A Nílò Àwọn Arákùnrin Púpọ̀ Sí i Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà
1 Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá láti “máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọr. 15:58) Fún ọ̀pọ̀, èyí túmọ̀ sí títẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Ní oṣù August tí ó kọjá, iye tí ó lé ní 460 àwọn ará ni ó dara pọ̀ mọ́ òtú aṣáájú ọ̀nà ní Nàìjíríà!
2 Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, iye tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní orílẹ̀-èdè yìí ní ó jẹ́ arábìnrin. (Sm. 68:11) Ẹ wo irú ìdùnnú tí yóò jẹ́ fún ìjọ bí àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i bá lè dara pọ̀ mọ́ òtú àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún! (Sm. 110:3) Ó yéni pé ọ̀pọ̀ arákùnrin ní láti bojú tó àwọn ojúṣe pàtàkì ti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ti ìdílé. Àwọn mìíràn pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́ kára láti bojú tó àìní tí ìjọ ní nípa tẹ̀mí. A mọrírì àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, tí wọ́n ń lo ara wọn tokunratokunra nítorí Ìjọba náà.—1 Tim. 4:10.
3 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ha ṣeé ṣe fún púpọ̀ sí i lára ẹ̀yin arákùnrin láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà bí? Bí aya rẹ bá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, o ha lè dara pọ̀ mọ́ ọn bí? Bí o bá ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, ìwọ kò ha ní gbà pé kò sí ọ̀nà tí ó dára jù tí o lè gbà lo àkókò rẹ ju nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lọ? Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣetán ní ilé ẹ̀kọ́, o ha ti ronú jinlẹ̀ tàdúràtàdúrà lórí títẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí òkúta àtẹ̀gùn kan sí àfikún àǹfààní?—Efe. 5:15-17.
4 Arákùnrin kan ta òwo rẹ̀ tí ń gbèrú, ó sì gba iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ kí ó baà lè ṣe aṣáájú ọ̀nà. Nítorí àpẹẹrẹ àtàtà tí ó fi lélẹ̀, mẹ́ta nínú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin di aṣáájú ọ̀nà, gbàrà tí wọ́n ṣe tán ní ilé ẹ̀kọ́. Èyí ẹ̀kẹrin ń hára gàgà láti dara pọ̀ mọ́ wọn. A ti bù kún arákùnrin yìí àti ìdílé rẹ̀ ní jìngbìnnì.
5 A Ṣí Ìlẹ̀kùn Ńlá Sílẹ̀: Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lè ṣí “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” sílẹ̀. (1 Kọr. 16:9) A lè lo àwọn arákùnrin tí wọ́n ń ṣe aṣáájú ọ̀nà gan-an nínú ìjọ. Ìgbòkègbodò onítara nínú pápá ń fi kún ìdúró wọn nípa tẹ̀mí, ó sì ń pa kún ìtẹ̀síwájú wọn ní ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún ọdún kan, ìbùkún lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà ń bẹ níbẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jẹ́ àpọ́n, lè nàgà láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Àwọn arákùnrín lè tóótun nígbẹ̀yìngbẹ́yín fún iṣẹ́ arìnrìn àjò. Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà máa ń ṣí ìlẹ̀kùn sílẹ̀ sí àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn títóbi lọ́lá wọ̀nyí nínú ètò àjọ Jèhófà.
6 Àwọn arákùnrin tí wọ́n lè wáyè láti ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé lè ní ayọ̀ gíga lọ́lá, tí ń wá láti inú fífúnni tí ń pọ̀ sí i.—Ìṣe 20:35.