ÌSỌ̀RÍ 2
Mọ Jèhófà Kó O Sì Máa Sìn Ín
Kí ló wà nínú ìwé àwọn wòlíì méjìlá wọ̀nyí tó máa mú ká fẹ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà? Kí nìdí tí iṣẹ́ tí Jèhófà fi rán àwọn wòlíì náà fi wúlò gan-an lónìí? Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Orí Ìkẹrin sí Ìkeje nínú ìwé yìí, wàá rí bó ṣe yẹ kó o máa jọ́sìn Ọlọ́run àti bó o ṣe lè fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Bí àpẹẹrẹ, wàá mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ rẹ nínú ọ̀nà tó o gbà ń bá àwọn ẹlòmíràn lò. Dájúdájú, wàá rí i pé àwọn ìwé méjìlá tí wọ́n jẹ́ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí lè mú kí ìgbésí ayé rẹ dára sí i.