‘Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Dídáríji Ara Yín Lẹ́nì Kíní Kejì’
“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kíní kejì kí ẹ sì máa dáríji ara yín fàlàlà lẹ́nì kíní kejì.”—KÓLÓSÈ 3:13.
1. (a) Nígbà tí Pétérù dámọ̀ràn pé kí a máa dárí ji àwọn ẹlòmíràn “títí dé ìgbà méje,” èé ṣe tí ó fi lè rò pé òun ti jẹ́ onínúure? (b) Kí ni ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé ó yẹ kí a dárí jini “títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje”?
“OLÚWA, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mí tí èmi yóò sì dárí jì í? Títí dé ìgbà méje ni bí?” (Mátíù 18:21) Pétérù ti lè rò pé àbá òun fi hàn pé òun jẹ́ onínúure. Ní àkókò yẹn, òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rábì wí pé ẹnì kan kò gbọ́dọ̀ nawọ́ ìdáríjì síni ju ìgbà mẹ́ta lọ lórí ẹ̀ṣẹ̀ kan náà.a Wo bí ẹnu yóò ti ya Pétérù tó, nígbà tí Jésù fèsì pé: “Mo wí fún ọ, kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje”! (Mátíù 18:22) Sísọ méje léraléra jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú sísọ pé “láìlópin.” Lójú ìwòye Jésù, iye ìgbà tí ó yẹ kí Kristẹni kan dárí ji ẹlòmíràn kò lópin rárá.
2, 3. (a) Àwọn ipò wo ni ó ti lè dà bíi pé ó ṣòro láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn? (b) Èé ṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé pé dídáríji àwọn ẹlòmíràn jẹ́ fún àǹfààní ara wa?
2 Ṣùgbọ́n, fífi ìmọ̀ràn yẹn sílò kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Ta ni nínú wa tí kò tí ì nímọ̀lára oró ọgbẹ́ àìbánilò lọ́nà tí ó tọ́ rí? Bóyá ẹnì kan tí o fọkàn tán lè dà ọ́. (Òwe 11:13) Ọ̀rọ̀ àìgbatẹnirò láti ẹnu ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan ti lè ‘gún ọ bí idà.’ (Òwe 12:18) Ìwà ìkà tí ẹnì kan tí o nífẹ̀ẹ́ sí tàbí tí o gbẹ́kẹ̀ lé hù sí ọ ti lè dá ọgbẹ́ jíjìn sí ọ lára. Nígbà tí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ìhùwàpadà wa lọ́nà ti ẹ̀dá lè jẹ́ láti bínú. A lè ní ìtẹ̀sí láti bá oníláìfí náà yodì, kí a yẹra fún un pátápátá bí ó bá ṣeé ṣe. Ó lè dà bíi pé, dídáríjì í yóò jẹ́ kí ó lọ láìjìyà ìpalára ti ó mú wa bá wa. Síbẹ̀, bí a bá ń di kùnrùngbùn, ara wa ni a óò pa lára nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
3 Nítorí náà, Jésù kọ́ wa láti dárí jì—“títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” Dájúdájú, àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ kò lè pa wá lára. Gbogbo ohun tí ó fi kọ́ni pilẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ‘Ẹni tí ó ń kọ́ wa fún èrè.’ (Aísáyà 48:17; Jòhánù 7:16, 17) Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, dídáríji àwọn ẹlòmíràn gbọ́dọ̀ jẹ́ fún àǹfààní wa. Ṣáájú kí a tó jíròrò ìdí tí ó fi yẹ kí a dárí jini àti bí a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè ṣèrànwọ́ láti kọ́kọ́ ṣàlàyé ohun tí ìdáríjì jẹ́ àti ohun tí kò jẹ́. Èrò wa nípa ìdáríjì lè ní í ṣe pẹ̀lú bí a ṣe lè dárí ji àwọn ẹlòmíràn nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá.
4. Kí ni dídáríji àwọn ẹlòmíràn kò túmọ̀ sí, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe túmọ̀ ìdáríjì?
4 Dídáríji àwọn ẹlòmíràn nítorí ìwà láìfí tí a hù sí wa kò túmọ̀ sí pé a gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí pé a ń fojú bíńtín wo ohun tí wọ́n ṣe; bẹ́ẹ̀ sì ni kò túmọ̀ sí pé a ń gbà kí àwọn ẹlòmíràn mú wa lọ́bọ. Ó ṣe tán, nígbà tí Jèhófà bá dárí jì wá, dájúdájú, kì í ṣe pé ó ń fojú bíńtín wo ẹ̀ṣẹ̀ wa, kò sì ní yọ̀ǹda láé pé kí ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ èyíkéyìí ṣi àǹfààní àánú rẹ̀ lò. (Hébérù 10:29) Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures ti sọ, ìdáríjì túmọ̀ sí “ìwà dídáríji oníláìfí kan; ṣíṣàìbínú sí i nítorí láìfí rẹ̀ àti kíkọ gbogbo àǹfààní láti gbẹ̀san lára rẹ̀ sílẹ̀.” (Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 861)b Bíbélì pèsè ìdí tí ó yè kooro fún wa láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn.
Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Dárí Ji Àwọn Ẹlòmíràn?
5. Ìdí pàtàkì wo fún dídáríji àwọn ẹlòmíràn ni a fi hàn nínú Éfésù 5:1?
5 Ìdí pàtàkì kan tí ó wà fún dídáríji àwọn ẹlòmíràn ni a fi hàn nínú Éfésù 5:1: “Nítorí náà, ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” Lọ́nà wo ni ó fi yẹ kí a “di aláfarawé Ọlọ́run”? Ọ̀rọ̀ náà, “nítorí náà,” so gbólóhùn náà mọ́ ẹsẹ ìṣáájú, tí ó sọ pé: “Ẹ di onínú rere sí ara yín lẹ́nì kíní kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín lẹ́nì kíní kejì fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfésù 4:32) Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ìdáríjì, ó yẹ kí a jẹ́ aláfarawé Ọlọ́run. Bí ọmọdékùnrin kan ṣe ń fẹ́ láti dà bíi bàbá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe yẹ kí àwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gidigidi, fẹ́ láti dà bíi Bàbá wa ọ̀run tí ń dárí jì. Ẹ wo bí inú Jèhófà yóò ti dùn tó bí ó bá bojú wolẹ̀ láti ọ̀run tí ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé tí wọ́n ń gbìyànjú láti dà bíi rẹ̀ nípa dídáríji ara wá lẹ́nì kíní kejì!—Lúùkù 6:35, 36; fi wé Mátíù 5:44-48.
6. Lọ́nà wo ni ìyàtọ̀ gígadabú fi wà láàárín ìdáríjì Jèhófà àti tiwa?
6 Lóòótọ́, a kò lè dárí jini lọ́nà pípé pérépéré bíi ti Jèhófà láéláé. Ṣùgbọ́n ìdí gan-an nìyẹn tí ó fi yẹ kí a máa dárí ji ara wa. Rò ó wò ná: Ìyàtọ̀ gígadabú wà láàárín ìdáríjì Jèhófà àti tiwa. (Aísáyà 55:7-9) Nígbà tí a bá dárí ji àwọn tí ó ṣẹ̀ wá, ó sábà máa ń jẹ́ pẹ̀lú èrò náà pé bó pẹ́ bó yá, a óò fẹ́ kí wọ́n ṣojú rere kan náà sí wa nípa dídáríjì wá. Ní ti ẹ̀dá ènìyàn, ó sábà máa ń jẹ́ ọ̀ràn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní ti Jèhófà, ọ̀nà kan ni ìdáríjì náà. Ó ń dárí jì wá, ṣùgbọ́n kò lè sí ìdí kankan fún wa láti dárí jì í. Bí Jèhófà, tí kì í dẹ́ṣẹ̀, bá lè fi ìfẹ́ dárí jì wá pátápátá porogodo, kò ha yẹ kí àwa ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ gbìyànjú láti dárí ji ara wa bí?—Mátíù 6:12.
7. Bí a bá kọ̀ láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn nígbà tí ìdí wà fún fífi àánú hàn, báwo ni ó ṣe lè ní ipa búburú lórí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà?
7 Èyí tí ó tún ṣe pàtàkì jù ni pé, bí a bá kọ̀ láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn nígbà tí ìdí wà fún fífi àánú hàn, ó lè nípa búburú lórí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Kì í wulẹ̀ ṣe pé Jèhófà ní kí a máa dárí ji ara wa ni; ó ń retí pé kí a máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́, ara ìsúnniṣe tí a ní fún dídáríjì ni pé, kí Jèhófà baà lè dárí jì wá tàbí nítorí pé ó ti dárí jì wá. (Mátíù 6:14; Máàkù 11:25; Éfésù 4:32; Jòhánù Kíní 4:11) Nígbà náà, bí a kò bá múra tán láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn nígbà tí ìdí yíyèkooro wà láti ṣe bẹ́ẹ̀, a ha lè retí irú ìdáríjì bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní ti gidi bí?—Mátíù 18:21-35.
8. Èé ṣe tí dídáríjini fi ń ṣiṣẹ́ fún àǹfààní wa?
8 Jèhófà ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ “ní ọ̀nà rere nínú èyí tí wọn ì bá máa rìn.” (Àwọn Ọba Kìíní 8:36) Nígbà tí ó fún wa nítọ̀ọ́ni láti máa dárí ji ara wa, a lè ní ìgbọ́kànlé pé ó ní ire wa dídára jù lọ lọ́kàn. Pẹ̀lú ìdí rere ni Bíbélì fi sọ fún wa pé kí a “yàgò fún ìrunú.” (Róòmù 12:19) Dídi kùnrùngbùn jẹ́ ẹrù tí ó nira láti máa rù kiri nínú ìgbésí ayé. Nígbà tí a bá di kùnrùngbùn, ó máa ń gba gbogbo ìrònú wa, ó máa ń gba àlàáfíà wa mọ́ wa lọ́wọ́, ó sì máa ń ba ayọ̀ wa jẹ́. Ìbínú tí ó wà fún ìgbà pípẹ́, bí owú, lè ní ipa búburú lórí ìlera wa nípa ti ara. (Òwe 14:30) Bí àwa sì ti ń bá èyí yí, oníláìfí náà lè máa bá ìgbésí ayé tirẹ̀ lọ láìtilẹ̀ mọ irú ìdààmú tí ó dé bá wa! Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ mọ̀ pé ó yẹ kí a múra tán láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn kì í ṣe kìkì fún àǹfààní wọn ṣùgbọ́n fún àǹfààní tiwa fúnra wa pẹ̀lú. Ní tòótọ́, ìmọ̀ràn Bíbélì náà láti máa dárí jini jẹ́ ‘ọ̀nà rere láti rìn.’
“Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Fífaradà Á fún Ara Yín Lẹ́nì Kíní Kejì”
9, 10. (a) Irú ipò wo ni kò fi dandan béèrè ìdáríjì àpilẹ̀ṣe? (b) Kí ni gbólóhùn náà, “ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kíní kejì,” túmọ̀ sí?
9 Ọgbẹ́ nípa ti ara lè jẹ́ láti orí ọgbẹ́ kékeré dorí ọgbẹ́ jíjìn, gbogbo wọn kò sì nílò irú ìtọ́jú kan náà. Bákan náà ni ìmọ̀lára tí a pa lára rí—àwọn ọgbẹ́ kan jìn ju àwọn mìíràn lọ. Ó ha pọn dandan kí a sọ gbogbo ọgbẹ́ kéékèèké tí a fara gbà nínú ipò ìbátan wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn di ọ̀ràn ńlá ní tòótọ́ bí? Ìfínniníràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, àìkanisí, àti ìmúnibínú jẹ́ apá kan ìgbésí ayé, kò sì fi dandan béèrè pé kí a máa retí ẹ̀bẹ̀ kí a tó lè dárí jini. Bí a bá mọ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń sára fún àwọn ẹlòmíràn nítorí gbogbo ìjákulẹ̀ kéékèèké, tí a sì ń rin kinkin mọ́ ọn pé, àfi tí wọ́n bá tọrọ àforíjì ni a óò tó lè bá wọn lò lọ́nà tí ó tọ́, a lè fipá mú wọn láti máa rọra ṣe nítòsí wa—tàbí láti máa pẹ́ wa tì!
10 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sàn jù láti “ní orúkọ rere fún jíjẹ́ afòyebánilò.” (Fílípì 4:5, Phillips) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé tí ń sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, ó bọ́gbọ́n mu kí a retí pé láti ìgbàdégbà àwọn arákùnrin wa lè hùwà tí yóò bí wa nínú, a sì lè ṣe ohun kan náà sí wọn. Kólósè 3:13 rọ̀ wá pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kíní kejì.” Gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí mímú sùúrù pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ríráragba àwọn nǹkan tí a kò fẹ́ tí wọ́n ń ṣe tàbí ríráragba àwọn ìwà tí a lè rí i pé ó ń bí wa nínú. Irú sùúrù àti ìfàyàrán bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àwọn ọgbẹ́ tí kò jìn tí a lè fara gbà nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn mọ́ra—láìdabarú àlàáfíà ìjọ.—Kọ́ríńtì Kíní 16:14.
Nígbà Tí Ọgbẹ́ Náà Bá Jìn
11. Nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá ṣẹ̀ wá, kí ní lè ràn wá lọ́wọ́ láti dárí jì wọ́n?
11 Ṣùgbọ́n, bí àwọn ẹlòmíràn bá ṣẹ̀ wá ńkọ́, ní dídá ọgbẹ́ tí ó ṣeé tètè rí sí wa lára? Bí ẹ̀ṣẹ̀ náà kò bá burú jù, a lè máà ní ìṣòro púpọ̀ ní lílo ìmọ̀ràn Bíbélì náà láti “dárí ji ara yín lẹ́nì kíní kejì fàlàlà.” (Éfésù 4:32) Irú ìmúratán bẹ́ẹ̀ láti dárí jini wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Pétérù náà tí a mí sí pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kíní kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (Pétérù Kíní 4:8) Níní i lọ́kàn pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti yọ̀ǹda fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí a bá sì tipa báyìí dárí jini, a óò tú kùnrùngbùn náà jáde dípò tí a óò fi dì í sínú. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ipò ìbátan wa pẹ̀lú oníláìfí náà lè má bà jẹ́ títí lọ, a sì tún lè ṣèrànwọ́ láti pa àlàáfíà ìjọ tí ó ṣeyebíye mọ́. (Róòmù 14:19) Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a lè máà rántí ohun tí ó ṣe mọ́ rárá.
12. (a) Àtinúdá wo ni àwa yóò ní láti lò láti baà lè dárí ji ẹnì kan tí ó pa ìmọ̀lára wa lára gidigidi? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Éfésù 4:26 ṣe fi hàn pé ó yẹ kí a tètè yanjú ọ̀ràn?
12 Ṣùgbọ́n, bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá lọ́nà tí ó túbọ̀ burú jáì, ní ṣíṣe wá léṣe gan-an ńkọ́? Fún àpẹẹrẹ, ọ̀rẹ́ kan tí o fọkàn tán ti lè tú àwọn ọ̀ràn ara ẹni kan tí o fi pa mọ́ sí i lọ́wọ́ síta. Ó dùn ọ́ gan-an, ó kó ìtìjú bá ọ, o sì nímọ̀lára pé a dà ọ́. O ti gbìyànjú láti gbàgbé rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀ràn náà kò kúrò lọ́kàn rẹ̀. Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ó lè pọn dandan fún ọ láti lo àtinúdá láti yanjú ìṣòro náà, bóyá nípa bíbá oníláìfí náà sọ̀rọ̀. Ó bọ́gbọ́n mu láti ṣe èyí kí ọ̀ràn náà tó di ńlá. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má sì ṣe ṣẹ̀ [ìyẹn ni, nípa dídi kùnrùngbùn tàbí gbígbégbèésẹ̀ lórí ìbínú wa]; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìtánnísùúrù.” (Éfésù 4:26) Ohun mìíràn tí ó fún ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ní ìtumọ̀ kíkún sí i ni òtítọ́ náà pé láàárín àwọn Júù, wíwọ̀ oòrùn sàmì sí òpin ọjọ́ kan àti ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tuntun. Nítorí náà, ìmọ̀ràn náà ni pé: Tètè yanjú ọ̀ràn náà!—Mátíù 5:23, 24.
13. Nígbà tí a bá tọ ẹnì kan tí ó ti hùwà láìfí sí wa lọ, kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ète wa, ìmọ̀ràn wo sì ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti lè mú un ṣẹ?
13 Báwo ni ó ṣe yẹ kí o tọ oníláìfí náà lọ? Pétérù Kíní 3:11 sọ pé: “Máa wá àlàáfíà kí o sì máa lépa rẹ̀.” Nítorí náà, ète rẹ kì í ṣe láti fi ìbínú hàn bí kò ṣe láti wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ. Láti ṣe ìyẹn, ó dára láti yẹra fún ọ̀rọ̀ tàbí ìfaraṣàpèjúwe tí ó lè múni bínú; ìwọ̀nyí lè ru irú ìhùwàpadà kan náà sókè nínú ẹnì kejì. (Òwe 15:18; 29:11) Ní àfikún sí i, yẹra fún ọ̀rọ̀ àsọdùn bí, “Ìgbà gbogbo ni o máa ń . . . !” tàbí, “Oò jẹ́ . . . !” Irú àwọn ọ̀rọ̀ àsọdùn bẹ́ẹ̀ yóò wulẹ̀ mú kí onítọ̀hún máa gbèjà ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ohùn rẹ àti ojú rẹ fi hàn pé ọ̀ràn kan tí ó dùn ọ́ wọnú egungun ni o fẹ́ yanjú. Sọjú abẹ níkòó, ní sísọ ìmọ̀lára rẹ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Fún onítọ̀hún ní àyè láti ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. Tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí ó fẹ́ sọ. (Jákọ́bù 1:19) Rere wo ni ìyẹn yóò mú wá? Òwe 19:11 ṣàlàyé pé: “Ìmòye ènìyàn mú un lọ́ra àtibínú; ògo rẹ̀ sì ni láti ré ẹ̀ṣẹ̀ kọjá.” Lílóye ìmọ̀lára onítọ̀hún àti ìdí tí ó fi gbé irú ìgbésẹ̀ tí ó gbé lè mú èrò àti ìmọ̀lára òdì tí o ní nípa rẹ̀ kúrò. Nígbà tí a bá kojú ipò náà pẹ̀lú ète àtiwá àlàáfíà àti láti ní ẹ̀mí ìrònú yẹn, ó ṣeé ṣe dáradára pé a óò lè yanjú èdè àìyedè èyíkéyìí, kí a tọrọ àforíjì tí ó yẹ, kí a sì nawọ́ ìdáríjì sí ara wa.
14. Nígbà tí a bá dárí ji àwọn ẹlòmíràn, lọ́nà wo ni ó fi yẹ kí a gbàgbé?
14 Dídáríji àwọn ẹlòmíràn ha túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́ bí? Rántí àpẹẹrẹ Jèhófà nípa ọ̀ràn yí, bí a ti jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú. Nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà ń gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ wa, èyí kò túmọ̀ sí pé wọn kò lè wá sí iyè rẹ mọ́. (Aísáyà 43:25) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń gbàgbé ní ti pé gbàrà tí ó bá ti dárí jì wá, òun kò ní ka ẹ̀ṣẹ̀ yẹn sí wa lọ́rùn mọ́ lẹ́yìnwá ọ̀la. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:14-16) Bákan náà, dídáríji ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa kò fi dandan túmọ̀ sí pé ohun tí wọ́n ṣe kò ní wá sí iyè wa mọ́. Ṣùgbọ́n, a lè gbàgbé ní ti pé a kò kà á sí ẹ̀ṣẹ̀ sí oníláìfí náà lọ́rùn mọ́ tàbí kí a tún pa dà hú u jáde lẹ́yìnwá ọ̀la. Nígbà tí ọ̀ràn náà bá ti yanjú, kò ní jẹ́ ohun yíyẹ láti máa sọ ọ́ káàkiri; bẹ́ẹ̀ sì ni kì yóò fi ìfẹ́ hàn láti yẹra fún oníláìfí náà pátápátá, ní bíbá a lò bíi pé a ti yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. (Òwe 17:9) Òtítọ́ ni pé, ó lè gba àkókò díẹ̀ kí ipò ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀ tó lè dán mọ́rán; a lè máà gbádùn wíwàpapọ̀ tímọ́tímọ́ bí a ti wà tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n a ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni arákùnrin wa, a sì ń ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti mú kí ipò ìbátan alálàáfíà máa bá a lọ.—Fi wé Lúùkù 17:3.
Nígbà Tí Ó Bá Dà Bíi Pé Kò Ṣeé Ṣe Láti Dárí Jì
15, 16. (a) Ó ha di dandan pé kí àwọn Kristẹni dárí ji oníwà àìtọ́ kan tí kò ronú pìwà dà bí? (b) Báwo ni a ṣe lè fi ìmọ̀ràn Bíbélì tí a rí nínú Orin Dáfídì 37:8 sílò?
15 Ṣùgbọ́n, bí àwọn mìíràn bá ṣẹ̀ wá lọ́nà tí ó dá ọgbẹ́ kan tí ó jìn gidigidi sí wa lára ńkọ́, síbẹ̀ tí wọn kò sì gbà pé àwọn ṣẹ̀ wá, tí oníláìfí náà kò ronú pìwà dà, tí kò sì tọrọ àforíjì ńkọ́? (Òwe 28:13) Ìwé Mímọ́ fi hàn ní kedere pé, Jèhófà kì í dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà, tí ọkàn wọ́n ti yigbì. (Hébérù 6:4-6; 10:26, 27) Àwa náà ńkọ́? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures sọ pé: “A kò fi dandan lé e pé kí àwọn Kristẹni dárí ji àwọn tí ó sọ ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, oníjàǹbá dàṣà, láìronú pìwà dà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 862) Kò yẹ kí Kristẹni èyíkéyìí tí a hùwà àìtọ́, ìwà ìríra, tàbí ìwà ẹ̀gbin sí nímọ̀lára pé ó di dandan fún òun láti dárí ji oníwà àìtọ́ kan tí kò ronú pìwà dà.—Orin Dáfídì 139:21, 22.
16 Lọ́nà tí ó yéni, àwọn tí a ti hùwà ìkà rírorò sí lè nímọ̀lára pé a pa wọ́n lára, wọ́n sì lè bínú. Ṣùgbọ́n, rántí pé dídi ìbínú àti kùnrùngbùn sínú lè ṣèpalára fún wa gidigidi. Dídúró de kí ẹnì kan gbà pé òun ṣẹ̀ wá tàbí kí ó wá tọrọ àforíjì, tí ẹni náà kò sì wá, lè túbọ̀ máa mú inú bí wa. Jíjẹ́ kí ìwà àìtọ́ náà gbà wá lọ́kàn lè mú kí inú wa máa ru gùdù, yóò sì ní ipa búburú lórí ìlera wa nípa tẹ̀mí, ní ti ìmọ̀lára, àti nípa ti ara. Ohun tí a ń ṣe ni pé, a ń yọ̀ǹda fún ẹni tí ó pa ìmọ̀lára wa lára náà láti túbọ̀ máa pa ìmọ̀lára wa lára. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé: “Dákẹ́ inú bíbí, kí o sì kọ ìkannú sílẹ̀.” (Orin Dáfídì 37:8) Nítorí náà, àwọn Kristẹni kan ti rí i pé lẹ́yìn àkókò díẹ̀ ó ṣeé ṣe fún àwọn láti ṣe ìpinnu láti dárí jini ní ti dídẹ́kun dídi kùnrùngbùn—kì í ṣe fífojú kéré ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n ṣíṣàìjẹ́ kí ìbínú mú kí wọ́n gbiná jẹ. Ní fífa ọ̀ràn náà lé Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo lọ́wọ́, wọ́n nírìírí ìtura púpọ̀, ó sì ṣeé ṣe fún wọn láti máa bá ìgbésí ayé wọn lọ.—Orin Dáfídì 37:28.
17. Ìdálójú atuninínú wo ni ìlérí Jèhófà tí a kọ sínú Ìṣípayá 21:4 pèsè?
17 Nígbà tí ẹnì kan bá ṣe ohun kan tí ó dùn wá gan-an, a lè máà kẹ́sẹ járí láti gbé e kúrò lọ́kàn wa pátápátá, pàápàá nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí. Ṣùgbọ́n Jèhófà ṣèlérí ayé tuntun kan nínú èyí tí ‘òun yóò ti nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, tí ikú kì yóò sí mọ́, tí kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Tí àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’ (Ìṣípayá 21:4) Ohunkóhun tí a bá rántí ní àkókò yẹn kò ní bà wá lọ́kàn jẹ́, tàbí fa ìrora ọkàn, tí ó lè kó ìdààmú bá ọkàn àyà wa nísinsìnyí.—Aísáyà 65:17, 18.
18. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti máa dárí jini nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa? (b) Nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá ṣẹ̀ wá, ọ̀nà wo ni a lè gbà dárí jì wọ́n, kí a sì gbàgbé rẹ̀? (d) Báwo ni èyí ṣe ṣàǹfààní fun wa?
18 Ní báyìí ná, a gbọ́dọ̀ máa gbé pa pọ̀ kí a sì máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìpé, ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. Gbogbo wa ni a ń ṣàṣìṣe. Láti ìgbàdégbà, a ń já ara wa kulẹ̀ lẹ́nì kíní kejì, a sì ń pa ìmọ̀lára wa lẹ́nì kíní kejì lára. Jésù mọ̀ dáradára pé a óò ní láti máa dárí ji ara wa, “kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje”! (Mátíù 18:22) Lóòótọ́, a kò lè dárí jini pátápátá porogodo bí Jèhófà ti ń ṣe. Síbẹ̀, nínú ọ̀pọ̀ ọ̀ràn, nígbà tí àwọn ará wa bá ṣẹ̀ wá, a lè dárí jì wọ́n ní ti bíborí dídi kùnrùngbùn, a sì lè gbàgbé ní ti ṣíṣàìka ẹ̀ṣẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn mọ́ láé lẹ́yìnwá ọ̀la. Nígbà tí a bá dárí jini, tí a sì gbàgbé lọ́nà yí, kì í ṣe àlàáfíà ìjọ nìkan ni a ń ṣèrànwọ́ láti pa mọ́ ṣùgbọ́n a ń pa àlàáfíà èrò inú àti ọkàn àyà wa mọ́ pẹ̀lú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a óò gbádùn àlàáfíà tí ó jẹ́ pé Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ nìkan, ni ó lè pèsè rẹ̀.—Fílípì 4:7.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìwé Talmud ti àwọn ará Bábílónì ti sọ, òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rábì kan sọ pé: “Bí ẹnì kan bá dẹ́ṣẹ̀ kan, lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́ẹ̀kejì àti lẹ́ẹ̀kẹta kí a dárí jì í, lẹ́ẹ̀kẹrin kí a máà dárí jì í.” (Yoma 86b) A gbé èyí karí àṣìlóye nípa àwọn ẹsẹ bí Ámósì 1:3; 2:6; àti Jóòbù 33:29.
b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a múra tán láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn?
◻ Irú ipò wo ni ó ń béèrè lọ́wọ́ wa pé kí a ‘máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara wa lẹ́nì kíní kejì’?
◻ Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn bá dùn wá wọnú egungun gidigidi, kí ni a lè ṣe láti fi pẹ̀lẹ́tù yanjú ọ̀ràn náà?
◻ Nígbà tí a bá dárí ji àwọn ẹlòmíràn, lọ́nà wo ni ó fi yẹ kí a gbàgbé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nígbà tí a bá ń di kùnrùngbùn, oníláìfí náà lè má mọ irú ìdààmú tí ó dé bá wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Nígbà tí o bá tọ àwọn ẹlòmíràn lọ láti wá àlàáfíà, ẹ lè tètè yanjú èdè àìyedè