Ẹ Máa Dárí Jini Látọkàn Wá
“Ọ̀nà kan náà ni Baba mi ọ̀run yóò gbà bá yín lò pẹ̀lú bí olúkúlùkù yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà yín wá.”—MÁTÍÙ 18:35.
1, 2. (a) Báwo lẹ́nì kan tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe fi ìmoore hàn fún Jésù? (b) Kókó wo ni Jésù sọ, nígbà tó ń fèsì?
ÀFÀÌMỌ̀ ni ò fi ni jẹ́ pé aṣẹ́wó paraku lobìnrin yìí, kì í ṣe ẹni tó yẹ ká rí nílé olùfọkànsin Ọlọ́run. Bó bá jẹ́ pé rírí i níbẹ̀ ya àwọn kan lẹ́nu, ohun tó ṣe gan-an tún bani lẹ́rù gidigidi. Obìnrin yìí lọ bá ọkùnrin kan tíwà rẹ̀ dára jù lọ, ó fi ìmoore hàn fún iṣẹ́ rẹ̀, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé rẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ ọkùnrin ọ̀hún, tó sì ń fi irun orí rẹ̀ nù ún.
2 Jésù ni ọkùnrin yẹn, kò lé obìnrin “tí a mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú ńlá náà,” bẹ́ẹ̀ ni kò sì jágbe mọ́ ọn pé kó wábi gbà. Ilé Símónì tó jẹ́ Farisí ni nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kò lè fara da ohun tí ń ṣẹlẹ̀ yìí mọ nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lobìnrin náà. Ni Jésù bá fèsì nípa sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin méjì tó jẹ ẹnì kan lówó. Ìkan nínú wọn jẹ gbèsè rẹpẹtẹ—gbèsè náà tó nǹkan bí owó tí lébìrà lè gbà lọ́dún méjì. Ìdá kan nínú mẹ́wàá owó yẹn ni èyí èkejì jẹ awínni náà—ìyẹn kò sì tó owó oṣù mẹ́ta. Nígbà tí kò sẹ́ni tó rí owó san nínú àwọn méjèèjì, ni awínni náà bá “dárí ji àwọn méjèèjì ní fàlàlà.” Táa bá ní ká wò ó dáadáa, ẹni táa dárí púpọ̀ jì ló yẹ kó fi ìfẹ́ hàn jù lọ. Lẹ́yìn tí Jésù fi hàn bí ìwà rere obìnrin yìí ṣe bá àkàwé náà mu, ó fi ìlànà yìí kún un pé: “Ẹni tí a dárí díẹ̀ jì, nífẹ̀ẹ́ díẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó wí fún obìnrin náà pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.”—Lúùkù 7:36-48.
3. Kí ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò nípa ara wa?
3 Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ, ‘Ká lémi lobìnrin yẹn tàbí ká lémi ló wà nípò tó wà, tẹ́nì kan ṣàánú mi, ǹjẹ́ n ò ní so àwọn ẹlòmíràn mú, tí máa ranrí pé n kò ní dárí jì wọ́n?’ O lè dáhùn pé, ‘Áà, ó tì o!’ Síbẹ̀, ǹjẹ́ ó dá ọ lójú pé o máa ń fẹ́ láti dárí jini? Ṣé ànímọ́ rẹ nìyẹn? Ǹjẹ́ o máa ń fínnúfíndọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, débi tí àwọn ẹlòmíràn fi lè máa pè ọ́ ní ẹlẹ́mìí ìdáríjì? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tó fi yẹ kí olúkúlùkù wa fún ọ̀ràn yìí láfiyèsí gidi, ká sì yẹ ara wa wò fínnífínní.
A Fẹ́ Ìdáríjì —A Sì Nawọ́ Rẹ̀ Sí Wa
4. Òótọ́ pọ́ńbélé wo ló yẹ ká gbà nípa àwa fúnra wa?
4 Gẹ́gẹ́ bíwọ náà ti mọ̀ dáadáa, aláìpé ni ọ́. Táa bá bi ọ́ pé, ṣe lóòótọ́ ni, kíá ni wàá gbà bẹ́ẹ̀ láìjanpata, tàbí kóo rántí ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Jòhánù 1:8 pé: “Bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan,’ a ń ṣi ara wa lọ́nà ni, òtítọ́ kò sì sí nínú wa.” (Róòmù 3:23; 5:12) Àmọ́ ṣá o, àwọn kan wà tó jẹ́ pé, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tí kò tiẹ̀ ṣeé gbọ́ sétí rárá, ló fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n, ká lá ò tiẹ̀ ká irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ ẹ lọ́wọ́, kò sí àní-àní pé, ọ̀pọ̀ ìgbà àti ọ̀pọ̀ ọ̀nà nìwọ pàápàá ti gbà ré àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run kọjá—tàbí tóo ti dẹ́ṣẹ̀. Àbírọ́ ni?
5. Èé ṣe tó fi yẹ ká fọpẹ́ fún Ọlọ́run?
5 Nítorí náà, ipò rẹ lè bá àpèjúwe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni mu, nígbà tó wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe yín àti nínú ipò àìdádọ̀dọ́ ẹran ara yín, Ọlọ́run sọ yín di ààyè pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ [Jésù]. Ó fi inú rere dárí gbogbo àṣemáṣe wa jì wá.” (Kólósè 2:13; Éfésù 2:1-3) Ṣàkíyèsí gbólóhùn náà, “dárí gbogbo àṣemáṣe wa jì wá.” Ìyẹn wé mọ́ ohun púpọ̀. Olúkúlùkù wa ló yẹ kó bẹ̀bẹ̀ bíi ti Dáfídì pé: “Nítorí orúkọ rẹ, Jèhófà, àní kí o dárí ìṣìnà mi jì, nítorí tí ó pọ̀ níye.”—Sáàmù 25:11.
6. Ìdánilójú wo ni a lè ní nípa Jèhófà àti ìdáríjì?
6 Báwo ló ṣe lè rí ìdáríjì, tàbí lọ́nà mìíràn, báwo ni ẹnikẹ́ni nínú wa ṣe lè rí ìdáríjì? Àṣírí kan ni pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń fẹ́ láti dárí jini. Ìyẹn jẹ́ ìkan lára ìwà rẹ̀. (Ẹ́kísódù 34:6, 7; Sáàmù 86:5) Abájọ́ tí Ọlọ́run fi ń retí pé, ká máa gbàdúrà sóun, ká máa bẹ̀bẹ̀ pé, kó jàre má ro èyí táa ṣe, kó dákun forí jì wá. (2 Kíróníkà 6:21; Sáàmù 103:3, 10, 14) Ó sì ti ṣètò fún ìpìlẹ̀ kan tó jẹ́ ti òfin, èyí tó fi lè nawọ́ irú ìdáríjì bẹ́ẹ̀ sí wa—ìyẹn ni ẹbọ ìràpadà Jésù.—Róòmù 3:24; 1 Pétérù 1:18, 19; 1 Jòhánù 4:9, 14.
7. Ọ̀nà wo ló yẹ ká gbà fara wé Jèhófà?
7 Bóo bá kíyè sí bí Ọlọ́run ṣe ń dárí jini, láìdìgbà táa bá rá bàbà tí-tí-tí, ìwọ pẹ̀lú yóò mọ bó ṣe yẹ kóo bá àwọn ẹlòmíràn lò. Èyí gan-an ni Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́, nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfésù 4:32) Kò sí iyè méjì pé lájorí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù wé mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú àpẹẹrẹ Ọlọ́run, nítorí ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sọ pé: “Nítorí náà, ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Ǹjẹ́ o rí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe so kọ́ra? Jèhófà Ọlọ́run dárí jì ọ́, nítorí náà—Pọ́ọ̀lù là á mọ́lẹ̀ pé—o ní láti fara wé E, kí o sì fi ‘ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí o máa dárí ji àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà.’ Ṣùgbọ́n, bi ara rẹ léèrè, ‘Ṣé mò ń ṣe bẹ́ẹ̀? Bí ò bá mọ́ mi lára, ǹjẹ́ mò ń sapá láti ri í pé ó mọ́ mi lára, ǹjẹ́ mò ń làkàkà láti lè fara wé Ọlọ́run ní ti dídárí jini?’
Ó Yẹ Ká Ṣiṣẹ́ Lórí Dídárí Jini
8. Kí ló yẹ ká mọ̀ nípa gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ wa?
8 Ì bá dára ká sọ pé nínú ìjọ Kristẹni, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan là ń ní láti fi ẹ̀mí ìdáríjì hàn. Àmọ́ òdìkejì èyí là ń rí. Lóòótọ́, àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ń gbìyànjú gan-an láti lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Jésù. (Jòhánù 13:35; 15:12, 13; Gálátíà 6:2) Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti fi ń sapá láti pa àwọn ìrònú, ọ̀rọ̀, àti ìwà tó wọ́pọ̀ nínú ayé burúkú yìí tì, títí di báa ti ń wí yìí, wọn ò tíì dẹ́kun ìsapá náà. Lóòótọ́, wọ́n fẹ́ fi ìwà tuntun hàn. (Kólósè 3:9, 10) Síbẹ̀síbẹ̀, a kò ní gbàgbé pé àwọn ènìyàn aláìpé ló wà nínú ìjọ jákèjádò ayé, àwọn náà ló sì wà nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan tó wà ládùúgbò wa. Táa bá wò ó lápapọ̀, a ó rí i pé wọ́n ti sàn ju bí wọ́n ti fìgbà kan jẹ́, àmọ́, síbẹ̀ aláìpé ni wọ́n.
9, 10. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí ó yà wá lẹ́nu bí ìṣòro bá dìde láàárín àwọn ará?
9 Nínú Bíbélì, Ọlọ́run dìídì sọ fún wa pé ká mọ̀ dájú pé àìpé tó wà lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lè jẹ yọ nínú ìjọ. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù táa kọ sínú Kólósè 3:13: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”
10 Lọ́nà tó gba àfiyèsí, níhìn-ín Bíbélì rán wa létí ìsopọ̀ tó wà láàárín dídárí tí Ọlọ́run ń dárí jì wá àti ojúṣe tiwa láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn, ó tún jẹ́ ká mọ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Èé ṣe tí èyí fi ṣòro? Nítorí Pọ́ọ̀lù sọ gbangba gbàǹgbà pé ẹnì kan lè ní “ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.” Ó mọ̀ pé ojú ò lè fẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kù. Kò sí àní-àní pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, àní láàárín àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ “ẹni mímọ́” pàápàá, ìyẹn ni àwọn ‘tí wọ́n ní ìrètí tí a fi pa mọ́ dè wọ́n ní ọ̀run.’ (Kólósè 1:2, 5) Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ ká wá rò pé nǹkan ò lè rí bẹ́ẹ̀ mọ́ lónìí, nígbà tó tiẹ̀ wá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni tòótọ́ kò sí lára àwọn tí ẹ̀rí fi hàn pé ẹ̀mí yàn láti jẹ́ “àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́”? (Kólósè 3:12) Nítorí náà, bó bá ṣẹlẹ̀ pé, nínú ìjọ wa, bí nǹkan ṣe ń lọ sí ò tẹ́ wa lọ́rùn, táa sì wá gbà pé nítorí nǹkan ti wọ́ níbì kan ló fà á—kò yẹ ká wá bẹ̀rẹ̀ sí fapá jánú nítorí àwọn ìwà àìtọ́ kan tó wáyé tàbí àwọn ìwà kan táa rò pé kò tọ́.
11. Kí ni ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù pe àfiyèsí wa sí?
11 Ọ̀rọ̀ Jákọ́bù, iyèkan Jésù, tún fi hàn pé a gbọ́dọ̀ retí pé bó ti wù kó rí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a ó dojú kọ ipò tí yóò béèrè pé ká dárí ji àwọn arákùnrin wa. “Ta ni nínú yín tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye? Kí ó fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ní owú kíkorò àti ẹ̀mí asọ̀ nínú ọkàn-àyà yín, ẹ má ṣe máa fọ́nnu, kí ẹ má sì máa purọ́ lòdì sí òtítọ́.” (Jákọ́bù 3:13, 14) “Owú kíkorò àti ẹ̀mí asọ̀” nínú ọkàn-àyà àwọn Kristẹni tòótọ́ kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ Jákọ́bù fi hàn kedere pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé ní ọ̀rúndún kìíní, yóò sì wáyé lónìí pẹ̀lú.
12. Ìṣòro wo ló dìde ní ìjọ Fílípì ìgbàanì?
12 Àpẹẹrẹ kan tó ṣẹlẹ̀ ni ti àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró táa mọ̀ dáadáa pé wọ́n lo gbogbo okun wọn láti bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́. O lè rántí pé o ti kà nípa Yúódíà àti Síńtíkè, àwọn mẹ́ńbà ìjọ Fílípì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn náà, Fílípì 4:2, 3 fi hàn pé aáwọ̀ kan wà láàárín wọn. Ṣé ọ̀rọ̀ òpònú, ọ̀rọ̀ tí kò fi ìgbatẹnirò hàn, ìrònú pé a fojú pa ìbátan ẹnì kan rẹ́ ló fa aáwọ̀ náà ni, àbí àwọn ohun mìíràn tó fi hàn pé wọ́n ń jowú ara wọn ló fà á? Ohun yòówù tó fà á, ọ̀ràn ọ̀hún gbóná débi pé Pọ́ọ̀lù gbọ́ sí i níbi tó wà lọ́hùn-ún ní Róòmù. Ó ṣeé ṣe kí àwọn méjèèjì yìí, tí wọ́n jẹ́ arábìnrin nípa tẹ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ sí bára wọn yodì, kó di pé, tí wọ́n bá dé ìpàdé, kí wọ́n máa ṣe bí ẹni pé wọn ò ríra wọn tàbí kí ọ̀kan máa sọ̀rọ̀ àìdáa nípa èkejì rẹ̀ fáwọn ọ̀rẹ́ wọn.
13. Kí ló jọ pé ó wáyé láàárín Yúódíà àti Síńtíkè, ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa?
13 Nínú ohun táa wí yìí, ǹjẹ́ a rí ohun tó fara pẹ́ ẹ lónìí, bóyá tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn kan nínú ìjọ rẹ tàbí tó jẹ́ pé ìwọ pàápàá ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kí irú ìṣòro yẹn wà dé àyè kan lónìí. Kí ni ṣíṣe? Nínú ọ̀ràn ti ìgbàanì, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn arábìnrin méjèèjì wọ̀nyẹn, ti wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ pé kí wọ́n “ní èrò inú kan náà nínú Olúwa.” Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti gbà láti jókòó sọ ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n lè yanjú ẹ̀, kí wọ́n fi hàn pé àwọn gbà láti dárí ji ara àwọn, kí wọ́n sì fara wé Jèhófà lóòótọ́ nípa fífi ẹ̀mí ìdáríjì hàn. Kò sídìí kankan láti rò pé aáwọ̀ tó wà láàárín Yúódíà àti Síńtíkè kò parí, àwa pẹ̀lú sì lè yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín wa. A lè fi irú ẹ̀mí ìdáríjì kan náà hàn lónìí, kí ọ̀ràn náà sì yanjú.
Ẹ Parí Aáwọ̀—Ẹ Máa Dárí Jini
14. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà ohun tó dáa jù ni pé ká gbàgbé aáwọ̀ náà?
14 Kí ló ń béèrè láti lè dárí jini nígbà tí aáwọ̀ bá wà láàárín ìwọ àti Kristẹni mìíràn? Ká kúkú sọjú abẹ níkòó, a kò lè sọ pé báyìí ni ká ṣe é, àmọ́, Bíbélì fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ tó lè ranni lọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn tó yè kooro. Ìmọ̀ràn pàtàkì ọ̀hún rèé—bó ti lẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn-ún fara mọ́, ká sì lò ó—ìyẹn ni pé, ká kúkú gbàgbé ọ̀ràn náà, ká mọ́kàn kúrò níbẹ̀ pátápátá. Lọ́pọ̀ ìgbà, tí aáwọ̀ bá wà, irú bó ṣe wà láàárín Yúódíà àti Síńtíkè, ẹnì kan a máa ronú pé ẹnì kejì ló jẹ̀bi tàbí pé onítọ̀hún gan-an ló dá wàhálà náà sílẹ̀. Níbi tọ́ràn bá ti rí báyìí, o lè máa rò pé Kristẹni yẹn ló jẹ̀bi tàbí pé òun gan-an ló jẹ̀bi jù. Síbẹ̀, ǹjẹ́ o kúkú lè gbójú fo ọ̀ràn náà, nípa dídárí jì í? Mọ̀ dájú, sì jẹ́ kò yé ọ pé, ká tiẹ̀ ní Kristẹni yẹn jẹ̀bi díẹ̀ tàbí tó jẹ́ pé òun ló jẹ̀bi gbogbo ọ̀ràn náà, ẹrù iṣẹ́ tìrẹ ni pé kóo gbàgbé ọ̀ràn náà, kóo forí jì í, kóo sì jẹ́ kó tán síbẹ̀.
15, 16. (a) Báwo ni Míkà ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà? (b) Kí ni ‘ríré tí Ọlọ́run ń ré ìṣìnà kọjá’ túmọ̀ sí?
15 Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé bí Ọlọ́run ṣe ń dárí jini la fẹ́ fara wé. (Éfésù 4:32–5:1) Ní ti ọ̀nà tí Òun ń gbà jẹ́ kí ọ̀ràn parí, wòlíì Míkà kọ̀wé pé: “Ta ni Ọlọ́run bí ìwọ, ẹni tí ń dárí ìrélànàkọjá jì, tí ó sì ń ré ìṣìnà àṣẹ́kù ogún rẹ̀ kọjá? Dájúdájú, òun kì yóò máa bá a lọ nínú ìbínú rẹ̀ títí láé, nítorí ó ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́.”—Míkà 7:18.
16 Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ‘ń ré ìṣìnà kọjá’, kò sọ pé kò lè rántí ìwà àìtọ́, kò sọ ọ́ dẹni tí iyè rẹ̀ ti ra. Gbé ọ̀ràn Sámúsìnì àti Dáfídì yẹ̀ wò, àwọn méjèèjì ló dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Ọlọ́run rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kódà lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti ṣẹ̀; ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ díẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí pé Jèhófà mú ká kọ wọn sínú Bíbélì. Síbẹ̀, Ọlọ́run wa tí ń dárí jini ṣàánú àwọn méjèèjì, ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ táa lè fara wé.—Hébérù 11:32; 12:1.
17. (a) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ré àṣìṣe, tàbí ohun táwọn ẹlòmíràn ṣe tó dùn wá kọjá? (b) Báa bá gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lé fara wé Jèhófà? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
17 Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti ‘ré ẹ̀ṣẹ̀ kọjá,’a àní gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti rọ̀ ọ́ léraléra láti ṣe. (2 Sámúẹ́lì 12:13; 24:10) Ṣé a lè fara wé Ọlọ́run nínú èyí, nípa gbígbà láti ré ohun tí kò tó nǹkan táwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa ṣe sí wa kọjá àti èyí tí wọ́n ṣe to dùn wá, nítorí tí wọ́n jẹ́ aláìpé? Gbà pé o wà nínú ọkọ̀ òfuurufú kan tó ń sáré geerege lórí ilẹ̀ kó tó gbéra. Yíyọjú tóo yọjú lójú fèrèsé ọkọ̀, lo bá rí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ń ṣe húù, ọ̀ọ́-bì, ọ̀ọ́-bì, bí ìgbà tọ́mọdé bá ń fínràn. O mọ̀ pé inú ló ń bí i, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ gan-an ló ń bá wí. Ó sì lè jẹ́ pé kò ronú kàn ọ́ rárá o. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, bí bàlúù náà ti ń pòòyì kó bàa lè fò lókè dáadáa, o ti ré obìnrin yìí kọjá ní tìrẹ, lo bá ń wò ó nísàlẹ̀-nísàlẹ̀, kò wá ju eèrà lọ mọ́. Láàárín wákàtí kan, ibi tóo ti fi jìnnà sí i ti tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùsọ̀, oò rí gbogbo húù, ọ̀ọ́-bì, ọ̀ọ́-bì tó ń ṣe lẹ́ẹ̀kan mọ́, oò rí gbogbo ìwà rẹ̀ tó ń bí ẹ nínú yẹn mọ́. Bákan náà, báa bá gbìyànjú láti fara wé Jèhófà, ká sì fi ọgbọ́n ré ìwà tẹ́nì kan hù tó dùn wá kọjá, ọ̀pọ̀ ìgbà ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè dárí jini. (Òwe 19:11) Lọ́dún mẹ́wàá síbi táa wà yìí tàbí táa bá fi máa lo igba ọdún nínú Ẹgbẹ̀rúndún tí ń bọ̀ yìí, ǹjẹ́ ìwà ẹ̀gàn náà kò ti ni di ohun tí kò tó nǹkan? Kí ló wá dé tóò fi gbójú fò ó?
18. Bó bá jọ pé ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa kò tíì kúrò lọ́kàn wa, ìmọ̀ràn wo la lè fi sọ́kàn?
18 Àmọ́ ṣá o, nígbà mìíràn, o ti lè gbàdúrà lórí ọ̀ràn kan, kóo sì gbìyànjú láti dárí ji onítọ̀hún, ṣùgbọ́n kóo rí i pé ọ̀ràn náà ò tán lọ́kàn rẹ. Kí wá ni ṣíṣe? Jésù rọni pé, ká lọ ba ẹni tí ọ̀ràn náà jọ dà wá pọ̀, ká sì gbìyànjú láti yanjú ọ̀ràn náà, kí àlàáfíà lè wà láàárín wa. “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mátíù 5:23, 24.
19. Ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní, èwo ló sì yẹ ká yẹra fún báa ti ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa?
19 Ó yẹ ká fiyè sí i pé, Jésù kó sọ pé kóo lọ bá arákùnrin rẹ, kóo lè fi yé e pé ìwọ ló jàre, òun ló sì jẹ̀bi. Ó lè jóun ló jẹ̀bi lóòótọ́. Àmọ́, àfàìmọ̀ ni kò fi jẹ́ pé ẹ̀yìn méjèèjì lẹ jẹ̀bi o. Bó ti wù kó rí, góńgó náà kò yẹ kó jẹ́ pé ká fipá mú ẹnì kejì láti fara mọ́ ohun táa bá sọ, kó lè máa pá kúbẹ́kúbẹ́ lọ́dọ̀ wa. Bó bá jẹ́ pé ọwọ́ tóo fi mú ìjíròrò náà nìyẹn, ó dájú pé ọ̀ràn náà ò ní yanjú. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, góńgó náà kò pọndandan pé kó jẹ́ láti tú gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn náà sílẹ̀ tàbí ká wá kó ẹjọ́ ohun táa rò pé onítọ̀hún ti ṣe sí wá kalẹ̀. Nígbà tẹ́ẹ bá jọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú ẹ̀mí ìfẹ́ Kristẹni, tó sì wá hàn pé àìgbọ́ra-ẹni-yé lásán ni olórí ohun tó fa aáwọ̀, ẹ̀yin méjèèjì lè gbìyànjú láti yanjú rẹ̀ pátápátá. Kódà, ká ní ẹ jọ jókòó sọ̀rọ̀ náà, ǹjẹ́ gbogbo ìgbà ló máa pọndandan pé kẹ́yin méjèèjì gbà pé ohun báyìí-báyìí ló fa aáwọ̀ náà, kí ọ̀rọ̀ tó lè yanjú? Ǹjẹ́ kò ní sàn jù, bí ìwọ pàápàá bá lè gbà pé lóòótọ́ ni ẹ̀yin méjèèjì fẹ́ sin Ọlọ́run wa tó ń forí jini? Nígbà tọ́ràn bá rí báyìí, ohun tí yóò dára jù fún ọ̀kọ̀ọ̀kan yín láti sọ látọkàn wá ni pé, “Dákun, máà bínú, àìpé ló fẹ́ fa aáwọ̀ sáàárín wa. Jọ̀wọ́, jẹ́ á gbàgbé ẹ̀.”
20. Kí lá lè rí kọ́ lára àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì?
20 Ẹ rántí pé aáwọ̀ wà láàárín àwọn àpọ́sítélì pàápàá, fún àpẹẹrẹ, aáwọ̀ wáyé nígbà tí àwọn kan lára wọn ń fẹ́ ipò ọlá. (Máàkù 10:35-39; Lúùkù 9:46; 22:24-26) Ìyẹn fa arukutu, àfàìmọ̀ lọkàn wọn ò gbọgbẹ́, tí wọn ò sì tutọ́ síra wọn lójú pàápàá. Àmọ́ wọ́n gbàgbé irú aáwọ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n tún jọ ń báṣẹ́ wọn lọ. Ọ̀kan lára wọn kọ̀wé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Ẹni tí yóò bá nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè, tí yóò sì rí àwọn ọjọ́ rere, kí ó kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu kúrò nínú ohun búburú àti ètè rẹ̀ kúrò nínú ṣíṣe ẹ̀tàn, ṣùgbọ́n kí ó yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí ó sì máa ṣe ohun rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.”—1 Pétérù 3:10, 11.
21. Ìmọ̀ràn jíjinlẹ̀ wo nípa ìdáríjì ni Jésù fún wa?
21 Níṣàájú, a kíyè sí apá kan nínú ohun tí a ń retí: Ọlọ́run ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ táa ti dá látẹ̀yìnwá jì wá, látàrí èyí, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ fara wé e, ká máa dárí ji àwọn ará wa. (Sáàmù 103:12; Aísáyà 43:25) Ṣùgbọ́n apá mìíràn tún wà nínú ohun tí a ń retí yìí. Lẹ́yìn tí Jésù kọ́ni bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà, ó wí pé: “Bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú.” Ọdún kan lẹ́yìn náà, ó tún ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ náà sọ, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní bí wọn ó ṣe máa gbàdúrà, ó ní: “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè.” (Mátíù 6:12, 14; Lúùkù 11:4) Lẹ́yìn náà, nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ kí Jésù kú, ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá sì dúró tí ẹ ń gbàdúrà, ẹ dárí ohun yòówù tí ẹ ní lòdì sí ẹnikẹ́ni jì í; kí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lè dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín pẹ̀lú.”—Máàkù 11:25.
22, 23. Báwo ni ìmúratán wa láti dárí jini ṣe lè nípa lórí ọjọ́ ọ̀la wa?
22 Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, báa ṣe ń retí pé kí Ọlọ́run máa dárí jì wá, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ṣe tán láti máa dárí ji ara wa. Nígbà tí aáwọ̀ bá wà láàárín Kristẹni méjì, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ rírí ìdáríjì Ọlọ́run kò ṣe pàtàkì ju fífi yé arákùnrin tàbí arábìnrin mi pé aláfojúdi ni, tó sì jẹ́ pé ọ̀ràn kékeré lásán, gbúngbùngbún tí kò tó nǹkan tàbí àìpé ẹ̀dá ni gbogbo rẹ̀ dá lé lórí?’ Ìwọ pẹ̀lú mọ ìdáhùn tó tọ́.
23 Àmọ́, bí ọ̀ràn náà bá ti wá kọjá aáwọ̀ tàbí gbúngbùngbún díẹ̀ láàárín ẹnì kan sí ẹnì kejì ńkọ́? Ibo la ti lè lo ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú Mátíù 18:15-18? Èyí la óò gbé yẹ̀ wò tẹ́ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ọ̀rọ̀ àfiwé tó jẹ̀ ti èdè Hébérù táa lò nínú Míkà 7:18 wá “láti inú ìwà arìnrìn-àjò kan tó kàn ń kọjá lọ ní tirẹ̀, tí kò mọ̀ pé ohun kan wà níbì kan, nítorí tí kò fiyè sí i. Kì í ṣe pé àpèjúwe yìí ń sọ pé, Ọlọ́run kì í kíyè sí ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn bá dá o, tàbí pé ó ń fojú kékeré wò ó tàbí pé o kà á sí ohun tí kò tó nǹkan, ṣùgbọ́n ohun tó ń sọ ni pé nínú àwọn ọ̀ràn kan, Ọlọ́run kì í kíyè sí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú èrò àtifìyàjẹni; nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ kò ní fìyà jẹni, ṣe ni yóò dárí jini.”—Onídàájọ́ 3:26; 1 Sámúẹ́lì 16:8.
Ṣé O Rántí?
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe fún wa ní àpẹẹrẹ táa lè tẹ̀ lé ní ti ìdáríjì?
◻ Kí ló yẹ ká rántí nípa àwọn táa jọ wà nínú ìjọ?
◻ Lọ́pọ̀ ìgbà, kí ló yẹ ká lè ṣe nípa àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan tàbí ohun kan tó dùn wá tẹ́nì kan ṣe sí wa?
◻ Bó bá pọndandan, kí la lè ṣe láti parí aáwọ̀ tó bá wà láàárín àwa àti arákùnrin wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bí aáwọ̀ bá wà láàárín ìwọ àti Kristẹni kan, gbìyànjú láti gbàgbé ẹ̀; nígbà tó bá yá, ọ̀ràn náà kò ní jọ ẹ́ lójú mọ́