“Ìwé Májẹ̀mú Láéláé” Tàbí “Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu”—Èwo?
LÓNÌÍ ó jẹ́ àṣà tí ó wọ́pọ̀ ní Kristẹndọm láti lo èdè náà “Ìwé Májẹ̀mú Láéláé” àti “Májẹ̀mú Titun” láti ṣàpèjúwe àwọn apá Bibeli tí a kọ lédè Heberu-òun-Aramaiki àti Griki. Ṣùgbọ́n idi èyíkéyìí tí a gbékarí Bibeli ha wà fún lílo àwọn èdè wọ̀nyí bí? Fún ìdí wo sì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lápapọ̀ fi ń yẹra fún lílò wọ́n nínú àwọn ìtẹ̀jáde wọn?
Lótìítọ́, 2 Korinti 3:14, ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli King James Version àti àwọn ìtumọ̀ ògbólógbòó mìíràn, bíi Septembertestament lédè German, ìtumọ̀ tí Martin Luther kọ́kọ́ ṣe (1522), lè dàbí èyí tí ó ti àṣà yìí lẹ́yìn. Nínú Bibeli King James Version [lédè Gẹ̀ẹ́sì], ẹsẹ yìí kà pé: “Ṣùgbọ́n ojú-inú wọn fọ́: nítorí pé títí fi di òní olónìí ní kíka ìwé májẹ̀mú láéláé, ìbòjú náà wà láìká sókè; ìbòjú tí a ti mú kúrò nínú Kristi.”
Bí ó ti wù kí ó rí, aposteli náà ha ń sọ̀rọ̀ níhìn-ín nípa àwọn ìwé 39 tí a sábà máa ń pè ní “Ìwé Májẹ̀mú Láéláé”? Ọ̀rọ̀ Griki tí a túmọ̀ sí “májẹ̀mú” níhìn-ín ni di·a·theʹke. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ gbígbajúmọ̀ lórí ẹ̀kọ́-ìsìn lédè German Theologische Realenzyklopädie, ń sọ̀rọ̀ lórí 2 Korinti 3:14, ó sọ pé bákan náà gẹ́lẹ́ ni ‘kíka di·a·theʹke láéláé’ àti ‘kíka Mose’ nínú ẹsẹ tí ó tẹ̀lé e ṣe rí. Nítorí náà, ó sọ pé, ‘di·a·theʹke láéláé’ dúró fún Òfin Mose, tàbí ó pọ̀ tán, àwọn Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ ti Mose. Ó dájú pé kò dúró fún àpapọ̀ Ìwé Mímọ́ tí a mísí tí ó ti wà ṣáájú sànmánì Kristian.
Aposteli náà ń tọ́ka sí kìkì apákan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, májẹ̀mú Òfin ti láéláé, èyí tí Mose kọ sílẹ̀ nínú Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ ti Mose; òun kò tọ́ka sí gbogbo Ìwé Mímọ́ lédè Heberu àti Aramaiki. Síwájú síi, òun kò ní i lọ́kàn pé àwọn ìwé Kristian tí a mísí ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E. papọ̀ jẹ́ “ìwé májẹ̀mú titun,” níwọ̀n bí èdè yìí kò ti farahàn ní ibikíbi nínú Bibeli.
Ó tún yẹ kí a kíyèsí i pé ọ̀rọ̀ Griki náà di·a·theʹke tí Paulu lò níhìn-ín níti gidi túmọ̀ sí “májẹ̀mú.” (Fún ìsọfúnni síwájú síi wo Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures—With References, Àsomọ́ 7E, ojú-ìwé 1585, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., 1984.) Nítorí náà ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ òde-òní kà lọ́nà tí ó tọ̀nà pé “májẹ̀mú láéláé” dípò “ìwé májẹ̀mú láéláé.”
Lórí ọ̀ràn yìí, ìwé ìròyìn “National Catholic Reporter” sọ pé: “Lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, èdè náà ‘Májẹ̀mú Láéláé’ múni ní ojú-ìwòye àìlọ́lá tó tàbí àìbágbàmu.” Ṣùgbọ́n Bibeli níti tòótọ́ jẹ́ àpapọ̀ odidi iṣẹ́, kò sì sí apákan tí kò bá ìgbà mu, tàbí tí ó jẹ́ ti “láéláé.” Ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ ṣọ̀kan délẹ̀ láti inú ìwé àkọ́kọ́ nínú apá tí a kọ lédè Heberu títí dé ìwé tí ó kẹ́yìn nínú apá tí a kọ lédè Griki. (Romu 15:4; 2 Timoteu 3:16, 17) Nítorí náà a ní ìdí tí ó fìdímúlẹ̀ láti yẹra fún àwọn èdè wọ̀nyí tí a gbé karí àbá ìméfò tí kò tọ̀nà, a sì yàn láti lo èdè tí ó tọ̀nà jùlọ náà “Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu” àti “Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki.”