ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/1 ojú ìwé 4-7
  • ‘A Kọ Wọ́n Láti Tọ́ Wa Sọ́nà’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘A Kọ Wọ́n Láti Tọ́ Wa Sọ́nà’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rọ̀ Nípa Ẹni Tó Ni Bíbélì
  • Ṣé Nǹkan Mìíràn Ti Rọ́pò Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù Ni?
  • Ìmọ̀ràn Nípa Bó Ṣe Yẹ Kéèyàn Máa Gbé Ìgbésí Ayé Rẹ̀
  • Bíbélì Jẹ́ Ká Nírètí Pé Ọ̀la Á Dára
  • Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Májẹ̀mú Láéláé Gbọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • “Ìwé Májẹ̀mú Láéláé” Tàbí “Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu”—Èwo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Kí Ni Bíbélì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Orukọ Ọlọrun ati “Majẹmu Titun” Naa
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/1 ojú ìwé 4-7

‘A Kọ Wọ́n Láti Tọ́ Wa Sọ́nà’

“NÍNÚ ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí.” (Oníwàásù 12:12) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé táwọn èèyàn ń tẹ̀ jáde lóde òní ti mú kí ọ̀rọ̀ yẹn jóòótọ́ lónìí gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà tí wọ́n kọ ọ́. Báwo wá ni òǹkàwé kan tó jẹ́ ọlọgbọ́n ṣe lè mọ ìwé tó dára láti kà?

Nígbà táwọn òǹkàwé bá ń ronú nípa bóyá káwọn ka ìwé kan tàbí káwọn má kà á, ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń fẹ́ mọ nǹkan kan nípa ẹni tó kọ ìwé náà. Àwọn òǹṣèwé lè fi ìpínrọ̀ kékeré kan kún ìwé náà tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìlú tí òǹkọ̀wé náà ti wá, bó ṣe kàwé tó, àtàwọn ìwé mìíràn tó ti ṣe jáde. Ó ṣe pàtàkì gan-an láti mọ ẹni tó kọ ìwé kan. Láwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá sẹ́yìn, àwọn obìnrin tó máa ń kọ̀wé nígbà yẹn sábà máa ń fi orúkọ ọkùnrin bojú káwọn tó máa ka ìwé náà má bàá sọ pé kì í ṣe ojúlówó ìwé nítorí pé obìnrin ló kọ ọ́.

Ó bani nínú jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, àwọn kan fojú di Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nítorí pé wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run tí wọ́n sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀ jẹ́ òǹrorò, tó máa ń pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run láìfi àánú hàn sí wọn rárá.a Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ fún wa nípa Ẹni tó ni Bíbélì.

Ọ̀rọ̀ Nípa Ẹni Tó Ni Bíbélì

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ, Ọlọ́run sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì kọ̀wé nípa Ọlọ́run pé: “Kò sì sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:17) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí táwọn kan fi rò pé Ọlọ́run tí wọ́n sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù yàtọ̀ sí Ọlọ́run ti inú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì?

Ìdáhùn rẹ̀ ni pé, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni onírúurú ànímọ́ Ọlọ́run ti fara hàn nínú Bíbélì. Nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì nìkan ṣoṣo, a sọ pé nǹkan máa ń “dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀,” a tún sọ pé òun ni “Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,” ó sì tún jẹ́ “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:6; 14:22; 18:25) Ṣé Ọlọ́run kan náà làwọn àpèjúwe tó yàtọ̀ síra yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni.

Bí àpẹẹrẹ, adájọ́ kan lè jẹ́ ẹni táwọn tó ti wá jẹ́jọ́ níwájú rẹ̀ nílé ẹjọ́ mọ̀ sẹ́ni tí kò gba gbẹ̀rẹ́, tó jẹ́ pé ohun tí òfin bá wí ló máa ń ṣe. Àmọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní tiwọn lè mọ̀ ọ́n sí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ tó sì jẹ́ ọ̀làwọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lè rí i pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ tó sì máa ń pani lẹ́rìn-ín ni. Ẹnì kan náà tó jẹ́ adájọ́ yìí náà ni bàbá, òun náà ló sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn kan. Ó kàn jẹ́ pé ohun tó bá ń ṣe lákòókò kan ló ń fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn.

Lọ́nà kan náà, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” Síbẹ̀, ó tún sọ fún wa pé “lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Àwọn nǹkan méjèèjì yẹn gbé ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run yọ. Ohun tí “Jèhófà” túmọ̀ sí ni “Alèwílèṣe.” Ìyẹn ni pé Ọlọ́run lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá yẹ ní ṣíṣe kó lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Ẹ́kísódù 3:13-15) Síbẹ̀ Ọlọ́run kan náà la ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Jésù sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ Jèhófà kan ṣoṣo.”—Máàkù 12:29.

Ṣé Nǹkan Mìíràn Ti Rọ́pò Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù Ni?

Àṣà tó wọ́pọ̀ lónìí ni kí wọ́n fi ìwé mìíràn rọ́pò ìwé táwọn èèyàn ń lò nílé ẹ̀kọ́ nígbà táwọn ìwádìí tuntun bá yọjú tàbí nígbà tí èrò táwọn èèyàn ní nípa ohun kan bá yí padà. Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti rọ́pò Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni? Rárá o.

Tó bá jẹ́ pé Jésù fẹ́ kí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àtàwọn ohun mìíràn táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kọ sílẹ̀ rọ́pò Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni, ó dájú pé ì bá ti sọ fáwọn èèyàn. Ohun tí àkọsílẹ̀ Lúùkù sọ nípa Jésù kó tó di pé ó lọ sọ́run ni pé: “Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì [inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù], ó túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹ mọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún [méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀].” Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù tún fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tí wọ́n jólóòótọ́ àtàwọn mìíràn. Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Wàyí o, ó wí fún wọn pé: ‘Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ mi tí mo sọ fún yín nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú yín, pé gbogbo ohun tí a kọ̀wé rẹ̀ nípa mi nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì àti àwọn Sáàmù ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ.’” (Lúùkù 24:27, 44) Tó bá jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kò bágbà mu mọ́, ǹjẹ́ Jésù á tún fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ nígbà tó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

Lẹ́yìn tí ìjọ Kristẹni fìdí múlẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì ń lo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí kò tíì nímùúṣẹ àtàwọn ìlànà tó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì látinú Òfin Mósè, wọ́n tún lò ó láti ṣàlàyé ìtàn àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé ìgbàanì tí àpẹẹrẹ rere wọn ń fún àwọn Kristẹni níṣìírí láti máa bá ìṣòtítọ́ wọn nìṣó. (Ìṣe 2:16-21; 1 Kọ́ríńtì 9:9, 10; Hébérù 11:1–12:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.”b (2 Tímótì 3:16) Báwo ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣe ń ṣàǹfààní lóde òní?

Ìmọ̀ràn Nípa Bó Ṣe Yẹ Kéèyàn Máa Gbé Ìgbésí Ayé Rẹ̀

Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó wà lóde òní. Ní ìlú kan ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù, ọkùnrin ará Etiópíà kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún sọ pé: “Ibikíbi tá a bá ń lọ, a máa ń rí i pé àwa bíi mélòó kan la jọ máa ń lọ. Bóyá tá a bá pọ̀, wọn ò ní kọjú ìjà sí wa.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “A ò lè jáde lẹ́yìn aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́, àgàgà láwọn ibùdókọ̀ abẹ́lẹ̀. Báwọn èèyàn bá ṣe wò wá báyìí, àwọ̀ wa ni wọ́n máa ń rí.” Ǹjẹ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ ohunkóhun nípa ìṣòro tó lágbára yìí?

Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì pé: “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àtìpó kan ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ yín, ẹ kò gbọ́dọ̀ fojú rẹ̀ gbolẹ̀. Kí àtìpó tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín dà bí ọmọ ìbílẹ̀ yín; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ, nítorí ẹ di àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì.” (Léfítíkù 19:33, 34) Láìsí àní-àní, òfin yẹn sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un máa gba ti àwọn tó jẹ́ àjèjì tàbí “àtìpó” rò, òfin náà sì wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Ǹjẹ́ o kò gbà pé àwọn ìlànà tó wà nínú òfin yẹn lè yanjú ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lóde òní?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa náwó, síbẹ̀ ó ní àwọn ìlànà tó wúlò gan-an nípa béèyàn ṣe lè fọgbọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ owó. Bí àpẹẹrẹ, ohun tá a kà nínú Òwe 22:7 ni pé: “Ayá-nǹkan . . . ni ìránṣẹ́ awínni.” Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbani nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ owó ló gbà pé tẹ́nì kan bá ń ra nǹkan àwìn láìronú, ìyẹn lè sọ onítọ̀hún di ẹdun arinlẹ̀.

Láfikún sí i, Sólómọ́nì Ọba tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó tíì lówó jù lọ láyé, sọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá ń lépa ọrọ̀ lójú méjèèjì, èyí tó wọ́pọ̀ gan-an láyé táwọn èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ yìí. Ó kọ̀wé pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá. Asán ni èyí pẹ̀lú.” (Oníwàásù 5:10) Ẹ ò rí i pé ìkìlọ̀ yẹn mọ́gbọ́n dání gan-an!

Bíbélì Jẹ́ Ká Nírètí Pé Ọ̀la Á Dára

Ẹṣin ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ni Bíbélì ní látòkè délẹ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ náà ni pé: Ìjọba tí Jésù ń ṣàkóso ni Ọlọ́run máa lò láti fi hàn pé òun lóun lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run, ìjọba náà ló sì máa lò láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.—Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 11:15.

Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa rí nínú Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn sì jẹ́ ìtùnú fún wa, ó tún jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Orísun ìtùnú náà. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àlàáfíà máa wà láàárín àwọn ẹranko àtàwọn èèyàn. Ó ní: “Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n.” (Aísáyà 11:6-8) Ohun àgbàyanu tó yẹ kéèyàn máa retí mà nìyí o!

Àwọn tó dojú kọ ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àtàwọn tó ń ṣàìsàn líle, tàbí àwọn tó níṣòro ìṣúnná owó ńkọ́? Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Kristi Jésù, ó ní: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.” (Sáàmù 72:12, 13) Àwọn ìlérí wọ̀nyí dára gan-an nítorí pé wọ́n mú káwọn tó gbà gbọ́ pé wọ́n á nímùúṣẹ gbà pé ọ̀la á dára, ìyẹn sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.—Hébérù 11:6.

Abájọ tí Ọlọ́run fi mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí”! (Róòmù 15:4) Ó dájú pé Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣì jẹ́ apá pàtàkì lára Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, ìyẹn Bíbélì. Wọ́n wúlò fún wa gan-an lóde òní. A nírètí pé wàá sapá láti túbọ̀ mọ̀ nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni látòkè délẹ̀, wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, ìyẹn Ẹni tó ni Bíbélì.—Sáàmù 119:111, 112.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a pe Májẹ̀mú Láéláé ní Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (Wo àpótí náà, “Ṣé Májẹ̀mú Láéláé Ni àbí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?” ní ojú ìwé 6.) Lọ́nà kan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pe Májẹ̀mú Tuntun ní Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

b Ọ̀pọ̀ ìlànà tó wúlò gan-an lóde òní wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká mọ̀ pé àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

ṢÉ MÁJẸ̀MÚ LÁÉLÁÉ NI ÀBÍ ÌWÉ MÍMỌ́ LÉDÈ HÉBÉRÙ?

Gbólóhùn náà “májẹ̀mú láéláé” wà nínú 2 Kọ́ríńtì 3:14. Níbí yìí, “májẹ̀mú” dúró fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà di·a·theʹke. Àmọ́, kí wá ni “májẹ̀mú láéláé” túmọ̀ sí?

Atúmọ̀ èdè kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edward Robinson sọ pé: “Níwọ̀n bí májẹ̀mú ayé ọjọ́un ti wà nínú àwọn ìwé tí Mósè kọ, ohun tí [di·a·theʹke] dúró fún ni àwọn ìwé májẹ̀mú tàbí àwọn ìwé tí Mósè kọ, ìyẹn òfin.” Òfin Mósè, tó jẹ́ apá kan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti wà ṣáájú àkókò Kristẹni, ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú 2 Kọ́ríńtì 3:14.

Kí wá ló yẹ ká máa pe àwọn ìwé mọ́kàndínlógójì àkọ́kọ́ nínú Bíbélì Mímọ́? Dípò tí Jésù Kristi àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ á fi sọ pé apá tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì yìí kò bóde mu mọ́ tàbí pé ó ti di ògbólógbòó, ohun tí wọ́n pè é ni: “Ìwé Mímọ́.” (Mátíù 21:42; Róòmù 1:2) Nítorí ìdí yìí, níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pe Májẹ̀mú Láéláé ní Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, nítorí pé èdè Hébérù nìkan ni wọ́n fi kọ apá yẹn nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bákan náà, a máa ń pe apá táwọn kan ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun nínú Bíbélì ní Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì, nítorí pé èdè Gíríìkì làwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run mí sí láti kọ apá yìí nínú Bíbélì fi kọ ọ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

A lè mọ ọkùnrin kan sí adájọ́ tí kò gba gbẹ̀rẹ́, ká tún mọ̀ ọ́n sí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, kó sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn èèyàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni Jésù lò ní gbogbo àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́