ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/8 ojú ìwé 25-27
  • Ìmọ̀ Ìjìnlẹ Sánmà Ni Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmọ̀ Ìjìnlẹ Sánmà Ni Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Mi
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìràwọ̀ àbí Pílánẹ́ẹ̀tì?
  • Ìrànlọ́wọ́ Wà
  • Òṣùpá àti Àwọn Pílánẹ́ẹ̀tì
  • Àwọn Ìràwọ̀
  • Ọ̀rọ̀ Ìkìlọ̀
  • Bí Oòrùn Àtàwọn Pílánẹ́ẹ̀tì Tó Ń yí i Po Ṣe Dèyí Tó Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí í Ṣẹ̀dá Àwọn Nǹkan
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Jí!—1996
g96 8/8 ojú ìwé 25-27

Ìmọ̀ Ìjìnlẹ Sánmà Ni Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Mi

MÒ Ń gbé Erékùṣù Àríwá New Zealand, ní ìha Gúúsù Òkun Pacific. Láti ìgbà tí mo ti wà léwe ọlọ́dún 15, ni mo ti nífẹ̀ẹ́ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ sánmà. Ìgbòkègbodò onípẹ̀lẹ́tù tí rírọrùn tàbí bí ó ṣe díjú pọ̀ gan-an sinmi lé bí o bá ṣe fẹ́ ẹ. Jẹ́ kí ó yé ọ pé o kò ní láti gba oyè jáde ní yunifásítì nínú ìmọ physics tàbí kí o jẹ́ ògbóǹtagí nínú ìmọ̀ ìṣirò kí o tóó lè gbádùn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà.

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìgbòkègbodò àfipawọ́ nílò àwọn ohun èèlò ìṣiṣẹ́ kan. Nítorí náà, kí ni ìwọ yóò nílò? Ní pàtàkì, ojú rẹ. Tí o bá kọ́kọ́ bọ́ sínú òkùnkùn láti inú iyàrá tí a tanná sí nínú ilé rẹ, yóò gba nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá kí ojú rẹ tóó lè mú ara bá ìmọ́lẹ̀ tí ó dín kù náà mu. Bí o bá jẹ́ olùgbé ìlú ńlá, o lè ṣàkíyèsí pé àwọn iná òpópónà àti àwọn tí a tàn sílé ń mú ọ lójú. Kí ni o lè ṣe nípa rẹ̀? Láti rí àbáyọrí rere, dúró níbi tí o kò ti ní i sí lábẹ́ ìmọ́lẹ̀ yìí.

Ìwọ yóò gbádun wíwà ní ipò ìwòran lọ́nà dídára jù lọ ní alẹ́ ṣíṣókùnkùn, tí kò sí ìkuukùu tí kò ní òṣùpá. Òṣùpá máa ń tan ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ sí afẹ́fẹ́ àyíká, tí èyí sì ń mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ìràwọ̀ tí kò fí bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ pòórá. Ìràwọ̀ mélòó ni o lè rí pẹ̀lú ojú lásán? O sábà máa ń jẹ́ láàárín 2,000 sí 4,000. Ó ṣòro jù láti rí àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n sún mọ́ ibi ìpàdé ilẹ̀ òun òfuurufú nítorí pé o ń wò kọjá láàárín afẹ́fẹ́ àyíká tí ó túbọ̀ dí, tí ó yọrí sí ìṣeràkọ̀ràkọ̀ àti àìhàn dáradára. Ó ń ya àwọn ènìyàn kan lẹ́nu pé kìkì ìwọ̀nba àwọn ìràwọ̀ díẹ̀ ni a lè fi ojú lásán rí, bí ó ti jọ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló wà níbẹ̀ nígbà tí a kọ́kọ́ wò ó lókè.

Ìràwọ̀ àbí Pílánẹ́ẹ̀tì?

Rírí ìtànṣán iná tí ó túbọ̀ mọ́lẹ̀ kan ń fa ìbéèrè náà, Ṣé ìràwọ̀ ni àbí pílánẹ́ẹ̀tì? Àwọn ìràwọ́ jẹ́ orísun ìmọ́lẹ̀, ẹ̀rọ àárín gbùngbùn tí ń fi tagbáratagbára bi àwọn àmì ìgbì ìtànṣán jáde sínú gbalasa òfuurufú. Wọ́n jìnnà gidi gan-an sí ilẹ̀ ayé, èyí tí ó sún mọ́ wa jù lọ—yàtọ̀ sí oòrùn—fi 4.3 ọdún ìmọ́lẹ̀ jìnnà sí wa. Ìmọ́lẹ̀ máa ń rìn ní nǹkan bí 299,000 kìlómítà láàárín ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ tí ń wá láti inú ìràwọ̀ ń rìn jìnnà gan-an kí ó tó dé ọ̀dọ wa, débi pé kì í lágbára mọ́. Ó wá ní láti la àárín ìtóbi afẹ́fẹ́ àyíká ilẹ̀ ayé tí ń pọ̀ sí i, tí ń mú kí àwọn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ máa dagun síhìn-ín sọ́hùn-ún, kọjá. Ìlà ewì àwọn ọmọdé kan tí ń fi arinrin díẹ̀ kún ìparọ́rọ́ ojú ọ̀rún kà léde Gẹ̀ẹ́sì pé: “Twinkle, twinkle, little star, how I wonder what you are.” Bí ó bá ń ṣẹ́jú wìwì, ìràwọ̀ ni.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn pílánẹ́ẹ̀tì wulẹ̀ máa ń ṣàgbéyọ ìmọ́lẹ̀ láti inú oòrùn ni, gan-an gẹ́gẹ́ bí òṣùpá ṣe ń ṣe. Wọ́n sún mọ́ wa ní ìfiwéra, nítorí pé wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé oòrùn, ètò ìgbékalẹ̀ ìràwọ̀. Nítorí náà, àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tí a lè rí pẹ̀lú ojú lásán ṣàgbéyọ ìmọ́lẹ̀ tí ó dúró sójú kan, tí kò sì ṣẹ́jú.

Ìrànlọ́wọ́ Wà

Bí o bá fẹ́ láti tẹ̀ síwájú, jẹ́ kí n wí fún ọ nípa àwọn ohun tí ó ràn mí lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbòkègbodò àfipawọ́ mi gidi gan-an. Àkọ́kọ́ ni ìwé àwòrán ìràwọ̀ kan. Ẹ̀dà tí mo ní lọ́wọ́ báyìí ni Norton’s Star Atlas, Ẹ̀dà Àtúnṣe. Ó ní àwọn àwòrán títayọ lọ́lá nípa ọ̀run, àti àwọn ìsọfúnni tí yóò mú kí ọ̀gbẹ̀rí di ojúlùmọ̀ àwọn èdè ìmọ̀ ìjìnlẹ sánmà.

Ìrànlọ́wọ́ mi kejì ni planisphere, tí ó ní àwọn ègé ike méjì, tí ọ̀kan wà lórí èkejì, tí a fi ohun olórí rìbìtì kan so pọ̀ láàárín. Ègé ti òkè, tí ó ní fèrèsé kan nínú, ṣeé yí kiri lórí èyí tí ó wà nísàlẹ̀ tí ó ní àwòrán ìràwọ̀ tí a tẹ̀ sórí rẹ̀, a sì lè gbé e sórí àkókò àti déètì tí a fẹ́. Nísinsìnyí, o wá lè pinnu ìràwọ̀ tí ó ṣeé rí láti ibi tí o wà ní wákàtí àti ìgbà nínú ọdún àti bí o ṣe jìnnà sí láti ìhà ìbú tí o wà. Ní New Zealand, a lè rí Philips’ Planisphere rà tàbí kí a kọ̀wé béèrè fún un láti ọ̀pọ̀ ilé ìtàwé. Tí o bá fẹ́ẹ́ ra planisphere, ó yẹ kí o mọ ibi tí ìlú rẹ wà, yálà àríwá tàbí gúúsù ìlà agbedeméjì ayé.

Ó ha yẹ kí o ra awò awọ̀nàjíjìn bí? Bí o bá ń lépa ìgbòkègbodò àfipawọ́ yìí, mo ronú pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ìwọ yóò rà á. Oríṣi mẹ́ta ló wà—ayípa-ìmọ́lẹ̀-padà, agbáwòrányọ, àti ayípa-ìmọ́lẹ̀-padà tó tún ń gbáwòrán yọ. Lọ sí láíbìri gbogbogbòò ní àdúgbò rẹ láti wo àwọn ìwé tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ sánmà àti àwọn awò awọ̀nàjíjìn. Lọ́nà yíyanilẹ́nu, ó rọrùn láti ṣe awò awọ̀nàjíjìn agbáwòrányọ fúnra rẹ. Ra iwé olówó pọ́ọ́kú kan tí ń sọ̀rọ̀ nípa bí o ṣe lè ṣe awò awọ̀nàjíjìn ti ìmọ̀ ìjìnlẹ sánmà. Yóò jẹ́ ìwéwèé amóríyá fún ọ.

Àwọn awò awọ̀nàjíjìn olójú méjì ń jẹ́ kí a lè rí òfuurufú dé ibi jíjìnnà réré. Ìwọ yóò rí àwọn ìṣùjọ ìràwọ̀ rírẹwà tí ó so rọ̀ bí iyùn nínú òfuurufú aláràn-án dúdú. Ìwọ yóò rí ìkúukùu fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ aláwọ̀ mèremère tí ó wá jẹ́ nebula, ìkúukùu eruku àti gáàsì, tí ó fi ọ̀pọ̀ ọdún ìmọ́lẹ̀ jìnnà nínú gbalasa òfuurufú lọ́hùn-ún. A lè rí ìdìpọ̀ akọmọ̀nà ti Milky Way láti ibikíbi lórí Ilẹ̀ Ayé. Bákan náà, àwọn awò awọ̀nàjíjìn olójú méjì dára jù lọ fún wíwò kiri ojú òfuurufú tí a bá ń wá tàbí tí a ń wo àwọn ìràwọ̀ onírù, àwọn alárìnká tí wọ́n máa ń já wọnú gbalasa òfuurufú nítòsí wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò lè máa gbé àwọn àpilẹ̀kọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí a ṣètò láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wo òfuurufú lálẹ́ jáde.

O ha ní kọ̀m̀pútà ti ara rẹ bí? Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan wà lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ sánmà tí ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀ kan lè gbádùn, àti àwọn kan tí wọ́n túbọ̀ jinlẹ̀. Mo ń fi kọ̀m̀pútà mi kó onírúurú ìsọfúnni tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbòkègbodò àfipawọ́ mi pa mọ́. Àwọn ìwé ìròyìn tí ó wọ́ pọ̀ tún wà nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ sánmà. Láti ìgbà dé ìgbà, Jí! ń tẹ àwọn ọ̀rọ̀ jáde lóri kókó ẹ̀kọ́ náà.

Òṣùpá àti Àwọn Pílánẹ́ẹ̀tì

Dájúdájú, ìṣòro kankan kò sí nípa rírí òṣùpá. Nígbà tí ó bá yọ, ó máa ń gba òfuurufú kan lálẹ́. Òṣùpá tí ó yọ tán lẹ́wà gan-an bí ó ti jọ pé ó ń rìn láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn bí ilẹ̀ ti ń mọ́ díẹ̀díẹ̀. Wíwò láwòfín, pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́nisọ́nà, fi hàn pé ìràwọ̀ ń rìn ní ti gidi gba ibì kan náà tí àwá ń gbà, láti ìwọ̀ oòrùn lọ sí ìlà oòrùn. Ṣàkíyèsí èyí fún wákàtí kan tàbí méjì tàbí fún alẹ́ méjì léraléra, kí o ṣàkíyèsí ipò àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n wà lójú kan ní ìfiwéra pẹ̀lú òṣùpá. Nítorí pé ayé ń yára yí lórí ọ̀gban-anran ìla rẹ̀ ju òṣùpá lọ, a ń fi òṣùpá sẹ́yìn.

Onímọ̀ ìjìnlẹ sánmà náà lè dojú kọ ìṣòro kan nígbà tí òṣùpá bá yọ tán—ìmọ́lẹ̀ tí ó pọ̀ jù. Mo ti sábà máa ń gbádùn wíwo òṣùpá jù lọ nígbà tí ó bá pé ọjọ́ 4 sí ọjọ́ 7 tàbí ọjọ́ 22 sí ọjọ́ 24 tí ó ti yọ, nítorí pé òjìji àwọn òkè ńlá àti ìtẹ̀wọnú rẹ̀ ti gùn, tí wọ́n sì mọ́lẹ̀ gan-an. Níwọ̀n bí òṣùpá ti jẹ́ ìṣẹ̀dá kan ṣoṣo tí ó sún mọ́ wa tó láti fi ojú lásán rí àwọn àbùdá ara rẹ̀ wíwà pẹ́ títí, ara rẹ̀ hàn yàtọ̀ látàri bóyá o wà ní àríwá tàbí gúúsù agbedeméjì ayé.

Òtítọ́ ni èyí jẹ́ nípa ìkójọ ìràwọ̀ tàbí bátànì ìràwọ̀ pẹ̀lú, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ó sàn jù fún ọ láti lo àwòrán tí a tẹ̀ jáde fún ìhà ìlàjì ayé tí o wà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn méjèèjì dorí kodò, wọ́n sì dojú kọ ẹ̀yìn—tí ń rúni lójú bákan ṣáá, ní pàtàkì sí ọ̀gbẹ̀rì kan. Ó yẹ kí a mẹ́nu kàn án pẹ̀lú pé awò awọ̀nàjíjìn àfiwosánmà máa ń gbé ohun tí a bá ń fi wò ní ìdoríkodò. Àmọ́, ibo ni àwọn pílánẹ́ẹ̀tì náà wà? Lákọ̀ọ́kọ́, ohun méjì ni a ní láti mọ̀: Kí ni amúǹkanṣókùnkùn àti àgbá òfuurufú.

Amúǹkanṣókùnkùn ni ipa ọ̀nà oòrùn nígbà ìrìn àjò rẹ̀ ọdọọdún, tí àwọn ìràwọ́ sì wá lẹ́yìn rẹ̀. Amúǹkanṣókùnkùn náà kọjá láàárín ìlà agbedeméjì ẹ̀dá ọ̀run náà ní nǹkan bí ìwọ̀n 23.5. Àgbá òfuurufú, tí ó túmọ̀ sí “ìlà roboto àwọn ẹranko,” ni àgbá àfinúwò tí ó fi nǹkan bí ìwọ̀n 8 tẹ̀ lé amúǹkanṣókùnkùn lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì. Oòrùn, òṣùpá, àti àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tí a lè fi ojú lásán rí máa ń fìgbà gbogbo wà láyìíká àgbá òfuurufú. Yóò ṣe kedere pé pílánẹ́ẹ̀tì kan lò ń wò lẹ́yìn wíwòran fún alẹ́ bíi mélòó kan léraléra, níwọ̀n bí pílánẹ́ẹ̀tì kan yóò ti wà ní ipò yíyàtọ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ tí ó hàn pé wọ́n wa lójú kan.

Ṣùgbọ́n pílánẹ́ẹ̀tì wo ni mo ń wò? Mercury àti Venus sábà máa ń wà ní apá ìwọ̀ oòrùn òfuurufú nírọ̀lẹ́, wọ́n sì máa ń wà ní apá ìlà oòrùn ní òwúrọ̀, wọn kò sí lọ́gangan òkè rí. Òṣùpá nìkan ló máa ń ṣe bíi Venus. Dájúdájú, o mọ̀ pé òun ni ìràwọ̀ òwúrọ̀ tàbí ìràwọ̀ àṣálẹ́. Àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tí ń yípo Oòrùn lóde ayé máa ń lọ láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn. Mars, Jupiter, Saturn, àti Uranus pẹ̀lú ṣeé rí pẹ̀lú ojú lásán. Ní ìbẹ̀rẹ̀, a óò ní láti yẹ orísun ìsọfúnni kan wò nípa ipò wọn, níwọ̀n bí kì í ti í rọrùn láti rí wọn láàárín àwọn ìràwọ̀.

Àwọn Ìràwọ̀

Ìwọ yóò máa fìgbà gbogbo rí àwọn ìràwọ̀ gẹ́gẹ́ bíi kókó ìmọ́lẹ̀ fífani lọ́kàn mọ́ra. Sísọ ara rẹ di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ìkójọ ìràwọ́ lè jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tuntun pẹ̀lú àgbàyanu iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá yìí.

Àwọn ìràwọ̀ kan fa ọkàn ìfẹ́ wa mọ́ra gan-an. Ọ̀kan ni Sirius; òun ni ìràwọ̀ mímọ́lẹ̀ jù lọ. Ó tún jẹ́ ìràwọ̀ oníbejì, ó jẹ́ ìràwọ̀ méjì tí ń yí po ibì kan náà. Ìràwọ̀ tí ó mọ́lẹ̀ ṣìkejì ní Canopus. Àwọn ìhùmọ̀ agbéniresánmà ti lo ìràwọ̀ yìí láti mọ ibi tí wọ́n wà nínú gbalasa òfuurufú àti láti yí mọ̀galà wọn síhà ilẹ̀ ayé láti mú kí ìdarísọ́nà nípasẹ̀ ìbánisọ̀rọ́ lè rọrùn.

Ọ̀rọ̀ Ìkìlọ̀

(1) Ìgbòkègbodò àfipawọ́ ló yẹ kí ìmọ̀ ìjìnlẹ sánmà jẹ́, kì í ṣe ìsúnniṣe tipátipá. Òfin ìdíwọ̀n dídára tayọ kan ni pé, “Ẹlẹ́dàá gbọ́dọ̀ ṣáájú ìṣẹ̀dá.” (2) Láé, má ṣe fi awò awọ̀nàjíjìn tàbí awò awọ̀nàjíjìn olójú méjì wo oòrùn tàbí wò kiri inú òfuurufú nítòsi rẹ̀; ó lè yọrí sí ìfọ́jú. (3) Má ṣe gba ohun gbogbo tí o bá kà gbọ́. Àwọn ìwé àtijọ́ lè ṣì ọ́ lọ́nà, bí àwọn àbá èrò orí tí a kò fìdí ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ ṣe lè ṣe. (4) Má ṣe máa yára náwó lórí ohun èèlò, nítorí èyí lè mú kí o pàdánù ọkàn ìfẹ́ nínú ìgbòkègbodò àfipawọ́ rẹ.

Ìdáwọ́lé tí kò lópin nípa ìṣàwárí àti ìyanu ńlá ni ìgbòkègbodò àfipawọ́ mi jẹ́. Kódà, nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, a kò lè mọ̀ nípa gbogbo àràmàǹdà àgbáyé tán. (Oníwàásù 3:11; 8:17) Ṣùgbọ́n nígbà náà yóò jẹ́ ohun tí ń fani lọ́kàn mọ́ra títí láé láti kọ́ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́