Ǹjẹ́ “Májẹ̀mú Láéláé” Ṣì Wúlò?
LỌ́DÚN 1786, oníṣègùn kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé tẹ ìwé kan jáde tó sọ nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹ̀yà ara àti ìṣesí àwọn ohun alààyè, ó sì pe orúkọ ìwé náà ní A Discussion of Anatomy and Physiology. Ìwé náà ni wọ́n kà sí èyí tó péye jù lọ nínú àwọn ìwé tó sọ nípa ẹ̀yà ara èèyàn lákòókò yẹn. Kódà, wọ́n ta ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà díẹ̀ tó ṣẹ́ kù lára ìwé náà níye tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n dọ́là lẹ́nu àìpẹ́ yìí! Síbẹ̀, bóyá la fi rí àwọn aláìsàn tó máa jẹ́ kí oníṣẹ́-abẹ tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ inú ìwé tó ti pẹ́ gan-an yìí ṣiṣẹ́ abẹ fáwọn lóde òní. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn àtohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yẹn kò lè jẹ́ kó fi bẹ́ẹ̀ wúlò fẹ́ni tó ń ṣàìsàn lóde òní.
Irú èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa ìwé tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé nìyẹn. Wọ́n fẹ́ràn ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nínú rẹ̀, ewì alárinrin tó wà níbẹ̀ sì máa ń wù wọ́n. Síbẹ̀, wọn ò gbà pé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tó ti wà lákọsílẹ̀ láti ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé irínwó [2,400] ọdún sẹ́yìn. Ìdí ni pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, kódà bí ọ̀rọ̀ ìdílé ṣe rí lóde òní, yàtọ̀ pátápátá sí bí nǹkan ṣe rí lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì. Ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Philip Yancey, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn Christianity Today, kọ sínú ìwé rẹ̀ kan tó pe orúkọ rẹ̀ ní The Bible Jesus Read ni pé: “Kì í ṣe gbogbo ìgbà lohun tó wà nínú Májẹ̀mú Láéláé bọ́gbọ́n mu, àpá tó bá sì dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu níbẹ̀ máa ń bí àwọn èèyàn nínú lóde òní. Nítorí ìdí yìí àtàwọn ìdí mìíràn, àwọn èèyàn kì í sábà ka Májẹ̀mú Láéláé tó jẹ́ pé òun ló kó ìdá mẹ́ta tá a bá pín Bíbélì sọ́nà mẹ́rin.” Irú èrò yẹn kì í ṣe ohun tuntun.
Nígbà tó kù díẹ̀ kí àádọ́ta ọdún pé lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù kú ní nǹkan bí ọdún 100 Sànmánì Kristẹni, ọ̀dọ́kùnrin kan tó lówó gan-an tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Marcion sọ fáwọn èèyàn pé kò yẹ káwọn Kristẹni máa ka Májẹ̀mú Láéláé. Òpìtàn kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Robin Lane Fox, sọ pé Marcion ṣàlàyé pé, “‘Ọlọ́run’ tó wà nínú Májẹ̀mú Láéláé jẹ́ ‘òǹrorò’ tó ń ṣojú rere sáwọn arúfin àtàwọn akópayàbáni bíi Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì. Àmọ́, Kristi jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run kan tó dára jùyẹn lọ fíìfíì tó sì yàtọ̀ pátápátá sí Ọlọ́run inú Májẹ̀mú Láéláé.” Ọ̀gbẹ́ni Fox kọ̀wé pé ohun tó jẹ́ èrò rẹ̀ yìí “wá di ohun tí wọ́n ń pè ní ‘ìgbàgbọ́ Marcion,’ àwọn kan sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àgàgà láwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Síríákì ní apá Ìlà Oòrùn ayé. Èyí sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí fi dìgbà tó kù díẹ̀ kí ọ̀rúndún kẹrin parí.” Àwọn kan tiẹ̀ ṣì fara mọ́ èròǹgbà rẹ̀ yìí dòní olónìí. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀gbẹ́ni Philip Yancey fi kọ̀wé ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn pé, “ìmọ̀ nípa Májẹ̀mú Láéláé ń pòórá kíákíá láàárín àwọn Kristẹni, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ohun táwọn èèyàn ò mọ̀ nípa rẹ̀ mọ́ lóde òní.”
Ṣé Májẹ̀mú Tuntun ti wá rọ́pò Májẹ̀mú Láéláé ni? Báwo la ṣe lè gbà pé ẹni tí Bíbélì pè ní “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” nínú Májẹ̀mú Láéláé ló tún pè ní “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà” nínú Májẹ̀mú Tuntun? (Aísáyà 13:13; 2 Kọ́ríńtì 13:11) Ǹjẹ́ Májẹ̀mú Láéláé lè ṣe ọ́ láǹfààní lóde òní?