Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà
“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.”—KÓL. 3:13.
1, 2. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu kí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa bí ara rẹ̀ bóyá òun ní ẹ̀mí ìdáríjì?
BÍBÉLÌ jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀ṣẹ̀ àti ohun tó máa ń ṣe bí ẹnì kan bá dẹ́ṣẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìdáríjì. Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a kọ́ nípa ohun tí Dáfídì àti Mánásè ṣe tó mú kí Jèhófà dárí jì wọ́n. Wọ́n kábàámọ̀, ọkàn wọn sì bà jẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ṣe. Wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n kọ ìwà búburú wọn sílẹ̀, wọ́n sì ronú pìwà dà látọkàn wá. Nítorí èyí, Jèhófà dárí jì wọ́n.
2 A ti rí bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini. Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ káwa náà máa dárí jini. Ká sọ pé ìbátan rẹ wà lára àwọn tí Mánásè hùwà ìkà sí, ǹjẹ́ o máa dárí jì í? Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì lónìí torí pé à ń gbé nínú ayé táwọn èèyàn ò ti bọ̀wọ̀ fún òfin, tí wọ́n ń hùwà ipá, tí wọ́n sì ń hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Torí náà, kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni kan ní ẹ̀mí ìdáríjì? Bí wọ́n bá kàn ẹ́ lábùkù tàbí tí wọ́n bá rẹ́ ọ jẹ, kí ni kò ní jẹ́ kó o ṣìwà hù? Báwo lo ṣe lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, kó o sì múra tán láti dárí jini?
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ NÍ Ẹ̀MÍ ÌDÁRÍJÌ
3-5. (a) Ìtàn wo ni Jésù sọ káwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ lè ronú lórí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ní ẹ̀mí ìdáríjì? (b) Kí la lè rí kọ́ nínú ìtàn ẹrú tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Mátíù 18:21-35?
3 A gbọ́dọ̀ múra tán láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, yálà wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyẹn á mú kí àwa, àwọn ìbátan wa, àwọn ọ̀rẹ́ wà àtàwọn míì lè máa bára wa gbé ní àlàáfíà. A ó sì tún wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà. Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwa Kristẹni máa dárí ji àwọn èèyàn, bó ti wù kí wọ́n máa ṣẹ̀ wá lemọ́lemọ́ tó. Kí Jésù lè jẹ́ ká rí bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé ká ní ẹ̀mí ìdáríjì, ó sọ ìtàn ẹrú kan tó jẹ ọ̀gá rẹ̀ lówó.
4 Owó tí ẹrú náà jẹ ọ̀gá rẹ̀ pọ̀ débi pé bó bá fi ọ̀kẹ́ mẹ́jọ [160,000] ọdún ṣiṣẹ́, kò lè san gbèsè náà tán. Síbẹ̀, ọ̀gá rẹ̀ fagi lé gbèsè náà. Lẹ́yìn náà, ẹrú náà jáde lọ ó sì rí ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ ẹ́ ní owó téèyàn lè sàn pa dà tó bá fi nǹkan bí oṣù mẹ́tà àtààbọ̀ ṣiṣẹ́. Ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yìí bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe sùúrù fún òun, àmọ́ kò gbà, ńṣe ló ní kí wọ́n lọ sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Inú bí ọ̀gá wọn nígbà tó gbọ́ ohun tó ṣe. Ọ̀gá náà wá bi í pé: “Kò ha yẹ kí ìwọ . . . ṣàánú fún ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú ti ṣàánú fún ọ?” Èyí mú kí ọ̀gá wọn “fà á lé àwọn onítúbú lọ́wọ́, títí yóò fi san gbogbo gbèsè tí ó jẹ padà.”—Mát. 18:21-34.
5 Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù ń fi ìtàn yìí kọ́ wa? Ní ìparí ìtàn náà, ó sọ pé: “Ọ̀nà kan náà ni Baba mi ọ̀run yóò gbà bá yín lò pẹ̀lú bí olúkúlùkù yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà yín wá.” (Mát. 18:35) Ẹ̀kọ́ tí Jésù ń fi ìtàn yẹn kọ́ wa ni pé ìgbà gbogbo là ń dẹ́ṣẹ̀ torí pé a jẹ́ aláìpé, kò sì sí bá a ṣe lè pá àwọn òfin Jèhófà mọ́ láìkù síbì kan. Síbẹ̀, Ọlọ́run ṣe tán láti dárí jì wá, kó sì pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́ pátápátá. Torí náà, bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, ó pọn dandan pé kó máa dárí ji àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè pé: “Bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú; nígbà tí ó jẹ́ pé, bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.”—Mát. 6:14, 15.
6. Kí nìdí tí kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti dárí jini?
6 O lè gbà pé òótọ́ ló yẹ ká máa dárí ji àwọn ẹlòmíì, ṣùgbọ́n kó o máa ronú pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí sì ni pé ó máa ń dùn wá gan-an báwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá. A lè bínú sí onítọ̀hún, a lè kà á sí ọ̀dàlẹ̀, a lè fẹ́ kó jìyà ohun tó ṣe tàbí ká fẹ́ láti gbẹ̀san. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé àwọn ò lè dárí ji onítọ̀hún láéláé. Bó bá jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ̀ nìyí, báwo lo ṣe lè ní ẹ̀mí ìdáríjì kó o bàa lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́?
MỌ OHUN TÓ Ń BÍ Ẹ NÍNÚ
7, 8. Kí ló lè mú kó o dárí ji ẹnì tó bá hùwà tí kò dára sí ẹ?
7 Ó máa ń dùn wá gan-an tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá tàbí tá a kàn ronú pé ó ṣẹ̀ wá. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa ìbínú, ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé: “Nígbà kan . . . tí inú bí mi gan-an, mo jáde kúrò nílé mo sì lérí pé mi ò tún ní pa dà wálé mọ́ láé. Oòrùn rọra ń tàn yẹ́ẹ́ bí mo ṣe ń rìn gba ojú ọ̀nà kékeré kan tí mo fẹ́ràn láti máa tọ̀. Torí pé ojú ọ̀nà náà pa rọ́rọ́ tó sì lẹ́wà, ara bẹ̀rẹ̀ sí í tù mí. Nígbà tó ṣe mo pa dà sílé, ó sì dùn mí gan-an pé mo jẹ́ kí inú bí mi tóyẹn.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin yìí fi hàn pé bí inú bá ń bí ẹ, ńṣe ni kó o ṣe sùúrù kó o sì ro ọ̀ràn náà síwá sẹ́yìn kó o má bàa ṣe ohun tó o máa kábàámọ̀ bó bá yá.—Sm. 4:4; Òwe 14:29; Ják. 1:19, 20.
8 Ká sọ pé inú ṣì ń bí ẹ lẹ́yìn tó o ti ṣe sùúrù ńkọ́? Gbìyànjú láti mọ ohun tó ń bí ẹ nínú. Ṣé nítorí pé ẹnì kan hùwà ìkà sí ẹ ni àbí torí pé wọ́n kàn ẹ́ lábùkù? Àbí ńṣe lo rò pé onítọ̀hún mọ̀ọ́mọ̀ ṣèkà fún ẹ? Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ohun tó ṣe burú tó ni? Tó o bá ronú lórí ọ̀ràn náà tó o sì mọ ohun tó ń bí ẹ nínú, wàá lè ronú kan àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó máa jẹ́ kó o yí èrò rẹ pa dà kó o lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Ka Òwe 15:28; 17:27.) Tó o bá ń ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ dípò bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ, á túbọ̀ máa rọrùn fún ẹ láti ní ẹ̀mí ìdáríjì. Èyí lè má rọrùn, àmọ́ ó máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ṣàyẹ̀wò “ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà [rẹ],” á sì mú kó o máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà tó máa ń dárí jini.—Héb. 4:12.
ṢÓ YẸ KÓ O GBÀ Á SÍ ÌBÍNÚ?
9, 10. (a) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá rò pé ẹnì kan ti ṣẹ̀ ọ́? (b) Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá ń fi ojú tó tọ́ wo nǹkan tó o sì ní ẹ̀mí ìdáríjì?
9 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń ṣẹlẹ̀ tó lè mú wa bínú. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń wa mọ́tò, àmọ́ tó kù díẹ̀ kí mọ́tò míì kọ lù ẹ́ ńkọ́, kí lo máa ṣe? Ó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn awakọ̀ tí inú bí débí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jà. Àmọ́, torí pé o jẹ́ Kristẹni, ó dájú pé o kò ní fẹ́ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.
10 Wo bí ì bá ṣe dára tó bó o bá ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Bóyá ńṣe nìwọ náà ò kọjú sí ibi tó ò ń lọ, kó o sì wá tipa bẹ́ẹ̀ pín nínú ẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀. Tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni nǹkan kan bà jẹ́ lára ọkọ̀ awakọ̀ kejì. Ohun tá a fẹ́ fà yọ nínú àpẹẹrẹ yìí ni pé ká máa ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó fà á táwọn èèyàn fi ṣe àṣìṣe. Ká gbà pé a ò lè mọ gbogbo ohun tó fà á, ká sì múra tán láti dárí jini. Ìwé Oníwàásù 7:9 sọ pé: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.” Má ṣe máa tètè gba nǹkan sí ìbínú. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń rò pé ńṣe ni ẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ̀ wá, àmọ́ tó jẹ́ pé àìpé ló fà á. Ó sì lè jẹ́ pé àwa fúnra wa la ò lóye ohun tó ṣẹlẹ̀. Bó o bá rò pé ńṣe ni ẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dáa tàbí ó sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí ẹ, má ṣe gbàgbé pé o kò lè mọ gbogbo ohun tó mú kí onítọ̀hùn ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, ṣe ni kó o múra tán láti dárí jì í. Bó o bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, inú rẹ máa dùn gan-an ni.—Ka 1 Pétérù 4:8.
‘KÍ ÀLÀÁFÍÀ YÍN PADÀ SỌ́DỌ̀ YÍN’
11. Ohun yòówù káwọn èèyàn ṣe sí wa tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí ló yẹ ká ṣe?
11 Báwo lo ṣe lè kó ara rẹ níjàánu bí ẹnì kan bá kàn ẹ́ lábùkù nígbà tó ò ń wàásù? Nígbà tí Jésù rán àwọn àádọ́rin [70] ọmọ ẹ̀yìn jáde láti lọ máa wàásù, ó sọ pé ní ilé kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá dé, kí wọ́n máa sọ pé: “Àlàáfíà fún ilé yìí o.” Ó wá fi kún un pé: “Bí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e. Ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò padà sọ́dọ̀ yín.” (Lúùkù 10:1, 5, 6) Inú wá máa ń dùn báwọn èèyàn bá tẹ́tí gbọ́rọ̀ wa, torí ìgbà yẹn ni wọ́n tó lè jàǹfààní nínú ìhìn rere tá à ń wàásù. Àmọ́, láwọn ìgbà míì, ìjà ni wọ́n máa ń gbé kò wá. Kí wá ló yẹ ká ṣe? Jésù sọ pé kí àlàáfíà wa pa dà sọ́dọ̀ wa. Ìyẹn ni pé, ohun yòówù kí àwọn tá a lọ wàásù fún ṣe sí wa, a kò gbọ́dọ̀ gbé ìbínú kúrò lọ́dọ̀ wọn. Tá a bá bínú torí pé wọ́n ṣe ohun tí a kò fẹ́ sí wa, kò sí bá a ṣe máa wà ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ.
12. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú Éfésù 4:31, 32, kí ló yẹ ká ṣe?
12 Máa sapá láti wà ní àlàáfíà ní gbogbo ìgbà, kì í ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nìkan. Bí ẹnì kan bá ní ẹ̀mí ìdáríjì, kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń gba ìgbàkugbà láyè tàbí pé ó máa ń fojú kéré ohun tó ń dun àwọn míì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń gbé ọ̀rọ̀ kúrò lọ́kàn táá sì máa bá a nìṣó láti wà ní àlàáfíà. Bí wọ́n bá hùwà tí kò dára sí àwọn kan, wọ́n kì í gbé e kúrò lọ́kàn, èyí kì í sì í jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Má ṣe jẹ́ kí ìbínú ba ayọ̀ rẹ jẹ́. Máa rántí pé kò sí bó o ṣe lè láyọ̀ tó o bá ń gbé ìbínú sọ́kàn. Torí náà, máa dárí jini!—Ka Éfésù 4:31, 32.
ÌWÀ TÓ WU JÈHÓFÀ NI KÓ O MÁA HÙ
13. (a) Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè “kó òkìtì ẹyín iná” lé ọ̀tá rẹ̀ lórí? (b) Bí ẹnì kan bá hùwà tí kò dáa sí wa, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá gbé e gbóná fún un?
13 Bí ẹnì kan bá hùwà tí kò dáa sí ẹ, o lè ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ fún irú ẹni bẹ́ẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “‘Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu; nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò máa kó òkìtì ẹyín iná lé e ní orí.’ Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:20, 21) Tí o kì í bá gbé e gbóná fún ẹni tó ṣe ohun tó bí ẹ nínú, o lè mú kí ẹni tí ìwà rẹ̀ burú jáì pàápàá yí pa dà, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó dáa. Bí ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ bá rí i pé o fòye bá òun lo, tó sì rí i pé o gba tòun rò, ó ṣeé ṣe kó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ìwà rere tó o hù á mú kó ronú nípa ìdí tí ìwà rẹ fi yàtọ̀.—1 Pét. 2:12; 3:16.
14. Bó ti wù kí ìwà tí ẹnì kan hù sí ẹ burú tó, kí nìdí tí kò fi yẹ kó o gbé e sọ́kàn?
14 Àwọn kan wà tí kò yẹ ká máa bá kẹ́gbẹ́. Lára irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ torí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọn kò sì ronú pìwà dà. Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá ti ṣe ohun tó dá ọgbẹ́ sí ẹ lọ́kàn, ó lè ṣòro gan-an fún ẹ láti dárí jì í. Kódà bó bá ronú pìwà dà, ohun tó ṣe fún ẹ ṣì lè máa dùn ẹ́. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o gbàdúrà sí Jèhófà kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o lè dárí ji oníwà àìtọ́ náà. Ó ṣe tán, kò sí bó o ṣe lè mọ ohun tó wà lọ́kàn onítọ̀hún tàbí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Jèhófà ló mọ̀ ọ́n. Òun ló mọ ohun tó wà ní kọ́lọ́fín inú ẹnì kọ̀ọ̀kan, ó sì máa ń mú sùúrù fún àwọn tó bá hùwà àìtọ́. (Sm. 7:9; Òwe 17:3) Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn. Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” (Róòmù 12:17-19) Ṣó tiẹ̀ tọ́ sí wa pé ká máa dá àwọn míì lẹ́jọ́? Rárá o. (Mát. 7:1, 2) Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ti Jèhófà ni ẹ̀san yóò sì gbẹ̀san.
15. Kí ló yẹ ká máa rántí nígbà táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá?
15 Bó bá ṣòro fún ẹ láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ọ́, àmọ́ tó ti ronú pìwà dà, ó máa dáa kó o rántí pé òun náà ní ohun tó ń bá a fínra. Aláìpé bíi tìẹ lòun náà. (Róòmù 3:23) Jèhófà máa ń fi àánú hàn sí gbogbo wa torí pé a jẹ́ aláìpé. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o máa gbàdúrà fún ẹni tó bá ṣẹ̀ ẹ́. Tá a bá ń gbàdúrà fún ẹni tó ṣẹ̀ wá, kò dájú pé a óò tún máa bínú sí i. Ó sì ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ Jésù pé a kò gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti bínú sí àwọn tó bá hùwà tí kò dáa sí wa. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.”—Mát. 5:44.
16, 17. Bí ẹnì kan bá ronú pìwà dà tí àwọn alàgbà sì gbà á pa dà kí ló yẹ kó o ṣe, kí sì nìdí?
16 Jèhófà ló yan àwọn alàgbà láti máa bójú tó ìwà àìtọ́ tó bá wáyé nínú ìjọ. Àwọn alàgbà kò ní òye tó jinlẹ̀ tó ti Ọlọ́run. Àmọ́ bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ń darí wọn, wọ́n máa ń sapá láti mú kí ìpinnu wọn bá ìlànà tó wà nínú Bíbélì mu. Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, ìpinnu wọn máa ń ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ojú tó fi wo ọ̀ràn náà.—Mát. 18:18.
17 Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa fara mọ́ ìpinnu táwọn alàgbà bá ṣe. Bí àwọn alàgbà bá gba ẹnì kan pa dà torí pé ó ti ronú pìwà dà, ǹjẹ́ o máa dárí ji onítọ̀hún kó o sì fi hàn pé o ṣì fẹ́ràn rẹ̀? (2 Kọ́r. 2:5-8) Èyí lè má rọrùn, pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ pé ìwọ tàbí ìbátan rẹ ló ṣẹ̀. Àmọ́, tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tó o sì gbà pé ọ̀nà tó tọ́ ló ń gbà bójú tó ọ̀ràn nínú ìjọ, wàá dárí ji onítọ̀hún.—Òwe 3:5, 6.
18. Àǹfààní wo ló máa jẹ́ tìrẹ tó o bá ní ẹ̀mí ìdáríjì?
18 Àwọn oníṣègùn ọpọlọ ti rí i nínú ìwádìí wọn pé ó dára kéèyàn máa dárí jini látọkànwá. Ara wa á máa yá gágá, torí pé a kò gbé ìbínú tó máa ń mú kéèyàn banú jẹ́ sọ́kàn. A sì máa ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn. Tí a kò bá ní ẹ̀mí ìdáríjì, a ò ní gbádùn ara wa, a ó máa níṣòro pẹ̀lú àwọn èèyàn, ọkàn wa ò ní balẹ̀, a ó sì máa kanra. Ṣùgbọ́n tá a bá ní ẹ̀mí ìdáríjì, a máa ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Baba wa ọ̀run, Jèhófà. Ìyẹn sì ni ìbùkún tó ga jù lọ tó máa jẹ́ tiwa.—Ka Kólósè 3:12-14.