Ìbí Ìràwọ̀ Nínú “Ìtẹ́” Idì Kan
● BÁWO ni a ṣe ń ṣẹ̀dá àwọn ìràwọ̀? Èé ṣe tí àwọn kan fi tóbi, tí wọ́n sì mọ́lẹ̀ ju àwọn mìíràn lọ? Lọ́nà gbígbàfiyèsí, àwọn fọ́tò kan tí Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú ti Hubble yà lè ṣàfihàn àwọn ìgbésẹ̀ ṣíṣẹ̀dá ìràwọ̀. Ìgbòkègbodò aláìlẹ́gbẹ́ yìí ń ṣẹlẹ̀ láàárín gbùngbùn Eagle Nebula, kùrukùru gáàsì òun erukuru inú ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way tiwa.
Lójú àwọn awòràwọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Eagle Nebula rí bí ẹyẹ kan tí ó na àwọn apá àti èékánná rẹ̀ jáde. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà Jeff Hester àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Arizona ní ọkàn ìfẹ́ nínú yíyàwòrán àgbègbè ibi èékánná náà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ní òpó bí ọwọ̀n tí ó jọ ọwọ́ ìjà erin. Níbẹ̀ ni ìtànṣán ultraviolet ti ń fọ́ àwọn molecule afẹ́fẹ́ hydrogen sí wẹ́wẹ́—ìyẹn ni pé, ó ń gba àwọn electron wọn kúrò lára wọn.
Àtòpọ̀ fọ́tò Hubble tí ọkọ̀ òfuurufú yà náà fi àwọn ìka kéékèèké tí ó yọ jáde ní góńgó orí àwọn ọwọ̀n náà hàn. Ní ṣóńṣó orí àwọn ìka náà, gáàsì tí ń dì sọ ara rẹ̀ di gílóòbù olóbìírí kan, nínú èyí tí àwọn ìràwọ̀, àti, gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kan ṣe wí, bóyá àwọn pílánẹ́ẹ̀tì pàápàá, ti ń dàgbà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtújáde àwọn gáàsì lílágbára kan láti inú àwọn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọmọ ìràwọ̀ tí ó ti kóra jọ nínú nebula náà ṣáájú ń dí ìdàgbà àwọn nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́. Èyí tí ó mọ́lẹ̀ jù lọ lára àwọn ìràwọ̀ wọ̀nyí lè mọ́lẹ̀ tó oòrùn wa ní ìlọ́po 100,000, kí ó sì gbóná tó o ní ìlọ́po mẹ́jọ. Ó ṣe kedere pé, ìtànṣán wọn ti ṣan àwọn apá tí kò wúwo tó bẹ́ẹ̀ lára nebula náà dà nù. Ìgbésẹ̀ yí, tí a mọ̀ sí fífa ìmọ́lẹ̀ gbẹ, lè ṣèdíwọ́ fún ìṣèmújáde ìràwọ̀ nípa mímú àwọn ohun tí àwọn kògbókògbó ìràwọ̀ ì bá gbé mì kúrò. Nínú àwọn fọ́tò náà, àwọn gáàsì tí ń gbẹ náà dà bí oruku tí ń gbéra láti inú àwọn òpó gáàsì òun erukuru.
Kí ọ̀kan lára àwọn gílóòbù onígáàsì wọ̀nyí tó lè bẹ̀rẹ̀ sí í tàn, ó gbọ́dọ̀ kàmàmà tó láti ṣe ìyípadà átọ̀mù. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú bù ú pé ó gbọ́dọ̀ tóbi tó ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n ìtóbi oòrùn. Ní àfikún sí i, a gbọ́dọ̀ mú èyí tí ó pọ̀ tó lára àwọn erukuru tí ó yí i ká kúrò kí ìmọ́lẹ̀ lè ráyè jáde. Bí ó ti wù kí ó rí, bí gílóòbù náà kò bá tóbi tó láti tànmọ́lẹ̀, ó wulẹ̀ lè di bọ́ọ̀lù gáàsì ṣíṣókùnkùn kan tí a mọ̀ sí aràrá aláwọ̀ ilẹ̀. Láìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ṣàwárí aràrá aláwọ̀ ilẹ̀ kíní tí wọ́n lè dá mọ̀.
Jíjọ tí kùrukùru eléruku inú Eagle Nebula jọ kùrukùru ààrá tí a máa ń rí nígbà òjò lè mú ọ nígàn-án láti rò pé àwọn kùrukùru eléruku náà kò tóbi púpọ̀. Ní ti gidi, ọ̀kọ̀ọ̀kan ọwọ̀n kùrukùru náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ tí ó bá wá láti ìkángun kan yóò rìnrìn àjò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gba ọdún kan kí ó tó dé ìkángun kejì. Pẹ̀lúpẹ̀lú, gílóòbù “tínńtínní” kọ̀ọ̀kan nínú àwòrán náà fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó ìgbékalẹ̀ oòrùn wa. Ní àfikún sí i, nebula náà jìnnà tó bẹ́ẹ̀ tí ìmọ́lẹ̀ tí ń wá láti inú rẹ̀ ń gba nǹkan bí 7,000 ọdún kí ó tó dé ọ̀dọ̀ wa—tí ó ń rìnrìn àjò ní ìwọ̀n ìyára 299,792 kìlómítà láàárín ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan. Èyí túmọ̀ sí pé a ń rí Eagle Nebula náà bí ó ṣe wà kí a tó dá ènìyàn.
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kíyè sí i pé, ó jọ pé àwọn nebula míràn bíi ti Orion Nebula pẹ̀lú ń ṣẹ̀dá ìràwọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ìhà tí a ti ń wo àwọn àpẹẹrẹ mìíràn wọ̀nyí ń ṣèdíwọ́ fún ṣíṣàkíyèsí ìgbésẹ̀ náà ní kedere. Àwọn ìràwọ̀ lè kú nípa wíwulẹ̀ jó dà nù, nípa bíbú gbàù nínú ìbúgbàù ìràwọ̀ kan, tàbí nípa kí agbára òòfàmọ́lẹ̀ tẹ̀ wọ́n pẹ̀nrẹ́n, kí wọ́n sì di ihò dúdú. Ẹlẹ́dàá àgbáyé, Jèhófà Ọlọ́run, ń pa àkọsílẹ̀ kan mọ́ nípa àwọn ìràwọ̀, nítorí pé ó mọ iye gbogbo wọn, ó sì sọ gbogbo wọn lórúkọ. (Aísáyà 40:26) “Ìtẹ́” idì àwọn ìràwọ̀ lè ṣàfihàn díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń “dá ìmọ́lẹ̀,” tí ó sì ń mú àwọn ìràwọ̀ tí ògo wọn yàtọ̀ síra jáde.—Aísáyà 45:7; Kọ́ríńtì Kíní 15:41.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 14]
J. Hester and P. Scowen, (AZ State Univ.), NASA