ÌSỌ̀RÍ 1
Ọlọ́run Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Múra Sílẹ̀ Fún Ọjọ́ Ńlá Rẹ̀
Wòlíì Ọlọ́run sọ pé, “ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé.” (Sefanáyà 1:14) Nítorí pé ọjọ́ yẹn ń yára sún mọ́lé, a ní láti máa fi í sọ́kàn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe nígbèésí ayé wa. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn ìwé Bíbélì táwọn kan ń pè ní Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré ní nǹkan kan pàtàkì láti bá ọ sọ nípa ọjọ́ ńlá yẹn? Orí Ìkíní sí Ìkẹta nínú ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ̀ nípa àwọn wòlíì méjìlá tó kọ àwọn ìwé yẹn àti kókó pàtàkì tó wà nínú wọn. Nípa báyìí, wàá jàǹfààní nínú ohun tí wọ́n kọ, wàá sì rí ẹ̀kọ́ kọ́, èyí tó o lè fi sílò nínú ìgbésí ayé rẹ.