Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Yanjú Aáwọ̀?
Ìrìn tí kò yẹ—èyí ẹ̀kẹta nínú àwọn erin àfàwoṣe márùn-ún náà sì jábọ́ láti orí pẹpẹ. A níláti tún un ṣe bọ̀sípò. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìṣọ̀kan tí ó wà láàárín gbogbo àwọn erin àfàwoṣe náà yóò di àfẹ́kù. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀nà àtiṣe é jẹ́ ẹlẹgẹ́, o kò sì lérò pé o tóótun. O gbọ́dọ̀ gba ìmọ̀ràn tàbí kí o tilẹ̀ sọ fún ògbóǹtagí kan láti ṣe iṣẹ́ náà.
ÌṢỌ̀KAN láàárín àwọn arákùnrin àti arábìnrin tẹ̀mí ṣeyebíye lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ohun-ọ̀ṣọ́ kan lásán lọ. Onipsalmu náà kọrin lọ́nà yíyẹ pé: “Kíyèsí i, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.” (Orin Dafidi 133:1) Píparí aáwọ̀ kan pẹ̀lú Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni lè jẹ́ ọ̀ràn ẹlẹgẹ́ nígbà mìíràn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn kan kìí ṣe èyí lọ́nà tí ó tọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà “ìtúnṣebọ̀sípò” náà jẹ́ èyí tí ń ronilára lọ́nà tí kò yẹ tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ yèkooro, ní fífi àwọn àpá tí kò bójúmu sílẹ̀ sẹ́yìn.
Láì pọndandan, àwọn Kristian kan máa ń wá ọ̀nà láti mú àwọn alàgbà tí a yànsípò wọnú ọ̀ràn tí wọ́n lè bójútó fúnraawọn. Èyí lè rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ohun tí ó yẹ kí wọ́n ṣe kò dá wọn lójú. Arákùnrin kan tí ó ní ìrírí nínú fífúnni ní ìmọ̀ràn Bibeli ṣàlàyé pé, “Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará wa kò mọ bí wọ́n ṣe lè fi ìmọ̀ràn Bibeli sílò láti yanjú àwọn aáwọ̀ wọn.” Ó ń bá a nìṣó pé, “Lọ́pọ̀ ìgbà wọn kìí tẹ̀lé ọ̀nà tí Jesu ń gbà ṣe àwọn nǹkan.” Nítorí náà, kí ni ohun tí Jesu sọ níti gidi nípa bí Kristian kan ṣe níláti yanjú àwọn aáwọ̀ pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀? Èéṣe tí ó fi ṣekókó láti di ojúlùmọ̀ dáradára pẹ̀lú ìmọ̀ràn yìí àti láti kẹ́kọ̀ọ́ bí a ṣe lè fi í sílò?
Àwọn Aáwọ̀ Tí Kò Tó Nǹkan
“Nítorí náà bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá sí ibi pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé, arákùnrin rẹ ní ohun kan nínú sí ọ. Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, sì lọ, kọ́ bá arákùnrin rẹ làjà ná, nígbà náà ni kí o tó wá íbun ẹ̀bùn rẹ.”—Matteu 5:23, 24.
Nígbà tí Jesu sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ó jẹ́ àṣà àwọn Ju láti máa ṣe àwọn ìrúbọ, tàbí fi àwọn ẹ̀bùn fúnni, níbi pẹpẹ tí ó wà ní tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu. Bí Ju kan bá ti ṣẹ̀ sí ọmọ Israeli ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan, ẹni tí ó ṣe láìfí náà lè ṣe ìrúbọ ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Àpẹẹrẹ tí Jesu sọ̀rọ̀ rẹ̀ wáyé níbi tí ọ̀rọ̀ ti ṣekókó fún ìpinnu. Nígbà tí ẹni náà bá ti wà nídìí pẹpẹ tí ó sì ti fẹ́ fi ẹ̀bùn rẹ̀ rúbọ sí Ọlọrun, ó rántí pé arákùnrin òun ní oun kan lòdìsí òun. Bẹ́ẹ̀ni, ọmọ Israeli kan gbọ́dọ̀ lóye pé bíbá arákùnrin òun làjà níláti ṣáájú ṣíṣe irúfẹ́ iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irúfẹ́ àwọn ìrúbọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tí Òfin Mose béèrè fún, nínú araawọn wọn kò ní ìníyelórí gíga jùlọ ní ojú Ọlọrun. Wòlíì Samueli sọ fún Ọba Saulu aláìṣòtítọ́ pé: “Oluwa ha ní inúdídùn sí ọrẹ sísun àti ẹbọ bíi pé kí a gba ohùn Oluwa gbọ́? kíyèsí i, ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.”—1 Samueli 15:22.
Nínú Ìwàásù rẹ̀ orí Òkè, Jesu tún ìtòtẹ̀léra ohun àkọ́múṣe yìí sọ ó sì fihàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ yanjú àwọn aáwọ̀ wọn ṣáájú kí wọ́n tó ṣe ìrúbọ wọ́n. Lónìí, ẹbọ tí a béèrè fún lọ́wọ́ àwọn Kristian jẹ́ tẹ̀mí—“ẹbọ ìyìn, . . . èyíinì ni eso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.” (Heberu 13:15) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìlànà náà ṣì fẹsẹ̀múlẹ̀. Aposteli Johannu fihàn lọ́nà kan náà pé yóò jásí asán fún ẹnìkan láti jẹ́wọ́ pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun bí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀.—1 Johannu 4:20, 21.
Lọ́nà tí ó gbani ní àfiyèsí, ẹni náà tí ó bá rántí pé arákùnrin òun ní ohun kan lòdìsí òun ni ó níláti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Ó ṣeéṣe kí ìrẹ̀lẹ̀ tí ó tipa báyìí fihàn mú àwọn ìyọrísí rere wá. Ó ṣeéṣe pé, ẹnìkan tí a ṣe láìfí sí kì yóò kọ̀ láti fọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan tí ó tọ̀ ọ́ wá láti jẹ́wọ́ ìkùnà araarẹ̀. Òfin Mose filélẹ̀ ní pàtó pé ohunkóhun tí a bá mú lọ́nà tí kò tọ́ ni a níláti dá padà pátápátá àti pé ìdámárùn-ún ni a níláti fikún un. (Lefitiku 6:5) Dídá ipò ìbátan alálàáfíà, tí ó wà ní ìṣọ̀kan padà bọ̀ sípò ní a óò túbọ̀ mú rọrùn bákan náà bí ẹni tí ó ṣe láìfí náà bá fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ṣe ju ohun tí a béèrè lọ hàn, kí a sọ ọ́ bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an, láti ṣàtúnṣe ìpalára èyíkéyìí tí òun ti lè ṣokùnfà.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìgbìdánwò láti mú ìbátan alálàáfíà padàbọ̀sípò kìí fìgbà gbogbo yọrísírere. Ìwé Owe rán wa létí pé ó ṣòro láti yanjú aáwọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan tí ó ṣòro fún láti dáhùnpadà. Owe 18:19 sọ pé: “Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí, ó ṣòro ju ìlú olódi lọ: ìjà wọn sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.” Ìtumọ̀ mìíràn kà pé: “Arákùnrin kan tí a ṣe láìfí sí ṣòro láti ṣẹ́gun ju ìlú-ńlá lílágbára lọ: Asọ̀ wọn sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ilé aláruru.” (The Englishman’s Bible) Bí ó ti wù kí ó rí, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìsapá olótìítọ́-inú àti onírẹ̀lẹ̀ ṣeéṣe kí ó kẹ́sẹjárí nínú ọ̀ràn ti onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ọkàn láti wu Ọlọrun. Ṣùgbọ́n níbi tí a bá ti fẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kanni, ìmọ̀ràn Jesu tí a kọsílẹ̀ nínú Matteu orí 18 ni ó yẹ kí a fi sílò.
Yíyanjú Àwọn Aáwọ̀ Lílekoko
“Pẹ̀lúpẹ̀lù bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un ti ìwọ tirẹ̀ méjì: bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ mú arákùnrin rẹ bọ̀sípò. Ṣùgbọ́n bí kò bá gbọ́ tìrẹ, nígbà náà ni kí ìwọ kí ó mú ẹnìkan tàbí méjì pẹ̀lú araarẹ, kí gbogbo ọ̀rọ̀ ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta baà le fi ìdí múlẹ̀. Bí ó bá sí kọ̀ láti gbọ́ wọn, wí fún ìjọ ènìyàn Ọlọrun: bí ó ba sì kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọrun, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ àti agbowóòde.”—Matteu 18:15-17.
Kí a sọ pé Ju kan (tàbí lẹ́yìn náà, Kristian kan) bá kówọnú àwọn ìṣòro lílekoko pẹ̀lú olùjọ́sìn Jehofa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ńkọ́? Ẹni náà tí ó ronú pé a ti ṣẹ òun ni ó yẹ kí ó gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Ó yẹ kí ó jíròrò àwọn ọ̀ràn pẹ̀lú ẹni tí ó ṣe láìfí síi ní ìdákọ́ńkọ́. Nípa ṣíṣàì gbìyànjú láti wá ìtìlẹ́yìn fún araarẹ̀ nínú ọ̀ràn náà, dájúdájú ó ṣeéṣe jùlọ pé kí ó jèrè arákùnrin rẹ̀ padà, pàápàá jùlọ bí ó bá jẹ́ pé kìkì èdèkòyedè kan tí a lè tètè yanjú kíákíá ni. Ohun gbogbo ni a óò yanjú lọ́nà tí ó túbọ̀ rọrùn bí ó bá jẹ́ pé àwọn wọnnì tí ọ̀ràn kàn ní tààràtà nìkan ni wọ́n mọ̀ nípa ọ̀ràn náà.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lè ṣaláìtó. Láti bójútó ipò ọ̀ràn yẹn, Jesu wí pé: “Mú ẹnìkan tàbí méjì pẹ̀lú araarẹ.” Ìwọ̀nyí lè jẹ́ àwọn tí ọ̀ràn náà kọ́kọ́ ṣojú wọn. Bóyá wọ́n ti gbọ́ tí ọ̀kan lára àwọn ẹni náà fi ọ̀rọ̀ èké ba ẹnìkejì jẹ́, tàbí bóyá àwọn wọnnì tí a mú lọ náà ti jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àdéhùn alákọsílẹ̀ kan èyí tí àwọn ènìyàn méjèèjì náà kò fohùnṣọ̀kan lé lórí nísinsìnyí. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, àwọn wọnnì tí a mú lọ lè di ẹlẹ́rìí nígbà tí a bá mú àwọn kókó abájọ èyíkéyìí bí àwọn gbólóhùn ẹ̀rí tí a fọwọ́sí tàbí tí a sọ lọ́rọ̀ ẹnu, jáde láti ṣàlàyé ìdí fún ìṣòro náà. Níhìn-ín bákan náà, kìkì iye kíkéré jùlọ tí ó bá ṣeéṣe—“ẹnìkan tàbí méjì”—ni ó yẹ kí ó mọ̀ nípa ọ̀ràn náà. Èyí kì yóò jẹ́ kí àwọn nǹkan burú síi bí ó bá jẹ́ pé èdèkòyedè lásán ni ọ̀ràn náà.
Irú èrò wo ni ó yẹ kí ẹni tí a ṣe láìfí sí náà ní? Ó ha níláti gbìyànjú láti tẹ́ Kristian arákùnrin rẹ̀ lógo kí ó sì fẹ́ kí ó rẹ̀ araarẹ̀ sílẹ̀ bí? Lójú ìwòye ìmọ̀ràn Jesu, àwọn Kristian kò níláti yára láti dẹ́bi fún àwọn arákùnrin wọn. Bí olùrélànàkọjá náà bá gba àṣìṣe rẹ̀, tí ó tọrọ àforíjì, tí ó sì gbìyànjú láti ṣàtúnṣe àwọn ọ̀ràn, ẹni ti a ṣẹ̀ sí náà yóò ti “mú arákùnrin rẹ̀ bọ̀sípò.”—Matteu 18:15.
Bí ọ̀ràn náà kò bá ṣeé yanjú, ó yẹ kí a wí fún ìjọ. Ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, èyí túmọ̀sí àwọn alàgbà àwọn Ju ṣùgbọ́n nígbà tí ó yá, àwọn alàgbà ìjọ Kristian. Oníwà-àìtọ́ tí kò ronúpìwàdà náà ni ó lè ṣeéṣe kí a lé jáde nínú ìjọ. Ìyẹn ni ìtumọ̀ jíjẹ́ ‘kí ó dàbí kèfèrí àti agbowóòde,’ àwọn ẹni tí àwọn Ju máa ń takété sí. Ìgbésẹ̀ lílekoko yìí ni Kristian kan kò lè ṣe ní òun nìkan. Àwọn alàgbà tí a yànsípò, tí wọ́n ń ṣojú fún ìjọ, ni kìkì àwọn ẹni tí a fún ní àṣẹ láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.—Fiwé 1 Korinti 5:13.
Ṣíṣeéṣe náà pé kí a yọ oníwà-àìtọ́ kan tí kò ronúpìwàdà lẹ́gbẹ́ fihàn pé Matteu 18:15-17 kò níí ṣe pẹ̀lú àwọn aáwọ̀ tí kò tó nǹkan. Jesu ń tọ́kasí àwọn láìfí tí ó wúwo, síbẹ̀ tí ó jẹ́ irú èyí tí a lè yanjú láàárín àwọn ẹni méjì tí ọ̀ràn kan náà. Fún àpẹẹrẹ, láìfí náà lè jẹ́ ìfọ̀rọ̀ èké banijẹ́, tí ó nípa lórí ìfùsì ẹni náà lọ́nà lílekoko. Tàbí ó lè níí ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn ìnáwó, nítorí pé àwọn ẹsẹ tí ó tẹ̀lé e ní àkàwé Jesu nípa ẹrú aláìláàánú tí a dárí gbèsè ńláǹlà jì nínú. (Matteu 18:23-35) Ẹ̀yáwó kan tí a kò san padà ní àkókò wulẹ̀ lè jẹ́ ìṣòro kan tí ó rọrùn láti gbójúfòdá tí a lè tètè yanjú láàárín àwọn ènìyàn méjì. Ṣùgbọ́n ó lè di ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, ìyẹn ni, olè jíjà, bí ayáwó náà bá fi oríkunkun kọ̀ láti san gbèsè tí ó jẹ padà.
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn ni a kò wulẹ̀ lè yanjú láàárín àwọn Kristian méjì. Lábẹ́ Òfin Mose, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo ni a gbọ́dọ̀ ròyìn. (Lefitiku 5:1; Owe 29:24) Bákan náà, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ lílékenkà tí ó wémọ́ ìjẹ́mímọ́ ìjọ ni a gbọ́dọ̀ ròyìn fún àwọn Kristian alàgbà.
Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ọ̀ràn aáwọ̀ láàárín àwọn Kristian kìí wá sábẹ́ ìgbésẹ̀ yìí.
Ìwọ Ha Wulẹ̀ Lè Dáríjinni?
Ní kété lẹ́yìn tí Jesu ti ṣàlàyé bí a ṣe lè yanjú àwọn aáwọ̀ lílekoko, ó kọ́ni ní ẹ̀kọ́ pàtàkì mìíràn. A kà pé: “Nígbà naa ni Peteru wá ó sì wí fún un pé: ‘Oluwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yoo ṣẹ̀ mí tí emi yoo sì dáríjì í? Títí dé ìgbà méje ni bí?’ Jesu wí fún un pé: ‘Mo wí fún ọ, kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bíkòṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.’” (Matteu 18:21, 22, NW) Ní àkókò mìíràn Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti dáríjinni ní “ẹ̀rìnméje ní òòjọ́.” (Luku 17:3, 4) Nígbà náà, ó ṣe kedere pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ni a késí láti yanjú àwọn aáwọ̀ nípa dídáríji ẹnìkínní kejì ní fàlàlà.
Èyí jẹ́ agbègbè kan tí ó béèrè ìsapá ńláǹlà. Ẹni náà tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ sọ pé, “Àwọn arákùnrin kan kò wulẹ̀ mọ bí a ṣe lè dáríjinni.” Ó fikún un pé: “Ó dàbí ẹni pé ó máa ń yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí ẹnìkan bá ṣàlàyé pé wọ́n lè yàn láti dáríjinni kí ó lè jẹ́ pé, lékè gbogbo rẹ̀ wọn yóò pa àlàáfíà mọ́ nínú ìjọ Ọlọrun.”
Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máa faradà á fún araayín, ẹ sì máa dáríji araayín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí [Jehofa] ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú.” (Kolosse 3:13) Nítorí náà, ṣáájú títọ arákùnrin kan tí ó lè ti ṣẹ̀ wá lọ, yóò dára láti ṣàṣàrò lórí àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lé e wọ̀nyí: Láìfí náà ha yẹ ní sísọ fún un bí? Ó ha jẹ́ ohun tí kò ṣeéṣe fún mi nítòótọ́ láti gbàgbé ọ̀rọ̀ àná pẹ̀lú ẹ̀mí tòótọ́ ti jíjẹ́ Kristian bí? Bí ó bá ṣe pé èmi ni, èmi kì yóò ha fẹ́ kí a dáríjì mí bí? Bí mo bá sì yàn láti máṣe dáríjinni, mo ha lè retí pé kí Ọlọrun dáhùn àwọn àdúrà mi kí ó sì dáríjì mí bí? (Matteu 6:12, 14, 15) Irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ dáradára láti lè máa dáríjinni.
Gẹ́gẹ́ bíi Kristian, ọ̀kan nínú àwọn ẹrù-iṣẹ́ wa tí ó ṣè pàtàkì ni láti pa àlàáfíà mọ́ nínú ìjọ àwọn ènìyàn Jehofa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ìmọ̀ràn Jesu sílò. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dáríjinni ní fàlàlà. Irú ẹ̀mí ìdáríjinni bẹ́ẹ̀ yóò dákún ìfẹ́ni ará tí ó jẹ́ àmì ìdánimọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.—Johannu 13:34, 35.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn Kristian lè yanjú àwọn aáwọ̀ wọn nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn Jesu