula, ìdìpọ̀ yíyanilẹ́nu àwọn “ìràwọ̀” bàìbàì
3 Nínú Orion Nebula lọ́hùn-ún —ibùdó ìbísí ìràwọ̀ ha ni bí?
[Àwọn Credit Line]
#2: Astro Photo - Oakview, CA
#3: C. R. O‘Dell/Rice University/fọ́tò NASA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Andromeda, ohun tí ó jìnnà jù lọ tí a lè fi ojú lásán rí. Ó jọ pé ìwọ̀n ìyípoyípo rẹ̀ tàpá sí òfin òòfàmọ́lẹ̀ Newton, ó sì gbé ìbéèrè dìde nípa ohun dúdú tí àwọn awò asọǹkan-di-ńlá kò lè rí
[Credit Line]
Astro Photo - Oakview, CA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Crab Nebula nínú Taurus—ibojì ìràwọ̀ ha ni bí?
[Credit Line]
Bill and Sally Fletcher
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Lápá òkè: Ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ Cartwheel. Ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ó kéré jù ú lọ kọ lù ú, ó gorí rẹ̀ kọjá, ó sì fi ìṣùjọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìràwọ̀ aláwọ̀ búlúù tuntun tí wọ́n yí ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ Cartwheel po sẹ́yìn
[Credit Line]
Kirk Borne (ST Scl), àti NASA
Lápá ìsàlẹ̀: Ojú Ológbò Náà, Nebula. Ipa tí àwọn ìràwọ̀ méjì tí ń yí ara wọn po ń ní máa ń ṣàlàyé àwọn ìṣètò dídíjú náà lọ́nà rírọrùn jù lọ
[Credit Line]
J. P. Harrington and K. J. Borkowski (University Maryland), àti NASA