Ohun Tí Ó Wà Nínú Ìwé Náà
Ìtògẹ̀nrẹ̀n àwọn ìwé lè pin ẹnì kan tí ó jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí yóò wọ ibi ìkówèésí lẹ́mìí. Ṣùgbọ́n, ní ṣíṣe ìwọ̀nba àlàyé díẹ̀ nípa bí a ṣe to àwọn ìwé náà, láìpẹ́ yóò mọ bí a ṣe ń wá nǹkan rí. Bákan náà, wíwá nǹkan rí nínú Bíbélì yóò rọrùn bí ó bá ti lóye bí a ṣe to àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀.
Ọ̀RỌ̀ náà “Bíbélì” ni a mú jáde láti inú ọ̀rọ̀ èdè Gírí ìkì náà bi·bliʹa, tí ó túmọ̀ sí “àwọn ìwé òrépèté kíká” tàbí “àwọn ìwé.”1 Ní tòótọ́, Bíbélì jẹ́ àkójọ ìwé—láíbìrì kan—tí ó ní ìwé 66 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú, tí kíkọ rẹ̀ gba nǹkan bí 1,600 ọdún, láti 1513 ṣáájú Sànmánì Tiwa sí nǹkan bí 98 Sànmánì Tiwa.
Ìwé 39 àkọ́kọ́, nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin ohun tí ó wà nínú Bíbélì, ni a mọ̀ sí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé èdè yẹn ni a fi kọ ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn. Ní gbogbogbòò, a lè pín ìwé náà sí ìsọ̀rí mẹ́ta: (1) Onítàn, Jẹ́nẹ́sísì dé Ẹ́sítérì, ìwé 17; (2) Eléwì, Jóòbù dé Orin Sólómọ́nì, ìwé 5; àti (3) Alásọtẹ́lẹ̀, Aísáyà dé Málákì, ìwé 17. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kárí ìtàn ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ ayé àti ti ìran ènìyàn àti ìtàn orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di ọ̀rúndún karùn ún ṣáájú Sànmánì Tiwa.
Ìwé 27 tí ó ṣẹ́ kù ni a mọ̀ sí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gírí ìkì, nítorí pé èdè Gíríìkì ni a fi kọ wọ́n, èdè tí a ń sọ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ìgbà náà. Ní pàtàkì, ṣe ni a tò wọ́n níbàámu pẹ̀lú kókó ẹ̀kọ́ wọn: (1) ìwé 5 tí ó jẹ́ onítàn—Àwọn Ìwé Ìhìn Rere àti Ìṣe, (2) àwọn lẹ́tà 21, àti (3) Ìṣípayá. Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gírí ìkì kó àfiyèsí jọ sórí àwọn ẹ̀kọ́ àti ìgbòkègbodò Jésù Kristi àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa.