Kí Ni Ojútùú Rẹ̀?
“ÈRÒ ìgbàgbọ́ tí ń gbalẹ̀ sí i wà pé ire aráyé, àti bóyá lílà á já wa gẹ́gẹ́ bí irú ẹ̀yà kan pàápàá, yóò sinmi lórí agbára wa láti lè mọ àwọn àrùn tí ń yọjú bọ̀. . . . Ibo ni àwa ì bá wà lónìí bí ó bá jẹ́ pé okùnfà àrùn tí afẹ́fẹ́ ń gbé kiri ni fáírọ́ọ̀sì HIV? Ìdánilójú wo ni a sì ní pé, èèràn kan tí ó jọ ọ́ kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ iwájú?” ni D. A. Henderson—tí ó kó ipa gíga nínú fífòpin sí àrùn olóde—wí fún àwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ní Geneva, Switzerland, ní 1993.
Báwo ni a ṣe lè mọ àwọn àrùn tí ń yọjú bọ̀? Ètò ìkìlọ̀ kan tí a ṣe ṣáájú àkókò náà nípa ìbẹ́sílẹ̀ àrùn ilẹ̀ olóoru ni a ṣe nípa ìsokọ́ra àwọn ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ 35 tí wọ́n jábọ̀ fún Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO). Síbẹ̀, ìwádìí kan tí a ṣe nípa àwọn ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ wọ̀nyí fi hàn pé, a kò rí tó ìdajì lára wọn tí ó ní ohun èèlò tí ó lè dá àrùn ìwúlé ọpọlọ ní ilẹ̀ Japan, fáírọ́ọ̀sì aṣenilemọ́lemọ́ àti ibà Rift Valley—tí gbogbo wọn jẹ àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí, mọ̀. Ìpín 56 nínú ọgọ́rùn-ún péré lára wọn ni ó lè dá àrùn ibà pọ́njú, fáírọ́ọ̀sì tí ẹ̀fọn ń gbé kiri, tí ń fa èébì, àìṣiṣẹ́-déédéé-ẹ̀dọ̀, àti ìṣẹ̀jẹ̀ sínú, mọ̀. Ní 1992, ó kéré tán àwọn ènìyàn 28 ni ibà pọ́njú pa ní Kenya, kí àwọn dókítà tó mọ okùnfà rẹ̀. Fún oṣù mẹ́fà, wọ́n lérò pé ibà lásán ni àwọn ń bá jà.
Àbùkù míràn tí ó wà nínú àwọn ètò ìwádìíkiri ni pé, wọn kò mọ ìgbà tí àwọn àrùn onífáírọ́ọ̀sì ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, fáírọ́ọ̀sì HIV lè sá pamọ́ sínú ẹnì kan, kí ó ran àwọn ẹlòmíràn, kí ó sì wá fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí àrùn AIDS ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àjàkáyé àrùn AIDS ti lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí yọjú lákòókò kan náà ní àgbáálá ilẹ̀ mẹ́ta, ó sì tètè ya bo 20 orílẹ̀-èdè míràn. Ó hàn gbangba pé, kò sí ìkófìrí kankan nípa ìyẹn!
Lójú àwọn ìṣòro náà, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣì ń wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára nípa àwọn àwárí pàtàkì àti ìlọsíwájú tí ó dájú pé yóò dé ní ọjọ́ iwájú. Ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ròyìn pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé, ìrètí dídára jù lọ fún ìlọsíwájú tòótọ́ ni àmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, lílo àwọn èròjà àjogúnbá nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì alààyè. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní àwọn ilé iṣẹ́ aṣàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè retí àtiṣẹ̀dá àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ń ṣèmújáde àwọn èròjà apakòkòrò, ìyẹn ni, ìran àwọn oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn tuntun tí a ń tọwọ́ ìlànà ìyípadà èròjà apilẹ̀ àbùdá darí.”
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn apá kan wà tí kò bára dé nípa èyí. Ìlànà ìyípadà èròjà apilẹ̀ àbùdá ti mú kí ó rọrùn láti ki àwọn apilẹ̀ àbùdá bọ inú fáírọ́ọ̀sì kan tí kò lè ṣèpalára, kí fáírọ́ọ̀sì náà lè gbé àwọn apilẹ̀ àbùdá lọ sára àwọn ènìyàn. A lè lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ yìí lọ́nà tí ó ṣàǹfààní, bóyá ní mímú ìṣèmújáde àwọn ohun tí a pè ní oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn tí a ń tọwọ́ ìlànà ìyípadà èròjà apilẹ̀ àbùdá darí ní ti gidi ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n a tún lè lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ yìí fún àwọn ète búburú.
Fún àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí a ṣèèṣì tàbí kí a mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn apilẹ̀ àbùdá tí ó wá láti inú fáírọ́ọ̀sì àrùn Ebola sínú fáírọ́ọ̀sì kan, bíi kòkòrò àrùn tí ń fa gágá tàbí olóde. Lẹ́yìn náà, fáírọ́ọ̀sì gbẹ̀mígbẹ̀mí yẹn ni a lè tàn kálẹ̀ nípasẹ̀ ikọ́ tàbí sísín. Dókítà Karl Johnson, ẹni tí ó fi gbogbo ọjọ́ ayé ṣèwádìí nípa àwọn fáírọ́ọ̀sì bíi Machupo àti Ebola, sọ pé, ó lè máà pẹ́ mọ́ tí “eléròkerò èyíkéyìí tí ó ní àwọn ohun èlò iṣẹ́ tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún dọ́là bíi mélòó kan, tí ó sì ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́lẹ́ẹ̀jì nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nipa ohun alààyè yóò fi ṣèmújáde àwọn ìdun tí yóò mú kí fáírọ́ọ̀sì Ebola fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí aláìlèṣèpalára mọ́.” Àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè gbà pẹ̀lú àníyàn tí ó ṣe.
Ojútùú Rẹ̀
Yíyanjú ìṣòro àwọn àrùn eléèràn kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn ṣíṣe àwọn egbòogi tuntun. Ó kan yíyanjú àwọn ìṣòro àrùn tí ó tan mọ́ ipò òṣì, ogun, àwọn olùwá-ibi-ìsádi, ìlòkulò oògùn líle, àkúnya àwọn ìlú ńlá, ìgbésí ayé tí kò sunwọ̀n, ìbàyíkájẹ́, àti pípa àyíká run. Má tan ara rẹ jẹ. Ǹjẹ́ o lérò pé ó lè ṣeé ṣe kí ẹ̀dá ènìyàn yanjú àwọn ìṣòro dídíjú wọ̀nyí?
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.” Nígbà náà, ta ni ó yẹ kí a wá gbẹ́kẹ̀ lé? Ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ náà ń bá a lọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní Ọlọrun Jakobu fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ìrètí ẹni tí ń bẹ lọ́dọ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ̀: Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.” Jehofa, Ẹlẹ́dàá aráyé, nìkan ni ó lè yanjú àwọn ẹtì tí ìran ènìyàn dojú kọ.—Orin Dafidi 146:3-6.
Nígbà tí Ọ̀rọ̀ onímìísí Jehofa, Bibeli, ń ṣàkọsílẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ pípabambarì tí Jesu sọ nípa “àmì . . . ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan,” ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọ̀ràn ìlera ṣíṣeni ní kàyéfì tí ń pọ́n ìran wa lójú. Jesu wí pé: ‘Awọn àjàkálẹ̀ àrùn yóò sì wà . . . lati ibi kan dé ibòmíràn.’—Matteu 24:3-8; Luku 21:10, 11.
Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli tún tọ́ka sí àkókò kan lọ́jọ́ iwájú lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọrun nígbà tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.” (Isaiah 33:24; Matteu 6:9, 10) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa ní ìdí tí ó lágbára láti gbà gbọ́ pé, láìpẹ́, aráyé onígbọràn yóò ní ìdásílẹ̀ títí lọ, tí kì í ṣe kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí tí ń yọ ẹ̀dá ènìyàn lẹ́nu nìkan ṣùgbọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tí ń dá kún àrùn náà. Àwọn Kristian tòótọ́ mọyì àwọn ipá tí àwọn àwùjọ elétò ìlera ń sà nínú ogun líle tí a ń bá àwọn kòkòrò àrùn jà. Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ojútùú pípẹ́ títí sí àrùn àti ikú wà lọ́wọ́ Ọlọrun, ẹni “tí ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn.”—Orin Dafidi 103:1-3, NW; Ìṣípayá 21:1-5; 22:1, 2.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bibeli ṣèlérí àkókò kan, tí kì yóò sí ẹni tí yóò wí pé, “Òótù ń pa mí”