Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Gbogbo Ìwé Inú Bíbélì Ṣì Wúlò Lóde Òní?
“Tá a bá yọwọ́ pé Bíbélì lè jẹ́ kéèyàn mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tàbí sáwọn ìbéèrè inú àwọn ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n, Bíbélì ò wúlò fún wa lóde òní.”
“Àwọn ohun tí Bíbélì sọ nípa ìlà ìdílé, wíwà láìní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run bá àṣà tó wà láyé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì mu, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ní Ọ̀rúndún Kọkànlélógún.”
“Kí wọ́n tó tẹ Bíbélì jáde rara làwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò ti bágbà mu.”
ORÍ ìkànnì kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì la ti mú àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu àìpẹ́ yìí, níbi tí wọ́n ti jíròrò àkòrí tó sọ pé, “Ṣé ìwé tí kò wúlò tí kò sì bágbà mu ni Bíbélì?” Kí lèrò tìẹ lórí ohun táwọn kan sọ yìí? Ṣó o gbà pẹ̀lú wọn?
Ó ṣeé ṣe kó o má fara mọ́ báwọn kan ṣe bẹnu àtẹ́ lu Bíbélì yìí, síbẹ̀ kó o máa ronú pé bóyá ni gbogbo ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣì wúlò lóde òní. Nígbà tó tiẹ̀ jẹ́ pé apá méjì ni wọ́n pín Bíbélì tí wọ́n ń lò nínú ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì sí, ìyẹn èyí táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa rò pé iye tó ju ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin lọ ló jẹ́ ìtàn láéláé tí kò sì bágbà mu.
A kì í fi ẹran rúbọ mọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Òfin Mósè. Kí wá nìdí tí gbogbo àlàyé nípa ẹbọ rírú ṣì fi wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Léfítíkù? (Léfítíkù 1:1–7:38) Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé 1 Kíróníkà, tó jẹ́ pé orúkọ àwọn ìlà ìdílé ló kún ibẹ̀. (1 Kíróníkà 1:1–9:44) Tí kò bá sẹ́nì kankan lóde òní tó lè tọpasẹ̀ ìlà ìdílé rẹ̀ títí dórí àwọn èèyàn tí ìwé yẹn dárúkọ, kí wá ni àǹfààní tó wà ńbẹ̀?
Ká sọ pé o ká èso látorí igi ápù kan. Tó o bá ká èso náà tán, ǹjẹ́ wàá sọ pé igi yẹn ò wúlò mọ́? Ó dájú pé o ò ní sọ bẹ́ẹ̀, torí o ṣì lè ká èso púpọ̀ sí i! A lè fi Bíbélì wé igi ápù yẹn. Ó dà bíi pé àwọn apá kan wà nínú Bíbélì táwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti kà tó sì sábà máa ń fà wọ́n lọ́kàn mọ́ra gan-an, irú bí ìwé Sáàmù tàbí Ìwàásù Orí Òkè. Téèyàn bá fẹ́ràn àwọn apá kan Bíbélì yìí, bí ìgbà téèyàn fẹ́ràn èso aládùn kan, ǹjẹ́ ó wá yẹ kó fojú pa ìyókù rẹ́? Kí ni Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí?
Ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì, ó rán an létí pé: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” Pọ́ọ̀lù wá fi kún un pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:15, 16) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní,” ṣé Májẹ̀mú Tuntun nìkan ló ń sọ ni?
Kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Tímótì pé ó ti mọ “Ìwé Mímọ” láti “ìgbà ọmọdé jòjòló.” Bí Tímótì bá ti lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún nígbà tí wọ́n kọ lẹ́tà yìí, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe sọ, ìyẹn túmọ̀ sí pé ọmọ jòjòló ló máa jẹ́ lásìkò tí Jésù kú. Ìyẹn sì jẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó ṣàkọsílẹ̀ apá èyíkéyìí nínú Májẹ̀mú Tuntun, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì. Júù ni ìyá Tímótì, torí náà, Ìwé Mímọ́ tó fi kọ́ Tímótì láti kékeré ti ní láti jẹ́ Májẹ̀mú Láéláé, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (Ìṣe 16:1) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu ba “gbogbo Ìwé Mímọ́,” kò sí àní-àní pé gbogbo Májẹ̀mú Láéláé tó sọ nípa àwọn ìlànà ẹbọ rírú àti ìtàn ìlà ìdílé wà lára ohun tó ní lọ́kàn.
Ní báyìí tó ti lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1,900] ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, a ṣì ń jàǹfààní látinú àwọn ìwé inú Bíbélì yìí lónírúurú ọ̀nà. Kò yẹ ká gbàgbé pé Ọlọ́run ló rí i dájú pé àwọn èèyàn tó yàn ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, wọ́n sì pa á mọ́. (Róòmù 3:1, 2) Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, àwọn Òfin Mósè kì í kàn ṣe ohun tí wọ́n ní láti tọ́jú fún àwọn ìran tó ń bọ̀, àmọ́ òun ni òfin orílẹ̀-èdè yẹn. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nínú Òfin yẹn tó lè dà bíi pé kò ṣe pàtàkì sí wa lónìí wà lára àwọn ohun tó jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí wọ́n ṣe máa là á já àti bí nǹkan ṣe gbọ́dọ̀ máa lọ sí ní orílẹ̀-èdè wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìtàn ìlà ìdílé tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì ló jẹ́ ká lè mọ Mèsáyà náà, ẹni tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wá láti ìlà ìdílé Ọba Dáfídì.—2 Sámúẹ́lì 7:12, 13; Lúùkù 1:32; 3:23-31.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin Mósè kọ́ ló ń darí àwọn Kristẹni, wọ́n ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, tó jẹ́ Mèsáyà tí a sọ tẹ́lẹ̀. Àwọn ìtàn ìlà ìdílé tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ni “ọmọ Dáfídì” tí a ṣèlérí. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó sì wà nínú Bíbélì nípa àwọn ìrúbọ jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ẹbọ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú, ó sì jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú ìtóye rẹ̀.—Hébérù 9:11, 12.
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ Kristẹni tó wà ní Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí rán wa létí pé àǹfààní wa làwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì wà fún, àmọ́ kì í ṣe fún àwa nìkan. Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [3,500] ọdún tí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tó wà nínú Bíbélì ti ń darí àwọn èèyàn Ọlọ́run, tó ń fún wọn ní ìtọ́ni, tó sì ń tọ́ wọn sọ́nà, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nínú aginjù Sínáì, ní Ilẹ̀ Ìlérí, nígbà tí wọ́n wà nígbèkùn Bábílónì, ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù àti ní báyìí kárí ayé. Kò sí ìwé míì tá a lè jẹ́rìí sí pé ó ṣé àwọn ohun tí Bíbélì ṣe yìí. Bó ṣe ṣòro díẹ̀ láti rí gbòǹgbò igi ápù, ó lè kọ́kọ́ ṣòro díẹ̀ láti mọ bí àwọn apá kan nínú Bíbélì ṣe wúlò tó. Èèyàn lè nílò láti walẹ̀ jìn díẹ̀ kó tó rí àwọn nǹkan yìí, síbẹ̀, ó dájú pé ìsapá yẹn kò ní já sásán!
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Látìgbà wo ni Tímótì ti mọ “ìwé mímọ́”?—2 Tímótì 3:15.
● Àwọn apá wo nínú Bíbélì ni Ọlọ́run mí sí, tó sì ṣàǹfààní?—2 Tímótì 3:16.
● Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú”?—Róòmù 15:4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ẹbọ tí Jésù fara rẹ̀ rú