ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/8 ojú ìwé 16-19
  • Matterhorn Òkè Ńlá Aláìlẹ́gbẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Matterhorn Òkè Ńlá Aláìlẹ́gbẹ́
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Tẹ Ibẹ̀ Dó
  • Ọkàn-Ìfẹ́ Tí Ń Pọ̀ Sí I fún Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Nípa Ìṣẹ̀dá
  • Wọ́n Ṣẹ́gun Òkè Ńlá Matterhorn!
  • Iye Giga Gan-an
  • Àwọn Ewu Rẹ̀
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Kilima—Njaro Ibi Gíga Jù Lọ ní Áfíríkà
    Jí!—1997
  • Àwọn Òkè Ńlá ti Òṣùpá
    Jí!—1998
  • Òkè Tí Ń “Rìn”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Jí!—1996
g96 2/8 ojú ìwé 16-19

Matterhorn Òkè Ńlá Aláìlẹ́gbẹ́

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SWITZERLAND

“ÒKÈ ńlá Matterhorn KAN ṣoṣo ni ó wà ní gbogbo àgbáyé; òkè ńlá KAN ṣoṣo tí ìwọ̀n rẹ̀ wà déédéé bẹ́ẹ̀. Ìran àgbàyanu gbáà ni!” Ohun tí pọ́nkèpọ́nkè ará Itali náà, Guido Rey, sọ nìyẹn.

Ní tòótọ́, òkè ńlá Matterhorn ga fíofío gan-an, ọ̀kan lára àwọn òkè ńlá tí a mọ̀ jù lọ lágbàáyé. Bóyá fọ́tò tí ó wà ní ojú ewé tí ó dojú kọ èyí kì í ṣe fọ́tò òkè agbàfiyèsí yìí tí ìwọ yóò kọ́kọ́ rí.

Òkè ńlá Matterhorn tí ó jọ òkìtì aboríṣóńṣó yìí wà ní ààlà ilẹ̀ Itali àti Switzerland, ní kìlómítà mẹ́wàá sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn abúlé Zermatt, Switzerland, ìlú tí a fi orúkọ rẹ̀ pe òkè náà. Ó ga ní mítà 4,478, ó sì ní orí ṣóńṣó méjì tí ó fi nǹkan bí 100 mítà jìnnà síra.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó jẹ́ apá kan Àárín Gbùngbùn Òkè Ńlá Alps, òkè ńlá Matterhorn dá dúró gedegbe ni, láìsí alámùúlégbè tí ó sún mọ́ ọ́n. Èyí ló ṣokùnfà ìrísí dídára tí òkè ńlá yìí ní láti ìhà gbogbo, ó sì mú kí fọ́tò rẹ̀ jojú ní gbèsè.

Àwọn kan ti ṣàpèjúwe òkè ńlá Matterhorn lọ́nà tí ó bá a mu bí èyí tí ó ní ìrísí ọwọ̀n aboríṣóńṣó onígun mẹ́rin. Ó yọ igun mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, orí ṣóńṣó kọ̀ọ̀kan sì ya igun kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ gedegbe.

Láìka bí òkè ńlá Matterhorn ṣe ga tó sí, òjò dídì kì í sábà bò ó. Ní apá ìparí ìgbà ìrúwé, ìlọ́wọ́ọ́wọ́ oòrùn máa ń yọ́ òjò dídì àti yìnyín tí ó wà lára àwọn àpáta ara rẹ̀ gíga fíofífo tí ó wà ní apá òkè. Ní ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún, àwọn ìṣàn òkìtì yìnyín ní ìhà ìlà oòrùn àti àríwá ìwọ̀ oòrùn máa ń lẹ̀ mọ́ ara òkè ńlá náà bí àmùrè funfun ní ìbàdí rẹ̀ jálẹ̀ ọdún.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn olólùfẹ́ òkè ńlá aláìláfiwé yìí ti ṣe kàyéfì nípa bí ó ṣe pilẹ̀ṣẹ̀. Kò sí òkìtì àwọn òkúta nídìí rẹ̀ tí a lè rí bí àfọ́kù ohun tí ó ti inú rẹ̀ yọ jáde. Èyíkéyìí irú ègé òkúta bẹ́ẹ̀ ní ó ní láti jẹ́ pé wọ́n ti wọ́ lọ láàárín ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí ó ti wà. Ẹ wo irú ipá ìṣẹ̀dá alágbára tí ó ní láti pa kún ìran rírẹwà yìí!

Àwọn Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Tẹ Ibẹ̀ Dó

Àwọn ènìyàn ti ń gbé àárín àfonífojì òkè tí ó lọ sí ìdí òkè ńlá Matterhorn láti ìgbà tí Ilẹ̀ Ọba Romu ti wà. Ìtàn ròyìn pé, ní ọdún 100 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ọ̀gágun Romu náà, Marius, la Ọ̀nà Theodul, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn òkè ǹlá Matterhorn, tí ó ga ní mítà 3,322, kọjá. Ọ̀nà àárín òkè ńlá yìí ni a tún lò lákòókò Sànmánì Ìtàn Europe fún gbígbé ẹrù láti ìhà gúúsù lọ sí àríwá.

Ní àwọn àkókò yẹn, àwọn olùgbé ibẹ̀ máa ń fi ọ̀wọ̀ ńlá fún òkè ńlá Matterhorn, kódà pẹ̀lú ìbẹ̀rù ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Wọn kò jẹ́ gun òkè ńlá náà tí wọ́n lérò pé Èṣù fúnra rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀! Àbí ta ló tún lè fi yìnyín àti òkìtì òjò dídì àti òkúta tí ó tóbi tó ilé sọ̀kò sílẹ̀?

Ọkàn-Ìfẹ́ Tí Ń Pọ̀ Sí I fún Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Nípa Ìṣẹ̀dá

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ohun tí àwọn onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn wọ̀nyẹn yẹra fún nítorí ìbẹ̀rù wá di ohun tí a kúndùn láwùjọ àwọn sàràkí aláfẹ́ ní England. Ọkàn-ìfẹ́ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, ní mímú kí àwọn awásọfúnnikiri máa gun àwọn òkè ńlá láti ṣèwádìí nínú àwọn pápá ẹ̀kọ́ bí ẹ̀kọ́ nípa ilẹ̀, ìyàwòrán atọ́nà ìrísí ilẹ̀, àti ẹ̀kọ́ nípa ewéko.

Ní tòótọ́, ní 1857, wọ́n dá Ẹgbẹ́ Alpine sílẹ̀ ní London, púpọ̀ àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ Faransé, Itali tàbí Switzerland láti kópa nínú gígun òkè ńlá Alps. Àwọn ọ̀dágbá náà pọ́n ṣóńṣó òkè kan dé òmíràn, títí kan Òkè Ńlá Blanc. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òkè ńlá yìí, tí gíga rẹ̀ jẹ́ 4,807 mítà, ló ga jù lọ ní Europe, kò fún àwọn pọ́nkèpọ́nkè ní ìṣòrò púpọ̀ tó bí òkè ńlá Matterhorn ti fún wọn.

Kì í ṣe gbogbo ìsapá wọ̀nyí ló jẹ́ kìkì nítorí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá. Ìlépa òkìkí wọnú rẹ̀. Òkìkí jíjẹ́ ẹni àkọ́kọ́, ẹni tí ó gbóyà jù lọ, ẹni tí ó ní akíkanjú jù lọ, wá di ohun bàbàrà. Ní àkókò yẹn ní England, ọ̀rọ̀ náà “eré ìdárayá” túmọ̀ sí òkè pípọ́n nìkan.

Ìgbà ẹ̀rùn 1865 jẹ́ ọ̀kan tí òkè pípọ́n ti gba àkókò jù lọ, ní pàtàkì ní ti ọ̀ràn òkè ńlá Matterhorn. Òkìtì aboríṣónṣó yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ṣóńṣó òkè tí a kò tí ì ṣẹ́gun. A kà á sí èyí tí a kò lè dé ibẹ̀, àwọn olùfinimọ̀nà àdúgbò sì tilẹ̀ kọ̀ láti gbìyànjú rẹ̀ pàápàá. Ìṣarasíhùwà wọn ni pé, ‘Àwọ́n lè gun ṣóńṣó òkè ńlá mìíràn—àmọ́ kì í ṣe ti òkè ńlá Horn.’

Bí ó ti wù kí ó rí, a kò lè yẹ ṣíṣẹ́gun òkè ńlá Matterhorn sílẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1860, àwọn ṣóńṣó òkè ńlá bíi mélòó kan ni a ṣẹ́gun. Àwọn pọ́nkèpọ́nkè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí, wọ́n sì gbé àwọn ọgbọ́n ìṣe tuntun kalẹ̀. Nígbà tí Edward Whymper, tí ó wá láti England, pé ẹni 20 ọdún, olùyẹ̀wòṣàtúnṣe kan láti London rán an lọ sí Switzerland láti ya àwòrán ìrísí àwọn òkè ńlá láti lò wọ́n fún àwòrán inú ìwé kan tí ó dá lórí òkè. Àwọn òkè ńlá náà wu Whymper, ó sì wá nífẹ̀ẹ́ òkè pípọ́n. Ó pọ́n òkè púpọ̀ ní ilẹ̀ Faransé àti Switzerland yọrí, ó sì gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti pọ́n òkè ńlá Matterhorn. Ṣùgbọ́n òkè ńlá Horn kò ṣeé gùn.

Wọ́n Ṣẹ́gun Òkè Ńlá Matterhorn!

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ní July 1865, ẹgbẹ́ àwọn pọ́nkèpọ́nkè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pàdé ní Zermatt—ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pinnu láti pọ́n òkè ńlá Matterhorn. Nítorí pé wọ́n ń kánjú nítorí ẹgbẹ́ kan tí ó wá láti Itali, tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣáájú wọn, àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pinnu láti para pọ̀ jẹ́ cordée kan, tàbí ìlà àwọn pọ́nkèpọ́nkè tí a fi okùn kan ṣoṣo so pọ̀. Àwọn ọkùnrin méje ló wà nínú ẹgbẹ́ náà—Edward Whymper àti Ọlọ́lá Francis Douglas, Charles Hudson àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀dọ́ Hadow—tí gbogbo wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—pẹ̀lú àwọn olùfinimọ̀nà méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Switzerland àti ọ̀kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé tí wọ́n rí háyà.

Nígbà tí wọ́n fi Zermatt sílẹ̀ ní òwúrọ̀ July 13, wọn kò kánjú títí wọ́n fi dé ìdí òkè ńlá náà láti ìhà ìlà oòrùn, wọ́n sì rí i pé àwọn apá ìsàlẹ̀ rẹ̀ rọrùn láti gùn. Wọ́n pa àgọ́ wọn sí ibi tí ó ga tó 3,300 mítà, wọ́n sì gbádùn ìyókù ọjọ́ tí oòrùn ràn gan-an náà ní gbẹ̀fẹ́.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, July 14, kí ilẹ̀ tóó mọ́, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ pípọ́nkè. Wọ́n ń lò okùn náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn apá ibì kan ṣòro ju àwọn mìíràn lọ, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń rí ọ̀nà àbáyọ nínú àwọn ìṣòro tí ó le. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi lẹ́ẹ̀mejì, wọ́n dé àpá ibi tí ó le koko jù lọ. Àádọ́rin mítà tí ó kẹ́yìn kún fún òjò dídì, nígbà tí ó di agogo 1:45 ọ̀sán, wọ́n dé orí òkè pátápátá. Wọ́n ṣẹ́gun òkè ńlá Matterhorn!

Kò sí ipa pé ẹ̀dá ènìyàn ti dé orí òkè náà pátápátá rí, ó dájú pé àwọn ni ẹni àkọ́kọ́. Ẹ wo bí ìmọ̀lára wọn yóò ti rí! Fún nǹkan bíi wákàtí kan, ẹgbẹ́ àwọn ajagunmólú yìí gbádùn ìran àrímálèlọ ní ìhà gbogbo, lẹ́yìn náà ni wọ́n múra láti sọ̀ kalẹ̀. Àwọn pọ́nkèpọ́nkè ara Itali tí wọ́n ń gbìyànjú láti pọ́nkè náà ní ọjọ́ yẹn kan náà wà lẹ́yìn gédégédé, wọ́n sì dẹ̀yìn nígbà tí wọ́n rí i pé àwọ́n ti pàdánú ìdíje náà.

Iye Giga Gan-an

Bí ó ti wù kí ó rí, bíborí tí àwọn pọ́nkèpọ́nkè náà borí yóò ná wọn ní iye gíga gan-an. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí ó ṣòrò kan nígbà tí wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀, wọ́n so pọ̀ mọ́ okùn kan náà, olùfinimọ̀nà tí ó nírìírí jù lọ sì wà níwájú. Láìka bí wọ́n ti lo ìṣọ́ra tó sí, olùkópa tí ó kéré jù lọ yọ̀, ó sì já lu ọkùnrin tí ó wà nísàlẹ̀ rẹ̀, ó sì ń wọ́ àwọn tí wọ́n wà lókè. Ìró ariwo mú kí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n gbẹ̀yìn ta gìrì, wọ́n sì gbá àwọn òkúta kan mú. Ṣùgbọ́n okùn náà já, kí wọ́n sì tóó pajú pẹ́ẹ́, àwọn ọkùnrin mẹ́rin àkọ́kọ́ ti pòórá sí ìsàlẹ̀ okè gogoro náà.

Kẹ́kẹ́ pa mọ́ Edward Whymper àti àwọn olùfinimọ̀nà méjì ọmọ ilẹ̀ Switzerland náà lẹ́nu, wọ́n sì wà ní ipò tí ó burú jáì. Wọ́n ní láti pàgọ́ ní alẹ́ náà, wọ́n sì padà sí Zermatt ní ọjọ́ kejì. Nípa bẹ́ẹ̀, ògo ọjọ́ náà yára yí padà di àgbákò tí ó ní ipa ńlá lórí àwọn tí wọ́n là á já jálẹ̀ ìyókù ìgbésí ayé wọn.

Mẹ́ta lára àwọn òkú mẹ́rin náà ni a rí láti inú ìṣàn òkìtì yìnyín tí ó fi 1,200 mítà jìnnà sí ọ̀gangan ibi tí jàm̀bá náà ti ṣẹ́lẹ̀. Òkú ẹnì kẹrin, Ọlọ́lá Douglas, ni a kò rí rárá.

Àwọn wọ̀nyí kọ́ ni olùfarapa tí ó kẹ́yìn lórí àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ orí òkè ńlá Matterhorn. Lójú pé, àwọn pọ́nkèpọ́nkè náà ti so okùn púpọ̀ mọ́ àpáta náà dan-indan-in ní apá ibi púpọ̀ tí wọ́n ń gbà lọ sókè tàbí yíká àwọn òkúta ara rẹ̀ àti àwọn ibi lílà tóóró lára rẹ̀, àti lójú ìrírí púpọ̀ tí wọ́n ti ní àti ohun èèlò ìpọ́nkè wọn tí wọ́n ti mú sunwọ̀n sí i lọ́pọ̀lọpọ̀, nǹkan bí 600 ènìyàn ló ti kú lórí òkè ńlá yìí nìkan ṣoṣo.

Àwọn Ewu Rẹ̀

Ohun kan tí ó pa kún ewu náà lọ́pọ̀lọpọ̀ ni ojú ọjọ́. Ó lè yí padà bàrà. Ọjọ́ kan lè bẹ̀rẹ̀ dáradára, ṣùgbọ́n kí ènìyàn tóó pajú pẹ́ẹ̀, kùrukùru kíki tàbí ojú sánmà dúdú kìjikìji lè ti bo òkìtì aboríṣóńṣó náà, ìjì akóniláyàsókè sì lè bẹ̀rẹ̀. Ìbùyẹ̀rì mànàmáná àti àrá bíbani lẹ́rù sì lè bá èyí rìn, pa pọ̀ pẹ̀lú ìjì líle lójijì, kí ó sì jálẹ̀ sí ìtúdàsílẹ̀ òjò dídì. Gbogbo èyí ní ọjọ́ kan tí ó jẹ́ ìgbà ẹ̀rùn!

Bí ìyípadà ipò bẹ́ẹ̀ bá ká àwọn pọ́nkèpọ́nkè mọ́, ó lè jẹ́ pé gbangba bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sùn mọ́jú, bóyá lórí ibi pẹrẹsẹ kékeré kan tí ó rọra gbà wọ́n dúro. Ojú ọjọ́ lè tutù níní jù. Ọ̀gbun sì wà nísàlẹ̀. Nígbà náà, ẹnì kan lè ronú pé, òun ì bá ti kí òkè ńlá Matterhorn látòkèèrè!

Ewu mìíràn ni àwọn òkúta tí ń já bọ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn pọ́nkèpọ́nkè aláìrònújinlẹ̀ máa ń ṣokùnfa kí òkúta já bọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ, àwọn okùnfà rẹ̀ jẹ́ ti ìṣẹ̀dá. Ìyípadà nínú ìdíwọ̀n ìtutù, yìnyín òun òjò dídì, òjò tí ń pọn, àti oòrùn gbígbóná janjan, títí kan afẹ́fẹ́ líle tí ó wà yíká òkè ńlá Horn, gbogbo wọn ń dà lu àpáta náà, tí èyí sì ń mú kí àwọn àpólà òkúta ńláńlá ya. Nígbà míràn, wọ́n máa ń wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, bí òkìtì abọ́ ńláńlá, ṣùgbọ́n àwọn ìṣù-bàǹbà òjò dídì lè sún wọn, tí wọn óò sì jábọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Ọ̀pọ̀ àwọn pọ́nkèpọ́nkè ti ṣe kàyéfì pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ń bá a lọ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, síbẹ̀ òkè ńlá náà ṣì ní ìrísí ọwọ̀n aboríṣóńṣó onígun mẹ́rin rẹ̀, tí kò sì fi àmì yíyí padà hàn nínú ìrísí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, bí a bá fi wéra pẹ̀lú 2.5 bílíọ̀nù mítà níwọ̀n ìbú, òró òun gíga àpáta rẹ̀ tí a ṣírò, àwọn òkúta tí ń já bọ́ náà kò ṣe pàtàkì tó láti yí ìrísí rẹ̀ padà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fa ìpalára àti òfò ẹ̀mí.

Ní báyìí ná, pípọ́n òkè ńlá Matterhorn ti di ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣe. Àwọn olùfinimọ̀nà kan ti lọ sí òkè pátápátá rẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà. Bákan náà, àwọn tọkùnrin-tobìnrin púpọ̀ ti pọ́n ọn léraléra, ní yíyan ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní àkókò kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣùgbọ́n àwọn kan tún wà tí wọ́n ń gbìyànjú rẹ̀, tí wọ́n wá rí i pé bóyá ipò nǹkan kò bára dé, tàbí agbára àwọn, ara àwọn, tàbí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí àwọ́n gbà kò tó. Nítorí náà, wọn jáwọ́ nínú pípọ́n ọn, wọ́n sì jẹ́ kí ọgbọ́n ìrònú borí òkìkí pé, àwọn “ti pọ́n” òkè ńlá Matterhorn.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, yálà o ti rí òkè ńlá agbàfiyèsí yìí nínú fọ́tò tàbí sinimá tàbí bóyá o ti dúró nítòsí rẹ̀ tìyanutìyanu, tí o sì ń mọrírì àwọn àwọ̀ rẹ̀ nípele-ǹ-pele nígbà tí oòrùn bá ń yọ tàbí tí ó bá ń wọ̀, ó lè ti rán ọ́ létí nípa Oníṣẹ́ Ọnà Àgbàyanu náà. Pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ọkàn-àyà rẹ lè ti ṣàtúnwí àwọn ọ̀rọ̀ inú Orin Dafidi 104:24 pé: “Oluwa, iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó! nínú ọgbọ́n ni ìwọ́ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún ẹ̀dá rẹ.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́