ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Olè Jíjà ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Britain
  • Ìṣẹ́yún Ń Pọ̀ Sí I ní Kánádà
  • Àwọn Ọmọ Ọwọ́ Tí Ó Ní Àrùn AIDS
  • Àwọn Obìnrin Oníwà Ipá Ń Pọ̀ Sí I
  • Àwọn Àlùfáà àti Ìgbeyàwó
  • “Ayọ́kẹ́lẹ́pani”
  • Ìṣekúpara-Ẹni Láti Orí Afárá
  • Ikú Ọkọ̀
  • Àwọn Ọmọdé Tí Ń Mu Sìgá
  • Ìtọ́jú Ẹnu fún Àwọn Arúgbó
  • Ènìyàn Ha Lè Ra Àìlèkú Bí?
  • Ìtọ́jú Ànímọ́ Àjogúnbá Lábẹ́ Àríwísí
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
Jí!—1996
g96 2/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Olè Jíjà ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Britain

Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London ròyìn pé: “Àwọn ènìyàn kò ka àwọn ilé ìjọsìn sí ibi mímọ́ mọ́.” Wọ́n ń jí àwọn ọ̀pá àbẹ́là, àga bíṣọ́ọ̀bù, tábìlì ìkabíbélì, ṣáágo ìgbà sànmánì agbedeméjì, àti àwọn ládugbó omi mímọ́ ìgbàanì nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì England, wọ́n sì ń tà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀ṣọ́ ọgbà. Òwò tí kò bófin mu yìí wà káàkiri orílẹ̀-èdè, àwọn nǹkan àtọwọ́dá pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ni àwọn ènìyàn sì ń bèèrè fún láti rà. Fèrèsé kan, tí a fi dígí tí a kùn láwọ̀ ṣe, tí wọ́n jí, fara hàn ní ilé oúnjẹ kan ní Tokyo. Ohun tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń pàdánù lọ́dọọdún fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí mílíọ̀nù méje dọ́là. Nísinsìnyí, wọ́n ti ṣe àwọn ohun ìhùmọ̀ ẹ̀rọ ìṣọ́ǹkan tí ó lágbára, wọ́n sì ti da àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ sẹ́nu iṣẹ́ láti máa ṣọ́ àwọn àyíká ṣọ́ọ̀ṣì náà.

Ìṣẹ́yún Ń Pọ̀ Sí I ní Kánádà

Iye oyún tí wọ́n ṣẹ́ ní Kánádà ní ọdún 1993 lọ sókè fíofío sí 104,403, èyí sì fi ìpín 2.3 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju tí ọdún tí ó kọjá lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star ti sọ, “ìyẹn tó ìpín 26.9 ìṣẹ́yún fún gbogbo ọgọ́rùn-ún ọmọ tí a bí sáyé.” Kí ló dé tí ó fi lọ sókè? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ pé pípọ̀ tí àwọn ilé ìṣẹ́yún aládàáni ń pọ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè náà ló fà á, àwọn òṣìṣẹ́ Ìfètòsọ́mọbíbí ti Orílẹ̀-Èdè Kánádà tọ́ka sí àìfararọ ipò ọrọ̀ ajé gẹ́gẹ́ bíi “lájorí ìdí tí a fi fúnni tí àwọn ènìyàn fi ń ṣẹ́yún.” Anna Desilets, tí ó jẹ́ alága olùdarí Ẹgbẹ́ Ẹ̀mí Ló Jù, ẹgbẹ́ kan tí ń gbèjà ìwàláàyè, nímọ̀lára pé “líléṣẹ́yún tí àwọn ènìyàn ní fàlàlà ń mú kí àwọn ènìyàn máa lò ó gẹ́gẹ́ bí oògùn ìfètòsọ́mọbíbí, tí ìjọba ń sanwó rẹ̀.”

Àwọn Ọmọ Ọwọ́ Tí Ó Ní Àrùn AIDS

Ìwé agbéròyìnjáde El Universal ti Caracas ròyìn pé iye àwọn ọmọ ọwọ́ ilẹ̀ Venezuela tí ń ní àrùn AIDS ń pọ̀ sí i lọ́nà tí ó lé kenkà. Ògbógi kan ṣàlàyé pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nǹkan bí ọmọdé méjì sí mẹ́fà ni à ń ròyìn pé wọ́n ní àrùn AIDS lọ́dọọdún, àmọ́ nísinsìnyí, a ní ọ̀ràn àrùn náà tí ó tó nǹkan bí méjì sí mẹ́fà lọ́sẹ̀.” Ìpíndọ́gba àwọn obìnrin tí wọ́n ní àrùn náà, tí wọn yóò sì wá kó kòkòrò àrùn náà ran àwọn ọmọ wọn, ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́. Ìròyìn ìwé agbéròyìnjáde náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé ìṣirò tí Ẹ̀ka Ìlera ṣe wulẹ̀ jẹ́ ìwọ̀nba ṣínkínní ọ̀ràn àrùn AIDS.”

Àwọn Obìnrin Oníwà Ipá Ń Pọ̀ Sí I

Ògbógi nípa ìwà ọ̀daràn ní Yunifásítì Ottawa, Tom Gabor, sọ pé: “Àwọn obìnrin sábà máa ń lọ́wọ́ nínú ìwà ipá lọ́pọ̀ ìgbà ju bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ.” Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail ròyìn pé: “Ohun tí ó ń wọ́pọ̀ síwájú sí i ni pé àwọn obìnrin tí ń mú ipò iwájú ní ń hu ìwà ipá náà, kì í ṣe àwọn tí wọ́n gbà kí a darí àwọn. Àwọn wọ̀nyí kì í ṣe irin iṣẹ́ ọwọ́ àwọn aṣebi tí ń ṣe bí ọkùnrin.” Àwọn ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí a fipá ṣe, tí a fi kan àwọn àgbàlagbà obìnrin, ti lọ sókè láti orí 6,370 ní ọdún 1983 sí 14,706 ní ọdún 1993. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọkùnrin ni ó ṣì ń hu ọ̀pọ̀ jù lọ ìwà ọ̀daràn tí a fipá ṣe síbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Globe ti wí, “ní ọdún 1993, ìpín 88.6 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà, àti ìpín 76.3 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èwe tí a fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí a fipá ṣe kàn jẹ́ ọkùnrin.”

Àwọn Àlùfáà àti Ìgbeyàwó

Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Australia náà, The Sydney Morning Herald, ròyìn pé, iye tí ń pọ̀ sí i lára àwọn sàràkí sàràkí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló ń jà sí pé “bí wọ́n bá fòpin sí òfin málàáya, kò ní jẹ́ kí iye àwọn àlùfáà máa joro mọ́.” Wọ́n fojú wo òfin málàáya gẹ́gẹ́ bíi lájorí ohun tí kò jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ inú iṣẹ́ àlùfáà. Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde Herald ń tẹnu mọ́ ìṣòro náà, ó sọ àwọn ìṣirò tí ó lè mú kí ènìyàn tètè lóye ọ̀ràn náà. Ẹ̀ka tí ó tóbi jù lọ tí ń dá àwọn àlùfáà lẹ́kọ̀ọ́ ní New South Wales ní góńgó ìpíndọ́gba 60 ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lọ́dún láti ọdún 1955 sí ọdún 1965. Ṣùgbọ́n iye àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí ó wà láàárín ọdún 1988 sí ọdún 1994 kò ju kìkì mẹ́sàn-án lọ lọ́dún. Adelé olùdarí ilé ẹ̀kọ́ gíga mìíràn tí a ti ń dá àwọn àlùfáà lẹ́kọ̀ọ́ ní Sydney sọ pé, ní èrò ti òun, gbígba àwọn àlùfáà láyè láti gbéyàwó lè jẹ́ ojútùú “pàjáwìrì,” àmọ́ kì í ṣe ojútùú tí ó wà pẹ́ títí fún àìní àwọn àlùfáà tí ó pọ̀ tó lọ́nà tí ó gọntiọ ní Australia.

“Ayọ́kẹ́lẹ́pani”

Ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ròyìn pé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń sakun láti kó dọ́là mílíọ̀nù 75 jọ láti bẹ̀rẹ̀ mímú àwọn ọta inú ilẹ̀ tí a fojú díwọ̀n pé ó tó mílíọ̀nù 110 kúrò nílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè 64. Ohun tí ń náni láti ṣe ọta inú ilẹ̀ kan tí kò tóbi ju páálí sìgá kan lọ, tí a fi ń kojú àwọn ọmọ ológun (AP) kò ju nǹkan bíi dọ́là mẹ́ta lọ. Àmọ́ láti lè wá irú ọta inú ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ rí, kí á sì mú un kúrò nínú ilẹ̀ yóò náni ní nǹkan bí 300 dọ́là sí 1,000 dọ́là. Ìṣòro mìíràn tún ń ṣèdíwọ́ fún mímú ọta inú ilẹ̀ náà kúrò nílẹ̀. Agbẹnusọ kan fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Lọ́dọọdún ni wọ́n ń kẹ́ mílíọ̀nù méjì ọta inú ilẹ̀ tí a fi ń kojú àwọn ọmọ ológun sílẹ̀ ní àfikún sí ohun tí ó lé ní 100 mílíọ̀nù tí ó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀.” Àwọn ògbógi gbà pé yóò gbà tó ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún láti palẹ̀ ohun tí ọ̀gágun ilẹ̀ Cambodia kan ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ayọ́kẹ́lẹ́pani tí kì í ṣákìí” mọ́ kúrò ní ilẹ̀ ayé.

Ìṣekúpara-Ẹni Láti Orí Afárá

Ohun tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àwọn ènìyàn ló ti ṣekú pa ara wọn nípa fífò láti orí Afárá Golden Gate lílókìkí ní San Francisco láti ìgbà tí wọ́n ti ṣí i ní 1937. Ògbógi kan nínú ọ̀ràn ìṣekúpara-ẹni, Richard Seiden, sọ pé: “Ṣíṣe bí ẹni akọ ló máa ń fa pípa ara ẹni nípa fífò láti orí Afárá Golden Gate, ó sì máa ń dan ènìyàn. Ó máa ń gbádùn mọ́ni níbẹ̀. Àwọn èrò asán kan wà tí ó máa ń bá a rìn ní pàtàkì.” Díẹ̀ lára àwọn tí ń fò náà ló ń là á já láti sọ ìtàn náà, èyí kò sì yani lẹ́nu níwọ̀n bí wọ́n ti ń já lumi ní nǹkan bí ìyára 120 kìlómítà ní wákàtí kan, tí wọ́n sì máa ń ba àwọn ìfun wọn jẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà. Ìwádìí tí a ṣe lórí àwọn 500 ènìyàn tí a ti rọ̀ láti má ṣe fò fi hàn pé ohun tí kò dín sí ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún ní ń pa ara wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Ikú Ọkọ̀

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Clarín ti Argentina ṣe sọ, pẹ̀lú ikú ìpín 26 nínú gbogbo 100,000 àwọn olùgbé, Argentina ni ó léwájú nísinsìnyí lágbàáyé nínú iye ènìyàn tí ikú ọkọ̀ ń pa lóòjọ́. Ní ọdún 1993, iye ènìyàn tí ikú bẹ́ẹ̀ ń pa ní orílẹ̀-èdè náà jẹ́ 8,116. Iye náà lọ sókè sí 9,120 ní ọdún 1994. Àmọ́ ní oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 1995, àwọn ènìyàn tí ikú ọkọ̀ pa ti ju 5,000 lọ. Ní ọdún 1994, ohun tí ó tó nǹkan bí ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ó kàgbákò náà jẹ́ àwọn tí ń fẹsẹ̀ rìn. Ní kìkì agbègbè Buenos Aires nìkan, iye àwọn tí ikú ọkọ̀ pa fi ìpín 79 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè. Ìpín tí ó pọ̀ jù lára àwọn jàm̀bá náà jẹ́ nítorí pé àwọn awakọ̀ kò fojú díwọ̀n ohun tí ó yẹ kí wọ́n ṣe dáradára, nígbà tí wọ́n bá ń ya ọkọ̀ míràn sílẹ̀.

Àwọn Ọmọdé Tí Ń Mu Sìgá

Ìròyìn ọdún 1993 sí 1994 kan fi hàn pé iye àwọn ọmọ tí ń mu sìgá ní Britain ń pọ̀ sí i. Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún 11 sí 15 tí ń mu sìgá ti lọ sókè láti orí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún sí ìpín 12 nínú ọgọ́rùn-ún. Ìwé agbéròyìnjáde Independent sọ pé, ìlọsókè yìí jẹ́ ìlọ́po méjì ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ìjọba retí fún ọdún 1994. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbàlagbà tí ń mu sìgá ti dín kù, ìpín 29 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin ilẹ̀ Britain àti ìpín 27 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ló ṣì ń mu sìgá síbẹ̀. Ìròyìn náà parí rẹ̀ pé: “Kí ìṣarasíhùwà àwọn ọ̀dọ́ tó lè yí padà lọ́nà tí ó jọjú, iye àwọn àgbàlagbà tí ń mu sìgá gbọ́dọ̀ ti dín kù sí i.”

Ìtọ́jú Ẹnu fún Àwọn Arúgbó

Ìwé agbéròyìnjáde Asahi Evening News sọ pé: “Ìtọ́jú ẹnu lè di ọ̀ràn ìyè àti ikú fún àwọn arúgbó.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ilẹ̀ Japan parí ọ̀rọ̀ pé, “àwọn arúgbó lè dín ewu ọ̀ràn òtútù àyà kù kìkì nípa fífọ eyín wọ́n lásán.” Nínú ìwádìí kan tí a ṣe lórí àwọn arúgbó 46, àwọn nọ́ọ̀sì ń fọ eyín mọ́ ṣáká lójoojúmọ́ fún ìpín kan tí ó ní ènìyàn 21 nínú. Wọ́n tún ń rí àyẹ̀wò ìtọ́jú ẹnu gbà ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀. Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, wọ́n rí i pé iye ọjọ́ tí àwọn 21 náà fi ní ibà dín ọjọ́ mẹ́wàá sí ti àwọn 25 tí wọn kò ṣe bí àwọn yòókù ti ń ṣe. Wọ́n sọ pé àìsí àwọn kòkòrò àrùn inú ẹnu ló fa ìlera wọn. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, ìwádìí kan tí a ṣe tẹ́lẹ̀ parí ọ̀rọ̀ pé, “tí ènìyàn bá ṣèèṣì fa itọ́ tàbí oúnjẹ sórí, tí ó sì lọ sínú ẹ̀dọ̀, ó máa ń fa òtútù àyà lọ́pọ̀ ìgbà.”

Ènìyàn Ha Lè Ra Àìlèkú Bí?

Ìwé agbéròyìnjáde The Register-Guard ti Eugene, Oregon, U.S.A., sọ pé: “Àìlèkú Lè Jẹ́ Tìrẹ fún Dọ́là 35.” Onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè tín-íntìn-ìntín, James Bicknell, sọ pé òun yóò tọ́jú DNA rẹ pamọ́ kí ó lè jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwé náà ṣe sọ ọ́, “ní ọ̀rúndún tí ń bọ̀, ọmọ tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kan lè lo ìṣọfúnni ohun alààyè tí ó wà nínú DNA náà láti ṣe irú rẹ gan-an.” Dokita Bicknell ń ta àtòjọ agolo DNA kan tí ó ní àwọ̀n tí a ti pa kòkòrò ara rẹ̀ méjì àti gologóló kékeré kan tí omi wà nínú rẹ̀. Ó sọ pé: “Ìwọ yóò fi àwọ̀n náà ha inú ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ, ki àwọ̀n náà bọ inú omi náà, kí o sì fi ránṣẹ́ sí mi.” Òun lẹ́yìn náà yóò yọ DNA tí ó wà lára sẹ́ẹ̀lì tí ó há mọ́ ara àwọ̀n náà jáde, yóò sì fi DNA náà sórí ìwé tí ó lu fótífótí kan. Lẹ́yìn náà ni yóò fi ìwé náà pamọ́ sí inú àpótí kékeré kan tí a fi ayọ́ ṣe, tí a tẹ orúkọ rẹ sára rẹ̀ fún ọ láti gbé e sójútáyé bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde Guard sọ pé: “Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ènìyàn ń fi eérú òkú pamọ́, ìdì irun àti èékánná ọwọ́. Àpótí DNA jẹ́ ohun tí àwọn ọmọ ọmọ lè jogún.”

Ìtọ́jú Ànímọ́ Àjogúnbá Lábẹ́ Àríwísí

Ohun tí àwọn ènìyàn retí ní ọdún mẹ́fà sẹ́yìn nígbà tí fífi àpilẹ̀ àbùdá ṣètọ́jú àwọn ènìyàn kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ga gan-an ni. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ retí pé, bí àkókò ti ń lọ, àwọn yóò wo àwọn àrùn apilẹ̀ àbùdá tí a bí mọ́ni nípa gígún aláìsàn ní abẹ́rẹ́ àwọn apilẹ̀ àbùdá tí ń ṣàtúnṣe. Wọ́n tún retí láti gún abẹ́rẹ́ ohun èèlò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú apilẹ̀ àbùdá tí ó lè mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ń pani lára, irú bíi sẹ́ẹ̀lì àrùn jẹjẹrẹ, pa ara wọn run. Síbẹ̀, lẹ́yìn gbogbo ìwádìí aláápọn tí wọ́n ṣe, ìtọ́jú náà ti ń bọ̀ wá sábẹ́ àríwísí. Ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune sọ pé: “Nínú gbogbo kòókòó làálàá wọn, a kò tí ì tẹ ìròyìn kankan jáde nípa aláìsàn kan tí wọ́n fi ìtọ́jú apilẹ̀ àbùdá ràn lọ́wọ́.” Àwọn òléwájú onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń bẹ̀rù pé ìwádìí èrè tí wọ́n lè rí jẹ nípa ti ìṣòwò àti ti ara wọn ló fà á tí wọ́n fi ń ṣe ìwádìí náà láìfara balẹ̀, kàkà kí ó jẹ́ nítorí àníyàn wọn fún àwọn aláìsàn. Ìṣòro kan ni pé ìṣètò tí ń gbógun ti àwọn kòkòrò àrùn inú ara lè kọlu àwọn sẹ́ẹ̀lì tí a bá tọ́jú nípa lílo apilẹ̀ àbùdá, kí ó sì pa wọn run, nítorí pé ó ń rí wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó jẹ́ àjèjì sí ara.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́