ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 6/8 ojú ìwé 18-19
  • Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Yí Padà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Yí Padà?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Ipò Nǹkan Bá Ṣe Rí Ni Jèhófà Ṣe Ń Gbà Bójú Tó Wọn
  • Àwọn Ànímọ́ Rẹ̀ Kì Í Yí Padà
  • “Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí!”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ta Ni Ọlọrun Tòótọ́ Náà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ǹjẹ́ “Májẹ̀mú Láéláé” Ṣì Wúlò?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Máa Fi “Ìwà Tuntun” Wọ Ara Rẹ Láṣọ Lẹ́yìn Tó O Ti Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 6/8 ojú ìwé 18-19

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Yí Padà?

ONÍMỌ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, George Dorsey ṣàpèjúwe Ọlọ́run “Májẹ̀mú Láéláé” gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run tó rorò.” Ó fi kún un pé: “Yahweh ò . . . nífẹ̀ẹ́ rárá. Ọlọ́run àwọn onísùnmọ̀mí ni, ti àwọn adánilóró, ti àwọn jagunjagun, ti ìṣẹ́gunṣẹ́tẹ̀ ni.” Àwọn mìíràn ti ronú bẹ́ẹ̀ nípa Yahweh, tàbí Jèhófà —Ọlọ́run “Májẹ̀mú Láéláé.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn kan ń ṣe kàyéfì lónìí pé bóyá ni kò ní jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run kan tó rorò tó wá ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ìwà ẹ̀ padà tó fi wá di Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú ti inú “Májẹ̀mú Tuntun.”

Irú èrò báyìí nípa Ọlọ́run Bíbélì kì í ṣe tuntun. Marcion ló kọ́kọ́ sọ irú èrò yẹn jáde, ẹni tó jẹ́ pé díẹ̀ nìgbàgbọ́ ẹ̀ fi yàtọ̀ sí tàwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ti ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa. Marcion kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba Ọlọ́run “Májẹ̀mú Láéláé.” Èrò rẹ̀ nípa Ọlọ́run yẹn ni pé ó jẹ́ oníwà ipá àti ẹlẹ́mìí ìgbẹ̀san, òǹrorò kan tó ń fi ẹ̀bùn fún àwọn tó ń sìn ín. Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, Marcion ṣàpèjúwe Ọlọ́run “Májẹ̀mú Tuntun”—bí a ti fi han nípasẹ̀ Jésù Kristi—gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípé, Ọlọ́run tó ní ògidì ìfẹ́ àti àánú, olóore ọ̀fẹ́ àti olùdáríjini.

Bí Àwọn Ipò Nǹkan Bá Ṣe Rí Ni Jèhófà Ṣe Ń Gbà Bójú Tó Wọn

Orúkọ Ọlọ́run gangan, Jèhófà, túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Èyí já sí pé Jèhófà ń sọ ara rẹ̀ di Olùmú gbogbo àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tí Mósè bi Ọlọ́run léèrè orúkọ rẹ̀, Jèhófà ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Ọ̀nà tí ìtumọ̀ Rotherham gbà sọ ọ́ nìyí: “Èmi Yóò Di ohunkóhun tí ó bá wù mí.”

Nítorí náà, Jèhófà ń yàn láti jẹ́, tàbí ń já sí, ohunkóhun tó bá yẹ láti mú àwọn ète àti ìlérí òdodo rẹ̀ ṣẹ. Ẹ̀rí kan tó wà nípa èyí ni òtítọ́ náà pé ó ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orúkọ oyè àti àwọn ọ̀rọ̀ àpèjúwe bíi: Jèhófà àwọn ọmọ ogun, Onídàájọ́, Ọba Aláṣẹ, Owú, Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹlẹ́dàá, Bàbá, Atóbilọ́lá Olùkọ́ni, Olùṣọ́ Àgùntàn, Olùgbọ́ àdúrà, Olùtúnnirà, Ọlọ́run aláyọ̀, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Ó ti yàn láti di gbogbo ìwọ̀nyí—àti púpọ̀ púpọ̀ sí i—kí ó bàa lè mú àwọn ète onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Ẹ́kísódù 34:14; Àwọn Onídàájọ́ 11:27; Sáàmù 23:1; 65:2; 73:28; 89:26; Aísáyà 8:13; 30:20; 40:28; 41:14; 1 Tímótì 1:11.

Nígbà náà, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àkópọ̀ ìwà tàbí àwọn ìlànà Ọlọ́run máa ń yí padà ni? Rárá o. Jákọ́bù 1:17 sọ nípa Ọlọ́run pé: “Kò sì sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè mójú tó ìpèníjà àwọn àyíká ipò yíyàtọ̀ síra nígbà tó jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ kì í yí padà?

Àpẹẹrẹ àwọn òbí tó bìkítà, tí wọ́n ń yíwọ́ padà nínú àwọn ipa iṣẹ́ wọn ní tìtorí àwọn ọmọ wọn ṣàpèjúwe bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀. Látàárọ̀ ọjọ́ kan ṣúlẹ̀, òbí kan lè jẹ́ agbọ́únjẹ, olùtọ́jú ilé, atúnnáṣe, olùtọ́jú aláìsàn, ọ̀rẹ́, olùgbani-nímọ̀ràn, olùkọ́, olùfúnni-níbàáwí, àti púpọ̀ sí i. Òbí náà kì í yí àkópọ̀ ìwà rẹ̀ padà nígbà tó bá ń bójú tó àwọn ipa iṣẹ́ wọ̀nyí; ó wulẹ̀ máa ń yíwọ́ padà láti mú ara rẹ̀ bá àwọn ipò àìní tó ń dìde mu ni. Bó ti rí nínú ọ̀ràn Jèhófà náà nìyẹn ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n kan tó gbòòrò gan-an. Kò sí ìdiwọ̀n fún ohun tó lè sọ ara rẹ̀ dà kí ó bàa lè mú ète rẹ̀ ṣẹ àti nítorí ti àwọn ẹ̀dá rẹ̀.—Róòmù 11:33.

Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà ni a fi hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pé ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti àánú. Wòlíì Míkà tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa béèrè nípa Jèhófà pé: “Ta ni Ọlọ́run bí ìwọ, ẹni tí ń dárí ìrélànàkọjá jì, tí ó sì ń ré ìṣìnà àṣẹ́kù ogún rẹ̀ kọjá? Dájúdájú, òun kì yóò máa bá a lọ nínú ìbínú rẹ̀ títí láé, nítorí ó ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Míkà 7:18) Bákan náà, àpọ́sítélì Jòhánù kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí a mọ̀ bí ẹní mowó náà: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.

Ní ìdàkejì, nínú apá Bíbélì méjèèjì, Jèhófà ni a fi hàn gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ òdodo fún àwọn aláìronúpìwàdà tí ń dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo tí wọ́n sì ń rú àwọn òfin rẹ̀ lemọ́lemọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ẹlòmíràn lára. Onísáàmù wí pé: “Gbogbo ẹni burúkú ni [Jèhófà] yóò pa rẹ́ ráúráú.” (Sáàmù 145:20) Bákan náà, Jòhánù 3:36 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.”

Àwọn Ànímọ́ Rẹ̀ Kì Í Yí Padà

Àkópọ̀ ìwà Jèhófà àti àwọn ànímọ́ rẹ̀ ṣíṣeyebíye—ìfẹ́, ọgbọ́n, àìṣègbè, àti agbára—kò tíì yí padà. Ó sọ fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Èyí jẹ́ nǹkan bí egbèjìdínlógún dín ọgọ́rùn-ún ọdún [3,500] lẹ́yìn ti Ọlọ́run ti ṣẹ̀dá ènìyàn. Ká sọ tòótọ́ nípa ọ̀rọ̀ àtọ̀runwá yẹn, ṣíṣàyẹ̀wò odindi Bíbélì kínníkínní fi Ọlọ́run kan tí kì í yí padà nínú àwọn ìlànà àti àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn. Àkópọ̀ ìwà Jèhófà Ọlọ́run kò yingin ní àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá, nítorí pé kò ní wúlò tí ó bá yingin.

Àìgbagbẹ̀rẹ́ Ọlọ́run ní ti ọ̀ràn òdodo ṣíṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn gbangba jálẹ̀ inú Bíbélì, kò túmọ̀ sí pé ìfẹ́ rẹ̀ dín kù tàbí pé ó pọ̀ sí i ju bó ti rí nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹ̀dá ènìyàn lò ní Édẹ́nì. Ní tòótọ́, àwọn ìyàtọ̀ nínú àkópọ̀ ìwà rẹ̀ tó fara hàn ní àwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì wulẹ̀ jẹ́ apá yíyàtọ̀ kan nínú àkópọ̀ ìwà rẹ̀ tí kì í yí padà. Ohun tó ń fa ìwọ̀nyí ni àwọn ipò yíyàtọ̀ àti àwọn ènìyàn tó bá ń bá lò, èyí tó ń béèrè fún ìṣarasíhùwà tàbí bíbá wọn lò lọ́nà tó yàtọ̀ síra.

Nítorí náà, Ìwé Mímọ́ mú kí ó ṣe kedere pé àkópọ̀ ìwà Ọlọ́run kò yí padà ní gbogbo ọ̀rúndún tó ti kọjá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní yí padà lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà ni àpẹẹrẹ gíga ju lọ tí a bá ń sọ nípa ìṣedéédéé àti ìṣọ̀kandélẹ̀. Ó jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé, tó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé nígbà gbogbo. A lè gbíyè lé e títí láé.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Ọlọ́run kan náà tó pa Sódómù àti Gòmórà run . . .

. . . yóò mú ayé tuntun òdodo kan wá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́