ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 181
  • Kí Ni Bíbélì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa Bíbélì
  • Kí ni Bíbélì dá lé?
  • Ṣé wọ́n ti yí Bíbélì pa dà?
  • Kí nìdí tí wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè?
  • Ta ló pinnu ohun tó yẹ kó wà nínú Bíbélì?
  • Ṣé àwọn ìwé Bíbélì kan ti sọ nù?
  • Bó o ṣe lè wá àwọn ẹsẹ Bíbélì rí
  • Àwọn ìwé inú Bíbélì
  • Ohun Tí Ó Wà Nínú Ìwé Náà
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Ǹjẹ́ A Lè Mọ Ẹni Tó Kọ Bíbélì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣó Pọn Dandan Kó O Kọ́ Èdè Hébérù àti Gíríìkì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Kí Nìdí Tí Oríṣiríṣi Bíbélì Fi Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 181
Bíbélì Mímọ́ rèé láàárín onírúurú àwọn ìwé ìwádìí míì.

Kí Ni Bíbélì?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Àpapọ̀ ìwé mímọ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) ló wà nínú Bíbélì. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ọdún ló gbà láti kọ ọ́. “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ló sì wà nínú rẹ̀.​—1 Tẹsalóníkà 2:13.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa Bíbélì

  • Kí ni Bíbélì dá lé?

  • Ṣé wọ́n ti yí Bíbélì pa dà?

  • Kí nìdí tí wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè?

  • Ta ló pinnu ohun tó yẹ kó wà nínú Bíbélì?

  • Ṣé àwọn ìwé Bíbélì kan ti sọ nù?

  • Bó o ṣe lè wá àwọn ẹsẹ Bíbélì rí

  • Àwọn ìwé inú Bíbélì

Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa Bíbélì

  • Ta ló kọ Bíbélì? Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, ṣùgbọ́n nǹkan bí ogójì [40] èèyàn ló lò láti kọ ọ́. Díẹ̀ lára àwọn èèyàn tó lò ni Mósè, Ọba Dáfídì, Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù.a Ọlọ́run fi èrò rẹ̀ sínú ọkàn àwọn òǹkọ̀wé náà kí wọ́n lè kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀.​—2 Tímótì 3:16.

    Bí àpẹẹrẹ: Bí oníṣòwò kan bá ní kí akọ̀wé òun bá òun kọ lẹ́tà kan, tó sì sọ ohun tó máa kọ sínú lẹ́tà náà, oníṣòwò náà ló ṣì ni ìsọfúnni tó wà nínú lẹ́tà náà. Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run lo àwọn èèyàn láti kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀, òun gan-an ṣì ni Òǹkọ̀wé Bíbélì.

  • Kí ni ọ̀rọ̀ náà “Bíbélì” túmọ̀ sí? “Bíbélì” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà biblia, tó túmọ̀ sí “ìwé kéékèèké.” Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pe gbogbo ìwé kéékèèké tó para pọ̀ di Bíbélì ní biblia.

  • Ìgbà wo ni wọ́n kọ Bíbélì? Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ Bíbélì ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n sì parí rẹ̀ ní ọdún 98 Sànmánì Kristẹni, tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ọ́.

  • Ibo ni Bíbélì àkọ́kọ́ wà? Kò sí èyíkéyìí lára Bíbélì àkọ́kọ́ mọ́. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé orí àwọn ohun èèlò tó lè tètè bà jẹ́ tó wà nígbà yẹn ni wọ́n kọ Bíbélì sí, irú bí òrépèté àti awọ. Ṣùgbọ́n, àwọn akọ̀wé tó mọṣẹ́ ṣe àdàkọ Bíbélì léraléra fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún, kí àwọn èèyàn lè rí i kà lọ́jọ́ iwájú.

  • Kí ni “Májẹ̀mú Láéláé” àti “Májẹ̀mú Tuntun”? Apá tí wọ́n fi èdè Hébérùb kọ lára Bíbélì ni àwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé, òun náà tún ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ṣùgbọ́n apá tí wọ́n fi èdè Gíríìkì kọ ni wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun, òun náà sì ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Apá méjèèjì ló para pọ̀ di ìwé kan ṣoṣo, tá a tún ń pè ní Ìwé Mímọ́.c

  • Kí ló wà nínú Bíbélì? Lára ohun tó wà nínú àwọn ìwé Bíbélì ni ìtàn, àwọn òfin, àsọtẹ́lẹ̀, ewì, àwọn òwe, àwọn orin àtàwọn lẹ́tà.​—Wo “Àwọn Ìwé Inú Bíbélì.”

Kí ni Bíbélì dá lé?

Bíbélì kọ́kọ́ ṣe àlàyé ṣókí nípa bí Ọlọ́run Olódùmarè ṣe dá ọ̀run àti ayé. Ọlọ́run tún lo Bíbélì láti jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ òun, ó sì fẹ́ káwa èèyàn mọ òun.​—Sáàmù 83:18.

Bíbélì ṣàlàyé pé àwọn èèyàn tí sọ ọ̀pọ̀ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe máa dá orúkọ rẹ̀ láre.

Bíbélì sọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nípa ayé àtàwọn tó ń gbé inú rẹ̀. Ó jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe máa mú ohun tó ń fa ìyà fún àwọn èèyàn kúrò lọ́jọ́ iwájú.

Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn tó dáa nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa lójoojúmọ́. Lára àwọn ìmọ̀ràn tó fún wa rèé:

  • Bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. “Torí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.”​—Mátíù 7:12.

    Ìtumọ̀: Bí a bá ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí wa ni káwa náà máa ṣe sí wọn.

  • Bá a ṣe lè máa fara da ìdààmú. “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀.”​—Mátíù 6:34.

    Ìtumọ̀: Dípò tí àá fi máa dààmú ṣáá nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó sàn ká má ṣe da àníyàn tòní mọ́ tọ̀la.

  • Bí ìgbéyàwó wa ṣe lè láyọ̀. “Kí kálukú yín nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; bákan náà, kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”​—Éfésù 5:33.

    Ìtumọ̀: Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ló ń mú kí ìgbéyàwó yọrí sí rere.

Ṣé wọ́n ti yí Bíbélì pa dà?

Rárá. Àwọn ọ̀mọ̀wé ti fara balẹ̀ wo àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì àtíjọ́, wọ́n sì fi wéra pẹ̀lú Bíbélì tó wà lóde òní, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò tíì yí pa dà. Ìyẹn mọ́gbọ́n dání, ó ṣe tán, bí Ọlọ́run bá fẹ́ ká ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká sì lóye ohun tó wà níbẹ̀, ṣé kò ní rí sí i pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò yí pa dà?d​—Àìsáyà 40:8.

Kí nìdí tí wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè?

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka Bíbélì lóde òní ò lóye èdè àtijọ́ tí wọ́n fi kọ ọ́. Síbẹ̀ “ìhìn rere” tó wà “fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èdè” ló wà nínú ẹ̀. (Ìfihàn 14:6, àlàyé ìsàlẹ̀) Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn fi nílò Bíbélì tá a túmọ̀ sí èdè tó lè yé wọn kí wọ́n lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó sì yé wọn dáadáa.

Oríṣi ìtumọ̀ Bíbélì mẹ́ta ló wà:

  • Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn kọ̀ọ̀kan láwọn ibi tí èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì bá ti fàyè gbà á.

  • Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ èrò inú rẹ̀ lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì.

  • Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ lóréfèé máa ń yí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pa dà bó ṣe fẹ́ kó lè dùn-ún kà. Ṣùgbọ́n, bí Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ lóréfèé ṣe ń yí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pa dà yìí lè yí ìtumọ̀ tí ẹsẹ kan ní pa dà.

Ìtumọ̀ Bíbélì tó dáa máa to àwọn ọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe wà nínú èdè tí wọ́n fi kọ ọ́, á tún fi èdè tó bóde mu, tó sì rọrùn láti lóye túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn lọ́nà tó ṣe kedere.e

Ta ló pinnu ohun tó yẹ kó wà nínú Bíbélì?

Torí pé Ọlọ́run ni Òǹṣèwé Bíbélì, òun ló pinnu ohun tó yẹ kó wà nínú Bíbélì. Ó kọ́kọ́ “fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ Ọlọ́run sí” ìkáwọ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ kí wọ́n lè pa àwọn ìwé Mímọ́ lédè Hébérù mọ́.​—Róòmù 3:2.

Ṣé àwọn ìwé Bíbélì kan ti sọ nù?

Rárá. Bíbélì pé pérépéré; èyíkéyìí ò “sọ nú” lára àwọn ìwé Bíbélì. Àwọn kan lè sọ pé, ó yẹ káwọn ìwé àtijọ́ kan tí wọ́n ti fi pa mọ́ tipẹ́tipẹ́ wà lára àwọn ìwé Bíbélì.f Ṣùgbọ́n, inú Bíbélì gan-an la ti lè rí ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ péye. (2 Tímótì 1:13) Bí Bíbélì fúnra rẹ̀ ṣe sọ, kò sí ohun tó ta kora nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí. Èyí ò rí bẹ́ẹ̀ nípa gbogbo ìwé àtijọ́ táwọn kan sọ pé wọ́n jẹ́ apá kan Bíbélì.g

Bó o ṣe lè wá àwọn ẹsẹ Bíbélì rí

Bó o ṣe lè wá àwọn ẹsẹ Bíbélì rí tá a bá lo 2 Tímótì 3:16 bí àpẹẹrẹ. Ìtọ́kasí náà sọ ìwé Bíbélì tó o fẹ́ wá, irú bí ìwé Tímótì Kejì (nínú àwọn orúkọ tó wà nísàlẹ̀ yìí, wo bá a ṣe sábà máa ń to orúkọ àwọn ìwé inú Bíbélì tẹ̀ léra). Nọ́ńbà àkọ́kọ́ sọ orí tó o máa wá, irú bí orí 3. Nọ́ńbà tàbí àwọn nọ́ńbà tó tẹ̀ lé e sọ ẹsẹ tàbí àwọn ẹsẹ tó o máa kà, irú bí ẹsẹ 16.

Àwọn ìwé inú Bíbélì

Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù (“Májẹ̀mú Láéláé”)

  • Ìtàn àti òfin

    • Jẹ́nẹ́sísì

    • Ẹ́kísódù

    • Léfítíkù

    • Nọ́ńbà

    • Diutarónómì

  • Ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì

    • Jóṣúà

    • Àwọn Onídàájọ́

    • Rúùtù

    • 1 àti 2 Sámúẹ́lì

    • 1 àti 2 Àwọn Ọba

    • 1 àti 2 Kíróníkà

    • Ẹ́sírà

    • Nehemáyà

    • Ẹ́sítà

  • Ewì

    • Jóòbù

    • Sáàmù

    • Òwe

    • Oníwàásù

    • Orin Sólómọ́nì

  • Àsọtẹ́lẹ̀

    • Àìsáyà

    • Jeremáyà

    • Ìdárò

    • Ìsíkíẹ́lì

    • Dáníẹ́lì

    • Hósíà

    • Jóẹ́lì

    • Émọ́sì

    • Ọbadáyà

    • Jónà

    • Míkà

    • Náhúmù

    • Hábákúkù

    • Sefanáyà

    • Hágáì

    • Sekaráyà

    • Málákì

Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì (“Májẹ̀mú Tuntun”)

  • Ìtàn ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù (Ìhìn Rere)

    • Mátíù

    • Máàkù

    • Lúùkù

    • Jòhánù

  • Ìtàn ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀

    • Ìṣe

  • Lẹ́tà sí onírúurú ìjọ Kristẹni

    • Róòmù

    • 1 àti 2 Kọ́ríńtì

    • Gálátíà

    • Éfésù

    • Fílípì

    • Kólósè

    • 1 àti 2 Tẹsalóníkà

  • Lẹ́tà sí àwọn Kristẹni kan

    • 1 àti 2 Tímótì

    • Títù

    • Fílémónì

  • Lẹ́tà sí gbogbo Kristẹni

    • Hébérù

    • Jémíìsì

    • 1 àti 2 Pétérù

    • 1, 2, àti 3 Jòhánù

    • Júùdù

  • Àsọtẹ́lẹ̀

    • Ìfihàn

a Tó o bá fẹ́ wo gbogbo ìwé tó wà nínú Bíbélì, ẹni tó kọ wọ́n, àti ibi tí wọ́n ti kọ wọ́n, jọ̀wọ́ wo “Àtẹ Àwọn Ìwé Inú Bíbélì.”

b Èdè Árámáìkì, tó fara jọ èdè Hébérù gan-an ni wọ́n fi kọ díẹ̀ lára àwọn ìwé inú Bíbélì.

c Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka Bíbélì máa ń pè é ní “Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù” àti “Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.” Pípe Bíbélì lọ́nà yìí ò ní jẹ́ káwọn èèyàn rò pé ìgbà tí “Májẹ̀mú Láéláé” ò wúlò mọ́ ni Ọlọ́run fi “Májẹ̀mú Tuntun” rọ́pò rẹ̀.

d Wo “Ṣé Wọ́n Ti Yí Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Pa Dà?”

e Ọ̀pọ̀ fẹ́ láti máa ka Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun torí pé ìtumọ̀ rẹ̀ péye ó sì dùn-ún kà. Wo “Ṣé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Péye?”

f Àpapọ̀ àwọn ìwé yìí ni wọ́n ń pè ní Àpókírífà. Bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ṣe sọ, “tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwé Bíbélì, [ọ̀rọ̀ yìí ni à ń lò fún] àwọn ìwé tí kò sí lára àkójọ àwọn ìwé inú Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí.

g Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo “Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Ti Àpókírífà​—Ǹjẹ́ Ìtàn Jésù Tí Bíbélì Kò Sọ Ni Lóòótọ́?”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́