Èéṣe tí A Fi Níláti Máa Dáríjini?
Ọ̀MỌ̀WÉ Ju tí ó tún jẹ́ òǹkọ̀wé, Joseph Jacobs ṣàpèjúwe nígbà kan rí pé ìdáríjì jẹ́ “èyí tí ó ṣòro tí ó sì ga jùlọ ninu gbogbo ẹ̀kọ́ ọ̀nà ìwà-híhù.” Ní tòótọ́, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ lati sọ pé, “Mo dáríjì ọ́.”
Ó dàbí ẹni pé, bí owó ni ìdáríjì rí. A lè ná an tàánú-tàánú ati ní fàlàlà lórí awọn ẹlòmíràn tabi kí a fi ìwà ahun kó o pamọ́ fún ara-ẹni. Èyí tí ó ṣáájú ni ọ̀nà Ọlọrun. A níláti mú ìwà níná an pẹlu ọ̀làwọ́ dàgbà nígbà tí ó bá kan ìdáríjì. Èéṣe? Nitori pe Ọlọrun fún èyí ní ìṣírí ati nitori pé ẹ̀mí ìgbẹ̀san, tí kìí dáríjini wulẹ̀ lè mú ọ̀ràn burú síi.
Awọn ọ̀rọ̀ tí a máa ń gbọ́ lemọ́lemọ́ ni pé: “N kìí jẹ́ kí orí mi gbóná; ṣugbọn mo máa ń gbẹ̀san!” Ó baninínújẹ́ pé, gbólóhùn yii jẹ́ ìlànà tí ń darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésí-ayé lónìí. Fún àpẹẹrẹ, obìnrin kan bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yodì fún ohun tí ó ju ọdún méje lọ nitori pé, gẹ́gẹ́ bí obìnrin naa ti sọ, “ó fi ẹ̀gbin oníyọ̀rọ̀ lọ̀ mi ń kò sì tíì dáríjì í lati ìgbà naa wá.” Ṣugbọn irú ìfinisínú bẹ́ẹ̀ kìí sábà tẹ́ ìfẹ́-ọkàn fún ìforóyaró lọ́rùn, nígbà tí a bá lò ó gẹ́gẹ́ bí ipa ìdarí lílágbára lati wá ẹ̀bẹ̀ lati ọ̀dọ̀ ẹni tí a fẹ̀sùnkàn tabi gẹ́gẹ́ bí ohun-ìjà lati fìyàjẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wulẹ̀ lè fa awuyewuye naa gùn síi, ní mímú kí kùnrùngbùn jíjinlẹ̀ jẹyọ. Bí a kò bá dẹ́kun àyípoyípo ìrora yii, agbára ìdarí lílágbára tí ìgbẹ̀san ní lè ba ipò-ìbátan ati ìlera ẹni pàápàá jẹ́.
Ewu tí Ń Bẹ Ninu Ẹ̀mí Àìnídàáríjì
Nígbà tí ẹnìkan bá jẹ́ aláìnídàáríjì, aáwọ̀ tí ń yọrísí máa ń dá másùnmáwo sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni, másùnmáwo lè jálẹ̀ sí awọn àìlera lílekoko. Dókítà William S. Sadler kọ̀wé pé: “Bíi ti dókítà kan, kò sí ẹni tí ó lè lóye lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ bí àrùn ati ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn tí a lè tọpasẹ̀ ní tààràtà dé ọ̀dọ̀ àníyàn, ìbẹ̀rù, aáwọ̀, . . . ìrònú tí kò sunwọ̀n ati ìgbésí-ayé oníwà àìmọ́ ti pọ̀ jáǹtirẹrẹ tó.” Bí ó ti wù kí ó rí, níti gidi, bawo ni ìpalára tí ìpòrúurùu ọkàn ń fà ṣe pọ̀ tó? Ìtẹ̀jáde ìṣègùn kan dáhùn pé: “Ìsọfúnni . . . fihàn pé ìdámẹ́ta ninu awọn aláìsàn agbàtọ́jú tí wọn lọ rí oníṣègùn ni àmì àrùn wọn jẹyọ tabi lekoko síi nitori pákáǹleke ọpọlọ.”
Bẹ́ẹ̀ni, kò dájú pé ìwà kíkorò, ìbínú, ati àránkàn kò léwu. Awọn ohun tí ń ṣàkóbá fún ìmọ̀lára wọnyi dàbí ìpẹtà tí ń mú kí ara ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan máa dógùn-ún díẹ̀díẹ̀. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ naa lè rí rèterète lóde, ṣugbọn ìbàjẹ́ kan ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀dà naa.
Èyí tí ó tún ṣe pàtàkì jù pàápàá ni pé, kíkọ̀ lati dáríjini nígbà tí ìdí bá wà fún fífi àánú hàn tún lè ṣe ìpalára fún wa nípa tẹ̀mí. Lójú Jehofa Ọlọrun, a lè dàbí ẹrú inú àkàwé Jesu. Ọ̀gá ẹrú naa dárí gbèsè rẹpẹtẹ jì í. Síbẹ̀, nígbà tí ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó dárí gbèsè tí ó kéré ní ìfiwéra ji oun, ó rorò kò sì fi ìdáríjì hàn. Jesu mú un ṣe kedere pé bí awa bákan naa kò bá múratán lati dáríjini, Jehofa yoo kọ̀ lati dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Matteu 18:21-35) Nítorí náà bí a bá jẹ́ aláìnídàáríjì, a lè pàdánù ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ tónítóní wa níwájú Ọlọrun ati ìrètí wa fún ọjọ́-ọ̀la pẹlu! (Fiwé 2 Timoteu 1:3.) Nígbà naa, kí ni a lè ṣe?
Kọ́ Lati Dáríjini
Inú ọkàn-àyà ni ìdáríjì tòótọ́ ti ń wá. Ó ní ninu fífi àṣìṣe ẹnìkan tí ó ṣẹni jì í kí á sì jáwọ́ ninu ìfẹ́-ọkàn èyíkéyìí lati foróyaró. Nipa bẹ́ẹ̀, a fi ìdájọ́-òdodo ìkẹyìn ati ẹ̀san tí ó bá ṣeéṣe lé Jehofa lọ́wọ́.—Romu 12:19.
Bí ó ti wù kí ó rí, a gbọ́dọ̀ ṣàkíyèsí pé, níwọ̀n bí ‘ọkàn ènìyàn ti kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, tí ó sì burú jáyì,’ kìí fi ìgbà gbogbo fẹ́ lati dáríjini àní nígbà tí ó bá yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. (Jeremiah 17:9) Jesu fúnraarẹ̀ wí pé: “Lati inú ọkàn ni ìrò búburú ti í jáde wá, ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè, ẹ̀rí èké, ati ọ̀rọ̀ búburú.”—Matteu 15:19.
A dúpẹ́ pé, ọkàn-àyà wa ṣe é dálẹ́kọ̀ọ́ lati ṣe ohun tí ó tọ̀nà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí a nílò gbọ́dọ̀ wá lati orísun kan tí ó ga ju tiwa lọ. A kò lè dá a ṣe. (Jeremiah 10:23) Onipsalmu tí a mísí látọ̀runwá mọ èyí dájú ó sì gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọrun. Ó bẹ Jehofa ninu àdúrà pé: “Máa kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Mú òye ọ̀nà ẹ̀kọ́ rẹ yé mi.”—Orin Dafidi 119:26, 27.
Gẹ́gẹ́ bí psalmu mìíràn ti sọ, Ọba Dafidi ti Israeli ìgbàanì wá ‘lóye ọ̀nà’ Jehofa. Ó nírìírí rẹ̀ ní tààràtà ó sì kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. Nipa bẹ́ẹ̀, oun lè sọ pé: “Oluwa ni aláàánú ati olóore, ó lọ́ra àtibínú, ó sì pọ̀ ní àánú. Bí baba ti í ṣe ìyọ́nú sí awọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni Oluwa ń ṣe ìyọ́nú sí awọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.”—Orin Dafidi 103:8, 13.
Ó yẹ kí a kẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣe. Kí a fi tàdúrà-tàdúrà kẹ́kọ̀ọ́ nipa àpẹẹrẹ pípé ti Ọlọrun nipa ìdáríjì, ati ti Ọmọkùnrin rẹ̀ pẹlu. Nipa bayii, a lè kọ́ lati máa dáríjini lati inú ọkàn-àyà wá.
Síbẹ̀, awọn kan lè béèrè pé: Kí ni nipa ti ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo? Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ha yẹ kí a dárí rẹ̀ jini bí?
Wíwá Ọ̀nà Lati Wàdéédéé
Nígbà tí a bá ti hùwà láìfí lọ́nà tí ń múnikẹ́dùn gidigidi sí ẹnìkan, ìrora rẹ̀ lè jẹ́ èyí tí ó pọ̀ gidigidi. Èyí sábà máa ń jẹ́ òtítọ́ nígbà tí ẹnìkan bá jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan tí ó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ bíbaninínújẹ́. Awọn kan tilẹ̀ lè ṣe kàyéfì pé, ‘Bawo ni mo ṣe lè dáríji ẹnìkan tí ó dà mí lọ́nà rírorò tí ó sì bà mí lọ́kàn jẹ́?’ Níti ọ̀ràn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tí ó lè yẹ fún ìyọlẹ́gbẹ́, ó lè béèrè pé kí òjìyà ìpalára naa fi ìmọ̀ràn Matteu 18:15-17 sílò.
Ohun yówù kí ọ̀ràn naa jẹ́, pupọ lè kù sí ọwọ́ olùṣe láìfí naa. Lati ìgbà tí ó ti hùwà àìtọ́ naa a ha ti rí ẹ̀rí èyíkéyìí tí ó fi ìrònúpìwàdà àtọkànwá hàn bí? Ẹlẹ́ṣẹ̀ naa ha ti yípadà bí, boya tí ó tilẹ̀ ti gbìyànjú lati ṣe awọn àtúnṣe gidi? Lójú Jehofa irú ìrònúpìwàdà bẹ́ẹ̀ jẹ́ kọ́kọ́rọ́ kan sí ìdáríjì àní ninu ọ̀ràn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó múni bẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ nítòótọ́ pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, Jehofa dáríji Manasse, ọ̀kan lára awọn ọba tí ó burú jùlọ ninu ìtàn Israeli. Lórí ìpìlẹ̀ wo? Ọlọrun ṣe bẹ́ẹ̀ nitori pé Manasse rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ níkẹyìn tí ó sì ronúpìwàdà kúrò ninu awọn ọ̀nà rẹ̀ bíburú jáyì.—2 Kronika 33:12, 13.
Ninu Bibeli, ojúlówó ìrònúpìwàdà wémọ́ yíyí ìwà padà tọkàn-tọkàn, kíkábàámọ̀ látọkànwá lórí awọn ìwà àìtọ́ tí ẹnìkan ti hù. Níbi tí ó bá ti yẹ tí ó sì ṣeéṣe, ìsapá lati san àsandípò fún òjìyà ìpalára ẹ̀ṣẹ̀ naa máa ń bá ìrònúpìwàdà rìn. (Luku 19:7-10; 2 Korinti 7:11) Jehofa kìí dáríjini níbi ti kò bá ti sí irú ìrònúpìwàdà bẹ́ẹ̀.a Síwájú síi, Ọlọrun kò retí pé kí awọn Kristian dáríji awọn wọnnì tí a ti là lóye nipa tẹ̀mí rí ṣugbọn tí wọn wá ń mọ̀ọ́mọ̀ hùwà àìtọ́, láìronúpìwàdà nísinsìnyí. (Heberu 10:26-31) Ninu awọn ọ̀ràn tí ó légbákan, ó lè ṣàìyẹ lati dáríjini.—Orin Dafidi 139:21, 22; Esekieli 18:30-32.
Yálà ìdáríjì ṣeéṣe tabi bẹ́ẹ̀kọ́, òjìyà ìpalára ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan lè fẹ́ lati gbé ìbéèrè mìíràn yẹ̀wò pé: Mo ha níláti jẹ́ kí ọkàn mi túbọ̀ pòrúurúu, kí n sì máa jẹ́ kí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ kí ó sì máa mú mi bínú gidigidi, títí tí ọ̀ràn naa yoo fi yanjú pátápátá bí? Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀wò. Ọkàn ọba Dafidi bàjẹ́ gidigidi nígbà tí balógun rẹ̀, Joabu, pa Abneri ati Amasa, “ọkùnrin méjì tí ó ṣe olódodo, tí ó sàn ju oun tìkáraarẹ̀ [Joabu] lọ.” (1 Awọn Ọba 2:32) Dafidi sọ ìbínú rẹ̀ jáde kò sì sí iyèméjì pé ó sọ ọ́ fún Jehofa ninu àdúrà. Ṣugbọn, nígbà tí ó ṣe, ó dàbí ẹni pé ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí Dafidi ní rọlẹ̀. Ìbínú naa kò bò ó mọ́lẹ̀ títí dí ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀. Dafidi tilẹ̀ ń bá a nìṣó ní bíba Joabu ṣiṣẹ́ pọ̀, ṣugbọn oun kò wulẹ̀ dáríji panipani aláìronúpìwàdà yii. Dafidi rí sí i pé ni àbárèbábọ̀ a ṣe ìdájọ́-òdodo.—2 Samueli 3:28-39; 1 Awọn Ọba 2:5, 6.
Ó lè gba ọ̀pọ̀ àkókò ati iṣẹ́ kí awọn wọnnì tí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo ẹlòmíràn bà lọ́kàn jẹ́ tó lè kó ìbínú wọn àkọ́kọ́ kúrò lọ́kàn. Ọ̀nà ìṣèwòsàn naa lè túbọ̀ rọrùn nígbà tí olùṣe láìfí naa bá mọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ronúpìwàdà. Bí ó ti wù kí ó rí, aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan tí a ṣẹ̀ sí gbọ́dọ̀ lè rí ìtùnú ati ìrọra ninu ìmọ̀ rẹ̀ nipa ìdájọ́-òdodo ati ọgbọ́n Jehofa ati ninu ìjọ Kristian, láìka ipa ọ̀nà olùṣe láìfí naa sí.
Tún mọ̀ dájú, pé, nígbà tí o bá dáríji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan, èyí kò túmọ̀sí pé iwọ ń gbojúfún ẹ̀ṣẹ̀ naa. Fún awọn Kristian, ìdáríjini túmọ̀sí fífi pẹlu ìgbẹ́kẹ̀lé fi ọ̀ràn naa lé Jehofa lọ́wọ́. Oun ní Onídàájọ́ òdodo fún gbogbo àgbáyé, oun yoo sì mú ìdájọ́-òdodo ṣẹ ní àkókò tí ó tọ́. Èyí yoo ní ninu ṣíṣe ìdájọ́ awọn aládàkàdekè “awọn àgbèrè ati awọn panṣágà.”—Heberu 13:4.
Awọn Àǹfààní Dídáríjini
Onipsalmu naa Dafidi kọrin pé: “Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o sì múra ati dáríjì; o sì pọ̀ ní àánú fún gbogbo awọn tí ń képè ọ́.” (Orin Dafidi 86:5) Iwọ ha “múra ati dáríjì” bí Jehofa ti ń ṣe? Awọn àǹfààní rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, dídáríji awọn ẹlòmíràn ń mú ipò ìbátan sunwọ̀n síi. Bibeli rọ awọn Kristian pé: “Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yin, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríji ara yin, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ninu Kristi ti dáríjì yin.”—Efesu 4:32.
Èkejì, ìdáríjì máa ń mú àlàáfíà wá. Èyí kìí wulẹ̀ ṣe àlàáfíà pẹlu ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni ṣugbọn àlàáfíà inú lọ́hùn-ún pẹlu.—Romu 14:19; Kolosse 3:13-15.
Ẹ̀kẹta, dídáríji awọn ẹlòmíràn ń ṣèrànwọ́ fún wa lati rántí pé awa fúnraawa nílò ìdáríjì. Bẹ́ẹ̀ni, “gbogbo ènìyàn ni ó sáà ti ṣẹ̀, tí wọn sì kùnà ògo Ọlọrun.”—Romu 3:23.
Lákòótán, dídáríji awọn ẹlòmíràn ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ kí Ọlọrun bà lè dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Jesu wí pé: “Nitori bí ẹyin bá fi ẹ̀ṣẹ̀ awọn ènìyàn jì wọn, Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yoo fi ẹ̀ṣẹ̀ ti yín jì yín.”—Matteu 6:14.
Ronú nipa ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó ti lè gba Jesu lọ́kàn ní ọ̀sán ọjọ́ tí yoo kú. Awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù, ati ní pàtàkì ìwàtítọ́ rẹ̀ sí Jehofa jẹ ẹ́ lógún. Síbẹ̀, nígbà tí ó ń jìyà rírorò lórí igi oró pàápàá, kí ni oun sọ̀rọ̀ nipa rẹ̀? Díẹ̀ lára awọn ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn rẹ̀ ní pé, “Baba, dáríjì wọn.” (Luku 23:34) A lè ṣe àfarawé àpẹẹrẹ pípé Jesu nipa dídáríji ẹnìkínní-kejì lati ọkàn wá.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ṣugbọn, Jehofa tún ń gbé awọn kókó abájọ mìíràn yẹ̀wò nígbà tí ó bá ń gbèrò yálà lati dáríjini. Fún àpẹẹrẹ, bí olùṣe láìfí kan kò bá mọ awọn ọ̀pá ìdíwọ̀n Ọlọrun, irú àìmọ̀kan bẹ́ẹ̀ lè dín ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kù. Nígbà tí Jesu rọ Baba rẹ̀ lati dáríji awọn tí ó ṣekú pa á, ó hàn gbangba pé Jesu ń sọ̀rọ̀ nipa awọn ọmọ-ogun Romu tí wọn pa á. Wọn “kò mọ ohun tí wọn ń ṣe,” níwọ̀n bí wọn kò ti mọ ẹni tí ó jẹ́ nítòótọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, awọn aṣáájú ìsìn tí wọn wà lẹ́yìn ìṣekúpani naa jẹ̀bi tí ó pọ̀ gan-an—ìdáríjì kò sì ṣeéṣe, fún pupọ lára wọn.—Johannu 11:45-53; fiwé Iṣe 17:30.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Iwọ ha lóye kókó àkàwé Jesu nipa ẹrú aláìnídàáríjì naa bí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Dídáríji awọn ẹlòmíràn ń mú ipò ìbátan sunwọ̀n síi ó sì ń mú ayọ̀ wá