ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/8 ojú ìwé 23-25
  • “Èso Ápù kan Lóòjọ́ Máa Ń Mára Le”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Èso Ápù kan Lóòjọ́ Máa Ń Mára Le”
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbin Ápù
  • Kíkórè Rẹ̀
  • Kíkó Wọn Pamọ́
  • Ìníyelórí Wọn fún Ìlera
  • Ìkìlọ Kan Nìyí O
  • Ṣé Gbogbo Ìwé Inú Bíbélì Ṣì Wúlò Lóde Òní?
    Jí!—2010
  • Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
    Kọrin sí Jèhófà
  • Ẹ̀kọ́ 5
    Ẹ̀kọ́ Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 2/8 ojú ìwé 23-25

“Èso Ápù kan Lóòjọ́ Máa Ń Mára Le”

WO ÀWỌN èso ápù tí pípọ́n wọn wu ènìyàn yẹn. Wọn kò ha fà ọ́ mọ́ra bí? Wọ́n fà ọ́ mọ́ra—kò sì sí iyè méjì pé ó nídìí. Ọlọrun dá ápù kí ó baà lè mú kí o máa wà lálàáfíà, kí ó sì lera. Nínú gbogbo ọ̀pọ̀ àwọn onírúurú èso tí ó wúlò fún oúnjẹ, èso ápù jẹ́ ọ̀kan tí ó gbawájú jù lọ. Nítorí bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fà ọ́ mọ́ra kí o lè jẹ wọn, kí o sì ṣe ara rẹ lóore.

Ọmọ ìyá rose (Rosaceae) ni igi ápù jẹ́, bí igi píà, igi quince, igi whitethorn, àti igi service náà ṣe jẹ́. Oje gbogbo àwọn igi yìí ni ṣúgà kún fọ́fọ́. Oríṣiríṣi àwọ̀ ni àwọn èso wọn tí ń ta sánsán ní, bí àwọ̀ ewé, òféfèé àti pupa, tí adùn wọn sì lè jẹ́ èyí tí ó kónu yẹ́ríyẹ́rí tàbí tí ó dùn.

Káàkiri gbogbo àgbáyé, nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì òṣùwọ̀n kàbìtì-kàbìtì èso ápù ni à ń mú jáde lọ́dún—nǹkan bíi tọ́ọ̀nù mílíọ̀nù 17 sí mílíọ̀nù 18. Ní United States, nǹkan bí ìdajì lára wọn ni à ń jẹ ní tútù. Wọ́n ń lo àwọn yòókù láti fi ṣe àwọn nǹkan bíi bọ́tà tí a fi èso ápù ṣe, omi èso ápù, ọbẹ̀ èso ápù, ẹkọtọ ìjẹǹkan èso ápù, ọtí èso ápù, omi èso ápù kíkan, ìpápánu èso ápù yíyan àti àwọn nǹkan yíyan mìíràn, ọtí kíkan, àti ọtí wáìnì èso ápù. Ní Europe, èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn èso náà ni a fi ń ṣe omi kíkan, ọtí kíkan, àti ọtí èso. Nínú èyí tí gbogbo àgbáyé ń pèsè, ìdá kan nínú mẹ́rin ni a fi ń ṣe omi kíkan.

Àmọ́, tipẹ́tipẹ́ ṣaájú kí èso náà tó di èyí tí ó gbádùn mọ́ wa lẹ́nu, igi ápù tí ó tanná látòkè délẹ̀ máa ń dùn ún wò. Ìdìpọ̀ àwọn òdòdó funfun tí abala wọn gbétí léra máa ń kún orí rẹ̀ jìngbìnnì débi pé, bí gbogbo wọn bá fi lọ dàgbà di èso ápù, igi náà kò ní lè gbà á dúró. Ìjì àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ìgbà ẹ̀rùn ni ó sábà máa ń rí sí i pé afẹ́fẹ́ gbé díẹ̀ lára àwọn òdòdó náà lọ.

Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbin Ápù

Igi ápù máa ń dàgbà dáradára ní àwọn Agbègbè Ọlọ́rinrin. Ọjọ́ sì ti pẹ́ tí wọ́n ti ń gbìn ín. A mẹ́nu kan igi ápù àti èso ápù lẹ́ẹ̀mẹfà nínú Bibeli.a Àwọn ará Romu gbádùn rẹ̀, níbi tí wọ́n sì ti ń jagun ṣẹ́gun káàkiri, wọ́n mú kí onírúuru ẹ̀yà igi ápù tàn káàkiri England àti àwọn apá ibòmíràn ní ilẹ̀ Europe. Àwọn agbókèèrè-ṣàkóso America ìgbàanì mú kóró èso ápù àti igi ápù bọ̀ láti England.

Nípa àṣedánwò tí ó pọ̀, ìran àwọn tí ń gbìn ápù ti mú kí ó túbọ̀ jẹ́ ojúlówó sí i nígbà mímú irú tuntun jáde. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kì í ṣe ohun tí ń yá bọ̀rọ̀bọ̀rọ̀. Pípèsè irú ápù tuntun tí ó ṣeé tà lọ́jà lè gbà tó 20 ọdún. Àmọ́ lónìí, ọpẹ́lọpẹ́ ìfaradà àwọn tí ń gbìn ín ni a fi ní àìmọye onírúurú àwọn èso ápù olómi nínú àti aláwọ̀ mèremère tí a lè ṣàṣàyàn nínú rẹ̀.

Kíkórè Rẹ̀

Àkókò ápù bẹ̀rẹ̀ ní July tàbí August ní apá Àríwá Ìlajì Ayé. Àmọ́ àwọn ẹ̀yà tí ó máa ń kọ́kọ́ pọ́n, irú bí ẹ̀yà James Grieve tàbí ẹ̀yà Transparent, kò ṣeé kó pamọ́ lọ títí. Ènìyàn gbọ́dọ̀ tètè jẹ wọn, yálà ní tútù tàbí ní bíbọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n máa ń mú kí ọ̀fun wa dá tólótóló fún àwọn irú ẹ̀yà tí yóò tẹ̀ lé e wọ̀nyí: Summerred, Gravenstein, Cox’s Orange, Jonathan, Boskop, Red Delicious, Golden Delicious, McIntosh, Granny Smith—láti mẹ́nu kan kìkì díẹ̀ lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀yà tí ó wà.

Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni wọ́n máa ń kórè èso ápù. Ènìyàn gbọ́dọ̀ fẹ̀sọ̀ ká wọn, kí àwọn ẹka tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ àti ewé wọn má baà bà jẹ́. Nígbà tí ápù bá ti pọ́n dáadáa, kìkì fífi ọwọ́ yí èso náà díẹ̀ yóò jẹ́ kí ó já bọ́ lára ìyá rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì pé kí ènìyàn ṣọ́ra, kí gaga èso náà máà kán bọ́ lára ápù náà, nítorí pé èyí lè jẹ́ kí ó ni ojú, tí yóò sì jẹ́ kí èso náà tètè bà jẹ́.

Ènìyàn gbọ́dọ̀ fi àwọn ẹ̀yà tí kì í tètè pọ́n sílẹ̀ sórí igi bí ó bá ti lè pẹ́ tó—bí ojú ọjọ́ bá gbà á láyè. Bí èso ápù náà bá dì sórí igi nítorí ojú ọjọ́ títutù ringindin, ènìyàn kò gbọ́dọ̀ ká wọn títí tí yìnyín ara wọn yóò fi yọ́. Àwọn èso ápù rára gba ojú ọjọ́ tí ó tutù ringindin tán pátápátá sí, ó sinmi lórí bí wọ́n bá ti pọ́n tó, àti bí ṣúgà inú wọn bá ti pọ̀ tó, àmọ́ tí wọ́n bá fi lè dì, tí yìnyín ara wọ́n sì yọ́, ènìyàn kò tún lè kó wọn pamọ́ mọ́. Ènìyàn gbọ́dọ̀ tètè fún omi ara wọn, kí ènìyàn bọ̀ wọ́n, tàbí fi wọ́n ṣe omi kíkan; wọn kò ṣeé sá gbẹ.

Kíkó Wọn Pamọ́

Ohun tí ó máa ń fani lọ́kàn mọ́ra nípa ápù ni pé wọ́n máa ń mí. Wọ́n máa ń gba èròjà oxygen láti inú afẹ́fẹ́, wọn sì máa ń tú èròjà carbon dioxide jáde gẹ́gẹ́ bí omi. Nítorí èyí, bí àyíká bá ti móoru tó, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe tètè gbẹ, tí wọn yóò sì súnra kì tó. Bí wọ́n ṣe ń mí ni wọ́n tún ń gba òórùn tí ó wà láyìíká sára. Nítorí èyí, ohun tí ó dára jù ni láti kó wọn pamọ́ pa pọ̀ ní àyíká tí ó ní ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù tí ó tó ìdiwọ̀n 5 lórí òṣùnwọ̀n Celsius.

Kíkó ápù pamọ́ sínú àjà ilẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ànàmọ́ yóò mú kí àwọn ápù náà pàdánù díẹ̀ lára adùn wọn. Síwájú sí i, a gbọ́dọ̀ kó àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ohun tí ó dára ju ni kí ènìyàn fi bébà yí ápù lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Èyí kì í jẹ́ kí ó tètè gbẹ, kì í sì í jẹ́ kí àwọn èyí tí ó bá ti ní kòkòrò kó o ran àwọn tí ó bá yí wọn ká.

Ìníyelórí Wọn fún Ìlera

Àwọn ènìyàn máa ń sọ pé, “èso ápù kan lóòjọ́ máa ń mára le.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ní ó máa ń rí bẹ́ẹ̀, èso ápù ṣì ní orúkọ rere yìí síbẹ̀. Èé ṣe? Nítorí àwọn nǹkan tí ó wà nínú rẹ̀ tí ó lè mú kí ìlera ènìyàn sunwọ̀n sí i.

Èso ápù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ilé kékeré kan tí àwọn èròjà aṣaralóore pàtàkì ba sí. Nígbà tí ó bá ti pọ́n, ó máa ń ní èròjà vitamin B1, B2, B6, C, àti E. Ní àfikún sí i, ó máa ń ní onírúurú ṣúgà, irú bíi dextrose, fructose àti sucrose. Àkópọ̀ ìtọ́wò kíkan tí ó wà nínú rẹ̀ ni ó máa ń jẹ́ kí ó ní adùn tí ó máa ń ní. Ó tún ní àwọn èròjà mineral kan, irú bíi calcium, magnesium, potassium àti àwọn mìíràn, pa pọ̀ pẹ̀lú pectin àti ṣákítí. Nǹkan bí ìpín márùndínláàádọ́rùn-ún lára èso ápù jẹ́ omi.

Èròjà míràn tí ó tún wà lára ápù ni ethylene, èyí tí ó máa ń ṣiṣẹ́ ní pàtàkì gẹ́gẹ́ bí adíwọ̀n ìdàgbàsókè àdánidá tí ó máa ń jẹ́ kí èso náà pọ́n. Èròjà onígáàsì yìí ni o lè lò dáradára bí o bá ní tìmáàtì tí kò tí ì pọ́n tàbí èso píà tí kò tí ì rọ̀. Kó wọn sínú àpò kan pẹ̀lú ápù pípọ́n bíi mélòó kan, wọn kò sì ní pẹ́ẹ́ pọ́n.

Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé èso ápù ní ìniyelórí fún ìlera, ó ṣe pàtàkì láti mọ ìgbà tí ó yẹ kí ènìyàn jẹ wọn àti bí ó ṣe yẹ kí ènìyàn jẹ wọn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ kí wọn pọ́n. Kò sì dára kí ènìyàn jẹ́ èso ápù tí ó bá tutù; jẹ́ kí wọ́n wà níbẹ̀ nínú yàrá fún ìgbà díẹ̀. Ó tún ṣe pàtàkì pẹ̀lú láti rún wọn kúnná lẹ́nu.

Ó dùn mọ́ni pé, èso ápù ní àwọn èròjà kan tí wọ́n sọ pé ó máa ń ṣàǹfààní fún fífọ inú. Èròjà yìí kan náà máa ń wo àìrígbẹ̀ẹ́yà àti àrunṣu sàn.

Ìkìlọ Kan Nìyí O

Èèhù máa ń tètè hù lára èso ápù àti àwọn èso mìíràn pẹ̀lú. Nítorí èyí, ó yẹ kí ènìyàn ló ìṣọ́ra díẹ̀. Àwọn oró tí èèhù bá fà lè fa ìnira àti àyà rírìn. Nítorí èyí, ṣọ́ra fún èèhù, kì í sì í ṣe pé kí o gé apá ibi tí ó bá ní èèhù dànù nìkan ni, àmọ́ gbogbo àyíká ibi tí ó ti bà jẹ́ náà pẹ̀lú, nítorí pé oró náà máa ń ràn.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èso ápù máa ń pa kún ìlera rẹ. Nítorí náà, bí o bá fẹ́ ‘kí ara rẹ máa le,’ nígbà náà, gbìyànjú láti máa jẹ ápù lójoojúmọ́!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Igi ápù: Orin Solomoni 2:3; 8:5; Joeli 1:12. Èso ápù: Owe 25:11; Orin Solomoni 2:5; 7:8.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Igi ápù tí ó tí ó tanná látòkè délẹ̀ máa ń wu ojúú rí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́