ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jd orí 1 ojú ìwé 5-13
  • Iṣẹ́ Tí Jèhófà Rán Sí Àwọn Èèyàn Ayé Ọjọ́un Ṣì Wà Fún Wa Lónìí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣẹ́ Tí Jèhófà Rán Sí Àwọn Èèyàn Ayé Ọjọ́un Ṣì Wà Fún Wa Lónìí
  • Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ṢÉ LÓÒÓTỌ́ NI “ÌWÉ ÀWỌN WÒLÍÌ KÉKERÉ” NÁÀ KÒ FI BẸ́Ẹ̀ ṢE PÀTÀKÌ?
  • Ọ̀NÀ WO NI WỌ́N GBÀ JẸ́ ÌWÉ ÀSỌTẸ́LẸ̀?
  • BÁ A ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ
  • Mọ Jèhófà Kó O Sì Máa Sìn Ín
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Ọlọ́run Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Múra Sílẹ̀ Fún Ọjọ́ Ńlá Rẹ̀
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Àwọn Wòlíì Tí Wọ́n Jíṣẹ́ Tó Lè Ṣe Wá Láǹfààní
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Ọjọ́ Jèhófà—Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Pàtàkì
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
Àwọn Míì
Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
jd orí 1 ojú ìwé 5-13

ORÍ KÌÍNÍ

Iṣẹ́ Tí Jèhófà Rán Sí Àwọn Èèyàn Ayé Ọjọ́un Ṣì Wà Fún Wa Lónìí

1, 2. Báwo ni àwọn kan ṣe ń wá ìṣúra kiri, àmọ́ kí ló lè mú ọ gbádùn ìgbésí ayé?

ỌJỌ́ pẹ́ tó ti máa ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn bíi pé kí wọ́n rí ìṣúra abẹ́ ilẹ̀, ìyẹn àwọn ohun iyebíye tó wà nínú ilẹ̀. Ǹjẹ́ o ti ka ìtàn nípa àwọn olùṣèwádìí, àwọn awalẹ̀pìtàn, àtàwọn mìíràn tí wọ́n ń wá ìṣúra abẹ́ ilẹ̀ kiri? Bí ìwọ ò tiẹ̀ máa wá irú ìṣúra bẹ́ẹ̀ kiri, ǹjẹ́ inú rẹ ò ní dùn tó o bá rí ohun iyebíye kan? Àǹfààní gidi nìyẹn á mà jẹ́ o tí ìṣúra ọ̀hún bá lè mú kó o túbọ̀ láyọ̀ nígbèésí ayé kó o sì ṣe ojúlówó àṣeyọrí!

2 Ìṣúra inú ilẹ̀ kọ́ ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wá kiri, àmọ́ wọ́n máa ń lépa ayọ̀, wọ́n sì máa ń forí ṣe fọrùn ṣe kí ọwọ́ wọn lè tẹ àwọn nǹkan tí wọ́n rò pé ó máa mú káwọn láyọ̀, irú bí owó, ìlera àti ìdílé aláyọ̀. Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìṣúra téèyàn ò lè rí nínú ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí àwòrán ilẹ̀ tó lè júwe ibi téèyàn ti lè rí wọn. Bí ìwọ náà ṣe mọ̀, èèyàn gbọ́dọ̀ sapá kọ́wọ́ rẹ̀ tó lè tẹ ìṣúra wọ̀nyí. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ fi máa ń mọyì rẹ̀ tí wọ́n bá rí ìmọ̀ràn tó wúlò nípa bí ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ àwọn ohun tí wọ́n ń wá àti bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ gbádùn ìgbésí ayé wọn kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí.

3, 4. Ibo lo ti lè rí ìmọ̀ràn tó wúlò nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa gbé ìgbé ayé rẹ̀?

3 Kò dìgbà tó o bá rìn jìnnà kó o tó lè rí ìmọ̀ràn tó wúlò, ìyẹn ìtọ́sọ́nà tó ti sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di aláyọ̀. Inú Bíbélì la ti lè rí ìmọ̀ràn tó dára jù lọ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn gbé ìgbé ayé, ọ̀pọ̀ ló sì ti mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ohun tí Charles Dickens tó jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ nípa Bíbélì ni pé: “Òun [ìyẹn Bíbélì] la mọ̀ sí ìwé tó dáa jù látìgbà táláyé ti dáyé, ohun táwọn ìran tó ń bọ̀ sì máa mọ̀ ọ́n sí náà nìyẹn . . . nítorí pé òun ló ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ . . . tó lè tọ́ ẹnikẹ́ni sọ́nà.”

4 Ohun tí òǹkọ̀wé yẹn sọ kò lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fáwọn tí wọ́n ka Bíbélì sí ìwé tí Ọlọ́run mí sí. Ó ṣeé ṣe kó o fara mọ́ ohun tí 2 Tímótì 3:16 fi dá wa lójú, pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” Lédè mìíràn, Bíbélì ní àwọn ẹ̀kọ́ tó lè jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè máa gbé ìgbé ayé wọn láìka bí ìṣòro ṣe pọ̀ láyé òde òní sí. Àwọn tí wọ́n bá ń jẹ́ kí Bíbélì máa tọ́ àwọn sọ́nà lè túbọ̀ gbádùn ìgbésí ayé, wọ́n sì lè túbọ̀ ṣe ojúlówó àṣeyọrí.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12

5-7. Apá ibo nínú Bíbélì lo lè kà láti rí ìtọ́sọ́nà tó máa ṣe ọ́ láǹfààní?

5 Àmọ́, inú àwọn ìwé Bíbélì wo lo rò pé o ti lè rí ìtọ́sọ́nà yẹn? Ibi tí ọkàn àwọn kan máa lọ ni àkọsílẹ̀ Ìwàásù Orí Òkè, níbi tí Jésù ti gbani nímọ̀ràn lórí onírúurú àwọn ohun tó kan ìgbésí ayé ẹ̀dá ojoojúmọ́. Àwọn mìíràn á rántí àwọn ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ. Sáàmù àti ìwé Òwe pẹ̀lú kún fún ọgbọ́n, ẹnikẹ́ni ló sì lè rí ìmọ̀ràn tó lè ràn án lọ́wọ́ nínú wọn. Ní tòdodo, èyíkéyìí nínú àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́, ó sinmi lórí ipò tó o bá wà àti ìṣòro tó o bá ní. Kódà àwọn ìwé Bíbélì tó jẹ́ pé ìtàn pọ́ńbélé ló wà nínú wọn, irú bí ìwé Jóṣúà àti ìwé Ẹ́sítérì, lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Àwọn ìtàn tó wà níbẹ̀ jẹ́ ìkìlọ̀ fún gbogbo àwọn tó ń wá bí wọ́n ṣe máa rí ayọ̀ nínú sísin Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìwé wọ̀nyẹn pèsè ìmọ̀ràn tó lè tọ́ ọ sọ́nà, ìmọ̀ràn tó o lè máa tẹ̀ lé kó o lè ṣe ojúlówó àṣeyọrí nígbèésí ayé. Rántí òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ, pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4; Jóṣúà 1:8; 1 Kíróníkà 28:8, 9.

6 Síbẹ́, apá ibì kan wà nínú Bíbélì tó dà bí ilẹ̀ tẹ́nì kan ò fọwọ́ kàn rí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìṣúra iyebíye wà níbẹ̀. Èyí ni àpapọ̀ ìwé kéékèèké méjìlá táwọn kan sábà máa ń pè ní Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré. Àwọn ìwé ọ̀hún wà ní ìkọjá ìwé Ìsíkíẹ́lì àti Dáníẹ́lì, kéèyàn tó dé ìwé Ìhìn Rere Mátíù. (Bí àwọn ìwé méjìlá náà ṣe tò tẹ̀ léra wọn nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì rèé: Hóséà, Jóẹ́lì, Ámósì, Ọbadáyà, Jónà, Míkà, Náhúmù, Hábákúkù, Sefanáyà, Hágáì, Sekaráyà, àti Málákì.) A ti rí i pé ìmísí Ọlọ́run ni wọ́n fi kọ àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì àti pé àwọn ìwé náà máa ń kọ́ni wọ́n sì máa ń jẹ́ kéèyàn mọ bó ṣe yẹ kó máa gbé ìgbé ayé rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn ìwé méjìlá tá a mẹ́nu kàn yìí náà wà lára àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí wọ̀nyẹn?

7 Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n wà lára wọn! Àní sẹ́, àwọn ohun iyebíye, tó ń fi bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa lóde òní hàn wá, wà nínú àwọn ìwé Bíbélì táwọn kan ń pè ní Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré wọ̀nyí. Kó o bàa lè mọ ìdí táwọn kan fi ń fojú kéré ìwé wọ̀nyí, ṣe àgbéyẹ̀wò ohun táwọn èèyàn ń pe àwọn ìwé náà ní ọ̀pọ̀ èdè, ìyẹn, Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré. Ǹjẹ́ ó yẹ kí ohun tí wọ́n ń pe ìwé wọ̀nyí mú káwọn èèyàn máa fojú kéré wọn? Ṣé ohun tí wọ́n ń pè wọ́n yìí ò tiẹ̀ ti mú kí ìwọ náà ní èrò tí kò tọ́ nípa wọn?

ṢÉ LÓÒÓTỌ́ NI “ÌWÉ ÀWỌN WÒLÍÌ KÉKERÉ” NÁÀ KÒ FI BẸ́Ẹ̀ ṢE PÀTÀKÌ?

8. (a) Ọ̀nà pàtàkì wo ni Ọlọ́run ti gbà pèsè ìtọ́sọ́nà? (b) Kí ni wọ́n máa ń pe àwọn ìwé méjìlá náà ní ọ̀pọ̀ èdè, kí sì ni ìdí tí wọ́n fi ń pè wọ́n bẹ́ẹ̀?

8 Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tó kọ sí àwọn Hébérù rèé: “Ọlọ́run, ẹni tí ó tipasẹ̀ àwọn wòlíì bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn lọ́pọ̀ ìgbà àti lọ́pọ̀ ọ̀nà, ti tipasẹ̀ Ọmọ kan bá wa sọ̀rọ̀ ní òpin ọjọ́ wọ̀nyí.” (Hébérù 1:1, 2) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló rán àwọn wòlíì náà níṣẹ́, kò yẹ ká wo èyíkéyìí lára wọn tàbí ìwé tí wọn kọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí “kò ṣe pàtàkì tó àwọn tó kù.” Síbẹ̀, pípè tí àwọn kan ń pe àwọn ìwé náà ní “Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré” ti mú kí àwọn kan máa wo àwọn ìwé náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Èrò àwọn míì tiẹ̀ ni pé ohun tó wà nínú àwọn ìwé náà kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tó ohun tó wà nínú àwọn ìwé tó kù nínú Bíbélì. Àmọ́, kì í ṣe torí pé àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí kò ṣe pàtàkì tó àwọn tó kù ni wọ́n ṣe ń pè wọ́n ní “Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré”a ní ọ̀pọ̀ èdè, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ nítorí pé wọn kò gùn tó àwọn ìwé tó kù.

9. Kí nìdí tí gígùn ìwé Bíbélì kan tàbí bó ṣe kúrú tó kò fi ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú bó ṣe wúlò tó?

9 Bí ọ̀kan nínú àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì ò tiẹ̀ gùn, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ìwé ọ̀hún kò ṣe pàtàkì tàbí pé kò wúlò fún ọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé Rúùtù kéré gan-an sí àwọn ìwé tó ṣáájú rẹ̀ àtàwọn ìwé tó wà ní ìkọjá rẹ̀, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì ló wà nínú rẹ̀! Ìwé tí kò gùn yìí fi hàn kedere pé ó yẹ ká rọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́, ó fi bí àwọn obìnrin ṣe ṣe pàtàkì tó lójú Ọlọ́run hàn, ó sì kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa ìlà ìdílé tí Jésù ti wá. (Rúùtù 4:17-22) Àpẹẹrẹ mìíràn ni ìwé Júúdà tí wàá kàn kó o tó kan ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì. Ìwé yìí kéré gan-an débi pé, nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan, kò tó ojú ewé kan. Síbẹ̀, ó kún fún ògidì ẹ̀kọ́ àti ojúlówó ìtọ́sọ́nà: Ó sọ nípa ohun tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn áńgẹ́lì búburú, ó kìlọ̀ fún wa nípa àwọn oníwà ìbàjẹ́ èèyàn tí wọ́n máa ń yọ́ wọnú ìjọ, ó sì gbà wá níyànjú pé ká máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́! O lè wá rí i dájú wàyí pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé táwọn kan ń pè ní Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré yìí kúrú, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ tó wà nínú wọn kì í ṣe kékeré, wọ́n wúlò gan-an.

Ọ̀NÀ WO NI WỌ́N GBÀ JẸ́ ÌWÉ ÀSỌTẸ́LẸ̀?

10, 11. (a) Kí ló ṣeé ṣe kí àwọn kan rò bí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “wòlíì”? (b) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi hàn, irú ẹni wo làwọn wòlíì jẹ́, kí sì ni iṣẹ́ àwọn wòlíì nígbà láéláé?

10 Ọ̀rọ̀ náà, “ìwé àsọtẹ́lẹ̀” àti “àwọn wòlíì,” ni ohun mìíràn tó tún yẹ ká gbé yẹ̀ wò. Téèyàn bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ohun tó ṣeé ṣe kó wá sọ́kàn èèyàn ni pé wọ́n jẹ mọ́ sísọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé àsọtẹ́lẹ̀ nìkan làwọn wòlíì máa ń sọ, àti pé ọ̀rọ̀ àdììtú tó lè ní ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ ni wọ́n máa ń lò. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé àwọn ìwé méjìlá tá à ń sọ̀rọ̀ nípa wọn kò ṣe pàtàkì tó àwọn ìwé tó kù nínú Bíbélì.

11 Ká sòótọ́, bó o bá ṣe ń ka ìwé méjìlá wọ̀nyí, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ló wà nínú wọn, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bọ̀. Ìyẹn bá ìtumọ̀ pàtàkì kan tí ọ̀rọ̀ náà, “wòlíì” túmọ̀ sí mu. Nígbà láéláé, wòlíì jẹ́ ẹnì kan tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, tí Ọlọ́run máa ń lò láti sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì ìgbàanì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, bẹ̀rẹ̀ látorí Énọ́kù, ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la.—1 Sámúẹ́lì 3:1, 11-14; 1 Àwọn Ọba 17:1; Jeremáyà 23:18; Ìṣe 3:18; Júúdà 14, 15.

12. Kí ló fi hàn pé kì í ṣe sísọ àsọtẹ́lẹ̀ nìkan ni iṣẹ́ àwọn wòlíì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn?

12 Àmọ́, a ní láti rántí pé sísọ àsọtẹ́lẹ̀ nìkan kọ́ ni iṣẹ́ tí Jèhófà máa ń rán àwọn wòlíì rẹ̀ láyé àtijọ́. Nígbà yẹn, Ọlọ́run sábà máa ń lo àwọn wòlíì gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ rẹ̀ láti sọ ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́ fún àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a lè má fi ojú ẹni tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wo Ábúráhámù, Ísáákì àti Jékọ́bù, síbẹ̀ Sáàmù 105:9-15 pè wọ́n ní wòlíì. Nígbà míì, Ọlọ́run máa ń lò wọ́n láti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, irú bí ìgbà tí Jékọ́bù ń súre fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Àmọ́, àwọn babańlá wọ̀nyẹn tún jẹ́ wòlíì ní ti pé, nígbà tí Jèhófà sọ fún wọn nípa ipa tí wọ́n á kó nínú ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe, wọ́n sọ èyí fún ìdílé wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 20:7; 49:1-28) Ohun mìíràn tó tún fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà, “wòlíì,” tá a rí nínú Bíbélì, ní ìtumọ̀ tó gbòòrò ni pé Áárónì ṣe wòlíì fún Mósè. Áárónì ṣe iṣẹ́ wòlíì ní ti pé ó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ tàbí “ẹnu,” fún Mósè.—Ẹ́kísódù 4:16; 7:1, 2; Lúùkù 1:17, 76.

13, 14. (a) Ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ pé kì í ṣe sísọ àsọtẹ́lẹ̀ nìkan ni iṣẹ́ tí àwọn wòlíì ṣe. (b) Báwo lo ṣe lè jàǹfààní nínú mímọ̀ tó o bá mọ̀ pé kì í ṣe sísọ àsọtẹ́lẹ̀ nìkan ni iṣẹ́ tí àwọn wòlíì ṣe?

13 Tún ronú nípa wòlíì Sámúẹ́lì àti wòlíì Nátánì. (2 Sámúẹ́lì 12:25; Ìṣe 3:24; 13:20) Jèhófà lo àwọn méjèèjì láti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ó tún mú kí wọ́n sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì láwọn ọ̀nà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, bí Sámúẹ́lì ṣe ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, ó pàrọwà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà kí wọ́n sì padà sẹ́nu ìjọsìn tòótọ́. Ó tún kéde ìdájọ́ Ọlọ́run lé Sọ́ọ̀lù Ọba lórí, èyí tó kọ́ wa pé Jèhófà ka ìgbọràn sí ju ẹbọ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, sísọ tí Sámúẹ́lì sọ èrò Ọlọ́run nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa jẹ́ ara iṣẹ́ tí Sámúẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. (1 Sámúẹ́lì 7:3, 4; 15:22) Bákan náà, wòlíì Nátánì sọ tẹ́lẹ̀ pé Sólómọ́nì yóò kọ́ tẹ́ńpìlì àti pé Ọlọ́run yóò fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 7:2, 11-16) Àmọ́ ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì náà ló ṣì ń ṣe nígbà tó lọ sọ fún Dáfídì pé ó dẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà àti pé ó ṣe ohun tó burú jáì sí Ùráyà. Ta ló lè gbàgbé bí Nátánì ṣe tú àṣírí ìwà panṣágà tí Dáfídì hù, bó ṣe lo àpèjúwe ọkùnrin olówó kan tó mú ọ̀dọ́ àgùntàn kan ṣoṣo tí ọkùnrin tálákà kan ní? Nátánì tún bá wọn lọ́wọ́ sí i nígbà tí wọ́n ń ṣètò ìjọsìn tòótọ́ nínú ilé ìjọsìn Ọlọ́run.—2 Sámúẹ́lì 12:1-7; 2 Kíróníkà 29:25.

14 Kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ ni pé kò yẹ ká máa rò pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la nìkan ló wà nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí. Àwọn nǹkan mìíràn tí Ọlọ́run sọ wà nínú wọn, títí kan ọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà yẹn lọ́hùn-ún máa gbé ìgbé ayé wọn àti bó ṣe yẹ kí àwa náà máa gbé ìgbé ayé wa lónìí. Ó dá wa lójú pé ohun tá a rí nínú Bíbélì, èyí tí àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí jẹ́ apá kan rẹ̀, wúlò gidigidi ó sì ṣeé fi sílò, ó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbé ìgbé ayé wọn. Àwọn ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run wọ̀nyí fún wa ní ojúlówó ìtọ́sọ́nà tó lè ràn wá lọ́wọ́ “láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Títù 2:12.

BÁ A ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ

15, 16. (a) Irú àwọn àpèjúwe wo la lè rí nínú “Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré”? (b) Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ wo ló wà nínú àwọn ìwé wọ̀nyẹn?

15 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè gbà ṣe wá láǹfààní. Àwọn ìwé Bíbélì kan sọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láwọn ìgbà kan fún wa, àwọn mìíràn jẹ́ orin nígbà tí àwọn mìíràn lo èdè ewì, kálukú ló sì ní àǹfààní tiẹ̀. Ní ti àwọn mìíràn sì rèé, àpèjúwe tàbí àpẹẹrẹ pọ̀ nínú wọn gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí. Bí àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ ohun tó wà nínú ìwé Jónà ni Jésù ń sọ̀rọ̀ bá nígbà tó sọ pé: “Ìran burúkú àti panṣágà tẹra mọ́ wíwá àmì, ṣùgbọ́n a kì yóò fi àmì kankan fún un àyàfi àmì Jónà wòlíì. Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí Jónà ti wà ní ikùn ẹja mùmùrara náà fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ènìyàn yóò wà ní àárín ilẹ̀ ayé fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta. Àwọn ènìyàn Nínéfè yóò dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí pé wọ́n ronú pìwà dà lórí ohun tí Jónà wàásù, ṣùgbọ́n, wò ó! ohun kan tí ó ju Jónà lọ wà níhìn-ín.”—Mátíù 12:39-41.

16 Ó hàn gbangba pé Jésù rí i pé ohun mìíràn tún wà nínú ìwé Jónà yàtọ̀ sí àkọsílẹ̀ ìtàn bí Ọlọ́run ṣe bá Jónà lò, iṣẹ́ Jónà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì ní Nínéfè àti ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ nígbà tó jíṣẹ́ ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run rán an. Jésù Kristi rí i pé ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jónà jẹ́ àpèjúwe tàbí àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun, ìyẹn ikú òun àti bóun ṣe máa jíǹde ní ọjọ́ kẹta. Kò mọ síbẹ̀ o, ohun tí àwọn ará Nínéfè ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìkìlọ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìwàásù Jésù tí wọ́n sì rí àwọn iṣẹ́ tó ṣe. (Mátíù 16:4) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a mọ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wà nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí tó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò lónìí. Irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń dùn mọ́ni ó sì lérè.b

17. Ọ̀nà wo ni ìwé tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí gbà ṣàlàyé àwọn ìwé méjìlá náà?

17 Àmọ́, a kò ṣe ìwé tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí láti fi ṣàlàyé ìtumọ̀ àwọn àpèjúwe tàbí àpẹẹrẹ tó wà nínú ìwé Jónà àtàwọn ìwé mọ́kànlá tó kù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbé àwọn ìwé méjìlá náà yẹ̀ wò ní ẹsẹ-ẹsẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdí pàtàkì tá a fi ṣe ìwé yìí ni ká lè mọ àwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé méjìlá náà tá a lè máa fi sílò nínú ìgbésí ayé wa. Bi ara rẹ pé: ‘Kí ni ìmọ̀ràn wíwúlò tí Jèhófà fún mi nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí? Báwo ni ìwé wọ̀nyí ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ láti “gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí”? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀, tó sì ti sún mọ́lé, kí ni ìwé wọ̀nyí sọ fún mi nípa bó ṣe yẹ kí Kristẹni máa gbé ìgbé ayé rẹ̀, irú ìwà tó yẹ kí Kristẹni máa hù, bó ṣe yẹ kí ìdílé rẹ̀ rí, àti bó ṣe yẹ kó máa ṣe ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko yìí?’ (Títù 2:12; Jóẹ́lì 2:1; 2 Tímótì 3:1) Bó o bá ṣe ń rí ojúlówó ìdáhùn, ó ṣeé ṣe kó o máa rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí o kò tíì lò rí nígbà tí ò ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì han àwọn ẹlòmíràn. Tó o bá fi àwọn ẹsẹ náà sọ́kàn, nǹkan tó o mọ̀ nínú Bíbélì á pọ̀ sí i.—Lúùkù 24:45.

18. Báwo la ṣe ṣètò ìwé yìí, báwo lo sì ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀?

18 Ìsọ̀rí mẹ́rin la pín àwọn orí tó wà nínú ìwé yìí sí. Gbìyànjú láti mọ ohun tí wàá bá pàdé ní ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan nígbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìsọ̀rí ọ̀hún. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan orí mẹ́tàlá tó tẹ̀ lé e, wàá máa rí àpótí méjì tó máa jẹ́ kó o rántí ohun tó o ti kọ́. Àwọn ìbéèrè tó wà nínú àwọn àpótí náà yóò jẹ́ kó o lè ronú lórí ohun tó o kà kó o sì ronú nípa bó ṣe wúlò tó àti bó o ṣe lè fi sílò. Àpótí àkọ́kọ́ wà ní agbedeméjì àwọn orí náà. Nígbà tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ débi àpótí náà, gbé àwọn ìbéèrè tó wà nínú rẹ̀ yẹ wò. Ìyẹn á jẹ́ kí ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ náà fìdí múlẹ̀ lọ́kàn rẹ. (Mátíù 13:8, 9, 23; 15:10; Lúùkù 2:19; 8:15) Wàá rí àpótí kejì ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpótí yìí ni wàá fi ronú lórí ohun tó o kọ́ ní apá tó gbẹ̀yìn orí náà kó lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin. Nítorí náà, máa wá àyè láti gbé àwọn àpótí náà yẹ̀ wò. Àwọn àpótí náà ló máa fi ọ̀nà tó o lè gbà jàǹfààní nínú ohun tó ò ń kọ́ hàn ọ́.

19. Kí ló yẹ kó o kọ́kọ́ mọ̀ nípa àwọn ìwé méjìlá náà?

19 Kó o lè gbára dì láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí, bi ara rẹ ní ohun tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí. Àwọn wo ni Ọlọ́run lò láti kọ àwọn ìwé náà, irú èèyàn wo sì ni wọ́n? Ìgbà wo ni wọ́n gbé ayé, irú ipò wo ni wọ́n sì ti sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì? (Àtẹ ìsọfúnni nípa ìgbà tí àwọn wòlíì náà gbé ayé, èyí tó wà ní ojú ìwé 20 àti 21, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; máa yẹ̀ ẹ́ wò lóòrèkóòrè bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn orí tó tẹ̀ lé e.) Kí ni iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ fáwọn èèyàn nígbà yẹn lọ́hùn-ún, báwo sì ni mímọ̀ tó o bá mọ̀ ọ́n yóò ṣe jẹ́ kó o lóye àwọn ìwé náà ní àyíká ọ̀rọ̀ tá à ń gbé yẹ̀ wò? Àwọn orí tó kàn lẹ́yìn èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì wọ̀nyí.

a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica, Ìdìpọ̀ Kejìlá, ojú ìwé kọkàndínláàádọ́ta sọ pé “ó dà bíi pé gbólóhùn náà wá látinú ọ̀rọ̀ Èdè Látìn náà, Prophetae Minores, tó jẹ́ orúkọ tí wọ́n fún àwọn ìwé náà nínú ìtumọ̀ Bíbélì Vulgate. Ọ̀rọ̀ àpèjúwe náà, ‘kékeré’ tó wà nínú gbólóhùn náà ‘Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré’ kò fi hàn pé àwọn ìwé méjìlá náà kò ṣe pàtàkì tó ìwé Aísáyà, Jeremáyà, àti Ìsíkíẹ́lì, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fi hàn ni pé wọn kò gùn tó wọn.”

b Bí àpẹẹrẹ, wo àlàyé lórí Hágáì àti Sekaráyà nínú ìwé Paradise Restored to Mankind—By Theocracy! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí, àmọ́ a kò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ O LÈ RÍ LÁTINÚ ÌWÉ WỌ̀NYÍ

  • Àwọn èrò tí kò tọ̀nà wo nípa “Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré” ni kò yẹ kó o ní? —Róòmù 15:4.

  • Kí nìdí tó o fi lè retí pé wàá jàǹfààní tó o bá gbé àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà yẹ̀ wò?—2 Tímótì 3:16.

  • Kí lo lè máa retí bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé wọ̀nyí?—1 Tẹsalóníkà 2:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́