ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 9/15 ojú ìwé 8-9
  • Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Nigeria

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Nigeria
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ọ̀dọ́ Ń Nàgà fún Ṣíṣe Aṣáájú-Ọ̀nà
  • Fídíò ati Gbọ̀ngàn Ìjọba
  • Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Eto-ajọ ti Ó Wà Lẹhin Orukọ Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • A Bù Kún Ìdánúṣe Tó Lò
    Jí!—2002
  • Ipa Tí Àwọn Fídíò Tá A Fi Ń Jẹ́rìí Ń Ní Lórí Àwọn Èèyàn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • A Nílò Àwọn Arákùnrin Púpọ̀ Sí i Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 9/15 ojú ìwé 8-9

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Nigeria

NÍ ibi títẹ̀ kọrọdọ ní ìsàlẹ̀ ibi tí ilẹ̀ Africa ti yọ gọnbu ni Nigeria múlé sí. Ó wà ní ibi ìyawọlẹ̀ Gulf of Guinea, ní ọ̀gangan àríwá ìlà agbedeméjì ìbú ayé tí ó sì ní awọn olùgbé tí ó lé ní million 88.a

Ní awọn ọdún iṣẹ́-ìsìn méjì tí ó kọjá, ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní Nigeria ti fún awọn ọ̀dọ́ ní àkànṣe àfiyèsí. Ìwádìí tí a ṣe káàkiri ìjọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fihàn pé ìpín 80 ninu ọgọ́rùn-⁠ún lára awọn tí wọn bẹ̀rẹ̀ ìwàásù ìhìnrere ní Nigeria ní 1992 jẹ́ ọmọ ọdún 10 sí 20. Lára awọn wọnnì tí wọn ṣe ìrìbọmi láàárín ọdún yẹn, ìpín 63 ninu ọgọ́rùn-⁠ún jẹ́ ọlọ́jọ́-orí kan naa pẹlu awọn wọ̀nyẹn.

Awọn Ọ̀dọ́ Ń Nàgà fún Ṣíṣe Aṣáájú-Ọ̀nà

Ọ̀pọ̀ awọn ọ̀dọ́ ń wọnú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Aṣáájú-ọ̀nà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hannah sọ pé: “Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí n jáde ilé-ẹ̀kọ́, mo bẹ awọn tí ń lọ sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà wò, níbi tí mo ti bá awọn arábìnrin àgbàlagbà méjì pàdé. Mo ronú lọ́kàn araàmi pé, ‘Bí awọn méjì wọ̀nyẹn bá lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, èéṣe tí èmi kò fi lè ṣe é?’

“Nitori naa nígbà tí mo jáde ilé-ẹ̀kọ́, mo di aṣáájú-ọ̀nà. Ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn naa mo bá Josephine ẹni ọdún 26 padé, tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà. Ó wí pé: ‘Ènìyàn burúkú ni ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ẹ kìí ṣe Kérésìmesì tabi lo oògùn ìṣọ́ra.’ Mo dá a lóhùn pé bí ó bá gbà mí láyè lati kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu oun, yoo lóye ìdí tí a kìí fi ṣe awọn nǹkan wọ̀nyẹn. Ó gbà kí n padà wá. Kò pẹ́ kò jìnnà ó bẹ̀rẹ̀ sí wá sí awọn ìpàdé ó sì ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà ninu ìgbésí-ayé rẹ̀. Ó ṣe ìrìbọmi ní December 1990. Lati August 1991, Josephine ti ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tí ó lọ sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà ní èṣí, ó fi mí han awọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bí ìyá oun nipa tẹ̀mí!”

Fídíò ati Gbọ̀ngàn Ìjọba

Ọ̀kan lára awọn fídíò Society ṣèrànwọ́ fún ìjọ kékeré kan lati rí ilẹ̀ fún Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní wíwá ilẹ̀ kan tí wọn yoo rà, awọn arákùnrin mẹ́rin tọ Onojie lọ, baálẹ̀ agbègbè naa. Ó fi gurè ilẹ̀ kan lọ̀ wọn fún 20,000 naira ($1,025, owó U.S.). Apá ìjọ naa kò ká iye owó yẹn, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé akéde 17 péré ni ó wà lati gbọ́bùkátà iṣẹ́ ìdáwọ́lé naa. Onojie wí pé oun yoo máa ronú nipa ilẹ̀ mìíràn.

Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn naa, ọ̀kan lára awọn alàgbà ìjọ naa ṣèbẹ̀wò sí ilé Onojie. Onojie naa ń wo fídíò ìwúyè rẹ̀ lọ́wọ́. Alàgbà naa wí pé: “Mo ní fídíò kan tí emi yoo fẹ́ kí ẹ wò. A ń pè é ní Jehovah’s Witnesses​—⁠The Organization Behind the Name.”

Nígbà tí ó ṣe, alàgbà naa bi Onojie nipa èrò rẹ̀ lórí fídíò naa. Onojie fèsì pé, “Ìgbà márùn-⁠ún ni mo wo fídíò naa.” Alàgbà naa rán Onojie naa létí nipa Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó ti wò ninu fídíò naa ó sì ṣàlàyé pe ìjọ àdúgbò naa fẹ lati kọ́ irú èyí tí ó rí bẹ́ẹ̀. Ó wá béèrè bí ìjọ naa bá lè ra ilẹ̀ kan tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ gurè ilẹ̀ kékeré kan tí ó jẹ́ tiwọn. Onojie naa fèsì padà pé: “Mo ronú nipa ohun kan naa, ní alẹ́ àná nígbà tí mo wo fídíò yẹn tán.” Láìfa ọ̀rọ̀ gùn, ó wọn mítà mẹ́fà síhà ibi ilẹ̀ ilé lílò ti ìjọ naa wà. Ó wí pé, “Ẹ fọwọ́ mú eléyìí. Ní òòró, ẹ lè mú un pọ̀ tó bí ẹ bá ṣe fẹ́. Ẹ ṣe ìwé rẹ̀, emi yoo sì bu ọwọ́ lù ú.”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé síwájú síi, wo 1994 Calendar of Jehovah’s Witnesses.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NIPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ

Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1993

GÓŃGÓ IYE AWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 174,582

ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 507

AWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 473,245

ÌPÍNDỌ́GBA AWỌN AKÉDE TÍ WỌN JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 19,777

ÌPÍNDỌ́GBA AWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 242,028

IYE TÍ Ó ṢÈRÌBỌMI: 8,888

IYE AWỌN ÌJỌ: 3,289

Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: BENIN CITY, EDO STATE

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́