Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
1 “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sef. 1:14) Sefanáyà àtàwọn wòlíì mọ́kànlá táwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Àwọn Wòlíì Kéékèèké fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn. Bá a ṣe máa gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọn yẹ̀ wò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbára dì de ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù náà.—Sef. 2:2, 3.
2 Àwọn Nǹkan Tó Mú Kó Yàtọ̀: Dípò tí ìwé Ọjọ́ Jèhófà ì bá fi sọ ìtumọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ táwọn wòlíì méjìlá náà kọ sílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ, ńṣe ló ṣàlàyé bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe kàn wá lóde òní. Ó tẹnu mọ́ ọn pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká máa jẹ́ kó hàn nínú ìpinnu àti ohun tá à ń ṣe. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìdílé, bí àárín àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ní láti rí, irú eré ìnàjú tó yẹ ká yàn, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti ohun tá a pinnu láti fìgbésí ayé wa ṣe.
3 Ìsọ̀rí 1 jẹ́ ká mọ àwọn wòlíì méjìlá náà dunjú àtàwọn ìwé tí wọ́n kọ. Ta ni wọ́n? Kí ló mú kí àkókò tiwọn àti tiwa jọra? Ìsọ̀rí 2 sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ànímọ́ rẹ̀. Òye tó jinlẹ̀ nípa Jèhófà àti àkópọ̀ ìwà rẹ̀ wo làwọn wòlíì yìí jẹ́ ká ní? Ìsọ̀rí 3 dá lé irú ìwà tá à ń hù àti bá a ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn. Láwọn ọ̀nà wo lohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́ ṣe lè máa múnú Ọlọ́run dùn? Ìsọ̀rí 4 sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa fayọ̀ lo ìgbé ayé wa bá a ṣe ń retí ọjọ́ Jèhófà.
4 Bẹ̀rẹ̀ sí Í Ṣètò Láti Jàǹfààní: Ìsinsìnyí ló yẹ kó o ti pinnu láti ṣe gbogbo ohun tó yẹ, kó o bàa lè jàǹfààní ní kíkún látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ọjọ́ Jèhófà, tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í kà lọ́sẹ̀ August 4, 2008! Pinnu pé oò ní í pa ọ̀sẹ̀ kan jẹ láìlọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Máa fara balẹ̀ múra ibi tá a bá máa kà lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀, kó o sì máa wo báwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ ṣe bá ohun tá a fẹ́ jíròrò mu. Máa ronú jinlẹ̀ lórí àlàyé náà, kó o sì máa bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi, ‘Ọ̀nà wo ni àlàyé yìí lè gbà wúlò nílé, níléèwé, níbi iṣẹ́, lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti nínú ọ̀nà tí mo gbà ń bá àwọn Kristẹni bíi tèmi lò?’ Múra sílẹ̀ láti dáhùn bó o ti ń lọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà.—Róòmù 1:12.
5 Ǹjẹ́ kí ẹ̀kọ́ tá a fẹ́ kọ́ nínú ìwé Ọjọ́ Jèhófà yìí múra wa sílẹ̀ ká bàa lè “dúró” dé ọjọ́ “amúnikún-fún-ẹ̀rù” náà, ìyẹn ọjọ́ Jèhófà. Ọjọ́ náà sì ti dé tán!—Jóẹ́lì 2:11.