Ojú Ìwòye Bibeli
Ohun Tí O Yẹ Kí O Ṣe Bí O Bá Ṣẹ Ẹlòmíràn
OHUN kan ti ṣẹlẹ̀. Ìwọ náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Kristian arákùnrin rẹ ń yàn ọ́ lódì. Kò tí ì sọ ohun tí ó ń bí i nínú, ṣùgbọ́n, agbára káká ní ó fi ń sọ pé báwo ni ò—ìyẹn yóò sì jẹ́ bí o bá kọ́kọ́ kí i! Ó ha yẹ kí o tọ̀ ọ́ lọ láti wádìí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ bí?
O lè ronú pé: ‘Ìṣòro tirẹ̀ nìyẹn. Bí mo bá ṣẹ̀ ẹ́, ó yẹ kí ó wá bá mi jíròrò rẹ̀.’ Ní tòótọ́, Bibeli fún ẹni tí a ṣẹ̀ ní ìṣírí láti lo ìdánúṣe láti wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀. (Fi wé Matteu 18:15-17.) Ṣùgbọ́n, ẹni tí ó ṣẹ ẹlòmíràn ńkọ́? Ẹrù iṣẹ́ wo ni ó ní, bí ó bá tilẹ̀ wà rárá?
Jesu sọ nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè pé: “Nígbà naa, bí iwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ wá síbi pẹpẹ tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà iwọ pẹlu arákùnrin rẹ, ati lẹ́yìn naa, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Matteu 5:23, 24) Ṣàkíyèsí pé, a darí ọ̀rọ̀ Jesu níhìn-ín sí ẹni tí ó ṣẹ̀ni náà. Kí ni ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ láti yanjú ọ̀ràn náà? Láti dáhùn ìyẹn, jẹ́ kí á gbé ohun tí ọ̀rọ̀ Jesu túmọ̀ sí fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Júù ní ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò.
‘Mímú Ẹ̀bùn Rẹ Wá Síbi Pẹpẹ’
Níhìn-ín, Jesu fúnni ní àkàwé ṣíṣe kedere: Olùjọsìn kan tí í ṣe Júù ti wá sí Jerusalemu fún ọ̀kan nínú àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún. Ó ní ẹ̀bùn kan—ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹran—láti fi rúbọ sí Jehofa.a Rírú ẹbọ kan dájúdájú yàtọ̀ sí ètò àṣà aláìnítumọ̀ kan. Ìwé Judaism—Practice and Belief ṣàlàyé pé: “Yíyan àwọn ohun ìrúbọ sísanra tí kò lábàwọ́n, jíjẹ́ kí àwọn ògbógi yẹ̀ wọ́n wò, títẹ̀ lé wọn dé itòsí pẹpẹ ìrúbọ, jíjọ̀wọ́ wọn, gbígbé ọwọ́ lé wọn lórí, jíjẹ́wọ́ àìmọ́ tàbí ẹ̀bi, tàbí lọ́nà míràn, yíya ẹran náà sí mímọ́, dídúḿbú rẹ̀, tàbí wíwulẹ̀ dì í mú—ìwọ̀nyí mú ìtumọ̀ àti ìtóbilọ́lá àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà dájú. . . . Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó gbà gbọ́ pé Ọlọrun ni ó pa gbogbo iṣẹ́ ìsìn náà láṣẹ . . . tí a kì yóò ru ìmọ̀lára rẹ̀ sókè bí ó ti ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀.”
Nípa báyìí, àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ní Matteu 5:23, 24 mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ronu nípa àkókò kan tí ó kún fún ìtumọ̀ àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún àwọn olùjọsìn tí wọ́n jẹ́ Júù. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bibeli kan ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́nà yìí: “Olùjọsìn náà ti wọnú Tẹ́ḿpìlì; ó ti gba gbogbo ọ̀wọ́ àwọn àgbàlá rẹ̀ kọjá, Àgbàlá àwọn Kèfèrí, Àgbàlá àwọn Obìnrin, Àgbàlá àwọn Ọkùnrin. Lẹ́yìn lọ́hùn-ún ni Àgbàlá àwọn Àlùfáà wà, níbi tí ọ̀gbẹ̀rì kò lè dé. Olùjọsìn náà dúró ní ibi tí a pa ààlà sí, ní ìmúratán láti kó àwọn ohun ìrúbọ rẹ̀ fún àlùfáà; ọwọ́ rẹ̀ ti wà [lórí ẹran náà] láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.”
Ní àkókò pàtàkì yẹn, olùjọsìn náà rántí pé, arákùnrin òún ní ohun kan lòdì sí òun. Ó lè jẹ́ pé, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sọ èyí fún un, tàbí ó lé jẹ́ pé, ó ti kíyè sí i láti inú ìwà arákùnrin rẹ̀ sí i pé inú ń bí i. Kí ni ó ní láti ṣe?
“Fi Ẹ̀bùn Rẹ Sílẹ̀ . . . , Kí O Sì Lọ”
Jesu ṣàlàyé pé: “Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ.” Èé ṣe? Kí ni ó tún lè ṣe pàtàkì ní àkókò yẹn ju láti rúbọ sí Jehofa lọ? Jesu ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Kọ́kọ́ wá àlàáfíà iwọ pẹlu arákùnrin rẹ, ati lẹ́yìn naa, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” Nítorí náà, olùjọsìn náà yóò fí ohun ìrúbọ rẹ̀ sílẹ̀ láàyè níwájú pẹpẹ ẹbọ sísun, yóò sì lọ láti wá arákùnrin rẹ̀ tí inú ń bí rí.
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ àjọyọ̀, kò sí iyè méjì pé, arákùnrin tí inú ń bí náà wà láàárín àwọn arìnrìn-àjò-ìsìn tí wọ́n ti kó jọ pọ̀ sí Jerusalemu. Pẹ̀lú àwọn òpópónà tóóró àti àwọn ilé tí wọ́n sún mọ́ra gádígádí, Jerusalemu tóbi níwọ̀nba. Ṣùgbọ́n àjọyọ̀ ni èyí, ìlú sì kún fọ́fọ́ fún àwọn àlejò.b
Kódà bí àwọn ènìyàn láti inú ìlú kan náà bá jọ rìnrìn àjò tí wọ́n sì jọ pàgọ́ síbì kan náà, wíwá ẹnì kan láàárín ìlú tí ó kún fún èrò náà yóò gba ìsapá díẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní àkókò Àjọyọ̀ Àtíbàbà, àwọn àlejò yóò pàtíbàbà káàkiri gbogbo àárín ìlú àti sí gbogbo ojú ọ̀nà àti sínú àwọn ọgbà yíkáàkiri Jerusalemu. (Lefitiku 23:34, 42, 43) Bí ó ti wù kí ó rí, olùjọsìn tí í ṣe Júù náà ní láti wá arákùnrin rẹ̀ tí a ṣẹ̀ sí náà títí tí yóò fi rí i. Kí ni ohun tí ó kàn lẹ́yìn náà?
Jesu sọ pé: “Wá àlàáfíà iwọ pẹlu arákùnrin rẹ.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “wá àlàáfíà” wá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe náà (di·al·lasʹso) tí ó túmọ̀ sí “‘láti ṣe ìyípadà kan, láti ṣe pàṣípààrọ̀,’ àti nítorí náà, ‘láti làjà.’” Lẹ́yìn ṣíṣe ìsapá gidigidi láti wá arákùnrin rẹ̀ tí inú ń bí, olùjọsìn tí í ṣe Júù náà yóò gbìyànjú láti wá àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀. Jesu sọ pé, nígbà náà, ó lè padà sí tẹ́ḿpìlì, kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ̀ rúbọ, nítorí pé, Ọlọrun yóò tẹ́wọ́ gbà á nísinsìnyí.
Nípa báyìí, àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ní Matteu 5:23, 24 kọ́ni ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan: Ìlàjà tàbí àlàáfíà, ṣáájú ìrúbọ. Ọ̀nà tí a gbà ń hùwà sí àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa ní ipa tààràtà lórí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọrun.—1 Johannu 4:20.
Ohun Tí O Ní Láti Ṣe Bí O Bá Ṣẹ Ẹlòmíràn
Nígbà náà, bí o bá bá ara rẹ nínú ipò tí a ṣàpèjúwe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ń kọ́—o kíyè sí i pé o ti ṣẹ olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ kan? Kí ní ó yẹ kí o ṣe?
Ní fífi ìmọ̀ràn Jesu sílò, lo ìdánúṣe láti tọ arákùnrin rẹ lọ. Pẹ̀lú ète wo? Ó ha jẹ́ láti mú un dá a lójú pé kò sí ìdí tí ó fi yẹ kí ó bínú? Rárá, kì í ṣe bẹ́ẹ̀! Ìṣòro náà lè ju èdèkòyédè lásán lọ. Jesu sọ pé: “Wá àlàáfíà.” Bí ó bá ṣeé ṣe, mú ẹ̀mí odì kúrò lọ́kàn rẹ̀. (Romu 14:19) Láti lè ṣe ìyẹn, o lè ní láti fi hàn pé o lóye ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pé kí o sọ pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. O tún lè ní láti béèrè pé, ‘Kí ní mo lè ṣe láti ṣàtúnṣe?’ Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, gbogbo ohun tí a nílò ni ìtọrọ àforíjì láti ọkàn wá. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan, ẹni tí a ṣẹ̀ sí náà lè nílò àkókò díẹ̀ láti yí ìmọ̀lára rẹ̀ padà.
Bí ó ti wù kí ó rí, bí kò bá ṣee ṣe fún ọ láti làjà láìka ìsapá tí o ṣe léraléra sí ńkọ́? Romu 12:18 sọ pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí-àlàáfíà pẹlu gbogbo ènìyàn.” Nípa báyìí, o lè ní ìfọkànbalẹ̀ pé, níwọ̀n bí o ti ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe láti wá àlàáfíà, inú Jehofa yóò dùn láti tẹ́wọ́ gba ìjọsìn rẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àkókò tí a sábà máa ń mú àwọn ohun ìrúbọ wá ni, ìgbà àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún mẹ́ta náà—Ìrékọjá, Pentekosti àti Àtíbàbà.—Deuteronomi 16:16, 17.
b Àwọn ìfojúdíwọ̀n tí a ṣe nípa iye àwọn arìnrìn-àjò-ìsìn tí wọ́n máa ń wá sí Jerusalemu ìgbàanì fún àwọn àjọyọ̀ náà yàtọ̀ síra. Òpìtàn Júù ọ̀rúndún kìíní, Josephus, fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́jọ ọ̀kẹ́ àwọn Júù tí wọ́n máa ń pésẹ̀ síbi Àjọ Ìrékọjá.—The Jewish War, II, 280 (xiv, 3); VI, 425 (ix, 3).